Deuteronomi 13:1-18; Galatia 1:6-9; 2 Johannu 9-11

Lesson 138 - Senior

Memory Verse
“OLUWA Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, on nikanṣoṣo ni ki iwọ mã sìn” (Matteu 4:10).
Cross References

IIkilọ Fun Awọn Wolii Eke ni Israẹli

1.Woli kan tabi alala le fi ami kan han ki o si ri bẹẹ ki o le mu ki awọn ẹlomiran bọ sinu idẹkun titẹle ọlọrun miiran lẹyin, Deuteronomi 13:1, 2; Jeremiah 14:14

2.Ki ẹnikẹni ma ṣe feti si i nitori Ọlọrun fẹ mọ bi awọn eniyan Rẹ fi gbogbo ọkàn wọn fẹ Ẹ, Deuteronomi 13:3; Jeremiah 5:30, 31

3.Wọn ni lati tẹle E, ki wọn gba ohùn Rẹ gbó, ki wọn si pa wolii tabi alala naa, Deuteronomi 13:4, 5

IIBi Woli Naa Ba Jẹ Ará tabi Ọrẹ

1.O le jé arakunrin, ọmọkunrin, ọmọbinrin, aya tabi ọrẹ ti o n tan ni labẹlẹ, Deuteronomi 13:6, 7; Orin Dafidi 41:9; Matteu 10:35, 36

2.Ki oun ki o ma ṣe feti si i, ṣugbọn ọwọ rẹ ni ki o kọkọ wà lara rẹ lati pa á, Deuteronomi 13:8, 9; Sekariah 13:3

3.Jẹ ki oun funra rẹ sọ ọ lokuta pa ki gbogbo Israẹli le bẹru, ki wọn si ranti igbala wọn kuro ni ilẹ Egipti, Deuteronomi 13:10, 11; Iṣe Awọn Apọsteli 5:10, 11

IIIBi Awọn Eniyan Ilu Kan ba Tẹle Ọlọrun Miiran

1.Awọn ọmọ Beliali le tan awọn eniyan lati lọ sin ọlọrun miiran, Deuteronomi 13:12, 13; 11:16

2.Bi o ba ri bẹẹ, ki Israẹli ki o pa wọn, ki o sun ilu naa, ki o si pa gbogbo ikogun, ki o si sọ ọ si okiti laelae, Deuteronomi 13:14-16; 7:25

3.Ki ọkan ninu ohun iyasọtọ naa ma ṣe mọ ọn lọwọ, Oluwa yoo si ṣaanu bi Israẹli ba pa awọn ofin Rẹ mó, Deuteronomi 13:17, 18

IVA Gegun lori Awọn Olukọni Eke

1.A mu awọn ara Galatia kuro ninu Ihinrere naa ti wọn ti gbagbọ tẹlẹ, sinu “ihinrere miran” Galatia 1:6; Heberu 13:9

2.Ko si ihinrere miiran, ṣugbọn awọn ti o n sin ẹsin awọn oniyapa Ju n fẹ yi Ihinrere ti Kristi pada, Galatia 1:7; Isaiah 8:20

3.Bi awa (Apọsteli), tabi angẹli kan lati Ọrun, tabi ẹnikẹni ba waasu ihinrere miiran, jẹ ki o di ẹni ifibu, Galatia 1:8, 9

4.Ẹ ma ṣe ba oluwarẹ dapọ ti o mu ẹkọ miiran wa lẹyin “ẹkọ Kristi,” 2 Johannu 9-11

Notes
ALAYE

Iha ti Ọlọrun Kọ si Igbọjẹgẹ labẹ Ofin

Kọ si ẹni ti o le fara balẹ ka Deuteronomi ori kẹtala ki o ma mọ pe oju Ọlọrun kan gidigidi si Igbọjẹgẹ. “Igbọjẹgẹ” ki i ṣe ọrọ ti a le ri ninu Bibeli, ṣugbọn ọrọ yii fi yé ni dajudaju iwa awọn ti o kọ Ọlọrun Israẹli silẹ, lẹyin ti wọn ti mọ Ọn ati ẹkọ Rẹ, ti wọn si yi pada si ọlọrun miiran ati ẹkọ miiran. Agbọjẹgẹ ni iru ẹni bẹẹ. Ninu Majẹmu Laelae, Balaamu jẹ apẹẹrẹ iru ẹni bẹẹ. Ẹri wà ninu Iwe Mimó pe ọkunrin yii ti mọ Ọlọrun tẹlẹ ri, ṣugbọn ki o ba le di olokiki ati ọlọla ayé yii, o kọ Ọlọrun Israẹli silẹ o si yipada si oṣó ati afọṣẹ. Nitori ọrọ, o fẹ fi awọn Ọmọ Israẹli bú, ṣugbọn bi o ti n lọ, o pade Angẹli Oluwa ti o fi iru ipo ti o wa han an bayii pe: “Ọna rẹ kọ tó niwaju mi.” Ṣugbọn Balaamu tẹ siwaju ninu iṣubu rẹ titi o fi mu ki Israẹli yipada si ibọriṣa awọn ara Midiani, ti ogunlọgọ ẹmi ṣegbe nitori bẹẹ, ti a si pa Balaamu paapaa.

