Deuteronomi 31:16-22; 32:1-47

Lesson 141 - Senior

Memory Verse
“Ibaṣepe nwọn gbón, ki oyé eyi ki o yé wọn, nwọn iba rọ igbẹhin wọn!” (Deuteronomi 32:29).
Cross References

IOrin Mose, Ẹri si Israẹli

1.Oluwa sọ asọtẹlẹ nipa Israẹli, bi wọn yoo ti pada maa bọ oriṣa ti wọn yoo si da majẹmu ti wọn ti dá nigba ti wọn ba de Ilẹ Ileri naa, Deuteronomi 31:16-18

2.O paṣẹ fun Mose pe ki o kọ orin naa silẹ ki o si fi kó awọn Ọmọ Israẹli ki o le jẹ ẹri si wọn, Deuteronomi 31:19

3. Nigba ti o ba dara fun wọn tan, wọn yoo pada tọ awọn ọlọrun miiran lẹyin, ibi yoo si wá sori wọn, Deuteronomi 31:20-22

IIỌla fun Ọlọrun ati Asọtẹlẹ Iṣubu Israẹli

1.Ẹkó Rẹ dabi kikan ojo, ohun ọrọ Rẹ si dabi iri ti n sẹ sori koriko, Deuteronomi 32:1-3; Isaiah 44:3, 4

2.Oun ni APATA Israẹli ti O mu wọn la aginju kọja gẹgẹ bi idì ti i gbe ọmọ rẹ lori iyẹ apa rẹ, Deuteronomi 32:4-12; Ẹksodu 19:4

3.O mu un gun ibi giga aye, ṣugbọn Jeṣuruni tapa si I, o si sin awọn ọlọrun miiran, Deuteronomi 32:13-17

IIIIbọriṣa Israẹli Rú Ibinu Ọlọrun Soke

1.Israẹli gbagbe Ọlọrun ti o dá wọn, Oun naa si korira wọn nitori iṣe buburu wọn, Deuteronomi 32:18-21

2.Iná kan ràn, o si jo de ipo-oku ti o wa ni isalẹ patapata, a si rán ọpọlọpọ egún si wọn lori, Deuteronomi 32:22-25; Lefitiku 26:14-19; Orin Dafidi 9:17

3.A o tu wọn ka patapata, a o si mu iranti wọn dẹkun, bi ko ṣe pe awọn ọta wọn yoo gbe ara wọn ga pe nipa agbara ti awọn tikara wọn ni wọn fi bori wọn, Deuteronomi 32:26, 27

IVỌlọrun Yoo Bu Iji Igbẹsan Lù Wón nigba ti Awọn Ọlọrun wọn ba Já Wọn Tilẹ

1.Israẹli jẹ eniyan ti ko ni imọ, apata wọn ki i ṣe APATA wa, Deuteronomi 32:28-34

2.Oluwa yoo ṣe idajọ awọn eniyan Rẹ, yoo si kaanu nigba ti O ba ri i pe agbara wọn lọ tan, Deuteronomi 32:35-39

3.Sibẹ Oluwa yoo pón ida Rẹ mú, yoo si san ẹsan fun awọn ọta wọn, yoo si ṣaanu fun Israẹli, Deuteronomi 32:40-43; Genesisi 12:3

VA Kó Awọn Ọmọ Israẹli ni Orin Mose

1.Mose ati Joṣua kó awọn eniyan ni gbogbo ọrọ orin naa ki o le jé ikilọ fun wọn, Deuteronomi 32:44, 45

2.Mose pa a laṣẹ fun wọn pe ki wọn gbe ọkan wọn le gbogbo ọrọ naa ti wọn ti gbọ, ki wọn si kó awọn ọmọ wọn lati maa pa Ofin mó, Deuteronomi 32:46

3.Eyi ki i ṣe ohun asán, ṣugbọn iyẹ wọn ni, nipasẹ eyi ti wọn yoo fi mú ọjọ wọn pé ni ilẹ naa, Deuteronomi 32:47

