Orin Dafidi 17:1-15

Lesson 135 - Senior

Memory Verse
“Bi o ṣe ti emi ni, emi o ma wọ oju rẹ li ododo: àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba ji” (Orin Dafidi 17:15).
Cross References

IAdura

1.Dafidi gbadura pẹlu itara si Ọlọrun pe ki O gba ọrọ oun rọ, ki o fiyesi oun, ki o fi eti si adura oun, Orin Dafidi 17:1, 6; 103:6; Romu 5:2; Efesu 1:6; 2:18

2.Dafidi bẹbẹ ki agbara Ọlọrun ti n mu ni duro le ràn án lọwọ ki o si pa á mó ni ọna ododo, Orin Dafidi 17:5; 119:116, 117, 121:3; 18:36

3.Dafidi bẹbẹ pe ki Ọlọrun dabo bo oun lọwọ awọn ọta oun nitori eyi jẹ anfaani olukuluku ọmọ Ọlọrun, Orin Dafidi 17:7-9, 13; 31:19-24; 57:1; Deuteronomi 32:9-12

IIỌran Dafidi

1.Dafidi ri i pe oun rin deedee niwaju Ọlọrun oun kọ si bẹru lati sọ fun Ọlọrun ki o ṣe ẹtọ nipa ọran oun, Orin Dafidi 17:2-4; 1 Johannu 3:21, 22; Heberu 10:22; Efesu 3:12

2.Dafidi sọ fun Ọlọrun nipa awọn ọta rẹ, ọna buburu wọn ati ikorira wọn, o si gbadura pe ki Ọlọrun le san ẹrẹ iṣẹ wọn fun wọn, Orin Dafidi 17:10-14; 73:5-9; Luku 16:25

3.Dafidi bẹbẹ ki Ọlọrun ki o le sọ imọ eniyan buburu di asán, ki O si já wọn tilẹ, ki O si gba ọkàn oun lọwọ wọn, Orin Dafidi 17:13

IIIIpari Ẹbẹ Rẹ

1.Dafidi fi eyi pari adura rẹ pe, oun ni igbagbó pe oun le duro niwaju Ọlọrun ni ododo iwa ni ayé yii ati pe ni ajinde oku, yoo jẹ itẹlọrun fun oun lati dabi Rẹ, Orin Dafidi 17:15; 36:7, 8; 63:5; Jeremiah 31:14; 1 Johannu 3:1, 2

Notes
ALAYE

Ọna si Ọdọ Ọlọrun

Orin Dafidi ikẹtadinlogun jẹ ọkan ninu ọpọlọpọ adura ti Dafidi gbà si Ọlọrun. O dabi ẹni pe nigba ti Saulu, Ọba Israẹli n lepa rẹ kikankikan ni o gba adura yii. Ọpọ idanwo ati wahala ti o de bá Dafidi mu ki o lọ si ori eekun rẹ lati tọrọ itọni ati iranlọwọ Ọlọrun. Bi ko ba si aabo Ọlọrun lori Dafidi nigba pupọ, ẹmi rẹ i ba ti bó.

Dafidi gẹgẹ bi ẹni ti o gbadura nitori aini nipa ti ara ati ti ẹmi, mọ bi a ti n gbadura nipa iriri ti o ni. Adura rẹ jẹ itunu fun awọn ti o wà ninu iṣoro ati aini. Adura jẹ anfaani ati ibukun iyebiye fun Onigbagbọ. Lati le ri oju rere Ọlọrun, lati le tọ Ọ lọ, lati le sọ ẹdun ọkàn wa fun Un, ki a si sọ iṣoro ati idanwo wa jẹ anfaani ti o niye lori pupọ.

Awọn ti ayé ko mọ riri adura nitori wọn ki i gbadura; wọn kọ si le ri ojurere Ọlọrun afi bi wọn ba ronupiwada. Ẹni bi ti inu Ọlọrun ni Dafidi i ṣe. Adura rẹ ninu Orin Dafidi ikẹtadinlogun jẹ eyi ti a le tẹle.

Ipa Rere

Adura si Ọlọrun ki i ṣe ohun ti kọ leto; nitori Ọba ni Ọlọrun i ṣe, O si fi ọna ti a le fi gbadura lelẹ. Dafidi bẹrẹ adura rẹ rere nigba ti o wi pe “Gbó otitọ, OLUWA.” A ni lati beere ohun ti o tó ninu adura wa si Ọlọrun. A kọ le mu ẹbẹ imọ-ti-ara-ẹni-nikan tabi igbẹsan tọ Ọlọrun, ki a si nireti lati ri esi gbà lọdọ Ọlọrun, nitori Ọlọrun kọ fi ara Rẹ wọlẹ to bẹẹ lati lọwọ ninu ikunsinu ati ẹṣẹ ọmọ eniyan. Jakọbu sọ fun ni pe, “Ẹnyin bẹre, ẹ kọ si ri gbà, nitoriti ẹnyin ṣì i bẹre, ki ẹnyin ki o le lọ o fun ifẹkufẹ ara nyin” (Jakọbu 4:3).

