Lesson 132 - Senior
Memory Verse
“Ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ẹmi nyin ohun ti ẹ ó jẹ, ati fun ara nyin ohun ti ẹ o fi bora. Ẹmi kọ ha jù onjẹ lọ? tabi ara ni kọ jù aṣọ lọ?” (Matteu 6:25).Cross References
IKristi ninu Ile Marta
1.Marta fi itara lati ṣe alejo hàn bi Jesu ti wọ ileto kekere yii, Luku 10:38; 2 Awọn Ọba 4:10; Matteu 27:55; Romu 12:13; 16:12; 1 Timoteu 3:2; 5:10; Heberu 13:2; 1 Peteru 4:9
2.Marta ni arabinrin kan, Maria, ti o jokoo lẹsẹ Jesu ti o si n gbó ọrọ Rẹ, Luku 10:39; Owe 20:12; Luku 8:40; Iṣe Awọn Apọsteli 2:41; 17:11
IIIkanra ati Aniyan
1.Marta kun fun ọpọ iṣẹ-ṣiṣe o si fi ẹjọ Maria sun Oluwa pe o fi oun nikan silẹ lati maa gbokegbodo, Luku 10:40; Orin Dafidi 142:2; Matteu 7:4; Johannu 6:43; 1 Kọrinti 10:10; Filippi 2:3
2.Jesu bá Marta wí nitori idaamu ọkàn rẹ, Luku 10:41; 12:29; Matteu 13:22; Filippi 4:6; 1 Peteru 5:7
3.Jesu wi pe: “Maria si ti yàn ipa rere na, ti a kọ le gbà lọwọ rẹ, Luku 10:42; Rutu 1:16; Heberu 11:25; 2 Kọrinti 4:18
Notes
ALAYEJesu wọ inu ilu kekere ti Bẹtani ti ó jé nnkan bi mile meji si Jerusalẹmu. Arabinrin meji, Marta ati Maria, ati arakunrin wọn Lasaru, n gbé ilu yii. Marta, ti i ṣe ẹgbọn wọn ati olórí ile, a maa gba Jesu ni alejo si ile wọn. Gẹgẹ bi olórí ile, Marta ri i pe o yẹ ki wọn ṣe itọju Jesu, ki wọn gbó ounjẹ fun Un lati jẹ.
Ohun ti o gba ọkàn Maria kan ni ifẹ lati gbó oore-ọfẹ ti o ti ẹnu Olukọni jade. Boya Marta n gbokegbodo lati ṣe ounjẹ ti o gbadun. O n ṣe “lãlã nitori ohun pipọ.” Boya bi o ba ṣe ounjẹ ti o mọ niwọn, oun pẹlu i ba ni àyẹ lati gbọrọ Jesu. Lọrọ kan, nnkan kọ rọgbọ ni ile-idana mó, boya nnkan ti o n dín fẹ jona, boya omi fẹrẹ tán ninu koroba, tabi o fẹ ki ẹni kan lọ ba oun ra nnkan si i lọja. Marta ri i pe ọwọ oun nikan kọ ká iṣẹ naa mó. O n fé iranwọ. Maria ti fi gbogbo rẹ silẹ fun oun nikan lati ṣe. Dajudaju, ko yẹ ki o jẹ oun nikan ni a fi iṣẹ naa silẹ fun nigba ti Maria lọ jokoo lẹsẹ Jesu lati maa gbọrọ Rẹ. Iru ero bawọnni ti le maa sọ si Marta lọkan. Ọkàn rẹ daru o si daamu. O pinnu lati sọ fun Jesu, nitori olootọ ati Ẹni mimọ ni Oun i ṣe, yoo si ṣe ohun ti o tó.
Ibawi Jesu
Jesu ri i pe ounjẹ ṣiṣe ti gbọkan Marta kan. Ko si ohun ti o buru lati gbó ounjẹ, ṣugbọn Marta ko fi ohun kin-in-ni si ipo kin-in-ni. “Ẹ tẹte mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin” (Matteu 6:33). Ohun kan ti o ṣe danindanin, ti o jẹ koṣe e-ma-ni, oun ni ki a fi manna ọrun bó ọkàn. Jesu wi pe, “Marta, Marta, iwọ nṣe aniyan ati lãlã nitori ohun pipọ: ṣugbọn ohun kan li a kọ le ṣe alaini. Maria si ti yàn ipa rere na, ti a kọ le gbà lọwọ rẹ” (Luku 10:41, 42).
Ọpọlọpọ lode oni ni ohun ti ayé, ati awọn ohun igba isisiyi ti kọ ni pẹ ṣegbe ti gbà lọkan. Bawo ni yoo ti dara to lati ṣe abojuto ti o tayọ eyi fun ọkàn ti yoo wà titi lae!