Notes
ALAYE

Ikilọ nipa Ibọriṣa

Ofin meji ti o ṣiwaju ninu Ofin Mẹwa kọ fun ni lati bọriṣa lọnakọna: “Iwọ kọ gbọdọ li ọlọrun miran pẹlu mi. Iwọ kọ gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti mbẹ ninu omi ni isalẹ ilẹ. Iwọ kọ gbọdọ tẹ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹẹni iwọ kọ gbọdọ sìn wọn” (Ẹksodu 20:3-5). Ijiya wà fun ẹni ti o ba rú ofin meji wọnyii: “Nitori emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ ẹṣẹ awọn baba wọ lara awọn ọmọ, lati irandiran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi” (Ẹksodu 20:5). Ọlọrun si tun ṣeleri ibukun fun awọn ti o ba pa ofin Rẹ mó: “Emi a si ma fi ãnu hàn ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fé mi, ti nwọn si npa ofin mi mó” (Ẹksodu 20:6). Ohun ti Ọlọrun fi bẹrẹ Ofin Mẹwaa wọnyii ni lati rán Israẹli leti nipa idande wọn kuro ni oko ẹru Egipti, “Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ jade lati ilẹ Egipti, lati oko-ẹrú jade wa.” “Ika Ọlọrun” ni a fi gbé ofin wọnyii sara okuta, a si fi fun Israẹli ni Oke Sinai lẹyin aadọta ọjọ ti wọn ti jade kuro ni Egipti. Awọn ipẹẹrẹ mọ ohun ti o ṣẹlẹ si awọn baba wọn nigba ti wọn gbé ẹre kalẹ lati maa sin in. Gbogbo Israẹli ni o mọ lati ipilẹṣẹ pe ibọriṣa jẹ ẹṣẹ nlá nlà si Ọlọrun, ikú si ni ẹrẹ rẹ.

A kọ fun Israẹli lati bá awọn orilẹ-ede ti o yi wọn ká ni Ilẹ Ileri dá majẹmu. Wọn ni lati pa iran abọriṣa wọnyii run, ki wọn si gé igbo oriṣa wọn lulẹ, ki wọn si pa ere wọn run tuutuu. “Ṣugbọn bayi li ẹnyin o fi wọn ṣe; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn, ẹ o si bi ọwọn wọn lulẹ, ẹ o si ke igbo oriṣa wọn lulẹ, ẹ o si fi iná jó gbogbo ere finfin wọn. Nitoripe enia mimó ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ: OLUWA Ọlọrun rẹ ti yàn ọ lati jé enia ọtọ fun ara rẹ, jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ” (Deuteronomi 7:5, 6). Oluwa si tẹ ẹ mọ wọn leti pe, “Ṣugbọn bi ẹnyin kọ ba lé awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; yio si ṣe, awọn ti ẹnyin jẹ ki o kù ninu wọn yio di ẹgún si oju nyin, ati ẹgún si nyin ni iha, nwọn o si ma yọ nyin lẹnu ni ilẹ na, ninu eyiti ẹnyin ngbé” (Numeri 33:55).

Asọtẹlẹ Iṣubu Israẹli si Ibọriṣa

Pẹlu gbogbo ofin ati ilana ti o le koko wọnyii ti a fi kó Israẹli nipa ibọriṣa, Ọlọrun mọ ọkàn wọn, O si sọ tẹlẹ pe wọn yoo yi pada si ọlọrun miiran nigba ti wọn ba de Ilẹ Ileri. Orin Mose fi iwa itiju ti wọn hù ni yiyi pada si oriṣa hàn ati iṣubu kuro ninu igbagbọ Ọlọrun Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu -- Ọlọrun ti o yàn wọn ṣe eniyan ara Rẹ, olu alufaa, ati orilẹ-ẹde mimó, Ọlọrun ti o mu wọn jade kuro ni oko-ẹru Egipti, ti O si fẹrẹ mu wọn de ilẹ ti n ṣàn fun wara ati oyin.

