Deuteronomi 12:1-32; Johannu 4:19-24

Lesson 137 - Senior

Memory Verse
“Wakati mbọ, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sin Baba li ẹmi ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sin on” (Johannu 4:23).
Cross References

IAṣẹ fun Iṣẹ Pataki

1.Ibi gbogbo ti awọn keferi ti jọsin– igbo oriṣa, pẹpẹ ọwọn – ati oriṣa wọn gbogbo, ni a ni lati parun patapata, Deuteronomi 12:1-3; 7:5; Ẹksodu 34:13

2.Oluwa yoo yan ibi ti awọn eniyan Rẹ, Israẹli, yoo maa jọsin, Deuteronomi 12:4, 5; 1 Awọn Ọba 8:29; 2 Kronika 7:12; Orin Dafidi 78:68

3.Wọn yoo maa mu idamẹwa ati ọrẹ wa si ibi ti Oluwa yoo yàn, ati awọn ati ara ile wọn yoo maa jẹ, wọn yoo si maa yọ niwaju Oluwa, Deuteronomi 12:6-14; 16:2

4.Bi ki i ba ṣe ẹbọ ọrẹ si Oluwa, wọn le pa a ki wọn si jẹ ohun gbogbo ti Oluwa ba fi fun wọn ni ile wọn, ṣugbọn wọn ko gbọdọ jẹ ẹjẹ rẹ, Deuteronomi 12:15-27; Lefitiku 17:11-14; Iṣe Awọn Apọsteli 21:25

5.A kọ gbọdọ kọ ọmọ Lefi silẹ, Deuteronomi 12:19; 14:27; Numeri 18:20; Orin Dafidi 16:5; Esekiẹli 45:4; Luku 10:7; 1 Kọrinti 9:13, 14

IIIkilọ

1.Wọn ni lati kiyesara ki wọn má ba bó sinu idẹkun ki wọn si tẹle ohun irira awọn keferi, Deuteronomi 12:28-31; Ẹksodu 23:2; 1 Samuẹli 8:20; 1 Awọn Ọba 16:31-33

2.A kọ gbọdọ yọ kuro tabi fi kún Ọrọ Ọlọrun, Deuteronomi 12:32; 4:2; Owe 30:6; Ifihan 22:18, 19

IIIIjọsin ti Ẹmi

1.Obinrin ara Samaria beere lọwọ Jesu ibi ti o yẹ lati jọsin, oke Samaria tabi Jerusalẹmu, Johannu 4:19, 20

2.Jesu wi fun un pe Ẹmi ni Ọlọrun, awọn olusin tootọ yoo si maa sin In ni ẹmi ati ni otitọ, Johannu 4:23, 24

Notes
ALAYE

A Pa Isin Eke Run

“Iwọ kọ gbọdọ li Ọlọrun miran pẹlu mi,” ni ofin kin-in-ni ti a kọ sori walaa okuta. Ọlọrun sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe ki wọn mu gbogbo ami ibọriṣa kuro niwaju wọn nigba ti wọn ba de Ilẹ Kenaani. Igbo oriṣa nibi ti awọn keferi gbe n bọriṣa ni wọn ni lati parun. Wọn ni lati dana sun pẹpẹ wọn, ki wọn si wó ẹre gbigbẹ wọn lulẹ. Ko gbọdọ ku ohun kan ti o le fa ọkàn wọn lati sìn ni ibi wọnni.

Awọn keferi a maa gbe oriṣa wọn kalẹ labẹ igi tutu ati lori oke giga, ki o ba le rọrun fun wọn lati lọ sin nibẹ.

Ọpọlọpọ lọjọ oni ni o ni itẹlọrun lati jokoo ti ẹrọ redio lati tẹti lelẹ si iwaasu rẹ. Wọn rọ pe ko ṣanfaani lati lọ si ile Ọlọrun mó niwọn igba ti wọn ti n gbọ iwaasu lori ẹrọ ninu ile wọn. Onilọra olusin! “Ẹ jẹ ki a yẹ ara wa wo lati rú ara wa si ifẹ ati si iṣẹ rere: ki a má mã kọ ipejọpọ ara wa silẹ, gẹgẹ bi àṣa awọn ẹlomiran” (Heberu 10:24, 25).