A ṣe inunibini si Dafidi gidigidi lati ọwọ Saulu ẹni ti o ni ikoro ni ọkàn si Ọlọrun nitori ẹṣẹ ti o ti dá. Nigba ti o ri ọwọ ibukun Ọlọrun lara Dafidi, Saulu bẹrẹ si jowu o si korira Dafidi, nitori ti Ọlọrun gba ijọba rẹ fun Dafidi. Ikorira ti o wà lọkan Saulu ni o mu ki Dafidi sá asala fun ẹmi ara rẹ. Dafidi mọ pe ọna oun tó nigba ti o n gbadura pe ki a daabo bo oun kuro lọwọ Saulu, eyi si ni ohun ti o fi ṣiwaju ninu adura rẹ.

Iwa Mimó

Bi o tilẹ jẹ pe ọna wa ti o tọ maa n mu ki inu Ọlọrun dùn lati dahun adura wa, ṣugbọn eyi kó ni idi pataki ti o mu ki O dahun adura wa. Dafidi mọ pe Ọlọrun a maa wo ọwó mimó ati ayà funfun. “Nitoriti oju OLUWA nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aiye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkàn pípe si ọdọ rẹ” (2 Kronika 16:9).

Dafidi ninu aini rẹ kọ kuna lati tọka si igbesi ayé rẹ fun Ọlọrun bi idi kan ti o le mu inu Ọlọrun dun lati ran an lọwọ ninu iṣoro rẹ. “Iwọ ti dan aiya mi wọ, iwọ ti bẹ ẹ wọ li oru; iwọ ti wadi mi, iwọ kọ ri nkan. . . . . . Niti iṣẹ enia, nipa ọrọ ẹnu rẹ emi ti pa ara mi mó kuro ni ipa alaparun.” Nigba ti a ba le tọka si igbesi ayé wa fun Ọlọrun lai si ifoyà pe Ọlọrun yoo bá ẹṣẹ nibẹ, a ni ọna si ọdọ Ọlọrun.

Dafidi sọ pe Ọlọrun ti dán ayà oun wọ kọ si ri ohun ibi kan nibẹ, ati pe ki yoo ri ohun ibi nibẹ lọjọ iwaju pẹlu. Lati gbé igbesi ayẹ mimó tẹlẹ jẹ ẹri fun Ọlọrun pe, nipa oore-ọfẹ Rẹ a o maa gbe igbesi ayé iwa mimó lọ. Ẹri atẹyinwa ni o fun Dafidi ni igboya lati gbadura pe, “Emi ti pinnu rẹ pe, ẹnu mi ki yio ṣẹ.” Ko si ẹni ti o le kó ahón rẹ ni ijanu bi o ti tó ati bi o ti yẹ lai si iranlọwọ Ọlọrun.

Satani ni olufisun awọn ara, ṣugbọn ifisun rẹ kọ lagbara lori igbesi ayé iwa mimọ. Nigba ti ẹni kan ba duro lori apata iwa mimọ o ni anfaani kan lọdọ Ọlọrun ti yoo bori nigbakuugba. Onisaamu sọ fun ni pe, “Oju OLUWA mbẹ lara awọn olododo, eti rẹ si ṣi si igbe wọn. Awọn olododo nke, OLUWA si gbó, o si yọ wọn jade ninu iṣé wọn gbogbo” (Orin Dafidi 34:15, 17).

Jobu, ninu idanwo igbagbọ ti o de ba a, mọ pe otitọ ọkàn niwaju Ọlọrun ni ohun ti o mu ki o ri iranlọwọ gba lọwọ Ọlọrun ninu ipọnju rẹ. Ẹri rẹ ni eyi pe, “Ẹsẹ mi ti tẹle ipasẹ irin rẹ, ọna rẹ ni mo ti kiyesi, ti nkọ si yà kuro. Bẹẹni emi kọ pada sẹhin kuro ninu ofin ẹnu rẹ, emi si pa ọrọ ẹnu rẹ mó jù ofin inu mi lọ” (Jobu 23:11, 12). “Titi emi o fi kú emi ki yio ṣi iwa otitọ mi kuro lọdọ mi. Ododo mi li emi dimú ṣinṣin, emi ki yio si jọwọ rẹ lọwọ; aiya mi ki yio si gan ọjọ kan ninu ọjọ aiye mi” (Jobu 27:5, 6). Jobu jé aṣẹgun lọdọ Ọlọrun, Ọlọrun gbó adura rẹ, O si dahun; igbesi ayé iwa mimó ti o n gbé niwaju Ọlọrun ni o mu un jé aṣẹgun.

