Luku 10:25-37

Lesson 131 - Senior

Memory Verse
“Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹnikẹji rẹ bi ara rẹ” (Luku 10:27).
Cross References

IIbeere Pataki ti Amofin naa Beere ati Idahun Rẹ

1.A mú ibeere daradara kan wá, Luku 10:25; Matteu 19:16

2.Niwọn bi oun ti jé amofin, a tọka rẹ si Ofin Mose, Luku 10:26

3.Amofin naa sọ ofin pataki meji, Luku 10:27; Matteu 22:37-40; Deuteronomi 6:5; Lefitiku 19:18

4.A yin amofin naa, a si sọ fun un pe ki o pa ofin mó ki o le yẹ, Luku 10:28

IIIbeere Keji ti Amofin naa Beere nipa Ẹni Keji Rẹ

1.O fẹ dá ara rẹ lare, o ni “Tani ẹnikeji mi” Luku 10:29

2.A ja ọkunrin kan lólẹ, wón ṣá a lọgbẹ, wón si fi í silẹ ni àpa ìpatán, Luku 10:30

3.Alufaa kan ti o ri i kọja lọ ni iha keji, Luku 10:31

4.Ọmọ Lefi kan ti o ri i kọja lọ ni iha keji, Luku 10:32

IIIAra Samaria Kan – Idahun si Ibeere Amofin naa

1.Ara Samaria naa ti o ri i ṣaanu fun un, Luku 10:33; Johannu 4:9

2.O ni oju-aanu, eyi si mu ki o ṣe itọju ọkunrin naa ti wón ṣá lọgbẹ, Luku 10:34, 35; Matteu 9:36

3.Ibeere Jesu: Tani. . . .. iṣe ẹnikeji rẹ?” Luku 10:36

4.Idahun rere ti amofin naa dahun ni pe: “Ẹniti o ṣãnu fun u” Luku 10:37

Notes
ALAYE

Agálámàṣà

Amofin kan dide kuro o si n dán Jesu wọ. Eyi fi han pe ki i ṣe ọkàn otitọ ni ọgbẹni yii mú wa lati wa ṣe iwadi nipa iye ainipẹkun, kaka bẹẹ o fẹ lọ ba Jesu fi iga gbága. Amofin yii fẹ dá ara rẹ lare kaka ki o gbọran si Ọrọ Ọlọrun. Ogunlọgọ ni o n ṣe bakan naa lonii, wọn n dá ara wọn lare kaka ki wọn ronupiwada ẹṣẹ wọn ki a ba le dá wọn lare niwaju Ọlọrun. Nigba ti a ba ba wọn sọrọ igbala, awọn eniyan yii a saba maa beere pe, “Ẹsin pupọ ni o wà -- bawo ni mo ṣe le mọ eyi ti o tọna?”

Imọ Ofin

Jesu ṣe suuru pẹlu ọgbẹni amofin ti o tọ Ọ wá lati wadii nipa iye ainipẹkun. Jesu beere lọwọ rẹ pe, “Kili a kọ sinu iwe ofin? bi iwọ ti kà a?’ Bi ọgbẹni yii ti jé amofin, o ni imọ nipa Ofin Mose. O fi imọ ti o ni nipa kókó ti ó wà ninu Ofin hàn nigba ti o ṣe atunwi Ofin nla meji ti “ofin ti awọn woli rọ mọ.” Eyi fi imọ ti o ni nipa bi ifẹ ti ṣe pataki to hàn. Ṣugbọn amofin yii fẹ fi han bi oun ti jẹ ogbogi ninu Ofin to ati bi oun ti n pa iwe ofin mọ lai naani ẹmi Ofin nigba ti o beere pe, “Tani ẹnikeji mi?” Eyi mu ki Jesu ṣe apẹẹrẹ ohun ti itumọ “ki iwọ fẹran ẹnikeji rẹ gẹgẹ bi ara rẹ” jé.

Alufaa

“Ọkunrin kan nti Jerusalẹmu sọkalẹ lọ si Jeriko, o si bọ si ọwó awọn ọlọṣà, ti nwọn gbà a li aṣọ, nwọn ṣá a lọgbẹ, nwọn si fi i silẹ lọ li aipa li apatan. Ni alabapade li alufa kan si sọkalẹ lọ lọna na: nigbati o si ri i, o kọja lọ niha keji.”

