Lesson 140 - Senior
Memory Verse
“Emi ha ni inu-didùn rara pe ki enia buburu ki o kú? ni OLUWA Ọlọrun wi: kọ ṣepe ki o yipada kuro ninu ọna rẹ, ki o si yẹ?” (Esekiẹli 18:23).Cross References
IAanu Nlá Nlà fun Awọn ti O Ronupiwada
1.Oluwa ṣeleri lati yi igbekun awọn Ọmọ Israẹli pada bi wọn ba ronupiwada ti wọn si yipada si Ọlọrun, Deuteronomi 30:1-3; 1 Awọn Ọba 8:46-52; Johannu 8:32-36
2.Ọlọrun yoo kó awọn eniyan Rẹ jọ lati gbogbo orilẹ-ede wa ati lati iha opin Ọrun wa, Deuteronomi 30:3, 4; Nehemiah 1:4-11; Sẹkariah 8:7, 8
3.A o tun mu awọn Ọmọ Israẹli pada si Ilẹ Ileri, Oluwa yoo si ṣe wọn ni oore ni ọjọ ti wọn ba yi pada si I, Deuteronomi 30:5-9; Isaiah 62:1-5; Luku 15:6-10, 12-24
4.Ileri wọnyii duro lori bi awọn Ọmọ Israẹli yoo ba pa ofin Ọlọrun mó pẹlu gbogbo àya wọn, Deuteronomi 30:6, 10; Esekiẹli 18:21, 22; 33:11, 19; Matteu 22:36-40
IIOfin Ọlọrun Ko Pamọ
1.Oluwa, nipasẹ Mose, tẹnu mọ otitọ yii pe ofin Ọlọrun wa nitosi, o si rọrun lati ye ni, Deuteronomi 30:11; Orin Dafidi 147:19, 20; Isaiah 45:19
2.A ko fi ofin naa si Ọrun, Deuteronomi 30:12; Johannu 1:9, 10, 14
3.A ko fun Ọrọ naa ka si iha keji okun ti Israẹli i ba fi ni lati ranṣẹ lati mu un, Deuteronomi 30:13; Matteu 12:42; Iṣe Awọn Apọsteli 8:35
4.Bi a ba fi tinutinu wá Ọrọ naa, a o ri I “li ẹnu rẹ, ati li àiya rẹ,” Deuteronomi 30:14; Romu 10:8, 10
IIIIku ati Iye ninu Eyi Ti A le Yàn
1.Oluwa fi siwaju Israẹli ati gbogbo eniyan, iye ati ire, iku ati ibi, Deuteronomi 30:15; Marku 16:16; Johannu 3:16
2.Lati maa fẹ Oluwa, lati maa rin ni ọna Rẹ, ati lati maa pa aṣẹ Rẹ mọ, yoo mu ibukun Ọlọrun ba Israẹli ni ilẹ naa ti wọn n lọ lati gbà, Deuteronomi 30:16; Johannu 14:21
3.Egun Ọlọrun ni a o fi le ori awọn ti o kọ lati gbó ti Ọlọrun, ati lori gbogbo awọn ti o ba yi pada lati sin oriṣa, Deuteronomi 30:17, 18; Joṣua 23:15, 16; Heberu 12:25
4.Mose gba awọn Ọmọ Israẹli niyanju lati fẹ Ọlọrun ati lati yan iye ki awọn ati awọn ọmọ wọn le wà pé ni ilẹ naa, Deuteronomi 30:19, 20; Luku 10:42; Iṣe Awọn Apọsteli 2:38-40
Notes
ALAYEEto Ọlọrun
A ni lati gba awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti o wa ninu iwe yii bi ileri, ti a gbọdọ ṣe ohun kan ki a to ri i gba; nitori naa wọn ki i ṣe fun Israẹli nikan ṣugbọn fun gbogbo eniyan agbaye pẹlu. Ohun ti ori iwe yii n fi ye ni daju ni pe bi ẹlẹṣẹ ti o buru ju ba ronupiwada ti a si yi wọn pada a o dari ẹṣẹ wọn ji wọn, wọn yoo si ri oju rere Ọlọrun. Ọpọlọpọ ileri iyanu ni o wà ninu Ọrọ Ọlọrun fun awọn ti o ba ronupiwada, ani ninu Majẹmu Laelae paapaa; a si rii pe gbogbo ohun ti Majẹmu Oore-ọfẹ si mu wa ni igbala ọkan ti ki i ku ati ilaja laaarin eniyan pẹlu Ọlọrun. “Otitọ li ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà, pe Kristi Jesu wá si aiye lati gbà ẹlẹṣẹ là; ninu awọn ẹniti emi jẹ pàtaki” (1 Timoteu 1:15).