Agbara ati Aabo

Dafidi gbadura pe ki Ọlọrun fi oore-ọfẹ hàn fun oun ki ẹsẹ oun ki o ma ṣe yẹ kuro ninu ododo lati dẹṣẹ. Agbara wà lọwọ Ọlọrun lati pa gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun mó ni ọna iwa mimó. Ohun ti a ni lati ṣe ni pe ki a beere oore-ọfẹ Ọlọrun ki a si mu un lọ nigba ti a ba ri i gbà. Ẹṣẹ ko le nipá lori wa niwọn igba ti a ba wà labẹ Ẹjẹ Kristi. Sibẹ a ni lati maa beere nigba gbogbo, nitori Ọlọrun a maa fun ni lati tán aini ti ọjọọjọ.

Ẹbẹ Dafidi pe ki Ọlọrun pa oun mó bi ọmọ oju ni ọpọlọpọ gbà si pe o n tọka si ẹyin oju. Ẹda eniyan jé iṣẹ ọwọ Ọlọrun Ẹlẹda, aabo ti Ọlọrun fi bo oju si jẹ iyanu ninu iyanu. A fi pamọ si agbárí nibi ti ohun kan ti o ba ṣeeṣi bó lu agbari ki yoo le de ibi ti oju wà. A fi ipenpeju bo oju eyi ti i maa yara pade ju bi a ti le roo lọ nigba ti ohun kan ba fẹ bó sinu ojú ti o si n daabo bo o kuro lọwọ ipalara. Lẹyin eyi, ipenpeju wà loke oju lati daabo bo o kuro ninu ewu ti o wù ki o de.

Pẹlu ọrọ diẹ ni Dafidi ṣe apejuwe iru aabo ti o fé. A o pa a mọ kuro ninu ewu, ni iha gbogbo, loke ati nilẹ, bi Ọlọrun ba pa a mó gẹgẹ bi o ti beere. Dafidi ri iṣẹ iyanu Ọlọrun ninu iṣẹda ojú, ko si lọra lati beere iru aabo bẹẹ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun. Bibeli kun fun ọpọlọpọ ileri ti o fi ẹsẹ rẹ mulẹ pe Ọlọrun yoo daabo bo awọn ọmọ Rẹ, Orin Dafidi ori kọkanlelaadọrun ati ori ikọkanlelọgọfa si jé apẹẹrẹ rere fun wa.

Awọn Ẹlẹṣẹ

Dafidi rán Ọlọrun leti igbesi ayé iwa ikà ti awọn ọta rẹ n gbe yatọ si igbesi ayé ododo ti rẹ. Bi a ti n lọ kaakiri laaarin igboro a o maa ri iru awọn eniyan ti Dafidi ṣe apejuwe yii. Awọn ọta rẹ n dọdẹ rẹ bi ohun-ọdẹ. Kiniun a maa fara pamọ ni ibuba, ninu papa tabi nibi ti o ba gbe ri nnkan fi boju, yoo si fọ mó ohun-ọdẹ rẹ bi o ti n kọja lọ. Peteru pe Satani, ọta eniyan ti o ga ju lọ, ni kiniun: “Ѐṣu, ọtá nyin, bi kiniun ti nke ramuramu, o nrìn kãkiri, o nwá ẹniti yio pajẹ kiri” (1 Peteru 5:8).

Dafidi gbadura fun igbala kuro “lọwọ awọn enia ti iṣe ọwọ rẹ, OLUWA, lọwọ awọn enia aiye, ti nwọn ni ipin wọn li aiye yi” (Orin Dafidi 17:14). O jẹ otitọ ti ko tete fara han pe awọn ẹni ti ayé ati awọn eniyan buburu ti gba ọrọ ati ipin ti wọn ni ayé yii.