Alejo Ṣiṣe
Ẹkọ gidi ni yii nipa alejo ṣiṣe. Laaarin awọn Onigbagbọ, iwọ yoo ri awọn wọnni ti wọn ṣetan lati gba awọn eniyan Ọlọrun ni alejo si ile wọn. Awọn miiran ko layẹ fun un. O le ya wa lẹnu pe boya ni iru wọn le ráyẹ fun Jesu bi O ba wá si ilu. Ọkan ninu awọn iwa ti o yẹ ki biṣọpu ni ni pe ki o jé “olufẹ alejo ṣiṣe” (Titu 1:8).
Anfaani nla ni Marta ni lati ṣe Jesu lalejo lọjọ naa. Ọrọ Mimọ sọ fun ni pe, “Ẹ máṣe gbagbé lati mã ṣe alejọ; nitoripe nipa bẹẹ li awọn ẹlomiran ṣe awọn angẹli li alejọ laimọ” (Heberu 13:2). Ẹni ti o ga ju awọn angẹli ni o wà ninu ile Marta, Ẹni ti o dá ohun gbogbo. Ẹleda Ọrun ati ayé, Ọmọ mimó Ọlọrun, ni Marta gbà ni Alejọ, O ni ẹtọ si ohun rere gbogbo ti ọwó Marta le pese fun Un. Ṣugbọn ohun ti ara ti gba Marta lọkan to bẹẹ ti ko fi naani ẹmi ara rẹ. A gbagbọ pe bi o ba pa iṣẹ rẹ tì diẹ ki o si jokoo lẹsẹ Jesu fun iwọn igba diẹ lati gbọrọ Rẹ, ohun gbogbo i ba lọ deedee ni ile-idana. Lai si aniani, ọkàn rẹ yoo maa kọrin iyin si Ọlọrun dipo kikanra ti o n kanra ti o si n kùn. Nigba pupọ ni a ri i pe “ọrọ wuyẹwuyẹ diẹ pẹlu Jesu yoo sọ ohun gbogbo dẹrọ -- patapata.”
Maria Olufọkansin
Ọna rere ti Maria yàn yatọ si igba ti a n sọ pe ohun kan dara ati pe omiran burú. Ṣugbọn ọna ti o dara jù ninu ọna meji ti a le fi sin Ọlọrun ni o yàn. Ohun ti ẹmi ni oun yàn. Ọkàn tutu ati ọkàn itẹlọrun rẹ pẹlu ifọkansin rẹ yatọ si igbokegbodo Marta ti ọkàn rẹ poruuru. Nigba ti awọn Marta bá wà ni mimó patapata fun Ọlọrun, ati awọn Maria ati awọn Marta ni yoo wulo fun Ijọ Ọlọrun.
Maria jẹ olufọkansin tootọ. O jokoo lẹsẹ Jesu bi akẹkọọ. O fẹ ni ọgbón ọrun. O mu amutẹrun lati inu orisun Omi Iye, “Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo: nitori nwọn ó yo” (Matteu 5:6). Oun ti yan ipa ti o dara ju, ipa rere ti a ko le gbà lọwọ rẹ. Ohun ti o ṣe pataki ju lọ ni ayé yii ni pe ki a jẹ mimó, ẹni bi ti inu Ọlọrun, ki a pese ọkàn wa silẹ lati lẹ gbé ni ayé ti n bọ. Eyi yii ni lati leke ọkàn wa ju iṣẹ ti ara lọ. Marta n ṣe aápọn ati wahala pupọ lati pese ounjẹ ti o n ṣegbe fun ara ti o n ṣegbe; ṣugbọn Maria jokoo o n jẹ ounjẹ ẹmi si ọkàn rẹ ti kọ ni i kú. Igbala ọkàn ni o ni lati jé aniyan kin-in-ni ti o si tobi ju lọ lọkan ẹnikẹni, “Ẹmí sa jù onjẹ lọ, ara si jù aṣọ lọ” (Luku 12:23). Ninu Iṣe Awọn Aposteli 6:1-5 a kà pe awọn Apọsteli yàn lati fi ara fun adura ati iwaasu Ọrọ Ọlọrun, wọn si yan awọn ti o kún fún Ẹmi Mimó ati ọgbón lati maa ṣe ipinfunni ounjẹ. A le sọ pe Marta ni ipe ti o ga ṣugbọn Maria ni ipe ti o ga ju lọ.
