Deuteronomi 19:1-21; Joṣua 20:1-9

Lesson 139 - Senior

Memory Verse
“Ọlọrun li àbo wa ati agbara, lọwọlọwọ iranlọwọ ni igba ipọnju” (Orin Dafidi 46:1).
Cross References

IIlana Ọlọrun fun Aabo Awọn Ọmọ Israẹli ti o Ṣeeṣi Paniyan

1.A o pin Kenaani si ọna mẹta, ilu aabo yoo si wa ni ibi kọọkan, Deuteronomi 19:1-3; Joṣua 20:7

2.Ilu ti o wa ni iha ila-oorun Jordani ni a o pin si ipa mẹta, yoo si ni ilu aabo mẹta pẹlu, Deuteronomi 19:7-9; 4:41-43; Numeri 35:9-14; Joṣua 20:8

3.Gẹgẹ bi ofin, apaniyan ni lati kú, ibatan ẹni ti a pa ni yoo si pa a, Deuteronomi 19:21; Gẹnẹsisi 9:6; Ẹksodu 20:13; 21:12; Lefitiku 24:17-22; Numeri 35:16-21, 29, 30; Owe 28:17

4.A ki yoo fi iku ṣe iya fun ipaniyan aimọọmọ. Ọlọrun ya awọn ilu aabo sọtọ lati daabo bo apaniyan naa, Deuteronomi 19:4-10; Joṣua 20:1-6, 9

5.Ọdaran naa ni lati wa ni ilu aabo naa lati fara pamọ, Numeri 35:22-28

6.Labẹ eto yii, a ki yoo yi idajọ po, ṣugbọn a o mu idajọ ṣẹ, Deuteronomi 19:11-13, 15; Numeri 35:31-34

7.Ijẹri eke jẹ ẹṣẹ ti o tobi, Deuteronomi 19:16-19

8.A ṣe ilana ijiya fun ẹṣẹ amọọmọ-dá lati jẹ apẹẹrẹ fun awọn ẹlomiran, Deuteronomi 19:20, 21

IIAabo fun Wa ninu Kristi

1.Ẹlẹṣẹ n fẹ ibi aabo kan nitori

(i)Egun ofin ti o ti rú, Galatia 3:10;

(ii)Idajọ Ọlọrun, Nahumu 1:3;

(iii)Ẹbi ẹṣẹ, Romu 3:19;

(iv)Agbara ẹṣẹ ati ti Satani, Romu 6:14; Kolosse 1:12, 13;

(v)Ibinu ti n bọ 2 Tẹssalonika 1:7-9

2.Ọlọrun pese aabo ninu Kristi, o si to fun gbogbo eniyan, gbogbo eniyan ni o le de ibẹ, o si le tan aini gbogbo, Johannu 3:16; 14:5, 6; 10:27-29; Ifihan 22:17; Orin Dafidi 9:9; 27:1-14; 57:1; 62:7, 8; 142:4-7

3.A ni lati maa gbe Ibi-aabo naa lati wà ni ipamọ Rẹ, Johannu 14:6; 15:4-7; Heberu 6:17-19

Notes
ALAYE

Apẹẹrẹ ti Igba Ihinrere

Eyi jẹ omiran ninu ọpọlọpọ eto ti o wà ninu Majẹmu Laelae, ti a da silẹ, ki i ṣe fun anfaani ti ara fun Israẹli nikan ṣugbọn wọn jẹ apẹẹrẹ tabi ojiji ti otitọ pataki ti Ihinrere – Ilu aabo ti Ọlọrun yàn fun anfaani awọn Ọmọ Israẹli ti o ba pa eniyan, ki a ma ba ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ lai tọ, jẹ apẹẹrẹ aabo ti a le ni ninu Ọlọrun, nipasẹ Kristi Jesu, kuro lọwọ ijiya ẹṣẹ.

Awọn ibukun Israẹli nipa ti ara jẹ apẹẹrẹ awọn ibukun ti ẹmi ti a le ni nigba Ihinrere yii. Wọn jogun ilẹ ti o n ṣan fun wara ati oyin ti o si kun fun ọpọlọpọ ohun alumọni. A ṣeleri “Kenaani ti ẹmi” fun wa, ti o n tán gbogbo aini nipa ti ẹmi, ọpọ ibukun ti o n ṣan lati Orisun Omi Iye wa, ani Ọlọrun Olodumare, nipasẹ Jesu Kristi, Ọmọ Rẹ.