Ọpọlọpọ le ro pe iṣura ti ayé yii gẹgẹ bi alumọni ni Dafidi n tọka si nihin. Otitọ ti ko ṣe e jà niyan ni eyi pe, ọpọlọpọ awọn eniyan ti o buru jai ni o ti jé ọlọrọ ni ayé yii. Ọrọ kọ ni o fi hàn pe eniyan ṣe daradara tabi pe ẹni rere ni iwaju Ọlọrun. Ogunlọgọ fé awọn ọlọrọ wọn si gan awọn talaka. “Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ lati wọ ijọba Ọlọrun! Nitori o rọrun fun ibakasiẹ lati gbà oju abẹrẹ wọle, jù fun ọlọrọ lati wọ ijọba Ọlọrun lọ” (Luku 18:24, 25). Dafidi kọ akọsilẹ yii nipa ọrọ awọn eniyan buburu: “Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣefefe, nigbati mo ri alafia awọn enia buburu. Nitoriti kọ si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ. Nwọn kọ ni ipin ninu iyọnu enia; bẹẹni a kọ si wahala wọn pẹlu ẹlomiran. . . . . Nigbati mo rọ lati mọ eyi, o ṣoro li oju mi. Titi mo fi lọ sinu ibi-mimó Ọlọrun; nigbana ni mo mọ igbẹhin wọn” (Orin Dafidi 73:3-5, 16, 17).

Awọn ọlọrọ a maa fi ohun ini wọn silẹ ki ọmọ wọn le jogun rẹ bi wọn ba kú. Awọn eniyan buburu a saba maa ni ohun ti ayé yii bi wọn ti n fé, ṣugbọn nigba ikú wọn, wọn dabi awọn ẹlomiran -- wọn fi ohun gbogbo silẹ. Awọn ti kọ mọ Ọlọrun “dabi ẹranko ti o ṣegbe” – laini ireti (Orin Dafidi 49:20).

Nigba pupọ ni awọn eniyan buburu jé ọlọrọ ti wọn si jẹ igbadun ẹṣẹ aye yii ṣugbọn wọn kú wọn si lọ sinu ìṣé oró lai si ohun rere kan lati tù wón ninu. A ri apẹẹrẹ yii ninu igbesi ayé Lasaru ati ọkunrin ọlọrọ (Luku 16:19-31). Lasaru a maa ṣagbe ni ẹnu ọna ọkunrin ọlọrọ, lati le ṣa ẹrún akara ti o ba bọ silẹ lati ori tabili rẹ jẹ. O dabi ẹni pe ipin rẹ buru laye yii, ṣugbọn nigba ti o kú, ìṣé ati iyà rẹ dopin laelae, o si lọ si ayeraye lọdọ Ọlọrun, nibi ti alaafia wà titi laelae. Ẹ wo iyatọ ti o wà ninu ipin rẹ ati ti ọlọrọ nigba ti o kú ti igbadun rẹ layé dopin, ti o si lọ si ọrun apaadi titi laelae.

Isimi Onigbagbó

Adura Dafidi pari pẹlu ifọkantan Ọlọrun, ati ọkàn ti o ni alaafia. Awọn ọmọ Ọlọrun ni alaafia pẹlu Ọlọrun, wọn si ni igbẹkẹle ninu eto Ọlọrun, ati ninu aabo Rẹ fun awọn ti Rẹ. Ireti lati maa wo oju Ọlọrun ninu ododo jé ipin ti o té Dafidi lọrun. “Àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba jí” (O n sọ nipa ajinde). A o ri I bi Oun ti ri a o si dabi Rẹ. O ṣoro fun ọkàn eniyan lati mọ ohun ti aiku jé; sibẹ Bibeli sọ fun wa pe a o gbé ara aiku wọ, a o dabi Kristi, a o si di ọmọ ati ajogun Ọlọrun ni kikún. Nigba naa ko ni ṣoro lati mọ idi rẹ ti Dafidi fi sọ tọkantọkan pe: “Àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba jí.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ewo ni ọna ti o tó lati gbadura?
  2. Njẹ a ni lati jẹ ki Ọlọrun dán ọkàn wa wọ, ki O si wá ayà wa rí lati mọ bi a ba ti dẹṣẹ?
  3. Ta ni oluparun eniyan?
  4. Ki ni Dafidi rọ nigba ti o beere pe ki Ọlọrun pa oun mó bi ọmọ-oju?
  5. Bawo ni a ṣe fi awọn ẹlẹṣẹ wé awọn kiniun?
  6. Njẹ awọn ẹlẹṣẹ n jẹ igbadun ninu ayé yii ju awọn ọmọ Ọlọrun lọ?
  7. Nigba wo ni awọn ọmọ Ọlọrun yoo jogun ohun rere gbogbo ti wọn?
  8. Ki ni Dafidi ro nigba ti o wi pe oun yoo ni itẹlorun nigba ti oun ba ji dide ni aworan Ọlọrun?