Lesson 133 - Senior
Memory Verse
“Ẹ bẹre, a o si fifun nyin; ẹ wá kiri, ẹnyin o si ri; ẹ kànkun a o si ṣi i silẹ fun nyin” (Luku 11:9).Cross References
IIbeere Ọmọ-ẹyin Kan
1.Igbesi ayé adura ti Jesu paapaa ran awọn ọmọ-ẹyin Rẹ lọwọ lati maa ṣe bẹẹ pẹlu, Luku 11:1; 3:21; 6:12; Matteu 26:36-44
2.Ẹni kan beere pe ki Jesu kó awọn ọmọ-ẹyin Rẹ bi a ti i gbadura gẹgẹ bi Johannu ti kó awọn ọmọ-ẹyin rẹ, Luku 11:1; 5:33; Romu 8:26, 27
IIAdura Oluwa
1.Adura Oluwa kó ni bi Ọlọrun ti jé si gbogbo ọmọ-ẹyin Kristi: “Baba wa,” Luku 11:2; Matteu 6:9; Romu 8:14-16; Isaiah 63:16
2.Adura naa kó awọn ọmọ-ẹyin lati bọwọ fun Ọlọrun, ati lati tẹriba fun aṣẹ ati ifẹ Rẹ, Luku 11:2; Matteu 6:9, 10
3.A fi han gbangba pe o yẹ ki a maa gbẹkẹle Ọlọrun fun aini wa ojoojumọ, Luku 11:3; Matteu 6:11; Ẹksodu 16:15-22; Isaiah 33:16; Johannu 6:27-33
4.A fi han pe o tó ki gbogbo ọmọ-ẹyin maa dariji awọn ẹlomiran, Luku 11:4; Matteu 6:12, 14, 15; Marku 11:25, 26
5.Jesu fi han pe, a n fẹ iranlọwọ Ọlọrun ni igba idanwo, Luku 11:4; 22:46; Matteu 6:13; Johannu 17:15
6.Aṣẹ agbara ati ogo Ọlọrun yoo wà titi lae, Matteu 6:13; Daniẹli 4:34; 1 Timoteu 6:14-16
IIIApẹẹrẹ bi Adura ti n Ṣiṣẹ
1.Ẹni kan wá beere iṣu akara mẹta lọwọ ọrẹ rẹ ni ọganjọ oru, Luku 11:5, 6
2.Ọrẹ rẹ dahun lati inu ile pe: “Má yọ mi lẹnu. . . . . emi ko le dide fifun ọ,” Luku 11:7
3.Ọrẹ naa ko jẹ dide lati fifun un nitori ọrẹ wọn, ṣugbọn nitori awiyannu rẹ, o fi fun un, ọkunrin naa bori, o si ri iranwọ ti o n fé gbà, Luku 11:8; 18:1-8; Gẹnẹsisi 32:26-29
4.Jesu wi pe awọn ti o ba n ṣafẹri ẹbun ẹmi yoo ri gba bẹẹ gẹgẹ bi wọn ba le beere lai sinmi ati lai ṣaarẹ, Luku 11:9, 10; Matteu 6:34
5.Ifẹ inu Baba ni lati fi Ẹmi Mimọ fun awọn ọmọ Rẹ ti wọn beere fun Un, gẹgẹ bi awọn eniyan ti n fi ẹbun rere fun awọn ọmọ wọn, Luku 11:11-13; 24:49; Iṣe Awọn Apọsteli 1:4, 5; 2:4
Notes
ALAYE“Kó wa bi ãti igbadura.” Ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin Jesu, ni o mú ẹbẹ yii wa ki Olukọni Nla ni le kó wọn ni ọna ti o tó lati ni idapọ pẹlu Ọlọrun. Jesu a maa gbadura nigba gbogbo, O si fi ye awọn ọmọ-ẹyin Rẹ bi o ti jẹ ohun pataki fun wọn lati maa gbadura. Awọn arayé ni apapọ ati awọn Onigbagbọ alafẹnujẹ pẹlu, ko mọ bi adura ti ṣe danindanin to. Ẹṣẹ ni o ya eniyan kuro lọdọ Ọlọrun; nitori naa ko rọrun fun awọn ẹni ti ayé ati awọn ọlọgbọn ori lati gbadura. Ẹlẹṣẹ rọ pe oun ni atukọ igbesi ayé oun ati pe oun ko ni i fi iranlọwọ ẹnikẹni ṣe, ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ ti ayidayida ba de ba ọmọ eniyan ti ko si ri ojutu ohun ti o de ba a, oun yoo yi ẹrọ buburu yii pada lẹsẹkẹsẹ.