“Nitoripe ipín OLUWA li awọn enia rẹ; Jakọbu ni ipín iní rẹ.

O ri i ni ilẹ aṣalẹ, ati ni aginjù nibiti ẹranko nke; o yi i ká, o tọju rẹ, o pa a mó bi ẹyin oju rẹ:

“Bi idì ti irú ité rẹ, ti iràbaba sori ọmọ rẹ, ti inà iyé-apa rẹ, ti igbé wọn, ti ima gbé wọn lọ lori iyẹ-apa rẹ:

“Bẹẹni OLUWA nikan ṣamọna rẹ, kọ si sí oriṣa pẹlu rẹ.

“O mu u gùn ibi giga aiye, ki o le ma jẹ eso oko; o si jẹ ki o mu oyin lati inu apata wá, ati oróro lati inu okuta akọ wá;

“Ori-amó malu, ati warà agutan, pẹlu ọrá ọdọ-agutan, ati àgbo irú ti Baṣani, ati ewurẹ, ti on ti ọrá iwe alikama; iwọ si mu ẹjẹ eso-ajara, ani ọti-waini.

“Ṣugbọn Jeṣuruni sanra tán, o si tapa; iwọ sanra tán, iwọ ki tan, ọrá bọ ọ tán: nigbana li o kọ Ọlọrun ti o dá a, o si gàn Apata igbala rẹ.” (Deuteronomi 32:9-15).

Nnkan ti awọn Ọmọ Israẹli ni lati ronu si gidigidi nigba ti wọn ba de Ilẹ Ileri niyii. Fun ogoji ọdun “ni aginju nibi ti ẹranko nke,” Ọlọrun n ba wọn lọ, O n kó wọn, O si pa wọn mọ “bi ẹyin oju rẹ.” O tọju Israẹli bi idì ti i maa tọju ọmọ rẹ, bi o tilẹ ṣe pe nigba pupọ ni wọn ti dide ti wọn si ṣọtẹ si Ọlọrun wọn. Nisisiyii, Ọlọrun fẹrẹ mu wọn kọja si ọdi keji Jordani ni ilẹ ti o kun fun ọpọ nibi ti ibukun ti ko ni oṣuwọn yoo jẹ ti wọn. Ki ni Israẹli yoo ha ṣe? Orin Mose fun ni ni idahun. “Jeṣuruni sanra tán, o si tapa. . . . . o kọ Ọlọrun ti o dá a, o si gàn Apata igbala rẹ.” “Jeṣuruni” ni orukọ ti o ṣọwọn ti Ọlọrun fun Israẹli. Ṣugbọn ninu gbogbo ifẹ Rẹ si awọn ọlọtẹ eniyan wọnyii, ati pẹlu gbogbo ibukun ti O fi fun wọn, wọn yoo yi pada si ọlọrun miiran.

Israẹli Fa Ibinu Ọlọrun

A kọ ó pe, “Nwọn fi oriṣa mu u jowú, ohun irira ni wọn fi mu u binu. Nwọn rubọ si iwin-buburu ti ki iṣe Ọlọrun, si oriṣa ti nwọn kọ mọ rí, si oriṣa ti o hù ni titun. . . . OLUWA si ri i, o si korira wọn” (Deuteronomi 32:16-19). Wọn da majẹmu, idapọ wọn pẹlu Ọlọrun já, O si pinnu lati rán wahala si wọn. O wi pe, “Iná kan ràn ninu ibinu mi, yio si jó dé ipó-okú ni isalẹ. . . . . Emi o kó ohun buburu jọ lé wọn lori; emi o si lọ ọfà mi tán si wọn lara: Ebi yio mu wọn gbẹ, oru gbigbona li a o fi run wọn, ati iparun kikorọ; . . . . . Ibaṣepe nwọn gbón, ki oyé eyi ki o yé wọn, nwọn iba rọ igbẹhin wọn!” (Deuteronomi 32:22-29).