Bi awọn Ọmọ Israẹli ti n sun mọ Ilẹ Ileri, a kilọ fun wọn ki wọn ki o ma ṣe ba awọn olugbe Kenaani dá majẹmu. Ṣugbọn wọn ni lati pa orilẹ-ede wọnyii run, ki Israẹli ma ba di alabapin ninu isin ibọriṣa ati irira wọn. “Ṣugbọn bayi li ẹnyin o fi wọn ṣe; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn, ẹ o si bi ọwọn wọn lulẹ, ẹ o si ke igbo oriṣa wọn lulẹ, ẹ o si fi iná jó gbogbo ere finfin wọn. . . . . Nitorina ki iwọ ki o mọ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ, on li Ọlọrun; Ọlọrun olõtọ, ti npa majẹmu mó ati ãnu fun awọn ti o fé ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ mó dé ẹgbẹrun iran; Ti o si nsan a pada fun awọn ti o korira rẹ li oju wọn, lati run wọn: on ki yio jafara fun ẹniti o korira rẹ, on o san a fun u loju rẹ” (Deuteronomi 7:5, 9, 10). Ibinu Ọlọrun gbona o si koro gidigidi si ibọriṣa ati irira lọnakọna ti o wu ki o jẹ, bi O ti fi han ninu ikilọ Rẹ si awọn Ọmọ Israẹli fun iyipada si ọlọrun miiran. Bi awọn ọmọ Beliali ba tan eyikeyi ninu awọn ilu wọn jẹ ti wọn si bọriṣa, ti wọn si yipada si ọlọrun miiran, awọn Ọmọ Israẹli ni lati pa wọn, ki wọn si fi ina sun ilu wọn, ki wọn pa ohunkohun ti wọn ba ko nibẹ run, ki wọn si sọ ilu naa di okiti titi lae. Oluwa si tun wi pe, “Ki ọkan ninu ohun iyasọtọ na má si ṣe mó ọ lọwọ; ki OLUWA ki o le yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ, ki o si ma ṣãnu fun ọ, ki o si ma ṣe iyọnu rẹ, ki o si ma mu ọ bisi i, bi o ti bura fun awọn baba rẹ”

Iha ti Ọlọrun kọ si Igbọjẹgẹ labẹ Oore-ọfẹ

Niwọn igba ti Ọlọrun ti sọ ninu ori kẹtala Deuteronomi ati nibomiran gbogbo ninu Majẹmu Laelae pe oju Oun kan si igbọjẹgẹ, a le maa beere pe, Iha wo ni Ọlọrun kọ si igbọjẹgẹ ni akoko oore-ọre yii. Awọn ẹlẹsin miiran sọ pe labẹ Ofin, Ọlọrun binu si awọn orilẹ-ede kan a si fi idajọ Ọlọrun bẹ wọn wo. Ṣugbọn wọn gba pe nisisiyii, a wa labẹ oore-ọfẹ; wọn si fi Ọlọrun han bi Ọlọrun ifẹ -- dajudaju, otitọ ni eyi. “Nitoripe nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wa” (Johannu 1:17). Ṣugbọn otitọ ni eyi pe, Ọlọrun idajọ ni Oun i ṣe sibẹ. Ọlọrun ofin ati ifẹ ni Oun i ṣe, kikoro oju Rẹ si ẹṣẹ ko yi pada rara, ki yoo si fara mọ ọn laelae lọnakọna bi o ti wu ki o ri. Lai si tabitabi, idajọ Ọlọrun n bọ lori ayé buburu ati ayé ẹṣẹ yii, gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun ti ko le yipada.