A Kọ Fun Wọn lati Jẹ Ẹjẹ

Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ba pa ẹran fun irubọ, wọn ni lati tú ẹjẹ rẹ sori pẹpẹ gẹgẹ bi ọrẹ fun Oluwa. Bi wọn ba pa ẹran ni ile wọn fun jijẹ, wọn ni lati tu ẹjẹ rẹ da silẹ; nitori ẹmi n bẹ ninu ẹjẹ, a si kọ fun wọn lati jẹ ẹjẹ.

Awọn irubọ wọnni tọka si, wọn si jẹ apẹẹrẹ Ọdọ-agutan Ọlọrun ti yoo ta Ẹjẹ Rẹ, silẹ ti yoo si fi ẹmi Rẹ lelẹ fun iye arayé. “Niwọnbi ẹnyin ti mọ pe, a kọ fi ohun ti idibajẹ rà nyin pada, bi fadaka tabi wura,……. bikoṣe ẹjẹ iyebiye, bi ti ọdọ-agutan ti kọ li abuku, ti kọ si li abawọn, ani ẹjẹ Kristi” (I Peteru 1:18, 19).

Ibi Ijọsin

“Ṣugbọn ibi ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn ninu gbogbo ẹya nyin lati fi orukọ rẹ si, ani ibujoko rẹ li ẹnyin o ma wálọ, ati nibẹ ni ki iwọ ki o ma wá” (Deuteronomi 12:5). Bi a ba gba awọn eniyan naa laye lati yàn, boya ija ati ariyanjiyan ni i ba wà laaarin wọn pe, nibo ni yoo gbé wà ati laaarin ẹya wo ni yoo wà.

Oke Sinai ni Ọlọrun gbe fun Mose ni apejuwe Agọ ti O fẹ ki a kó lati maa jọsin ninu rẹ. Agọ tikara rẹ jẹ ọbọrọ, ṣugbọn awọn ohun elo inu rẹ dara pupọ. Lẹyin ti a ti kọ Agọ, ibẹ ni ibi pataki ti Jehofa ati awọn eniyan Rẹ gbe n pade (Numeri 11:24, 25; 12:4; 16:19; Deuteronomi 31:14).

Lẹyin ti wón ti dé ilẹ Kenaani tán, wọn n gbe Agọ lati ibudo kan de ekeji titi wọn fi gba ilẹ naa; lẹyin naa ni a gbe e kalẹ si Ṣilo (Joṣua 18:1). Nibẹ ni o wa ni gbogbo ọjọ Eli alufaa, nigba ti awọn ara Filistini gba Apoti-Ẹri. Lati igba naa ni ogo Agọ ti dinku (1 Samuẹli 4:22). A gba Apoti-Ẹri pada lọwọ awọn Filistini, Dafidi si gbe e wá si Jerusalẹmu nibi ti a gbe kọ ile titun bo o lori (2 Samuẹli 6:17). Lẹyin ti Sọlomọni kó Tẹmpili ni Jerusalẹmu, a kọ lo Agọ mó.

Tẹmpili

Ni akoko ti Sọlomọni wa lori oye, ijọba Israẹli wa ninu ogo nla, O ti di alagbara, ọlọrọ ati orilẹ-ede alaafia.

Ki Dafidi to kú, o ri i pe ẹwa awọn ile, paapaa ju lọ ile ti oun n gbe dara ju Agọ lọ. O ri i pe ko yẹ ki eyi ri bẹẹ; ni ọjọ kan bi o ti jokoo ni ile rẹ ti o n ba wolii Natani sọrọ, o wi pe, “Wọ o, emi ngbe inu ile kedari, ṣugbọn apoti ẹri majẹmu OLUWA ngbe abẹ aṣọ-tita.” Nigba naa ni Natani wi fun Dafidi pe, “Ṣe ohun gbogbo ti mbẹ ni inu rẹ; nitoriti Ọlọrun wà pẹlu rẹ” (1 Kronika 17:1, 2).

Nitori Dafidi jẹ jagunjagun o si ti ta ẹjẹ pupọ silẹ, Ọlọrun kọ gba fun un lati kó Tẹmpili, ṣugbọn O sọ fun un pe Sọlomọni, ọmọ rẹ, le kó ọ.