A mu Asọtẹlẹ si Israẹli Ṣẹ

Wọn ha ro igbẹyin wọn wo? Rara o. Mose kó awọn Ọmọ Israẹli ni orin naa, ṣugbọn igbesi ayé wọn lẹhin naa ni o sọ itan naa. Gbogbo asọtẹlẹ naa ni o ṣẹ patapata. A gbe ọpọlọpọ wolii nla nla dide ni Israẹli; a kede Otitọ, a si n ba isin lọ ni Tẹmpili; ṣugbọn diẹ diẹ ni ifẹ wọn si Ọlọrun bẹrẹ si tutu, isin wọn si di aṣa lasan. Ni opin gbogbo rẹ, a pin orilẹ-ẹde wọn. Awọn ẹya mẹwaa bọ si Samaria nibi ti wọn gbe oriṣa kalẹ, a si mu wọn dapọ lati huwa irira pẹlu awọn orilẹ-ede ti o yi wọn ká nipa “ẹṣẹ Jeroboamu.” Baali di ọlọrun wọn, nigbooṣe a kó wọn lẹru a si tú wọn ká lọ si Assiria.

Fun iwọn igba diẹ, isin ko dẹkun ni Tẹmpili ni Jerusalẹmu, ṣugbọn lai pẹ jọjọ, Juda ati Bẹnjamini pẹlu pada tọ ọlọrun miiran lẹyin. Ohun ti a kọ nipa wọn ni eyi, “Awọn enia mi ṣe ibi meji: nwọn fi Emi, isun omi-iye silẹ, nwọn si wà kanga omi fun ara wọn, kanga fifó ti kọ le da omi duro” (Jeremiah 2:13). Lai pẹ titi, a kó awọn naa ni igbekun lọ si Babiloni. A wó Tẹmpili ati ogiri Jerusalemu lulẹ, a si sun ilu naa.

Fifi Ibi San Ifẹ Ọlọrun

Ọlọrun fẹran Israẹli, ki i ṣe nitori wọn jẹ orilẹ-ede nla, tabi pe wọn ni ire kan. Iwa wọn fi han pe ko si ire kan ninu wọn. O fẹ wọn, nitori Majẹmu ti O bá Abrahamu baba wọn dá ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin. A kọ ọ sinu Ọrọ Ọlọrun pe, “OLUWA kọ fi ifé rẹ si nyin lara, bẹẹni kọ yàn nyin, nitoriti ẹnyin pọ ni iye jù awọn enia kan lọ, nitoripe ẹnyin li o tilẹ kére jù ninu gbogbo enia: ṣugbọn nitoriti OLUWA fé nyin, ati nitoriti on fé pa ara ti o ti bú fun awọn baba nyin mó, ni OLUWA ṣe fi ọwó agbara mú nyin jade, o si rà nyin pada kuro li oko-ẹrú, kuro li ọwó Farao ọba Egipti. Nitorina ki iwọ ki o mọ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ, on li Ọlọrun; Ọlọrun olõtọ, ti npa majẹmu mó ati ãnu fun awọn ti o fé ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ mó de ẹgbẹrun iran” (Deuteronomi 7:7-9).

A fi ọrọ wọnyii kó awọn Ọmọ Israẹli ki wọn to de Ilẹ Ileri. Bi o tilẹ jẹ pe wọn la ọpọlọpọ iṣoro kọja ni aginju ti a si fi manna bó wọn lati rẹ ọkàn wọn silẹ (Deuteronomi 8:2, 3), sibẹ nigba ti wọn ni anito ni ilẹ ti n ṣàn fun wara ati fun oyin yii, wọn kọ fi ire san ifẹ Ọlọrun, ki wọn si pa ofin Rẹ, ti a fi kó wọn mó. Apata ti o mu wọn jade ni wọn ko naani, wọn si gbagbe Ọlọrun ti o dá wọn.