Ipadabọ sọdọ Ọlọrun
“Nigbati idajọ rẹ mbẹ ni ilẹ, awọn ti mbẹ li aye yio kó ododo” (Isaiah 26:9). Ninu irónú-aanu, Ọlọrun a maa digba fi àyẹ silẹ fun iṣoro lati ba eniyan ki ẹni naa ba le kó ododo. Nigba ti ayé ba lo ẹni kan ni ilokulo, ọkàn rẹ yoo ronu lati pada sile Baba.
Orin kan sọ fun ni pe, “Adura ni kọkọrọ si ilẹkun oore ọfẹ.” Jesu wi pe, “Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là” (Johannu 10:9). Johannu Baptisti ké pé, “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹdẹ” (Matteu 3:2). Ọna kanṣoṣo si Ijọba Ọrun ni ọna ironupiwada, ilẹkun oore-ọfẹ ni ẹnu abawọle, adura nikan ni a fi n ṣi i. Nihin a le ri bi adura ti niye lori to – on ni ọna kanṣoṣo ti eniyan le gbà lati ni idapọ pẹlu Ọlọrun ki a si ri oju rere Rẹ.
Ọna Ibukun
Nigba ti eniyan kan bá di atunbi, ti o si ni iriri yii ni ookan àyà rẹ, ẹmi ti Ọmọ Ọlọrun n fi fun ni yoo maa gbé inu rẹ. Adura ati kika Ọrọ Ọlọrun ni ohun meji ti yoo jé ounjẹ ẹmi fun un. Bi ẹni kan ba fẹ ki iye Ọlọrun maa dagba si i ninu rẹ, oun ko ni fi anfaani meji yii jafara; eyikeyi ti o ba ṣe alainaani ninu mejeeji yii yoo mu ki o joro ninu ẹmi.
Nigba ti Jesu wi pe, “O yẹ ki a mã gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣãrẹ,” O ti ri oorun ẹmi ati ẹṣẹ ti yoo gbilẹ ninu ayé. “Nitori ẹṣẹ yio di pipọ, ifẹ ọpọlọpọ yio di tutù” (Matteu 24:12). Jesu ti mọ tẹlẹ pe ọjọ n bọ ti awọn eniyan kọ ni naani lati ṣiṣẹ gidigidi fun Ọlọrun ati lati maa gbadura kikankikan, pẹlu igbagbọ ati ifararubọ, wọn yoo gba ẹmi ainaani ti yoo si rán wọn lọ si iparun ti o daju bi wọn ko ba kọ ọna naa silẹ. Gbogbo ẹni ti o ba fẹ fara mọ Ọlọrun ni lati maa gbadura, nitori igba ti ẹni kan ko ba gbọwọ adura soke mó, yoo daku ninu ẹmi. Idaku-daji nipa ti ara ki i jẹ ki a ni idagba soke ti ara; ibi ti idaku-daji ti ẹmi n ṣe si idagba soke nipa ti ẹmi ko kere rara.
Adura ni ọna ti oore-ọfẹ gba n ṣan ninu ọkàn lọjọọjọ. Nipa rẹ ni a gbe le ni idapọ tootọ pẹlu Ọlọrun. Oun ni ọna ti a gba le ni ororo ti yoo mu ki iná Ọlọrun maa jo geerege ni igbesi ayé wa. (Wo Matteu 25:1-13). Adura ni ohun ti o le pese ọkàn wa silẹ ni imurasilẹ de bibọ Jesu.Apẹẹrẹ Bi O Ti Yẹ Ki A Gbadura
Jesu mu ibeere ọmọ-ẹyin yii ṣẹ O si kó gbogbo Onigbagbọ bi a ti i gbadura. Ṣugbọn ẹnikẹni ko gbọdọ ro pe Jesu fi dandan le e fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ tabi awọn Onigbagbọ lati maa gbadura nigbagbogbo lọna bayii nikan. Oluwa wa wi pe, “Nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ mã wipe,” ṣugbọn ko fi kọ wa pe ki a sọ adura ti O kọ ni di atunwi asan. Ṣugbọn jẹ ki awọn eniyan fi igboya sunmọ itẹ aanu, ki o sọ aini rẹ lọna ti Ẹmi Mimọ ba gba tọ ọ.
