Deuteronomi 11:26-32; 27:11-26; 28:1-68

Lesson 136 - Senior

Memory Verse
“Emi fi iye ati ikú, ibukún ati egún siwaju rẹ: nitorina yàn iye, ki iwọ ki o le yẹ, iwọ ati irú-ọmọ rẹ” (Deuteronomi 30:19).
Cross References

IA Pin Israẹli Sori Oke Gerisimu ati Ebali

1.A fi Oke Gerisimu ṣe oke ibukún, Deuteronomi 11:27, 29; 27:11, 12

2.A kọ ofin, a si fi Oke Ebali ṣe oke egún, Deuteronomi 11:28-32; 27:4-8, 13

IIOfin ati Egún fun Aigbọran si I

1.“Iwọ kọ gbọdọ yá ere fun ara rẹ,” Deuteronomi 5:8; 27:15

2.“Bọwọ fun baba ati iya rẹ,” Deuteronomi 5:16; 27:16

3.“Bẹẹni iwọ kọ gbọdọ jale,” Deuteronomi 5:19; 27:17-19

4.“Bẹẹni iwọ kọ gbọdọ ṣe panṣaga,” Deuteronomi 5:18; 27:20-23

5.“Iwọ kọ gbọdọ pania,” Deuteronomi 5:17; 27:24, 25

IIIAsọye Kikún nipa Ibukún ti o wà fun Igbọran

1.A ṣeleri ọpọ ini, Deuteronomi 28:1-6, 8, 11-14

2.Iṣẹgun ninu ogun jija yoo wa dajudaju, Deuteronomi 28:7

3.Wọn o jẹ ẹni ọtọ nipa isin otitọ, Deuteronomi 28:9, 10

IVAsọye Kikún nipa Egún ti o wà fun Aigbọran

1.Ipọnju ati iyan yoo wà, Deuteronomi 28:15-20, 23, 24, 38-40

2.Arun yoo kọlu wọn, Deuteronomi 28:21, 22, 27-29, 35, 58-61

3.Iṣubu ninu ogun, ibanujẹ ati ituka yoo bá wọn, Deuteronomi 28:25, 30-34, 36, 37, 41-57, 62-68

Notes
ALAYE

Ni Pẹtẹlẹ More

Nigba ti Abrahamu kó de ilẹ Kenaani, o duro ni pẹtẹlẹ More nibi ti Oluwa gbe fara han an ti o si ṣeleri lati fi ilẹ naa fun iru-ọmọ rẹ. Abrahamu té pẹpẹ kan o si sìn nibẹ. Ni apa kan pẹtẹlẹ More yii ni Oke Ebali wà nibi ti Mose gbe paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati té pẹpẹ kan lori eyi ti a o kọ Ofin si. Nihin ni awọn Ọmọ Israẹli yoo gbe rubọ alaafia, lati jẹ ati lati yọ.

Gẹgẹ bi akọsilẹ Bibeli, a le foju ẹmi wo bi ibẹ yoo ti ri bi Joṣua ti bẹrẹ si mu ofin Ọlọrun ṣẹ. Idaji awọn eniyan naa duro ni gẹrẹgẹrẹ Oke Ebali ti o ga ni iwọn ẹgbẹrun ẹsẹ lẹyin wọn. Awọn wọnyii wà nihin ni oluranni-leti egun ti ó wà lori ẹni ti o ba rú Ofin. Awọn aabọ ẹya iyoku duro lẹgbẹ Oke Gerisimu, lati fi idi ibukun Ọlọrun mulẹ lori awọn ti o ba gbọran. Awọn ọmọ Lefi ti o duro ti Apoti Ẹri ninu afonifoji laaarin gbe oju wọn soke si Oke Gerisimu wọn si kigbe pe, Ibukún ni fun ọkunrin naa ti kọ yá erekere. Iro Amin si bú jade lohun kan lati ẹnu awọn eniyan ti o wà ni Oke Gerisimu. A tun le gbọ bi awọn ọmọ Lefi ti tun kọju si Ebali ti wọn si wi pe, Egún ni fun ọkunrin naa ti o ba yá erekere. Idahun Amin ti o ti Oke Ebali jade wa fi ojuṣe ti o n bẹ lori ẹni kọọkan ti o ṣe alabapin ninu eto naa hàn. Ibukún ati egún wọnyii tẹle ara wọn titi gbogbo eniyan fi dahun Amin si gbogbo Ofin.

Imuṣẹ Ibukun

Itan Israẹli jẹri ni kinni-kinni si otitọ Ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi a ti fi i lelẹ ninu ibukun ati egun wọnni. Niwọn igba ti wọn ba gbọran si Ofin Ọlọrun, wọn ni ibukun. Nigba ijọba Dafidi, Sọlomọni ati awọn miiran ti o dari awọn eniyan si isin Ọlọrun otitọ, Israẹli di orilẹ-ede alagbara ati ọlọrọ.