“Agbo Kekere”

Nigba ti a bi Jesu ni Bẹtlẹhẹmu, ilẹ ọjọ titun mọ, gẹgẹ bi a ti maa n sọ, otitọ si ni eyi. Majẹmu Laelae, ti a ba Israẹli dá ni Oke Sinai fẹrẹ dopin nitori Israẹli ti dà á, wọn si ti yi pada kuro lọdọ Ọlọrun ti O fé wọn. Majẹmu Titun, ti a ṣeleri fun Abrahamu (Gẹnẹsisi 12:3), ni a mu ṣẹ nigba ti Jesu lọ, ti O gbe agbelebu Rẹ, ti O si ta Ẹjẹ Rẹ silẹ ni Kalfari. “O pari,” ni igbe ti O ké kẹyin lori agbelebu. Eyi ni Oun i ba fi kun un pe, “Nisisiyii gbogbo ayé bó lọwọ gbese,” nitori a ti sanwo irapada, ilẹkun aanu si ṣi silẹ fun gbogbo ọkan ti n ṣegbe. Ni Oke Kalfari ni itumọ gbolohun pataki ti ó wà ninu Johannu 3:16 gbé fara han, “Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹẹ gẹ, ti o fi Ọmọ bibi rẹ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbó má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun.”

Gẹgẹ bi ti awọn Ọmọ Israẹli, aye ko naani ifẹ yii, ṣugbọn awọn diẹ naani rẹ. Bakan naa ni awọn oloootọ diẹ wà ni akoko Israẹli ti o fara mọ Ọlọrun ti wọn ko si yi pada si ọlọrun miiran. Ọlọrun rán Elijah leti pe, “Ṣugbọn emi ti kù ọdẹgbarin enia silẹ fun ara mi ni Israẹli, gbogbo kun ti kọ ti ikunlẹ fun Baali, ati gbogbo ẹnu ti kọ iti fi ẹnu kọ o li ẹnu.” Bakan naa ni o ri lode oni, nigba ti ogunlọgọ ti tọ ọlọrun miiran lẹyin, ti wọn si n tọ ọnà gbooro, ọnà iparun, sibẹ “agbo kekere” kan wà, eyi ti o jẹ didun inu ti Baba lati fi Ijọba fún.

Oluwa, mo n rin ninu mọlẹ didan

Ti o n tan sọna mi lat’ọrun wa;

Mo dagbere faye at’ẹṣẹ rẹ,

Mo ti bẹrẹ n’nu Jesu n o là a ja.

Ọpọ lo bẹrẹ ire ‘je naa;

T’o si kọ lati rin n’nu imọlẹ;

Wọn gba a’tori pe o jẹ ọtun,

Ṣugbọn ki i ṣe ọpọ lo fẹ là a ja.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nigba pupọ, “Orin” wà fun iyin, ki ni orin Mose wà fún?
  2. Ẹṣẹ wo ni awọn ofin meji ti o ṣiwaju Ofin Mẹwaa kọ fun ni?
  3. Nigba ti Israẹli ba de Ilẹ Ileri, ki ni a kọ fun wọn lati ṣe pẹlu awọn orilẹ-ede ti o yi wọn ká?
  4. Ki ni ewu ti ó wà ninu biba awọn orilẹ-ede wọnyii dá majẹmu?
  5. Awọn alahesọ ati alatako Bibeli sọ pe Ọlọrun ṣe aiṣododo lati paṣẹ pe ki a pa orilẹ-ede wọnyii run. Lọna wo ni a fi le sọ pe ki i ṣe aiṣododo?
  6. Ilẹ Ileri kun fun ọwọ ẹran, eso, ati ọkà. Ki ni ohun ti ọrọ wọnyii mu ba Israẹli?
  7. Ki ni asọtẹlẹ ti Ọlọrun sọ nipa Israẹli nigba ti wọn fẹrẹ rekọja odo Jordani? Ta ni “Jeṣuruni”?
  8. Sọ iṣẹlẹ pataki kan ni igbesi aye awọn Ọmọ Israẹli ti o fi imuṣẹ asọtẹlẹ yii han.