Gẹnẹsisi 45:1-28

Lesson 13 - Elementary

Memory Verse
“Ọlọrun ifẹ ati alafia yio wà pẹlu nyin” (2 Kọrinti 13:11)
Notes

Awọn arakunrin Josẹfu ti kaanu fun gbogbo iwa buburu wọn. Nisisiyii wọn fẹran baba wọn, wọn ko fẹ mú Bẹnjamini kuro lọdọ rè̩ ki o ma ba banujẹ. Josẹfu ti sọ fun awọn arakunrin rè̩ pe oun ni Josẹfu. Ẹru ba wọn nitori wọn ro pe yoo jẹ wọn niya nitori wọn ta a, ṣugbọn oun ko ṣe bẹẹ, o sọ fun wọn pe Ọlọrun ni O rán oun ṣaaju lati ràn wọn lọwọ. Ọlọrun mọ nipa ohunkohun ti o le ba wa, bi a ba fẹran Rè̩ Oun yoo ràn wá lọwọ.

Josẹfu ranṣẹ lọ pe baba rè̩ ki o ba le tọju rè̩ ati awọn arakunrin rè̩ ni akoko iyàn. O fẹnu ko awọn arakunrin rè̩ ni ẹnu, o si fun wọn ni agbado ati è̩bun pupọ. Nigba ti awọn arakunrin Josẹfu sọ fun baba wọn pe Josẹfu wa ni aaye sibẹ ati pe oun ni o n ta agbado, ẹnu yà á gidigidi. Wọn sọ fun un pe Josẹfu fẹ ki o tọ oun wá. Inu Jakọbu dùn lati gbọ pe ọmọ rè̩ wa laaye sibẹ. Ọlọrun sọ fun un pe ki o má ṣe bẹru lati lọ. Ọlọrun sọ pe Oun yoo boju to Jakọbu. O di ẹrù rè̩, o si mu ọna ajo rè̩ pọn lati lọ bá Josẹfu.

Inu ọba dun nigba ti a sọ fun un pe baba Josẹfu dé nitori o mọ pe eyi yoo mú inu Josẹfu dùn pẹlu. Ọba fẹ ki Josẹfu layọ nitori o ti ran ọba lọwọ. Awọn arakunrin Josẹfu ti ṣe ohun ti ko tọ lati ta Josẹfu, ṣugbọn dajudaju wọn ti gbadura si Ọlọrun fun idariji, O si ti dari ji wọn. Inu Josẹfu dùn lati ni baba rè̩ ati awọn arakunrin rè̩ lọdọ rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ṣe ti a ta Josẹfu si Egipti? Gẹnẹsisi 45:7

  2. 2 Njẹ Josẹfu dari ji awọn arakunrin rè̩ tọkàntọkàn? Gẹnẹsisi 45:5-8, 14, 15

  3. 3 Ki ni Ọlọrun sọ fun wa nipa idariji Marku 11:25; Luku 6:37

  4. 4 Bawo ni ọkàn Jakọbu ti ri nigba ti o gbọ pe Josẹfu wà laaye sibẹ? Gẹnẹsisi 45:26-28