Ni abẹ Ofin, ipo giga ni awọn alufaa ní ninu iṣẹ Ọlọrun. Iṣẹ wọn ni lati kó awọn eniyan, lati gbadura fun wọn ati lati rubọ fun wọn. Lai si aniani, ẹni giga bayii ni lati fi apẹẹrẹ iwa rere hàn bi ẹni ti a ti ọwó Ọlọrun pẹ, ki o si fi ifẹ han gẹgẹ bi a ti pa a laṣẹ ninu Ofin. Nigba pupọ ni awọn alufaa kàn n tẹle ilana isin ti Ofin fi lelẹ gẹgẹ bi aṣa lasan ṣá. Dajudaju, alufaa ti o n sọkalẹ lati Jerusalẹmu wá yii ni lati ti pari iṣẹ-isin rẹ nibẹ o si n pada lọ si ile rẹ. Boya o ro pe oun ti ṣe iṣẹ isin ti o yẹ ki oun ṣe fun eniyan ẹlẹgbẹ rẹ gẹgẹ bi ilana Ọlọrun. O ti ṣe ipa ti rẹ tán. Jẹ ki ẹlomiran boju to ọgbẹni yii.

O Fẹ Aanu

Israẹli n pa ọjọ irubọ ati ọjọ aawẹ mó ni akoko Isaiah nigba ti Ọlọrun ké si wọn pe: “Awẹ ti mo ti yàn kó eyi?. . . . . Kì ha ṣe lati fi onjẹ rẹ fun awọn ti ebi npa, ati ki iwọ ki o mu awọn otọṣi ti a ti sode wá si ile rẹ? nigbati iwọ ba ri arinhọho, ki iwọ ki o bọ o, ki iwọ, ki o má si fi ara rẹ pamọ kuro lọdọ ẹran-ara tirẹ” (Isaiah 58:6, 7).

Ewu n bẹ bi isin wa si Ọlọrun ba di aṣa lasan to bẹẹ ti a gbagbe iṣẹ aanu ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe. Gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, a pe wa si iṣẹ ṣiṣe, oju wa si ni lati ṣi silẹ lati fi aanu hàn fun awọn ti o wà ninu aini. Jesu wi pe, “Nitori ebi pa mi, ẹnyin si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin si fun mi li ohun mimu: mo jẹ alejọ, ẹnyin si gbà mi si ile: Mo wà ni ìhoho, ẹnyin si daṣọ bọ mi: mo ṣe aisan, ẹnyin si bojuto mi: mo wà ninu tubu, ẹnyin si tọ mi wá. Nigbana li awọn olõtọ yio da a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li ounjẹ?. . . . . Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi” (Matteu 25:35-40).

Ọmọ Lefi

Bi alufaa ti n kọja lọ lọwọ Lefi kan n gba ọna kan naa sọkalẹ lati Jerusalẹmu lọ si Jeriko. Awọn ọmọ Lefi jẹ oluranlọwọ fun awọn alufaa ninu iṣẹ-isin ni Tẹmpili. Nigba ti ọmọ Lefi yii n kọja lọ ti o si ri ọkunrin ti wón ṣá lọgbẹ yii, oun pẹlu gba ọna odi keji lọ, o fi ọgbẹni yii silẹ ninu irora ikú lai ran an lọwọ ati lai ṣe itọju rẹ rara. Boya oun naa ti ri i pe alufaa, ti i ṣe aṣaaju rẹ ninu iṣẹ Ọlọrun, ti ri ọgbẹni ti wón ṣá lọgbẹ yii ti ko si ṣe nnkan kan fun un, oun pẹlu ko bikita mó. Gẹgẹ bi Onigbagbọ, a ni lati jé apẹẹrẹ igbesi aye iwa-bi-Ọlọrun. Awọn ayé n wo iṣesi wa. Wọn n fi iwa wa diwọn igbagbọ. Paulu kọwe si awọn ara Kọrinti bayii pe, “Ẹnyin ni iwe wa, ti a ti kọ si wa li ọkàn, ti gbogbo enia ti mọ, ti nwọn sì ti kà” (2 Kọrinti 3:2).