Gẹgẹ bi Agọ ti ri ni a ṣe kó Tẹmpili. A sọ fun ni pe apẹẹrẹ Agọ ti Ọrun ni wọn i ṣe (Heberu 9:23, 24). Dipo aṣọ tita, igi kedari ni a fi kó Tẹmpili, a si fi wura bọ ó ninu. Ọke aimoye naira ni wura ti a lọ lati fi kọ Tẹmpili. Ẹwa rẹ ko ṣe e fi ẹnu royin. Ile-isin gbogbo orilẹ-ede kan ni i ṣe. Gbogbo ijọsin ati iṣẹ-isin, niwọn igba ti a ba ṣe e tọkantọkan pẹlu igbagbọ; yoo mu ki ifarahan, agbara ati ogo Ọlọrun sọkalẹ. Ọna kan ti awọn orilẹ-ede yii le gba sun mọ Ọlọrun wọn ni yii.

Tẹmpili yii duro fun irinwo (400) ọdun. Awọn ara Babiloni ni o wo o lulẹ nigba ti wọn ko awọn Ju ni igbekun. Lẹyin aadọrin (70) ọdun, Ẹsra tun un kọ a si lo o fun ẹẹdẹgbẹta (500) ọdun. Hẹrọdu tun un ṣe o si wa fun aadọrun (90) ọdun si i. Ni nnkan bi aadọrin (70) ọdun lẹyin iku Oluwa wa ni awọn ara Romu wo o lulẹ. Lati igba naa ni awọn Ju ti tu kaakiri laaarin awọn orilẹ-ede, wọn ko si ni Tẹmpili tabi ibilẹ ti wọn titi di ọdun 1948, nigba ti awọn Ju tun di orilẹ-ede. Gẹgẹ bi asọtẹlẹ, a o tun Tẹmpili kó.

Idọgba Isin

Eto Ọlọrun ni pe ki gbogbo Israẹli jumọ jọsin ni ibi kan, ani ibi ti Oluwa yoo yàn (Deuteronomi 12:5). A fun wọn ni awọn ilana ati ajọ ti wọn ni lati maa ṣe (Ẹksodu 18:20; Lefitiku 23). Ogo Rẹ yoo kún Agọ naa (Ẹksodu 29:45; Lefitiku 26:11, 12; 1 Awọn Ọba 8:10, 11). Irubọ wà inu iṣẹ-isin wọn (Ẹksodu 10:25; Lefitiku 1:2; 2 Kronika 5:6), lilo ohun elo-orin, orin kikọ, iyin Oluwa, (2 Kronika 5:12, 13), adura (2 Kronika 6:13), kika Ọrọ Ọlọrun ati iwaasu (Ẹksodu 24:7; Deuteronomi 31:11; Nehemiah 8:5, 6). Wọn ni lati wa sibi isin (Ẹksodu 23:17; Deuteronomi 16:11). Wọn ni lati mọ ofin (Lefitiku 10:11), ki wọn si pa a mọ (Deuteronomi 16:12). “Ohunkohun ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin, ẹ ma kiyesi lati ṣe e: iwọ kọ gbọdọ bukún u, bẹẹni iwọ kọ gbọdọ bù kuro ninu rẹ” (Deuteronomi 12:32). Eniyan ẹlẹran ara ko le ran Ọlọrun lọwọ lati fi kun Ọrọ Rẹ tabi lati yọ kuro nibẹ. Lati ọpọ ọdun sẹyin ni awọn diẹ ti n ṣe eyi, ṣugbọn Ọrọ Ọlọrun wa duro titi lae (Isaiah 40:8). A sọ fun ni ninu Iwe Ifihan ohun ti yoo ṣẹlẹ si ẹni ti ó bá yọ kuro tabi ti o fi kún Ọrọ Ọlọrun (Ifihan 22:18, 19).

A n ṣe itọju ile Ọlọrun ati awọn iranṣẹ Ọlọrun lati inu idamẹwa ati ọrẹ atinuwa ti awọn eniyan mu wa (Deuteronomi 16:17; Numeri 18:21; Ẹksodu 25:2, 8). A yan awọn ẹya Lefi lati sin ati lati ṣe iranṣẹ awọn ohun mimó. Ninu ẹkọ yii, Mose paṣẹ fun awọn eniyan ki wọn ma ṣe alainaani ẹya Lefi.