Dafidi ṣe akojọ wura ọkẹ aimoye naira lati fi kó Tẹmpili. Sọlomọni kó fadaka ati wura “pọ bi okuta” ni Jerusalẹmu. Nigba ti a ya Tẹmpili si mimó, ọba fi ẹgbaa mọkanla (22,000) maluu ati ọkẹ mẹfa (120,000) agutan rubọ. Ọlọrun ti ṣeleri pe, “Ibukún ni fun ọ ni ilu, ibukún ni fun ọ li oko.” Gbogbo ọba ayé ni o fẹ ri Sọlomọni ati lati gbọ ọrọ ọgbọn rẹ. Ileri Ọlọrun ni pe, “OLUWA yio si fi ọ ṣe ori, ki yio si ṣe iru; iwọ o si ma leke ṣá, iwọ ki yio si jé ẹni ẹhin.”

Nigba ti Gideoni ati ọdunrun ọkunrin dó yika ibudo awọn ara Midiani, “gbogbo ogun na si sure, awọn si kigbe, nwọn si sá.” Bayii ni Ọrọ Ọlọrun ṣẹ lọna gbogbo: “OLUWA yio mu awọn ọtá rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlù niwaju rẹ: nwọn o jade si ọ li ọna kan, nwọn o si sá niwaju rẹ li ọna meje.” Ayaba Ṣeba mọ pe Ọlọrun wa pẹlu Israẹli nigba ti o sọrọ yii jade pe, “Olubukún li OLUWA Ọlọrun rẹ: ti o fẹran rẹ lati gbé ọ ka ori ité rẹ, lati ṣe ọba fun OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoriti Ọlọrun rẹ fẹran Israẹli (2 Kronika 9:8). Oluwa ti wi pe, “Gbogbo enia aiye yio si ri pe orukọ OLUWA li a fi npẹ ọ.”

Ohun kan n bẹ lati ṣe ki a to ri ibukun Ọlọrun gba, nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ba ṣe nnkan wọnyii, wọn n ri ibukun gba. Awọn ibukun ẹmi ti Ọlọrun n fi fun ni lonii duro lori igbọran. “Ṣugbọn bi awa ba nrin ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ni idapọ pẹlu ara wa, ẹjẹ Jesu Kristi Ọmọ rẹ ni nwẹ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo” (1 Johannu 1:7).

Imuṣẹ Egun

Ọlọrun mọ pe awọn Ọmọ Israẹli yoo maa ṣe aigbọran, O si ṣe wahala pupọ lati la ohun ti yoo de ba wọn bi wọn ba ṣaigbọran si I ye wọn yekeyeke. O fi iye ati iku siwaju wọn. Ọna naa mọlẹ kedere. Wọn le wà lai si labẹ egun; Ọlọrun ko tilẹ fẹ ki wọn wa labẹ egun. Esekiẹli kigbe pe, “Ẹ yipada kuro ninu ọna buburu nyin; nitori kini ẹnyin o ṣe kú, Ile Israẹli?” (Esekiẹli 33:11). Awọn eniyan lonii ko ṣalaini mọ ẹrẹ ẹṣẹ, ṣugbọn ogunlọgọ ni o tẹra mọ ọn lati maa rin ni ọna iparun. Jesu n kede ọna iye ainipẹkun sibẹ fun awọn ti yoo ba jẹ tọ Ọ wa.

Arun

“Bi iwọ o ba tẹtisilẹ gidigidi si ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, . . . . . emi ki yio si fi ọkan ninu àrun wọnni ti mo múwa sara awọn ara Egipti si ọ lara” (Ẹksodu 15:26). Bi ko tilẹ ṣe fun ohun miiran ju ati ni alaafia, ere Israẹli yoo pọ bi wọn ba gbọran si Ọlọrun lẹnu. A ṣe apejuwe awọn arun buburu ti Oluwa yoo fi kọlu wọn bi wọn ba ṣaigbọran. Akọsilẹ iru arun bẹẹ wà ninu itan awọn Ọmọ Israẹli. Jesu sọ pe ọpọlọpọ adẹtẹ ni o wà ni Israẹli ni akoko Eliṣa.

Ìṣé

Eso ilẹ rẹ, ati gbogbo iṣẹ-lãlã rẹ, ni orilẹ-ẹde miran ti iwọ kọ mọ yio jẹ; iwọ o si jé kiki ẹni inilara ati ẹni itẹmọlẹ nigbagbogbo.” Eyi ṣẹlẹ lera-lera nigbakigba ti Israẹli ba ṣẹ si Ọlọrun. A mu ọrọ wọnyii jade lati inu Awọn Onidajọ 6:3-6 fun apẹẹrẹ: “O si ṣe, bi Israẹli ba gbin irugbìn, awọn Midiani a si gọke wá, ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ iha ila-õrùn; nwọn a si gọke tọ wọn wá; Nwọn a si dótì wọn, nwọn a si run eso ilẹ nã, titi iwọ o fi dé Gasa, nwọn ki isi fi ounjẹ silẹ ni Israẹli, tabi agutan, tabi akọmalu, tabi kẹtẹkẹtẹ. . . . . . . Oju si pón Israẹli gidigidi.”