Nitori naa ẹ jẹ ki a wo ohun ti Majẹmu Titun sọ nipa igbọjẹgẹ. Paulu Apọsteli, ninu irin-ajo rẹ nigba ti o n waasu kaakiri bẹ ẹkùn Galatia wo nibi ti awọn eniyan naa fi tayọtayọ gbọ ọrọ rẹ. Labẹ iwaasu rẹ, ọpọlọpọ ninu wọn gbagbọ, a si ka wọn kun agbo ijọ Ọlọrun, Paulu Apọsteli si da ijọ silẹ nibẹ pẹlu (Galatia 1:2). Wọn bẹrẹ daradara, ṣugbọn lai pẹ awọn ẹlẹsin ofin bẹrẹ si gboke gbodo nibi ti Paulu ti waasu tẹlẹ, wọn si n yi awọn ti o ṣẹṣẹ gbagbọ lọkan pada si Ofin Mose, bi o tilẹ jẹ pe akoko ofin ti kọja ti ogo rẹ si ti wọmi nigba ti imọlẹ Ihinrere mọ, bi itanṣan oorun ti n bo irawọ imọlẹ nigba ti oorun ba yọ (2 Kọrinti 3:7, 8, 11; Heberu 8:13). Awọn ẹlẹsin kan wa lode oni ti wọn n waasu ohun kan naa ti awọn olofin ti igba ni n waasu. Awọn alakoso rẹ fẹ mu awọn Onigbagbọ wa si abẹ Ofin ti o ti kọja lọ nigba ti Majẹmu Titun de; nitori naa ẹkọ eke ni ẹkọ wọn; ti Paulu Apọsteli si ti da ṣiọ rẹ ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin. O sọ bayii ninu Episteli rẹ si awọn ara Galatia pe “Ẹnu yà mi nitoriti ẹ tete kuro lọdọ ẹniti o pẹ nyin sinu ore-ọfẹ Kristi, si ihinrere miran: Eyiti ki iṣe omiran; bi o tilẹ ṣe pe awọn kan wà ti nyọ nyin lẹnu, ti nwọn si nfẹ yi ihinrere Kristi pada. Ṣugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọrun wá, li o ba wasu ihinrere miran fun nyin ju eyiti a ti wasu fun nyin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu. Bi awa ti wi ṣaju, bẹẹni mo si tún wi nisisiyi pe, Bi ẹnikan ba wasu ihinrere miran fun nyin jù eyiti ẹnyin ti gbà lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu” (Galatia 1:6-9). O han gbangba lati inu awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii pe egun Ọlọrun wà lori awọn wolii eke ti o n yi awọn ọmọ Ọlọrun lọkan pada kuro ninu Otitọ.

Nipa Ihinrere ti Paulu waasu rẹ fun awọn ara Galatia, o sọ bayii ninu Episteli rẹ si awọn ara Romu pe, “Nitori emi kọ tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbó; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu” (Romu 1:16). Nipa Ofin, Apọsteli kan naa sọ bayii pe, “Nitori Kristi li opin ofin si ododo fun olukuluku ẹniti o gbagbó” (Romu 10:4). “Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a ki yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ” (Romu 3:20). “Nitorina ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbó” (Galatia 3:24).

Nitori naa bi ẹnikẹni ti o ba ti di ominira ninu Jesu Kristi, ba tun feti si ijiyan ti awọn iranṣẹ eṣu, ti o ba si yọ diẹ kinun kuro ninu awọn ẹkọ Bibeli wọnni ti o ti n bẹ ni ọkàn rẹ, iru ẹni bẹẹ kọ si ninu oore-ọfẹ mọ -- o ti di ẹni itiju, o si ti pada sinu igbekun ẹṣẹ. Ki i ṣe ohun ti o rọrun fun iru ẹni bẹẹ lati le yọ bọ kuro ninu ajaga ti eṣu ti fi bọ ọ lọrun. Bi o ti buru to niyii lati gbọjẹgẹ lọnakọna nipa Otitọ ti Ọlọrun ti fi han fun ni. Johannu Apọsteli kọwe lori ọran yii pe: “Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ẹre kikún gbà. Olukuluku ẹniti o ba nru ofin ti kọ si duro ninu ẹkó Kristi, kọ gba Ọlọrun. Ẹniti o ba duro ninu ẹkó, on li o gbà ati Baba ati ọmọ. Bi ẹnikẹni bá tọ nyin wá, ti kọ si mu ẹkó yi wá, ẹ máṣe gbà a si ile, ki ẹ má si ṣe ki i. Nitori ẹniti o ba ki i, o ni ọwó ninu iṣẹ buburu rẹ” (2 Johannu 8-11).

“Kiyesi i, emi mbọ nisisiyi: di eyiti iwọ ni mu ṣinṣin, ki ẹnikẹni ki o máṣe gbà ade rẹ” (Ifihan 3:11).