Israẹli ninu Igbekun
Ṣiwaju igba ti awọn Ọmọ Israẹli de Ilẹ Kenaani, Oluwa ti ri i pe wọn yoo da majẹmu wọn pẹlu Oun, wọn yoo si maa sin oriṣa. Nitori ẹṣẹ yii, Ọlọrun ṣeleri pe Oun yoo le Israẹli lọ si oko-ẹru laaarin awọn orilẹ-ede. Ninu igbekun wọn, bi Israẹli ba ranti ẹgun ati ibukun ti Ọlọrun fi siwaju wọn, ti wọn si ke pe Ọlọrun, ti wọn si yi pada si Oluwa Ọlọrun wọn lati gbọran si aṣẹ Rẹ, Ọlọrun ṣeleri lati yi igbekun wọn pada, yoo si ṣaanu fun awọn Ọmọ Israẹli.
Ifiyesi ni iṣisẹ kin-in-ni si iyipada ọkàn. “Ẹ gbà a si ọkàn, ẹnyin alarekọja” (Isaiah 46:8). Iye ọmọ onikuna kó sọji ná, o si wa ranti anfaani ti ko loṣuwọn ti ó wà ni ile baba rẹ. Bi ẹlẹṣẹ yoo ba ronu gidigidi nipa alaafia ati ayọ ti wọn ti padanu nipa ẹṣẹ, ati iṣé on iyà ti wọn kó ba ara wọn, bi wọn ba le ronu pe nipa ironupiwada, wọn yoo bó lọwọ iṣé on iyà naa, wọn yoo si ni alaafia, wọn yoo pada sọdọ Ọlọrun kiakia.
Lati pada tọ Oluwa lọ, ati ipinnu lati gba ohun Rẹ gbọ ni koko pataki ti ó wà ninu ironupiwada. Lai si iwọnyi, asan ni gbogbo ohunkohun ti a le ṣe lati fi han pe a ronupiwada. Ohun ti o tọna gan an ni ọmọ oninakuna ṣe nigba ti o dide ti o si lọ si ile baba rẹ. Bi o ba jokoo ti agbo ẹlẹdẹ, ebi ni yoo pa a ku bi o ti wu ki o maa ranti ile ati ọpọ ounjẹ ajẹti ti o wà lọhun to. “Jẹ ki enia buburu kọ ọna rẹ silẹ, ki ẹlẹṣẹ si kọ ironu rẹ silẹ: si jẹ ki o yipada si OLUWA, on o si ṣãnu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi jì li ọpọlọpọ” (Isaiah 55:7).
Ailoṣuwọn Aanu Ọlọrun
Aanu Ọlọrun si onirobinujẹ ọkàn kọ loṣuwọn. Bi a ba si lé ẹni rẹ kan lọ si iha opin ọrun, lati ibẹ ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio kó ọ jọ’ (Deuteronomi 30:4). Ọlọrun le mu ẹlẹṣẹ ti o lẹgbin ti o si buru ju lọ ki O sọ wọn di ẹni rere; Oun yoo sọ wọn di eniyan mimọ, bẹẹ ni olurekọja ni wọn ti jẹ tẹlẹ. Bawo ni eyi ṣe le ri bẹẹ? Nipa aanu Ọlọrun ati Ẹjẹ Ọdọ-agutan nigba ti ẹlẹṣẹ naa ba wa ti o si tọrọ aanu. “OLUWA mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là” (Orin Dafidi 34:18). “Ṣugbọn agbowode duro li ọkere, kọ tilẹ jẹ gbé oju rẹ soke ọrun, ṣugbọn o lù ara rẹ li õkan-àiya, o wipe, Ọlọrun, ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ. Mo wi fun nyin, ọkunrin yi sọkalẹ lọ si ile rẹ ni idalare jù ekeji lọ: nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ ga, on li a o rẹ silẹ; ẹniti o ba si rẹ ara rẹ silẹ on li a o gbéga” (Luku 18:13, 14).
A o mu un pada bọ sipo yoo ni idapọ ati oju rere Ọlọrun ni kikún. “On o si ṣe ọ li ore, yio si mu ọ bisi i jù awọn baba rẹ lọ.” Fun Israẹli ni ileri yii, ṣugbọn bawo ni ileri Ọlọrun fun wa ti pọ to! “Njẹ ki o yé nyin, ará, pe nipasẹ ọkunrin yi li a nwasu idariji ẹṣẹ fun nyin: ati nipa rẹ li a ndá olukuluku ẹniti o gbagbọ lare kuro inu ohun gbogbo, a kọ le da nyin lare ninu ofin Mose” (Iṣe Awọn Apọsteli 13:38, 39). Awawi wo ni ẹnikẹni le ṣe bi a ba ri ẹṣẹ ni igbesi aye rẹ? Inu Ọlọrun kọ dùn si awọn ti wọn taku sinu ẹṣẹ (Deuteronomi 29:20), ṣugbọn aanu Rẹ wà fun awọn ti yoo ba ronupiwada tọkan-tọkan (Jeremiah 31:18-20).