Sinagọgu

Ni akoko awọn ọmọ Makabea, sáà kan lẹyin wolii Malaki ati ṣiwaju ibi Jesu, o fẹrẹ jẹ pe ilu kọọkan ni awọn Ju kọ sinagọgu si. Itumọ sinagọgu ni awujọ. Nigba miiran awọn eniyan a maa pejọ si eti odo tabi lẹba iṣan omi kékẹké lati jọsin (Iṣe Awọn Apọsteli 16:13). Sinagọgu kọọkan ni alaṣẹ tabi alufaa ti rẹ, a si n ka Ofin Mose tabi iwe awọn wolii ni Ọjọ Isinmi. Ni sinagọgu wọnyii ni Jeusu gbe lọ n kó awọn eniyan ni Ọjọ Isinmi. Ni Nasareti ni Jesu gbe wọ sinagọgu lọ ti O si ṣe iwaasu iyanu nì lati inu Iwe Isaiah ori ikọkanlelọgọta, “Gbogbo awọn ti o mbẹ ninu sinagọgu si tẹjumọ ọ. . . . . Gbogbo wọn si jẹri rẹ, ha si ṣe wọn si ọrọ ore-ọfẹ ti njade li ẹnu rẹ” (Luku 4:15-22). O ni lati jẹ pe sinagọgu ni awọn Onigbagbọ igba ni fi ṣe awokọ lati kó ile-isin wọn.

Imuṣẹ Majẹmu Laelae ninu Titun

Wiwa Jesu mu igba titun de, igba Ihinrere. Igba yii yoo jẹ akoko ti awọn olusin yoo sin lati ọkàn wa ti ki i ṣe aṣa tabi eto isin lasan ni wọn yoo maa tẹle. Ọlọrun yan iru-ọmọ Abrahamu bi eniyan ọtọ fun ara Rẹ. Nipasẹ orilẹ-ede yii, orilẹ-ede ti Ọlọrun yàn, Oun yoo fi eto igbala nla Rẹ hàn fun araye. Ofin ni olukọni lati mu wa wá si ọdọ Kristi. Irubọ, aṣa, áti eto rẹ jẹ ojiji awọn ohun rere ti o n bọ wa. Wọn ko le sọ awọn oluṣe rẹ di pipe. Bi wọn ba le ṣe bẹẹ, wọn ko ni dẹkun ati maa rubọ. O mu ti iṣaaju kuro ki o le fi idi ekeji mulẹ (Heberu 10:4, 9).

A bó si inu akoko Ihinrere yii nipasẹ ọna aaye ati ọna titun, ani Ẹjẹ Jesu. A bi wa sinu Ijọba Rẹ. A n pe e ni “ijọ-akọbi,” ti a kọ orukọ rẹ ni Ọrun. Nigba ti a ba tun wa bi, Ẹmi Ọlọrun sọ ọkàn kiku wa di aayẹ. A wa laayẹ, a di ẹda titun ninu Kristi Jesu. Nigba yii ni a le sin Ọlọrun ni ẹmi ati ni otitọ.

Isin Ti Ẹmi

Nigba ti obinrin ara Samaria ni n ba Jesu sọrọ, o wi pe, “Awọn baba wa sìn lori ọke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalẹmu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sin.” Jesu wi fun un pe, “Gbà mi gbó, obirin yi, wakati na mbọ, nigbati ki yio ṣe lori ọke yi, tabi ni Jerusalẹmu, li ẹnyin o ma sin Baba. Ẹnyin nsìn ohun ti ẹnyin kọ mọ: awa nsin ohun ti awa mọ: nitori igbala ti ọdọ awọn Ju wá. Ṣugbọn wakati mbọ, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sin Baba li ẹmi ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sin on. Ẹmi li Ọlọrun: awọn ẹniti nsin I ko le ṣe alaisin I li ẹmi ati li otitọ” (Johannu 4:20-24).

Nigba ti Jesu ba wọ inu ọkàn wa, ẹmi isin yoo wa nibẹ nigba gbogbo, sibẹ Ọlọrun fẹ ki a ni ibi ijọsin nibi ti a le pejọ pọ lati jọsin pẹlu orin, ẹri, adura, kika Ọrọ Ọlọrun ati iwaasu Ọrọ Rẹ.