“Baba wa.” Jesu kọ ni pe Obi ti o ni aanu ati iyọnu ni Ọlọrun i ṣe, ẹni ti O mọ aini ọmọ Rẹ, O si n tẹti silẹ si ẹbẹ wọn. “Ti mbẹ li ọrun”: O lọla ju ẹnikẹni ninu awọn baba wa nipa ti ara. “Ki a bọwọ fun orukọ rẹ”: Jesu n fi han nihin yii bi orukọ Ọlọrun ti ni ọwọ tó ati pe otitọ ni ofin naa ti o wi pe, “Iwọ kọ gbọdọ pẹ orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ lasan; nitoriti OLUWA ki yio mu awọn ti o pẹ orukọ rẹ lasan ni alailẹṣẹ li ọrùn” (Ẹksodu 20:7).
“Ki ijọba rẹ de”: Ki a to le gbadura yii tọkantọkan eniyan ni lati jọwọ ara rẹ lọwọ fun Baba patapata, ki o si fi ọkàn rẹ fun Ọlọrun, ni opin gbogbo rẹ, oun yoo jé Onigbagbọ tootọ. “Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe”: A ni lati gbọran si aṣẹ Ọlọrun, a si ni lati tẹle ofin Rẹ kinni-kinni. Ifẹ Ọlọrun ni eyi pe, ki awọn ọmọ Rẹ sọ itan irapada yii fun awọn ẹlomiran ki wọn si maa gbadura fun iyipada ọkan ati pe ki a le mú wọn wá si jọba Ọlọrun. “Bi ti ọrun, bẹni li aiye:” Nigba Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, ti Jesu yoo gbe itẹ Rẹ kalẹ lati jọba ni alaafia fun ẹgbẹrun ọdun, gbogbo eniyan yoo mọ ifẹ Ọlọrun, wọn o si maa ṣe e gẹgẹ bi awọn ti ó wà ni Ọrun lonii ti mọ ọn ti wọn si n ṣe e. Awọn ọmọ Ọlọrun tootọ yoo ni anfaani lati bá Kristi jọba fun ẹgbẹrun ọdun, ijọba alaafia ni ayé. Awọn ẹbẹ mẹta ti ó wà ninu adura Oluwa yii ni a ko gbọdọ ṣalai ma beere fun ninu adura wa, lẹyin aini wa gẹgẹ bi ẹni kọọkan.
Aini nipa ti Ara
Fun wa li ounjẹ ojọ wa li ojojumó”: Eyi kó gbogbo aini wa nipa ti ara pọ. A n kọ awọn ọmọ lati gbẹkẹle Baba wọn ti n bẹ ni ọrun bi a ti n pese fun aini wọn ojoojumọ. A fi han nihin pe bi a ti n jẹ ounjẹ nipa ti ara bẹẹ ni a ko gbọdọ ṣalai ma jẹ Ounjẹ Ọrun lojoojumọ lati té ọkàn wa lọrun. “Ki o si dari ẹṣẹ wa ji wa”: Apa kan adura Oluwa yii ko fun ẹnikẹni láyẹ lati taku sinu ẹṣẹ tabi ki o maa dẹṣẹ bi ó bá ti fé ṣá. Ohun ti a n fi yé ni nihin ni pé, Ọlọrun yoo dari aṣiṣe tabi titẹ ofin Rẹ jì wá. “Nitorina ẹniti o ba mọ rere iṣe ti ko si ṣe, ẹṣẹ ni fun u” (Jakọbu 4:17). A ki i ka ẹṣẹ si ni lọrun afi bi a ba mọ rere, ṣugbọn nigba ti a ba mọ ire ti a si n ru ofin Ọlọrun sibẹ, ẹṣẹ ti a mọọmọ dá yii ni a o ka si ẹni naa lọrun, ki i si ṣe ọmọ Ọlọrun mó. “Nitori awa tikarawa pẹlu dariji olukuluku ẹniti o jẹ wa ni gbese”: Bi awọn eniyan ba fẹ ki Ọlọrun dari ẹṣẹ ti wọn dá si I ji wọn, awọn naa ni lati dari ẹṣẹ ji awọn ti o ba ṣẹ wón.