Ofin Wà Nitosi
Mose fi ye awọn Ọmọ Israẹli pe ofin Ọlọrun kọ le, o si rọrun lati pamọ. Israẹli kọ le ṣe awawi pe ofin Ọlọrun jẹ ohun ti ko ṣe e ṣe tabi pe ko ye ni ni wọn ṣe ṣaigbọran si i. A ti fun wọn ni Ofin lati Ọrun wa ni Oke Sinai o si wa pẹlu wọn ni gbogbo irin-ajo wọn ni aginju, a si kọ ọ sara tabili okuta ki o ba le wa titi. A kọ aṣẹ Ọlọrun ati ilana Ọlọrun sinu Iwe Ofin pẹlu a si fi pamọ sinu Apoti Ẹri (Deuteronomi 31:26). Israẹli le lọ yẹ awọn aṣẹ wọnyii wo nigbakigba ti wọn ba fẹ; wọn kọ ṣẹṣẹ ni lati ranṣẹ si Ọrun fun ofin titun, bakan naa ni ko si le ṣe wọn ni ire kan lati wa oye titun miiran titi de opin aye nipa Ọlọrun. “Nitori Emi li OLUWA, Emi kọ yipada” (Malaki 3:6). Ọrọ ti Ọlọrun ba sọ ki i yi pada, bakan naa ni titi. “Emi kọ sọrọ ni ikọkọ ni ibi okùnkun aiye: Emi kọ wi fun iru-ọmọ Jakọbu pe, Ẹ wá mi lasan: emi OLUWA li o nsọ ododo, mo fi nkan wọnni ti o tó hàn” (Isaiah 45:19).
Oore-Ọfẹ ti Ko Lẹgbẹ
Nigba ti Israẹli ba fi gbogbo ọkan ati ifẹ wọn sin Ọlọrun, wọn a ri i pe wọn le pa aṣẹ Ọlọrun mọ. Bi a ba fi Ofin we akoko Oore-ọfẹ ti a wa yii, a o ri i pe Ofin wuwo. Bibeli sọ fun ni pe Ofin ni ojiji awọn ohun rere ti n bọ wa (Heberu 10:1). A ko si labẹ ojiji mó, a wà ninu imọlẹ Ihinrere ti o mọlẹ kedere. Ko ṣe anfaani fun ẹnikẹni lati ṣẹṣẹ ranṣẹ si Ọrun fun Kristi, nitori O ti wá, O si ti gbe ara eniyan wọ, O ti fun ni ni imọ ti o mó kedere bi kristali, nipa fifun ni ni Ọrọ Rẹ lati mọ ohun ti eniyan le ṣe ki o ba le ri igbala. Ko ṣanfaani lati ṣẹṣẹ ranṣẹ si isalẹ ilẹ fun Jesu nitori bi a tilẹ ti kan An mógi ti a si sin In, O tun jinde! Nigba ti O si goke re Ọrun, O di Alagbawi wa lọdọ Baba (1 Johannu 2:1). “Nitorina o si le gba wọn là pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ Ọlọrun wá nipasẹ rẹ, nitoriti o mbẹ lãye titi lai lati mã bẹbẹ fun wọn” (Heberu 7:25).
Bawo ni eniyan ẹlẹran ara ṣe le tọ Ọlọrun wa? Ki ni awọn ileri aanu ti o wà fun ẹni ti o ba ronupiwada? “Ẹnikẹni ti o ba sá pẹ orukọ Oluwa, li a o gbàlà” (Romu 10:13). “Ẹniti o ba si tọ mi wá, emi ki yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri” (Johannu 6:37). Ọna kan wà ti o ṣe itẹwọgba lati tọ Ọlọrun wa ati lati ke pe E. Johannu Baptisti kede ọna naa nigba ti o wi pe “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹdẹ. . . . . ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada” (Matteu 3:2, 8). Lẹyin naa Jesu waasu ohun kan naa, nipa bẹẹ O fi han pe ohun ti o ṣe pataki ni. Nigba kan a beere lọwọ ọmọde kekere kan kin ni itumọ “ironupiwada.” O dahun pe “Ki a kaanu fun ohun ti a ṣe to bẹẹ ti a ko ni ṣe bẹẹ mọ.” Eyi yii fara mọ itumọ ti Bibeli fun un. “Nitoripe ibanujẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun a maa ṣiṣẹ ironupiwada si igbala ti ki mu abamọ wá: ṣugbọn ibanujẹ ti aiye a ma ṣiṣẹ ikú” (2 Kọrinti 7:10). Ileri wọnyii wà fun awọn ti o ba ronupiwada tootọ -- ọkunrin tabi obinrin ti o ba banujẹ tọkantọkan fun awọn ẹṣẹ ti o ti dá, ti o ni oungbẹ fun idande, ti o si n fẹ lati gbe igbesi aye ti ko lẹṣẹ mọ; iru igbe bayii ko ni ṣe alai de iwaju itẹ Ọlọrun.
