Johannu 9:1-41; 10:19-21

Lesson 134 - Senior

Memory Verse
“Emi kọ le ṣe alaiṣe iṣẹ ẹniti o rán mi, nigbati iṣe ọsan: oru mbọ wá nigbati ẹnikan ki o le ṣe iṣẹ” (Johannu 9:4).
Cross References

IImọlẹ Tootọ

1.Jesu ninu idahun Rẹ si ibeere awọn ọmọ-ẹyin nipa ọkunrin kan ti a bi ni afọju, sọ fun wọn pe ipo ti o wà ki iṣe nitori o dẹṣẹ, bi ko ṣe ki a ba le fi iṣẹ Ọlọrun hàn lara rẹ, Johannu 9:1-4; 11:4

2.Iṣẹ Ọlọrun farahan ki o ba le fi idi otitọ yii mulẹ pé Kristi ni Imọlẹ Ayé, Johannu 9:4, 5; 8:12; 1:9; 12:35-41;Matteu 13:13-17

3.Jesu fi amọ ti Ó ti fi itó pọ pa oju afọju naa, nigba ti o si wẹ ni Adagun Siloamu, o riran, Johannu 9:6, 7

IIẸri Tootọ

1.Ọpọ awọn ti o ri iṣẹ iyanu ti o mu ki oju afọju naa riran ṣiyemeji pé Jesu lo mu ki o riran, Johannu 9:8-21

2.Awọn obi afọju naa ati awọn aladugbo rẹ bẹru idojukọ ati inunibini awọn Farisi si Kristi wọn si bẹru lati sọ pe awọn mọ daju pe Kristi lo ṣe iṣẹ iyanu naa, Johannu 9:8, 9, 18, 22; 16:2; 12:42; 10:19-21

3.Ọkunrin ti a bi lafọju naa kọ ṣiyemeji lati fi igboya dahun pe oun ni ẹni ti a la oju rẹ ati pé Kristi ni o ṣe iṣẹ naa, Johannu 9:9, 11, 12, 17

4.Awọn Farisi gan ẹri afọju naa, sibẹ o n fi igboya sọrọ lati pa aigbagbọ ọkàn wọn ré, o ni, “Mo ti fọju ri, mo riran nisisiyi,” Johannu 9:15-17, 24-34

IIIWọn Kọ Imọlẹ

1.Wọn taari afọju naa kuroninu sinagọgu nitori o fi igboya jẹri Kristi,Johannu 9:22, 34

2.Nigba ti Jesu gbọ pe wọn ti i sode, O wa a ri, O si fi ara Rẹ hàn fun un, O kọ ọ bi a ṣe le sin isin tootọ, Johannu 9:35-38; 4:23, 24; Romu 16:25, 26; Filippi 3:3

3.Jesu sọ fun awọn Farisi pe ẹṣẹ wà ninu igbesi ayẹ wọn, nitori naa afọju amọna ni wọn nipa ti ẹmi Johannu 9:39-41

Notes
ALAYE

A Fi Imọlẹ ati Otitọ Hàn

Ihinrere ti Johannu sọ nipa Kristi bayii pe: “Ninu rẹ ni iye wà, iye na si ni imọlẹ araiye,” ati pẹlu pe, Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn imọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye” (Johannu 1:4, 9). A le ri i bi a ti fi eyi hàn fun ayé ti kọ gbagbọ yii ninu akọsilẹ nipa ọkunrin afọju ti Kristi fun ni iriran.

Awọn ọmọ-ẹyin beere ẹni ti o dẹṣẹ ti ibi yii fi bá ọkunrin afọju yii lati inu iya rẹ wá. Ko dabi ẹni pe wọn ṣiyemeji pe ẹṣẹ ẹni kan ni o fa a – boya ẹṣẹ ọkunrin afọju yii tikara rẹ tabi ti awọn obi rẹ. Jesu fi ye wọn pe bi o tilẹ jẹ ẹṣẹ ni o mu aisan ba ọmọ-eniyan lapapọ ki i ṣe pé nigba gbogbo ni ẹni ti aisan n ṣe naa ti dẹṣẹ. Ni ti ọkunrin yii, Jesu sọ fun wọn pe ki a ba le fi ogo Ọlọrun hàn ni.