Iyapa ti Igba Ikẹyin

Paulu Apọsteli sọ tẹlẹ pe ki Jesu to pada wa “iyapa” ko le ṣalai kọ de ki a si fi “ẹni ẹṣẹ ni” hàn, ati Aṣodi si Kristi: “Ẹ máṣe jẹki ẹnikẹni tàn nyin jẹ lọnakọna: nitoripe Ojọ na ki yio de, (eyi ni ọjọ dide Oluwa), bikoṣepe iyapa ni ba kó de, ki a si fi ẹni ẹṣẹ ni hàn, ti iṣe ọmọ ẹgbé” (2 Tẹssalonika 2:3). Itumọ “iyapa” nihin yii ni iṣubu tabi iyipada kuro ninu Igbagbọ. Akoko iyapa ti Paulu sọtẹlẹ nipa rẹ ti de. Awọn ijọ miiran ti wọn ti ni agbara ati ibarẹ Ọlọrun laaarin wọn, ti sé awọn ẹkọ ipilẹṣẹ ti inu Bibeli ti i ṣe odi agbara fun awọn Ijọ Onigbagbọ. Ki ni abayọri rẹ? Awọn Ijọ wọnyi ko ni agbara Ọlọrun mọ, Ẹmi Ọlọrun ti fi abayọri rẹ? Awọn Ijọ wọnyii ko ni agbara Ọlọrun mọ, Ẹmi Ọlọrun ti fi wọn silẹ, wọn ti di oku. Wọn ti kọ Orisun Omi Iye silẹ, wọn si gbẹ kanga omi fun ara wọn, kanga fifọ ti ko le gba omi duro. Ọkan ninu awọn Ijọ ti o ti kun fun ina Ẹmi tẹlẹ ri, ti isọji rẹ ti gba ilu oyinbo ati Amẹrika kan lẹẹkan ri, ti pa ẹkọ wọnni yii ti awọn ijọ rẹ duro le lori tì ni igba ikẹyin yii, wón si ti fara mọ igbagbọ igbalode. Iyapa awọn ijọ wọnyii kuro ninu Igbagbó jẹ apẹẹrẹ ti o ba ni lẹru nipa ohun ti o le jẹ abayọri kikọ Otitọ Ọrọ Ọlọrun silẹ.

Episteli Paulu to kọ kẹyin si Timoteu kun fun ọrọ ṣiri: “Nitorina mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ẹniti yio idajọ alãye ati okú, ati nitori ifarahàn rẹ ati ijọba rẹ. Wasu ọrọ na; ṣe aisimi li akokọ ti o wọ, ati akokọ ti kọ wọ; baniwi, ṣe itóni, gbà-ni-niyanju pẹlu ipamọra ati ẹkó gbogbo. Nitoripe igba yio de, ti nwọn ki yio le gba ẹkó ti o yẹ koro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrin nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. Nwọn ó si yi etí wọn kuro ninu otitọ, nwọn ó si yipada si itan asan” (2 Timoteu 4:1-4). A le sọ lọjọ oni pe, igba naa ti de ti awọn eniyan ko le gba ẹkọ ti o ye kooro.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ikilọ ti Ọlọrun ṣe fun Israẹli nipa awọn orilẹ-ede miiran nigba ti wọn ba de Ilẹ Ileri?
  2. Ewu wo ni o wà fun wọn ni didapọ pẹlu orilẹ-ede wọnyii?
  3. Iru iha wo ni Ọlọrun kọ si ẹni ti o ba kọ Ọlọrun Israẹli silẹ lati tọ ọlọrun miiran lẹyin?
  4. Ijiya wo ni o wà fun ẹni ti o ba ṣe eyi?
  5. Ki ni a ni lati ṣe si wolii ti o ba mu ki awọn Ọmọ Israẹli tọ ọlọrun miiran lẹyin?
  6. Bi iru wolii bẹẹ ba jé ibatan tabi ọrẹ ti o sun mọ ni; ta ni o ni lati kó ṣe idajọ rẹ?
  7. Bi odidi ilu kan ba tọ ọlọrun miiran lẹyin, ki ni a ni lati ṣe si awọn eniyan ti o n gbé ibẹ, ilu naa ati ikogun rẹ?
  8. Iru iha wo ni Ọlọrun kọ si ẹni ti o ba kọ ẹkọ Rẹ silẹ labẹ oore-ọfẹ ti o si yipada si ẹkọ miiran?
  9. Ki ni itumọ ọrọ wọnyii ti a maa n ba pade lẹẹkọọkan ninu Majẹmu Titun, “ẹkó Kristi”?
  10. Iha wo ni o yẹ ki Kristiani kọ si ẹni ti o bá wá ti kọ si mu ẹkọ Kristi wá?