“Má si fà wa sinu idẹwọ:” Eyi jẹ ẹbẹ pe ki awọn ọmọ Ọlọrun má ṣe bó sinu idanwo ti yoo wu ọkàn wọn lewu. Pẹlu ijọwọ ara ẹni lọwọ fun ohunkohun ti Ọlọrun ba mu wa ni ẹbẹ yii gba jade nitori Jesu fi eyi kun un lẹsẹkẹsẹ, “Ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi”: Lọna miran O n fi ye ni pé, bi awọn ọmọ Rẹ ba bọ sinu idanwo ti o le wu ọkan wọn lewu fun wọn ni agbara lati bori ati lati jẹ aṣẹgun.
Labẹ nnkan mẹta ti o jẹ mọ ohun ti ayé yii a le ri ohun gbogbo ti olukuluku eniyan kọ le ṣai ma beere fun ara rẹ ninu adura. Gbogbo ileri ibukun Ọlọrun fun arayé ni o wà ninu adura kukuru yii. Jesu fi apele yii pari adura naa lati fi titayọ Ọlọrun han, “Nitori ijọba ni tirẹ, ati agbara, ati ogo, lailai.” “Amin” yii fi han pẹ gbogbo ọkàn ti o n gbadura yii ni o fara mọ ọn.
Ilana Adura
Awọn ẹlomiran rọ pé ohun kan ti adura wa fun ni lati maa fi gba ohun ti wọn n fẹ fun ara wọn, ṣugbọn ilana Bibeli nipa adura ni pe ki ogo Ọlọrun, ẹwa iwa-mimọ Rẹ ati ipinnu Rẹ, ati awamaridi etọ Rẹ ki o le ṣẹ. Lotitọ, Bibeli la ni loye ọpọlọpọ ibukun ti ẹni kọọkan le ri gba nipa adura nikan; iriri awọn ibukun wọnyii gba a si mu ki ẹni naa di ọmọ-ogun tootọ si i fun Kristi, yoo si mu ki o le jẹri fun Ọlọrun ati lati mu idagba soke ba Ijọba Ọlọrun ati ti Kristi ni ayé yii. Jesu fi apẹẹrẹ iru ọkan ti o yẹ ki a ni ninu adura hàn nigba ti O wà ninu idanwo nla ati irora kikorọ ni Gẹtsemane. Bi O ti n gbadura tọkantọkan, O kigbe pe, “Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yi ki o kọja kuro lori mi, ṣugbọn ki má ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ” (Matteu 26:39).
“Ṣugbọn ki ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ”: Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, Ẹni keji Mẹtalọkan, mọ ọn ni ohun danindanin lati gbadura bayii si Baba Rẹ, ki O ba le ni agbara lati ṣe iṣẹ-iranṣẹ Rẹ ti yoo mu igbala ọfẹ wa fun eniyan ni aṣeyọri. A le kiyesi i nigba naa bi aini wa ti pọ to gẹgẹ bi ẹda, pe ki a jẹ ki Alakoso ayé ati Ọrun maa tó wa! Ọmọ eniyan ko mọ ohun ti iṣẹju kan si i le mu wa, ṣugbọn Ọlọrun mọ opin lati ibẹrẹ. Gbogbo eniyan, paapaa ju lọ, awọn Onigbagbọ ni lati tẹle apẹẹrẹ Kristi ki wọn si jẹ ki Ọlọrun tọ wọn si ọna ti wọn yoo tọ tabi lati fi ohun ti Oun ti pinnu fun igbesi ayé wọn hàn wọn. Ifẹ Ọlọrun ni lati ṣe bẹẹ nitori a ka pe, “A ṣe ilana ẹsẹ enia lati ọwọ OLUWA wá” (Orin Dafidi 37:23).
Agbara pẹlu Ọlọrun
Ohun iyanu ni pe eniyan le jẹ aṣẹgun pẹlu Ọlọrun – ani pe adura ati ẹbẹ ọmọ eniyan le mi ọwọ Ọlọrun. Ohun ti Ọlọrun yoo ṣe fun eniyan ko lopin bi a ba beere fun igbeleke ogo orukọ Rẹ. “Eyi si ni igboiya ti awa ni niwaju rẹ, pe bi awa ba bẹre ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ, o ngbọ ti wa: Bi awa ba si mọ pe o ngbó ti wa, ohunkohun ti awa ba bẹre, awa mọ pe awa rí ibere ti awa ri bẹre lọdọ rẹ gbà” (1 Johannu 5:14, 15).