Jesu ki i ṣe iṣẹ iyanu lati té agalamaṣa ọmọ-eniyan lọrun. Nigba ti Oun ba ṣe iṣẹ aanu ati iṣẹ iyanu wọnni, O n fi ye awọn eniyan pe o tọ o si yẹ fun wọn lati tẹti silẹ si Ẹni ti o lagbara lati ṣe nnkan wọnni. Jesu sọ bayii nipa ara Rẹ, “Bi emi kọ ba ṣe iṣẹ Baba mi, ẹ máṣe gbà mi gbó. Ṣugbọn bi emi ba ṣe wọn, bi ẹnyin kọ tilẹ gbà mi gbó, ẹ gbà iṣẹ na gbó: ki ẹnyin ki o le mọ, ki o si le ye nyin pe, Baba wà ninu mi, emi si wà ninu rẹ” (Johannu 10:37, 38).

Nigba ti Jesu tutọ silẹ ti O si fi ṣe amọ ti O fi kùn ọkunrin naa ni oju, ohun ti o wà lọkan rẹ tayọ lila ọkunrin yii loju lasan. Bi o tilẹ ṣe pe iṣẹ iyanu pataki ni eyi, sibẹ ko jamọ nnkan nigba ti a ba fi wé otitọ ẹni ti Jesu i ṣe ati ki ni iṣẹ Rẹ. Jesu sọ nihin yii pe, “Niwọn igbati mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye.” Iṣẹ-iranṣẹ Jesu fara han nihin yii. Oun ki i ṣe oluwosan ara nikan. Oun ni olugbala araiye, nitori O wi pe, “Emi li ọna, ati otitọ, ati iye” (Johannu 14:6). Oun ni Imọlẹ aye. Nipa lila oju ọkunrin afọju yii, O fẹ fi han fun gbogbo eniyan pe, Oun le la oju gbogbo awọn ti o fọju si otitọ yi pe, ẹlẹṣẹ ni gbogbo eniyan ati pe wọn ṣe alai ni igbala Ọlọrun nikan ni o si le fi fun ni.

Lati Inu Okunkun Sinu Imọlẹ

Lati riran, ọkunrin yii ṣe ohun ti Jesu sọ pe ki o ṣe: o lọ si Adagun Siloamu, o wẹ amọ ati itó ti Jesu fi pa oju rẹ kuro. Eyi ni o ṣe. O pada wá, o si riran!

Ko si agbara egbogi ninu amọ ti Jesu fi pa ọkunrin yii loju. Bakan ni kọ si agbara iwosan ninu Adagun Siloamu. Iwe Mimọ sọ pe ki a pe awọn alagba ijọ lati fi ororo kun wa ki wọn si gbadura fun wa bi a ba n ṣaisan (Jakọbu 5:14, 15). Kọ si agbara iwosan ninu ororo naa. Igbọran si aṣẹ Ọlọrun, ati igbagbọ ninu Kristi ni o n fa agbara iwosan lati ọdọ Ọlọrun wa.

Abuku pupọ ni a ti mu ba Ihinrere nitori awọn kan n sọ pe awọn le wo eniyan sàn. Aye kun fun ọpọlọpọ “a fi ‘gbagbọ ṣe iwosan” ti wọn n sọ pe wọn le wosan. Ṣugbọn igbọran si Ọrọ Ọlọrun, ati igbagbọ ni o n mu iwosan wá lati ọdọ Ọlọrun – ki i ṣe ohun miiran.

A le fi oju ẹmi wo bi ọkunrin yii ti gboju soke pẹlu iyanu lẹyin ti o ti wẹ oju rẹ tán ti o si riran kedere. Ta ni le sọ bi ọkàn rẹ yoo ti ri a fi ẹni ti ko ri imọlẹ ọjọ ri, ti ko ri ohun meremere ati iṣẹ ọwọ Ọlọrun ri? Lẹyin naa ki oju rẹ là ki o si maa riran kedere! Pẹlu iyanu ni ẹlẹṣẹ n la oju rẹ ti o ti fọ ri si awọn otitọ Ihinrere! Bi iyanu naa ti pọ to lati ri ẹwa Kristi fun igba kin-in-ni, bẹẹ ni ko le ri ohunkohun tẹlẹ ri!