Igbagbó Ori Lasan
Ki a kan gba otitọ Jesu Kristi ati Ihinrere Rẹ lasan lai naani ẹṣẹ ninu igbesi aye wa – eyi ti o ti kọja, ti isisiyii, tabi ti ọjọ iwaju -- Ọlọrun ko naani iru igbagbọ bẹẹ. Ki a gba Jesu tabi ki a kan fi ẹnu jẹwọ Rẹ lasan ko le fun ni igbala. Iṣisẹ kin-in-ni si iyipada ọkàn ni eyi jé. Ọlọrun beere pe ki a wẹ ọkan ati aya wa ninu Ẹjẹ Ọdọ-Agutan; nigba naa ni ẹni naa wà ninu Kristi – “o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun” (2 Kọrinti 5:17).
Imọran Atọkanwa
Mose pari ọrọ rẹ si awọn Ọmọ Israẹli pelu ikadi ọrọ ti o le, o n fi han gangba pe ireti nla wà fun ọkan ti o ba ronupiwada, ṣugbọn idajọ gbigbona ni ipin alaigbọran. Gbogbo eniyan ni o n fẹ ire ati iye ainipẹkun. Mose fi han pe Israẹli yoo ri gbogbo ibukun ti wọn n fẹ gba, ibi ti wọn si n bẹru rẹ ki yoo de ba wọn bi wọn ba gbọran ti wọn si fẹran Ọlọrun ati Ofin Rẹ: Ipinnu ti wọn funra wọn ni yoo fi ohun ti ọjọ ọla yoo mu wa hàn; ọrùn Mose mó. Ni ipari ọrọ rẹ, o bẹ awọn Ọmọ Israẹli lati yan iye nitori ẹni ti o ba yan iye nikan ni o le ri i gba. Awọn ti o kú ni o yan iku funra wọn, ẹbi wọn si wa lori wọn nitori wọn kọ lati ni iye ainipẹkun ni ọna ti a là silẹ.
“Ẹnikẹni ti o ba gàn ofin Mose, o kú li aisi ãnu nipa ẹri ẹni meji tabi mẹta: melomelo ni ẹ ro pe a o jẹ oluwa rẹ ni iya kikan, ẹniti o ti tẹ Ọmọ Ọlọrun mọlẹ ti o si ti kà ẹjẹ majẹmu ti a fi sọ ọ di mimó si ohun aimó, ti o si ti kẹgan Ẹmí ore-ọfẹ” (Heberu 10:28, 29).
Ohun ti o lewu ni fun ẹnikẹni lati fi gbogbo ọjọ aye rẹ gbọ ti aye ati ẹṣẹ, ki o si ro pe oun yoo gbadura fun idariji lori akete ikú. Nigba miiran irora a maa pọ nigba ti eniyan ba wà lori akete iku to bẹẹ ti ko ni le ranti lati ronupiwada tabi ki o gbadura. Lọna miiran ẹwẹ, ọpọlọpọ ni a n ké kuro lori ilẹ alaaye lojiji lai ro tẹlẹ ti ayẹ ko si ni si lati gbadura. Eyi a maa ṣẹlẹ si ewe ati agba bakan naa. Bi iwọ ko ba ti i di Onigbagbọ, pinnu lonii lati gba Kristi ati iyẹ, ayọ ati iye ainipẹkun. Ma ṣe duro de ọjọ ọla nitori, “Nisisiyi ni akokọ itẹwọgbà; kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala” (2 Kọrinti 6:2).
Questions
AWỌN IBEERE- Nigba ti a ba kó Israẹli lọ si oko-ẹru, ki ni Ọlọrun sọ pe ki wọn ṣe?
- Bi Israẹli ba yi pada si Ọlọrun, Ọlọrun yoo ha ṣe rere tabi buburu fun wọn?
- Ofin Ọlọrun ha fara pamọ tabi o jinna?
- Nibo ni a gbe le ri Ọrọ Ọlọrun?
- Iru igbesi aye wo ni Israẹli ni lati gbe ki wọn to le ni idaniloju ire ati iye? Bawo ni awa naa lonii ṣe ni lati gbe igbesi aye wa lati le ri ire ati iye?
- Ki ni yoo fa ibi ati ikú?
- Njẹ igba Oore-ọfẹ fi ireti kankan fun onirobinujẹ ọkan lọjọ oni?
- Ṣe àlàyé bi eniyan ṣe le ri igbala. Ki ni ẹni naa ni lati ṣe?