Ofin Nipa Ipaniyan

Bi ẹni kan ba paniyan, ni akoko Majẹmu Laelae, a ni lati ṣe idajọ ki a si jẹ ẹlẹbi niya. Kaini, apaniyan kin-in-ni, mọ iwuwo idajọ Ọlọrun ti o wa lori rẹ, o wi pe, o pọ ju ohun ti oun le fara da, niwọn igba ti oun yoo jẹ isansa ati alarinkiri lori ilẹ ayé. Ofin lile ti igba ni ni pe, “Ẹnikẹni ti o ba ta ẹjẹ enia silẹ, lati ọwó enia li a o si ta ẹjẹ rẹ silẹ”(Gẹnẹsisi 9:6). Lai si aniani bi akoko ti n lọ, ọpọlọpọ ni o ti jiya lai tọ nipa ikanju ati aṣiṣe olugbẹsan. Nitori ki a le mu ofin mimọ Ọlọrun ṣẹ pẹlu iru ẹmi ti a fi ṣe ofin wọnyii ati fun anfaani awọn eniyan Rẹ, Ọlọrun ṣe eto ti o wà niwaju wa ninu ẹkọ yii, ki o ma ba si aṣiṣe ki a si le ki aiṣootọ wọ.

Ipaniyan jẹ ẹṣẹ ti o wuwo lọpọlọpọ. Iyatọ wà ninu ipaniyan ati ṣiṣeeṣi-paniyan. Ki a paniyan pẹlu ikorira, arankan, ikannu tabi ki o jẹ pe pẹlu ọkan lati gbẹsan ni a n pẹ ni ipaniyan. Ṣugbọn ki a ṣeeṣi paniyan, lai ni ikorira, arankan, ikannu tabi ọkàn igbẹsan si ẹni ti a pa ni a n pẹ ni ṣiṣeeṣi-paniyan. Ọlọrun tikara Rẹ ni Olupilẹṣẹ ẹmi eniyan, ko si ẹni ti o ni ẹtọ lati fi opin si ẹmi naa bi ko ṣe Ọlọrun tikara Rẹ. Oriṣiriṣi ọna ni O n gba fi opin si i, nigba miiran lati ọwọ alaṣẹ ilu ti O ti fi ida lé lọwọ, ki wọn ki o ba le ṣakoso riru ofin.

Akoko ti a ba wa láàyẹ ni a le mura silẹ fun ayeraye, nigba miiran igbala ẹlomiran rọ mó ẹmi gigun rẹ. Nitori naa o ṣe danindanin ki eniyan lo iye ọjọ aye ti Ọlọrun fi fun un de opin, ki ẹlẹbi le ni anfaani ti o tọ lati ronupiwada ki o si ba Ọlọrun laja. Nitori naa ẹni ti o ba gba ẹmi ẹlomiran ṣiwaju akoko rẹ jẹ olupa ara ati ẹmi rẹ, a si ni lati ṣe ofin ti o le gidigidi nipa iru iwa bẹẹ, fun ijẹniya ati lati gbá iwa irufin wọlẹ.

Awọn ẹṣẹ miiran wa ti o ni idajọ iku labẹ Ofin Mose, bi agbere, blasfemi si Ọlọrun, biba ọjọ Isinmi jé, tabi ki ọmọ ṣọtẹ. Ṣugbọn awọn ẹṣẹ wọnyii ki i ṣe eyi ti o le ru ibinu awọn eniyan soke si arufin naa nitori naa ko wọpọ pe ki ẹnikẹni dide lati kọlu ọdaran naa lati pa a ni aitọ. Ṣugbọn nigba ti a ba mọọmọ tabi ṣeeṣi paniyan, ibinu awọn ẹbi rẹ a rú soke, awọn ibatan rẹ ti o wa laaye le pa ẹlomiran tabi apaniyan ti ko jẹbi, lati gbẹsan, nitori igbona ara nipa ibatan rẹ ti a pa ko ni jẹ ki o le ronu bi o ti tọ fun iwọn igba diẹ. Wọn yoo ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ, wọn yoo si ti ipa bẹẹ ṣi ofin ti Ọlọrun fi lelẹ nipa apaniyan lọ, nipa bayii wọn o mu ẹgan ba ofin Ọlọrun.