Peteru sọ bayii nipa Kristi ati Ọrọ Ọlọrun, “Awa si ni ọrọ asọtẹlẹ ti o fẹsẹmulẹ jubẹẹlọ; eyiti o yẹ ki ẹ kiyesi bi fitila ti ntàn ni ibi ọkunkun, titi ilẹ yio fi mó, ti irawọ owurọ yio si yọ li ọkàn nyin” (2 Peteru 1:19).

Imọlẹ ọjọ titun mó fun ọkunrin ti a bi ni afọju yii. Sibẹ ohun ti o ri gbà ju iriran ti oju nikan lọ. O di Onigbagbọ tootọ ni Ọwọ ti o wo o sàn. Irawọ Owurọ ti igbala Kristi fẹrẹ bẹrẹ si i tàn ninu ọkàn rẹ pẹlu ẹwa Rẹ pipe. A la a loju ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, iye ati oju inu rẹ ṣí si ohun ti i ṣe ododo Ọlọrun.

Oore-ọfẹ Irapada

Pẹlu iyanu ni awọn eniyan fi tẹwọ gba a lẹyin ti o ti Adagun Siloamu bọ. Iyalẹnu nlá nlà ni iṣẹ ami ti wọn ri jẹ fun wọn. Ọpọ ni kọ mọ ọn mọ. Nigba ti ẹni kan ba ti wa pẹlu Kristi, ti o si ti ri agbara Ọlọrun gba lati ọdọ Rẹ, oun yoo di ẹni titun. Kọ si ẹni ti o ti ni idapọ pẹlu Kristi ri fun igba pipẹ ti ayé rẹ ko yipada. Awọn diẹ ninu awọn aladugbo rẹ wi pe oun ni ọkunrin afọju naa, awọn ẹlomiran wi pe, o jọ ọ ni. Ṣugbọn o dahun pe, “Emi ni.”

Wọn bi i lere pe, “Njẹ oju rẹ ti ṣe là?” O wi fun wọn pe, “Ọkunrin kan ti a npẹ ni Jesu li o ṣe amọ, o si fi kùn mi loju, o si wi fun mi pe, Lọ si adagun Siloamu, ki o si wẹ; emi si lọ, mo wẹ, mo si riran.” Wo bi ọkunrin yii ti sọ itan iṣẹ iyanu naa lọna ti o rọrùn lati yé ni. O pade Jesu; a sọ fun un lati lọ ati lati ṣe ohun kan. Ni kukuru o wi pe: Mo lọ, mo ṣe e, mo si ri gbà! Ilẹkun Ọrun wuwo, ki yoo ṣi fun awọn alaigbagbọ. Ṣugbọn pẹlu irọrun ni yoo ṣi fun ẹnikẹni ti o ba gbagbọ.

Awọn iranṣẹ ọkunrin kan ti o tọ Jesu wá nipa ti ọmọ rẹ ti o wà loju iku sọ fun un pe ọmọ naa ti kú. Nigba naa ni Jesu wi fun un pe, Má bẹru, sá gbagbó nikan” (Marku 5:36). Jesu lọ si ile rẹ O si ji ọmọbinrin yii dide. Ẹni ti o ba fẹ tumọ ohun ijinlẹ Ọlọrun le kuku maa ṣe itumọ awọn ohun ijinlẹ ti ó wà ni awọsanma. “Njẹ oju rẹ ti ṣe la?” ayé n fẹ mọ sibẹ.