Bi awọn obi ko ti le gbagbe awọn ọmọ wọn, bakan naa ni Ọlọrun ko jẹ gbagbe awọn ti Rẹ. Nigba ti ọmọ ba beere akara lọwọ obi rẹ, o n ri akara gba, ki si i ṣe okuta; bi o ba beere ẹyin, a ko ni fun un ni akeeke dipo. Jesu wi pe, “Melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi Ẹmi Mimó rẹ fun awọn ti o mbẹre lọdọ rẹ?” (Luku 11:11-13). Ẹbun ti o tobi ju lọ ti eniyan le ri gbà, ani agbara Ẹmi Mimó, ni a fi fun un bi o ba beere, a o si kun ọkàn mimó ti o ti di funfun laulau. Igbagbọ tootọ ki i ṣe aṣeti.
“Ohunkohun ti ẹnyin ba si bẹre li orukọ mi, on na li emi ó ṣe, ki a le yin Baba logo ninu Ọmọ” (Johannu 14:13). “Li orukọ mi” fi han pe gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun ni. Ẹni kan ko lẹtọọ lati beere ohun kan ni orukọ Jesu lodi si ifẹ Rẹ, ki o si ni ireti lati ri esi gbà, o ha ṣe e ṣe? “Ẹ tẹte mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin” (Matteu 6:33). Ogunlọgọ eniyan ni o n wá ohun ti ara ṣiwaju ti wọn si n wá ti ẹmi nikẹyin, ẹnu a si maa yà wọn ohun ti kọ jẹ ki adura wọn gbà.
Niniyelori Ipinnu
Bibeli sọrọ pupọ nipa iduroṣinṣin ninu adura. Ọlọrun yẹ ipinnu si ni wiwá ibukun lati ọdọ Rẹ. Didun inu Ọlọrun ni lati dahun adura awọn eniyan ti wọn mọ daju pe ibukun ti wọn n beere jé ifẹ Ọlọrun, ti wọn si mu ẹbẹ naa wá pẹlu ipinnu ati iduroṣinṣin lai yẹsẹ, pẹlu otitọ ọkàn ati itara, awiyannu ati iforiti. Ọlọrun n gbó adura. Adura ti kọ ni jọwọ silẹ, bi adura Jakọbu (Gẹnẹsisi 32:24-29); adura ti kọ ni gba lọ ká bọ bi ti obinrin ara Sirofenika (Marku 7:25-30); adura ti a gba ninu ipọnju, bi ti ẹlẹmi eṣu ara Gadara (Marku 5:1-20); adura awiyannu, bi iru eyi ti o wà ninu ẹkọ wa ti oni (Luku 11:5-8); adura ti a gbà fun ogo Ọlọrun nikan, bi adura Elijah lori Oke Karmẹli (1 Awọn Ọba 18:22-39) -- awọn wọnyii ni apẹẹrẹ adura ti Ọlọrun n dahun. Bi O ti gbọ ti Ó si dahun adura awọn ti igba ni, bakan naa ni O ṣetan lati gbọ adura ti wa nitori “Ọlọrun kì iṣe ojusaju enia” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:34). “Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ” (Jakọbu 5:16).
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni adura?
- Ki ni ṣe ti o fi jé dandan fun awọn Onigbagbọ lati maa gbadura?
- Njẹ iwọ le ka Adura Oluwa latorí?
- Otitọ wo ni a ri kó ninu Adura Oluwa?
- Njẹ erọ Jesu ni pe adura yii nikan ni ki awọn ọmọ-ẹyin Rẹ ati awọn Onigbagbọ maa ka nigba gbogbo ṣá nigbakuugba ti wọn ba n gbadura?
- Nigba ti eniyan ba n gbadura, o ha ṣe pataki fun un lati fẹ ṣe ifẹ Ọlọrun? Ki ni ṣe?
- Ẹlẹṣẹ ha le ni ireti lari ri idahun si adura Rẹ gba lati ọdọ Ọlọrun? Iru adura wo ni o yẹ ki ẹlẹṣẹ gbà bi o ba fẹ ki Ọlọrun dahun?
- Darukọ awọn ibukun diẹ ti eniyan n ri gba nipa adura.
- Ki ni iwọ le sọ pe o niyelori jù nipa adura?