Aabo Ọlọrun fun Alaiṣẹ

A yan ilu mẹfa, ni ibi mẹfa ọtọọtọ ni ilẹ naa. Wọn wa ni aarin ilu, ọna gbooro pupọ si wọ inu rẹ lọ, a ko si gbọdọ fi ohun idabu tabi idigbolu kankan sọna wọnyii, awọn opitan sọ fun ni pe a kọ akọle yii sibẹ -- “Aabo.” Bi ẹnikẹni ba ṣeeṣi paniyan, o ni ẹtọ lati sare lọ si ọkan ninu ilu wọnyii fun aabo titi ewu yoo fi kọja lori rẹ.

Dajudaju awọn ẹlomiran ti ko ni ẹtọ si anfaani yii ko ni ṣalai sá wá si ilu wọnyii, nitori bẹẹ a ṣe eto kan lati mu Ofin Ọlọrun ṣẹ ati lati daabo bo alaiṣẹ ki a si ṣe idajọ otitọ. Nigba ti ẹnikan ba paniyan, ti a si ri apaniyan naa ni ilu aabo, a o mu un wa siwaju awọn alaṣẹ ilu, wọn o si ṣe iwadi ọran rẹ. Bi ko ba jẹbi, eyi ni pe, o ṣeeṣi paniyan lai si ikorira, arankan tabi fun igbẹsan, wọn o gba a láyẹ lati maa gbe ilu aabo titi iku olori alufaa. Bi o ba fi ilu aabo silẹ ṣiwaju iku olori alufaa, o wà labẹ ewu pipa lati ọwọ olugbẹsan ẹjẹ, ẹni ti i ṣe ibatan timọtimọ ti o sun mọ ẹni ti oun ti ṣeeṣi pa.

Ko si iru anfaani yii fun ẹni ti o fi mọómọ paniyan. Ẹni naa ni lati jiya fun ẹṣẹ rẹ. Nigba ti o ba wa siwaju awọn alaṣẹ, ti wọn si gbọ ẹjọ rẹ, wọn yoo sọ bi o jare tabi o jẹbi ipaniyan. A o fi apaniyan le olugbẹsan ẹjẹ lọwọ, lati mu idajọ ṣẹ lori rẹ gẹgẹ bi a ti lana rẹ silẹ ninu Ofin Ọlọrun. Ẹlẹri kan ko to lati jẹri ọran ẹni ti a o da lẹbi iku. A ni lati mu ẹlẹri meji tabi mẹta wa, ẹri wọn si ni lati dọgba lọna gbogbo. Olugbẹsan ẹjẹ ko le gba abẹtẹlẹ lati yi idajọ po, ẹni ti o ba jẹri eke ni a o mu bi ẹlẹbi fun ẹṣẹ ti oun fi ẹlomiran sun fun. A ko ri i kà ninu Bibeli pe eto Ọlọrun nipa ilu aabo wọnyii kuna lọnakọna, tabi pe ẹnikẹni ṣi anfaani yii lọ.

Awọn ilu ti a yàn jẹ eyi ti awọn ọmọ Lefi n gbé. Eyi fi han pe awọn ti o ba sa lọ sibẹ fun aabo yoo ba awọn eniyan Ọlọrun pade nibẹ ti a ti yàn lati maa kọ ni ni Ofin. Wọn o ba awọn eniyan Ọlọrun kẹgbẹ, wọn yoo sun mọ Ọlọrun, wọn yoo si tubọ mọ nipa Ọlọrun ati ọna Rẹ ni akoko ti wọn yoo fi wà nibẹ.

Kristi, Aabo Wa

Awọn ẹlomiran ti gbiyanju lati ṣe àlàyé ati ifiwera ti o gbadun laaarin orukọ ilu wọnyii ati awọn ibukun ti igbala ti a ti pese fun ẹlẹṣẹ. Eyi fẹrẹ ma jamọ nnkan kan. Sibẹ, wi pe awọn ilu wọnyii jẹ apẹẹrẹ daradara nipa Kristi, jẹ otitọ kan pataki ti gbogbo awọn akẹkọọ Bibeli fara mọ.