Igbagbọ ati Aigbagbọ

Lẹyin naa awọn Farisi beere lọwọ rẹ bi oju rẹ ti ṣe là. Bi igbala ba jẹ igbekalẹ ti o duro lori ẹkọ tabi imọ pupọ, awọn ayé yoo maa wó tọ ẹni ti o n fi kó ni. Igbala ki i ṣe ero ori lasan tabi igbekalẹ ọgbọn ayé yii. Otitọ ni, nipa igbagbọ ni a n ri otitọ yii gba, ki i ṣe nipa imọ tabi ọgbọn lasan. O wu Ọlọrun ninu ifẹ ati aanu Rẹ lati fi igbala yii han awọn ọmọ ọwọ, O si fi pamọ loju awọn oniyemeji ati alaigbagbọ. Jesu ni o sọ otitọ yii pe, “Mo dupẹ lọwọ rẹ, Baba, Oluwa ọrun on aiye, pe, iwọ pa nkan wọnyi mó kuro lọdọ awọn ọlógbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ ọwọ: bẹẹni, Baba, bẹẹli o sá yẹ li oju rẹ. Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kọ si si ẹniti o mọ ẹniti Ọmọ iṣe, bikoṣe Baba; ati ẹniti Baba iṣe, bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti o ba si wù Ọmọ lati fi i hàn fun” (Luku 10:21, 22).

A mọ pe ọkunrin yii ri igbala, nitori nikẹyin, Kristi fara han fun un. Awọn Farisi, ẹlẹsin ti o kún fun igberaga wọnyii ko le ri i pe Ọlọrun ni Kristi i ṣe nitori wọn ti jinlẹ ninu ofin atọwọdọwọ ara wọn ati aigbagbọ. Ọlọrun ko ni inu didun si ọgbọn ti o n gbá ọmọ-eniyan kuro ninu igbagbọ ninu Ọlọrun. A le wi pe ọmọ ọwọ ni ọkunrin afọju ti a la loju yii, lọna bayii pe kọ mọ pupọ ninu ẹkọ ijinlẹ nipa isin tabi igbekalẹ ijọ, ṣugbọn ẹni ti igbagbọ rẹ n dagba soke ni oun jẹ niwaju Ọlọrun nitori ti o mọ pe Jesu ki i ṣe eniyan kan lasan. Ko wadii bi Kristi lagbara lati wo oun sàn. O ṣe ohun ti a pa laṣẹ fun un, o si riran.

Eniyan Ọlọrun kan ti wọn beere lọwọ rẹ pe ki o ṣe àlàyé igbala, dahun pe oun kọ jẹ daba lati ṣe àlàyé igbala, iṣẹ ati anfaani oun ni lati gba a gbọ ati lati kede ihin rere rẹ.

Ọpọlọpọ awọn ẹlẹsin ti ode oni ni o ti dawọ le lati tumọ igbala yekeyeke to bẹẹ ti wọn ko jẹ fi ẹnu kan ironupiwada pẹlu igbagbọ ninu Ọlọrun ninu ẹkọ ijọ wọn. Lati mọ pe Ọlọrun d’eniyan ni Kristi i ṣe ko kun wọn loju rara, agbara ti o wa ninu Ẹjẹ Rẹ ti O ta silẹ kọ si jamọ nnkan kan fun wọn.

Awọn Farisi sọ pe wọn kọ mọ “ọkunrin” yii (Kristi) tabi ibi ti o ti wá. Ọkunrin ti a la loju dahun rere: Ohun iyanu sá li eyi, pe, ẹnyin kọ mọ ibiti o gbé ti wá, ṣugbọn on sá ti là mi loju. Awa mọ pe, Ọlọrun ki igbó ti ẹlẹṣẹ: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣe olufọkansin si Ọlọrun, ti o ba si nṣe ifẹ rẹ, on ni igbó tirẹ. Lati igba ti aiye ti ṣẹ, a kọ ti igbó pe, ẹnikan là oju ẹniti a bí li afọju rí. Ibaṣepe ọkunrin yi ko ti ọdọ Ọlọrun wá, kì ba ti le ṣe ohunkohun” (Johannu 9:29-33).

Awọn Farisi sa ipa wọn lati lu ọkunrin ti a bi ni afọju yii lẹnu gbọ ọrọ, ki wọn ba le ló ọrọ rẹ si ibi ti o wù wọn. Ṣugbọn o fi ohun ti ẹnikẹni ti o ba n sọ ọrọ igbala gbọdọ fi le ni lọwọ le awọn Farisi lọwọ - otitọ gidi, ki i ṣe àlàyé nipa imọ ijinlẹ. “Olododo yio wà nipa igbagbó”, eyi ni ilana Ọlọrun (Romu 1:17).