Ọdá

Nitori ẹṣẹ Israẹli ni Elijah ṣe duro niwaju Ahabu ti o si kede pe, “Bi OLUWA Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, ki yio si ìri tabi ọjo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọrọ mi” (1 Awọn Ọba 17:1). A ti sọ fun Israẹli pe ojo ilẹ wọn yoo di etu ati ekuru. “Ọrun rẹ ti mbẹ lori rẹ yio jé idẹ, ilẹ ti mbẹ nisalẹ rẹ yio si jé irin.”

Ìyàn

“Bẹẹni awa sẹ ọmọ mi, awa si jé ẹ: emi si wi fun u ni ijọ keji pe, Mu ọmọ rẹ wá ki awa ki o jé ẹ; on si ti fi ọmọ rẹ pamó.” Eyi ni ẹsun ti obinrin Israẹli kan mu tọ ọba wa. Ọlọrun ti kilọ fun Israẹli tẹlẹ pe bi wọn ba ṣe aigbọran, awọn obinrin ẹlẹgẹ ati alailagbara laaarin wọn yoo pa ọmọ inu wọn jẹ. Lai si aniani Ọrọ Ọlọrun ṣẹ!

Iṣubu ninu Ogun ati Ituka

Nigba ti Israẹli sin Ọlọrun, Ọlọrun jà fun wọn. O fi ohun ti o wù Ú ba ọta wọn jà. Deborah, wolii obinrin, wi pe, “Awọn irawọ ni ipa wọn bá Sisera jà,” Ko ri bẹẹ nigba ti Israẹli dẹṣẹ -- wọn sá nigba ti ẹni kan ko le wọn. A ko wọn ni igbekun lọ si Egipti, Assiria, Babiloni, a si tu wọn kaakiri laaarin awọn eniyan, lati opin kan de opin keji ilẹ aye. Titi di oni-oloni wọn jẹ “ẹni iyanu, ati ẹni owe, ati ẹni ifiṣọrọsọ ninu gbogbo orilẹ-ẹde.” Israẹli ti ṣubu, igbala ti tẹ awọn Keferi lọwọ. Israẹli ni a tọka si bi ẹka igi ọróró, awọn keferi ni a si tọka si bi ẹka igi ororo igbẹ ti a ló si ara igi ọróró; ṣugbọn a kilọ fun ni pe, “Bi Ọlọrun kọ ba da ẹkaiyẹka si, kiyesara ki o máṣe alaida iwọ na si. Nitorina wo ore ati ikannu Ọlọrun: lori awọn ti o ṣubu, ikannu; ṣugbọn lori iwọ, ore, bi iwọ ba duro ninu ore rẹ: ki a má ba ke iwọ na kuro” (Romu 11:21, 22). Akoko “kíkún awọn Keferi” ti de ba wa, Ọlọrun si ti n yi pada si Israẹli gẹgẹ bi ileri Rẹ. “Ni Sioni li Olugbala yio ti jade wá, yio si yi aiwa-bi-Ọlọrun kuro lọdọ Jakọbu” (Romu 11:26).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Njẹ a mu ikilọ ti Mose ṣe ni Deuteronomi 27:11-13 ṣẹ?
  2. Ewo ninu awọn Ofin Mẹwaa ni a le ri mu jade ninu egún ti ó wà ni ori 27?
  3. Wa apẹẹrẹ ibi ti awọn Ọmọ Israẹli gbe ri ibukun ti ara ti Ọlọrun ṣeleri fun wọn gbà.
  4. Sọ ogun mẹta ti Ọlọrun ṣé fun wọn gẹgẹ bi ileri Rẹ.
  5. Nigba wo ni Israẹli jẹ “ori” ti a si gbé wọn “ga” ju awọn orilẹ-ede miiran?
  6. Nibo ninu Iwe Mimó ni a gbe sọ fun ni nipa iyàn ni Israẹli?
  7. Njẹ aṣa jijẹ eniyan ṣẹlẹ ni Israẹli bí?
  8. Darukọ awọn ilu diẹ ninu eyi ti a tú awọn Ọmọ Israẹli ká si nigba laelae.
  9. Wa ileri kan ti o sọ nipa imupadabọ awọn Ọmọ Israẹli.
  10. Darukọ awọn orilẹ-ẹde diẹ ni igba ti wa yii nibi ti inira gbe wa fun awọn Ju, gẹgẹ bi a ti sọ tẹlẹ ni Deuteronomi 28:65.