Ara Samaria

Ṣugbọn ara Samaria kan, bi o ti nrẹ àjo, o de ibi ti o gbé wà: nigbati o si ri i, ãnu ṣe e,” Ifẹ ti o yẹ ki awọn Ju ni nipa imọ ti wọn ni nipasẹ Ofin ti sọnu nitori wọn kuna lati tẹle ọna ti Ọlọrun là silẹ fun wọn tọkan tọkan. Jesu wá si ọdọ awọn Ju, ara Rẹ, ṣugbọn wọn ko gba A. Ṣugbọn nihin, a le ri ara Samaria kan, orilẹ-ede ẹni ti awọn Ju kẹgan, ti o n fi ifẹ ti awọn Ju ko ni hàn. Paulu sọ nipa awọn Keferi ti ko ni Ofin ṣugbọn nipa ẹda ti wọn n ṣe ohun ti o wà ninu Ofin. Abuku nla kan awọn Ju lati ri i pe ara Samaria ni ifẹ ti awọn alufaa wọn ati ọmọ Lefi ko ni. Ko ha yẹ ki ẹkọ yii mu ki awọn Onigbagbọ ṣọra gidigidi ki awọn ti ayé ma ta wón yọ nipa ṣiṣe aanu fun awọn alaini? Ara Samaria naa ran ọkunrin yii lọwọ, ki i ṣe ki eniyan le ri i, ṣugbọn aanu ṣe e lati inu ọkàn rẹ wá. O di ọgbé rẹ. O gbe e ka ori ẹranko oun tikara rẹ, oun si n fi ẹsẹ rin. O sùn si ile ero ni alẹ ọjọ yii, o si n tọju ọkunrin ti wón ṣá lọgbẹ yii; ko fi mọ bẹẹ, o ṣeto fun itọju ọkunrin naa titi yoo fi sàn patapata. Eyi jẹ apẹẹrẹ ifẹ si ọmọnikeji ẹni.

Idahun

Amofin naa ri idahun si ibeere rẹ pe “Tani ha si li ẹnikeji mi?” gbà. Ki i ṣe aladugbo wa nikan, ṣugbọn ẹni ti awọn eniyan korira, ti wọn ṣá tì, ẹlẹṣẹ, ani ẹnikẹni ti o ba wa ninu aini. “Bi ebi ba npa ọta rẹ, fun u li onjẹ; bi ongbẹ ba si gbẹ ẹ, fun u li ohun mimu. Nitoriti iwọ o kó ẹnyin iná jọ si ori rẹ, OLUWA yio san fun ọ” (Owe 25:21, 22). Ẹkọ ti Jesu kó ọgbẹni amofin naa pe, “Lọ, ki iwọ ki o si ṣe bẹẹ gẹgẹ” fi han fun un iru aini ifẹ Ọlọrun ti o n bẹ ninu ọkan oun paapaa gẹgẹ bi a ti dahun ibeere rẹ pe, “Kili emi o ṣe ki emi ki o le jogún iyẹ ainipẹkun?”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ibeere meji ti amofin yii beere lọwọ Jesu?
  2. Ki ni idahun ti Jesu fun un?
  3. Bawo ni amofin naa ṣe fi imọ ti ó ní nipa Ofin hàn?
  4. Ki ni iṣẹ awọn alufaa? Ki ni ti awọn ọmọ Lefi?
  5. Ta ni awọn ara Samaria i ṣe?
  6. Awọn ara Samaria miiran wo ni a darukọ ninu Majẹmu Titun?
  7. Ki ni ikuna awọn Ju ti ẹkọ yii fi hàn?
  8. Ki ni o ro pe o mu ki Jesu sọrọ awọn alufaa ati ọmọ Lefi lọna bayii?
  9. Ẹlomiran wo ni o beere pe, “Kili ki emi ki o ṣe ki emi ki o le jogún iye ainipẹkun” lẹyin ọgbẹni amofin yii?
  10. Ki ni ẹkọ ti Jesu kó amofin yii nikẹyin?