Iru ipo kan naa ni Nikodemu wà nigba ti Jesu ba a sọrọ nipa aigbọdọ ma ni ibi titun nipa ti ẹmi. Oye ko ye e. Kristi fi afẹfẹ ṣe apejuwe ati àlàyé fun un. Iwọ le mọ bi afẹfẹ ba n fẹ ṣugbọn iwọ kọ le ri afẹfẹ. Bakan naa ni a ko le ṣe àlàyé ibi ti afẹfẹ ti wa ati ibi ti o n lọ (Johannu 3:1-13).

Awọn iṣẹ iyanu nla nla ti Jesu ṣe ni lati fi han pe Ọmọ Ọlọrun ati Olurapada arayé ni Oun i ṣe. Bi iṣẹ iyanu kan ba ṣe lonii, lati tọka eniyan si ọdọ Ẹni ti o ṣe e ni, Ọlọrun Olodumare ati Ọmọ Rẹ, Jesu Kristi. Gbogbo Ọrun pẹlu n tọka awọn eniyan si Ẹlẹda. Sibẹ ọpọlọpọ ni o lo gbogbo ọjọ ayé wọn lati ṣe alayé awọn ohun ijinlẹ Ọrun. Wọn dabi awọn Farisi ti ko le ri i pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe lẹyin gbogbo iṣẹ iyanu ti O ṣe.

A Le e Jade

Awọn Farisi kọ gba ẹri Jesu Kristi. Wọn kọ gba ẹri ọkunrin ti a bi ni afọju yii, bi o tilẹ ṣe pe awọn ti wọn dagba pẹlu rẹ mọ pe iṣẹ iyanu ni ati pe Ọlọrun nikan ni o le ṣe e. Ogunlọgọ ni ode-oni ni ko gba ẹri awọn ọmọ Ọlọrun. Wọn si n fẹ mọ eredi eyi ati eyi ni.

Jesu tọ ọkunrin yii lọ nigba ti O gbọ pe wọn le e jade, O si fi ara Rẹ hàn án. Nigba ti Jesu beere lọwọ ọkunrin ti a bi ni afọju yii pe, njẹ o gba Ọmọ Ọlọrun gbó, o beere pe ta ni Oun i ṣe. Jesu dahun pe, “Iwọ ti ri i, on na si ni ẹniti mba ọ sọrọ yi.” Bi ẹri ọkunrin yii ti já gaara to, o wi pe, “Oluwa, mo gbagbó”! Bi o ti ṣe pe ọkunrin yii ti a bi ni afọju ti ri iṣẹ iyanu nla nipa pe a la a loju, o dabi ẹni pe ko ri igbala titi Jesu fi ba a sọrọ, nigba ti O fi ara Rẹ hàn fun un. Nipa ibeere yii pe, “Tani, Oluwa, ki emi le gbà a gbó?” ati ẹri yii gẹrẹ lẹyin naa pe, “Oluwa mo gbagbó,” o ri igbala ọkàn rẹ. “Nitori ọkàn li a fi igbagbó si ododo, ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala” (Romu 10:10).

Awọn Farisi gbó ti Jesu wi pe, “Nitori idajọ ni mo ṣe wá si aiye yi, ki awọn ti kọ riran le riran; ati ki awọn ti o riran le di afọju.” Wọn dahun pe, “Awa pẹlu fọju bi?” Jesu wi fun wọn pe, “Ibaṣepe ẹnyin fọju, ẹnyin ki ba ti li ẹṣẹ: ṣugbọn nisisiyi ẹnyin wipe, Awa riran; nitorina ẹṣẹ nyin wà sibẹ.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti a bi ọkunrin yii ni afọju?
  2. Ki ni Jesu ṣe lati wo ọkunrin yii sàn?
  3. Nibo ni agbara lati wo ọkunrin naa sàn gbé ti wá?
  4. Bawo ni awọn Onigbagbọ ṣe n ri iwosan gbà lọjọ oni?
  5. Ki ni ṣe ti awọn Farisi kọ gba ẹri ọkunrin yii gbó?
  6. Ki ni awọn Farisi rọ nipa Jesu?
  7. Ki ni ọkunrin yii rọ nipa Jesu?
  8. Awọn Farisi ha fọju bi?
  9. Ki ni ifọju ti ẹmi?