Kristi ni ilu aabo wa nibi ti a n sá sí nigba ti ọta ba n le wa; bi a ba ti wọle, a wa ni ailewu. Ofin ko lagbara lori wa mọ. Idalẹbi ko ni si mọ. A bọ lọwọ ẹbi ẹṣẹ ati irekọja wa. Iyatọ kan wà lọna kan ninu apẹẹrẹ ti ilu aabo jẹ, ati imuṣẹ apẹẹrẹ naa. Awọn ti o le wa lailewu ninu ilu aabo ni awọn ti o ṣeeṣi paniyan nikan, ṣugbọn ninu Kristi, aabo wà fun gbogbo eniyan -- niwọn igba ti gbogbo awọn ti o jẹbi ẹṣẹ le ri aabo ati idariji gbà ninu Rẹ.

Nigba ti a tọ Ọlọrun wá, gbogbo wa ni a jẹbi ẹṣẹ ti a mọómọ dá ati riru ofin Ọlọrun. Ṣugbọn aanu Ọlọrun jinlẹ o si pọ to bẹẹ gẹẹ, ti oore-ọfẹ a maa tẹwọ gba wa nigba ti a ba sa si ibi aabo bi o ti wu ki ẹṣẹ wa pọ to, tabi ki o buru to, bi o si ti wu ki ẹru ẹṣẹ wuwo to. Kristiani, ẹni kan pataki ninu “Iwe Ilọsiwaju Ero Mimó,” sare lọ si ẹnu ọna kekeré naa o fi ọwọ di eti rẹ ki o maa ba gbọ igbe awọn ti o fẹ pa a laya dà, o si n ke bi o ti n sare pe “Iye! Iye!”

Awa pẹlu le ni “idakọro ọkàn, ireti ti o daju ti o si duro ṣinṣin, ti o si wọ inu ile lọ lẹhin aṣọ ikele; nibiti aṣaju wa ti wọ lọ fun wa, ani Jesu, ti a fi jẹ Olori Alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.’ Niwọn igba ti Oun ti jé Olori Alufa titi lae, a kọ ni lati fi ibi aabo naa silẹ. Agbara Rẹ yoo pa wa mọ niwọn igba ti a ba wa labẹ iṣọ Rẹ. Ọwọ ara wa ni a fi le fa ara wa jade kuro labẹ aabo Rẹ. A le ni ibarẹ ati ibalo Rẹ titi lae. Titobi ni aanu Ọlọrun!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ofin Ọlọrun nipa ipaniyan lati ayebaye?
  2. Amuyẹ wo ni ilu aabo kọọkan ni lati ni, ki wọn to le wulo fun awọn eniyan?
  3. Awọn ta ni ni anfaani aabo ni ilu wọnyii? Nigba wo ni akoko aabo wọn pin?
  4. Darukọ ilu mẹfa naa.
  5. Ki ni ohun daradara ti o fi ara jọ ipo ati igbesi aye Kristi ti iwọ ri ni ilu aabo yii?
  6. Ki ni itumọ nipa ti ẹmi ti a le fi fun Heberu 6:17-19 ninu ẹkọ wa yii?
  7. Wo inu Iwe Mimọ fun itumọ “aabo” ki o si wo bi ireti wa nipa ayeraye ti rọ mọ otitọ Bibeli yii.
  8. Ihinrere Johannu ori keloo ni o sọ fun ni bi o ti ṣe danindanin to lati maa gbe inu Kristi? Fara balẹ ka a pẹlu adura.
  9. Sọ fun ni bi ẹkọ yii ṣe tako ẹkọ odi ti o sọ fun ni pe bi a ba ti ri igbala lẹẹkan ri, a wa labẹ aabo titi lae?
  10. A jẹ ẹnikẹni ti o ba jẹbi ipaniyan niya fun ẹṣẹ rẹ labẹ eto yii. Bawo ni eyi ṣe fara jọ awa, bi o tilẹ jẹ pe a ti dẹṣẹ, ṣugbọn ti a le sa di Kristi fun aabo? Ewo ninu iwa Ọlọrun ni o mu ki eyi ṣe e ṣe?