Ipe Titi Ayé
Bi a ba ṣe akiyesi igbesi-ayé awọn arabinrin meji yii, a ri i pe Marta n ṣe iṣẹ ipinfunni sibẹ (Johannu 12:2). Ṣugbọn o ti ya ọkàn rẹ sọtọ patapata fun isin Ọlọrun; nigba ti Lasaru arakunrin rẹ kú, oun ni o kó pade Jesu nigba ti o wá si ilu wọn. Igbesi ayé rẹ fi han wa pe Ẹmi Ọlọrun le yí ayé wa pada ki o si mu aniyan ati wahala kuro nibẹ lati mu wa gbájú mó iṣẹ ti Ọlọrun ti yàn fun wa lati ṣe pẹlu ọpẹ ninu ọkàn wa dipo kíkùn. Ọrọ Mimọ Ọlọrun sọ funni pe, “Ẹ máṣe aniyàn ohunkohun” (Filippi 4:6), o si tun wi pe, “Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin, ki ọkàn nyin ki o máṣe kún fun wọbia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan aiye yi, ti ọjọ na yio fi de ba nyin lojiji bi ikẹkun” (Luku 21:34).
“Jesu si fẹran Marta, ati arabinrin rẹ, ati Lasaru” (Johannu 11:5). Nigba ti ara Lasaru ko da awọn arabinrin rẹ ranṣẹ si Jesu pe, “Oluwa, wo o, ara ẹniti iwọ fẹran kọ da” (Johannu 11:3). A sọ pe Lasaru kú ati pe Jesu ji i dide kuro ninu oku. Nitori iṣẹ iyanu yii, ọpọlọpọ ninu awọn Ju ni o gba Jesu gbọ. Nigba ti O si wa si Bẹtani, ni ọjọ mẹfa ṣiwaju Ajọ Irekọja, wọn tọju ounjẹ fun Un. A ri i pe Marta n ṣe iranṣẹ, ṣugbọn a ri i pẹlu pe Maria yan ipa ọna ti o dara. Nigba ti Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin n jẹ ounjẹ adidun ti a ti pese fun wọn, Maria wọle wa pẹlu ororo ikunra nardi, oṣuwọn litra kan, ailabula, olowo iyebiye, o si n fi kun Jesu ni ẹsẹ o si n fi irun ori rẹ nu ẹsẹ Rẹ nu (Johannu 12:3).
Inu bí diẹ ninu awọn ọmọ-ẹyin, wọn si fẹ mọ eredi rẹ ti a ko fi ta ororo ikunra naa ki a si fi owo naa fun awọn alaini. Jesu ba wọn wi, O ni, “Ẹ jọwọ rẹ, o ṣe e silẹ de ọjọ sisinku mi. Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin; ṣugbọn emi li ẹ kọ ni nigbagbogbo” (Johannu 12:7, 8).
A ri pe Maria n tọ ipa ọna rere ti o ti yàn sibẹ, o fi apẹẹrẹ silẹ fun wa anfaani ti o wà ni jijokoo lẹsẹ Jesu lati kẹkọọ lọdọ Rẹ. A ko ni du ọkàn ti o ba n ṣafẹri ounjẹ ẹmi láyẹ ni ẹsẹ Jesu.
Marta n ṣe wahala pupọ lati tọju ounjẹ ni ile-idana; ṣugbọn Maria n jẹ ninu ounjẹ adidun ti Olukọni tikara Rẹ ti pese silẹ. Marta daamu; ọkàn Maria balẹ. Marta n wo wahala ti o de ba a, Maria n wo ohun ti ọrun. Ogunlọgọ lode oni ni o wà bi Marta, wọn n ro nipa ohun isisiyii nikan; awọn diẹ, bi Maria wà ti n wo ohun ti wà niwaju lati mọ ohun ti a ti pese silẹ fun wọn. Awọn tí ohun ti ayé yii nikan gbà lọkan, ko ni ni ireti nigba ti wọn ba doju kọ ayéraye. Ki ni ṣe ti o kọ ni yan ipa rere naa – ani lẹsẹ Jesu – nibi ti wahala ko si?
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni orukọ ilu kekere naa ti Jesu wọ?
- Bawo ni o ti jinna to si Jerusalẹmu?
- Ile awọn ta ni Jesu wọ sí?
- Iṣoro wo ni o bé silẹ laaarin awọn arabinrin meji ninu ile yii?
- Bawo ni Jesu ṣe ba Marta wi?
- Ki ni Jesu sọ nipa Maria?
- Ki ni ohun pataki ninu ayé yii?
- Ki ni ohun rere ti Maria ṣe ti a ko ye sọ nipa rẹ lati igba naa wá?
- Iru ipa wo ni iwọ yàn, eyi ti Marta yàn? tabi eyi ti Maria yàn?