Bi o ti dara bi o si ti dun to fun awọn eniyan mimọ Ọlọrun lati pejọ pọ lati sin Ọlọrun ni ẹmi ati ni otitọ. Iru isin bẹẹ ki i ṣe aṣà lasan. Ki iṣe eyi ti “ko ni ifarahan Ọlọrun.” Ko si labẹ igbekun aṣà tabi eto ti kọ ni laari. Ọkàn awọn olusin wà pẹlu ara wọn ni idapọ mimọ ati ifọkansin ninu ifẹ si Ọlọrun pẹlu ọkàn kan lati jọwọ ayé awọn fun Un, ki awọn ẹlẹṣẹ le mọ iṣina wọn, ki awọn Onigbagbọ si ri itọni gbà. Ipinnu wọn ni pe ki ohunkohun ma ṣe pa ina tabi di Ẹmi Mimọ lọwọ lọnakọna.

“Nibiti Ẹmi Oluwa ba si wà, nibẹ li omnira gbé wà” (2 Kọrinti 3:17). Nigba ti ohun gbogbo ba wa ni ikawọ Rẹ, a o ṣe ohun gbogbo tẹyẹtẹyẹ, letoleto, fun imuduro awọn ti pejọ. Ihinrere ti Arọkuro Ojo yii ti ri Ifarahan Ọlọrun ni ọna iyanu lati igba ti o ti bẹrẹ. Ko si eyi ti o tayọ itujade ologo wọnyii ninu Majẹmu Laelae, afi ti igba ti Ẹmi Ọlọrun jẹri si iṣẹ ati ifararubọ ti a ti ṣe boya ni akoko ti a n ya Tẹmpili Sọlomọni si mimó. Ogo ati ọla akoko ti a wa yii fi ara hàn ninu eyi pe a ko ṣofin pe ki a wa si Jerusalẹmu, tabi ibi kan gan an, ṣugbọn Ẹmi Mimọ a maa fara han nibikibi ti awọn ọkan ti ebi n pa ba gbe ke pe E. Ki i ṣe akoko ibukun nla nikan ni Ẹmi Ọlọrun n farahan. Nigba pupọ ninu awọn ohun wọnni ti o kere ti o si dabi ẹni pe ko ni laari ninu eyi ti ekinni fi ara kọ ekeji lati mu iṣẹ-isin pe, Ọlọrun ti tọ ni O si ti fi ifẹ Rẹ hàn wa dajudaju.

Awọn ti kọ ni anfaani lati le ba ni pejọ ni iru ipejọpọ bayii ni itunu ninu ileri ti Ọlọrun ṣe pe nibi ti ẹni meji tabi mẹta ba pejọ pọ ni orukọ Rẹ, pe Oun yoo wá saarin wọn. Nihin a tun le ri aanu Ọlọrun. Obinrin kan nibi kanga, agbẹ kan ninu oko, alagbaṣe nibi iṣẹ oojọ, ati awọn olusin laaarin awujọ, gbogbo wọn ni wọn le ri omi iye ati itọni ati itunu ẹmi ti wọn n fẹ gba – bi wọn ba jẹ fi tọkantọkan gboju soke pẹlu igbagbọ si Olufunni ni gbogbo ẹbun rere ati ẹbun pipe.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni Ọlọrun fẹ ki a ṣe si igbo oriṣa ati oriṣa nibi ti awọn keferi gbe n sin?
  2. Ta ni yoo yan ibi ti Israẹli yoo gbe maa jọsin?
  3. Bawo ni a ṣe ni lati ṣe itọju awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi?
  4. A ha le san idamẹwa si ibikibi ṣá?
  5. Njẹ a le fi kun Ọrọ Ọlọrun?
  6. Ki ni wọn ni lati fi ẹjẹ awọn ẹran ti a pa ṣe?
  7. Nibo ni ibi isin tootọ, lori oke ni Samaria tabi ni Jerusalẹmu?
  8. Awọn ibi kan pato ha wa fun isin Ọlọrun?
  9. Bawo ni a ṣe ni lati jọsin fun Ọlọrun?
  10. Darukọ oriṣiriṣi ile ti awọn Ju lo fun isin?