Deuteronomi 33:1-29

Lesson 142 - Senior

Memory Verse
“Ibukún ni fun awọn enia na, ti ẹniti Ọlọrun OLUWA iṣe” (Orin Dafidi 144:15).
Cross References

IỌla Nlá Ọlọrun

1.Ọkan ninu awọn iṣẹ ti Mose ṣe kẹyin gẹgẹ bi olori ni lati sure fun awọn Ọmọ Israẹli, Deuteronomi 33:1; Genesisi 49:1-28; Luku 24:50, 51

2.Mose kó sọ nipa gbogbo ifarahan Ọlọrun si wọn nigba ti Oun fun wọn ni Ofin, Deuteronomi 33:2; Eksodu 19:18-20; Awọn Onidajọ 5:4, 5

3.Ọlọrun fi Ofin fun awọn Ọmọ Israẹli nitori O fẹran wọn, Deuteronomi 33:3; Jeremiah 31:1-3; 1 Johannu 4:19

4.Oluwa fẹ ki Israẹli maa ṣe iranti Mose pe nipasẹ rẹ ni a ti fi Ofin fun wọn, Deuteronomi 33:4, 5; Johannu 1:17; Iṣe Awọn Apọsteli 7:37, 38

IIAwọn Ire ti Mose Sú fun Wọn

1.A sure ẹmi gigun fun Reubẹni, ati pe eniyan ẹya rẹ yoo pọ lọpọlọpọ, Deuteronomi 33:6; Numeri 26:2, 7

2.Mose sure fun Juda ni ireti pe wọn yoo jẹ eniyan ti yoo maa gbadura ti yoo si ṣiṣẹ fun Ọlọrun, Deuteronomi 33:7; Awọn Onidajọ 1:1, 2; Mika 5:2; Heberu 7:14

3.Awọn ọmọ Lefi gba ire ti o kun fun oore-ọfẹ nitori Ọlọrun ni o yàn wọn, Deuteronomi 33:8-11; Ẹksodu 32:26-29

4.Bẹnjamini gba ileri pe wọn yoo ni ini kan nitosi ile Ọlọrun, wọn yoo si ni ọpọlọpọ ibukun pẹlu rẹ, Deuteronomi 33:12; Joṣua 18:11-28; Awọn Onidajọ 1:21

5.Efraimu ati Manasse ni ipin ninu ire ti a sú fun Josẹfu, Deuteronomi 33:13-17; Gẹnẹsisi 49:22-26

6.Ire ti a su fun Sebuluni ati Issakari ni pe wọn yoo maa gbe ni alaafia, wọn yoo si ni iṣẹ ti yoo mu ere wa, Deuteronomi 33:18, 19; Joṣua 19:10-23; 1 Kronika 12:32, 33; Isaiah 2:3

7.A ti sure fun Gadi tẹlẹ nipa ini ti Mose, olufunni-ni-ofin ti fi fun wọn; ṣugbọn ibukun naa yoo jẹ ti rẹ lẹyin ti o ba ti ran awọn arakunrin rẹ lọwọ lati ṣẹgun Kenaani, Deuteronomi 33:20, 21; Numeri 32:1-6, 16, 17

8.Dani yoo jẹ ẹya ologun ti o muna, Deuteronomi 33:22

9.A o fi oju rere té Naftali lọrun, yoo si kún fun ibukun Oluwa, Deuteronomi 33:23; Isaiah 9:1, 2; Matteu 4:13-16

10.Ilọpo mẹrin ire ni Mose sú fun Aṣeri, o si pari rẹ pẹlu ileri yi pe “Bi ọjó rẹ, bẹẹli agbara rẹ yio ri,” Deuteronomi 33:24, 25; Owe 3:3, 4; Isaiah 40:29

IIITitobi Israẹli

1.Israẹli tayọ awọn orilẹ-ede miiran gbogbo nitori o gbẹkẹle Ọlọrun ayeraye Ẹni ti a ko le fi we ohunkohun, Deuteronomi 33:26, 27; Isaiah 26:4; 43:10-15; Juda 24, 25

2.Ko si orilẹ-ede miiran ti a fi si ibi itura, tabi ti a bukun to bi a ṣe bukun Israẹli ni Ilẹ Ileri, Deuteronomi 33:28, 29; 2 Samuẹli 7:23; Orin Dafidi 33:12; Romu 2:28, 29

Notes
ALAYE

Ire Ikẹyin

Akoko ti awọn Ọmọ Israẹli yoo rekọja Odo Jordani lọ si Ilẹ Ileri n sun mọ tosi, nitori naa Mose mọ pe oun ko ni ọjọ pupọ lati lo lori ilẹ aye mọ. Mose ti ṣe alakoso, olukọ, alagbawi ati wolii fun Israẹli fun bi ogoji ọdun tabi ju bẹẹ lọ, o si fẹran awọn eniyan yii ju ẹmi oun tikara rẹ lọ. Nigbakigba ti aisan tabi ajakalẹ-arun ba bé silẹ, Mose a gbadura; bi ọta ba gbogun, Mose a tọ Ọlọrun lọ fun iranwọ ati itọni: nigbakigba ti iyọnu ba dide ni ibudo, ohunkohun ti o wu ki o fa a, Mose a bẹbẹ niwaju Ọlọrun titi a o fi mu ohun gbogbo bọ sipo. Lotitọ, Mose ti ṣe aniyan awọn eniyan wọnyii, nisisiyii o fẹ ṣe wọn ni oore kan si i ki o to dagbere fun wọn.

Bi Jakọbu ti sure fun awọn ọmọ rẹ nigba ti ọjọ aye rẹ n lọ sopin, ti o si sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si wọn ni ọjọ iwaju (Gẹnẹsisi 49:3-28), ni ọna kan naa ni Mose sure fun ẹya Israẹli kọọkan. Ohun iyanu ni pe Ọlọrun ṣí wọn loju diẹ kinun, O si fi aṣiri ohun ti yoo ṣẹlẹ ni ọjọ iwaju han awọn aṣiwaju ninu igbagbọ wọnyii.

Ire Jesu

Awọn ire wọnyi rán wa leti ọjọ kan ti Alakoso rere kan duro lori oke kan lati sure fun awọn eniyan Rẹ; bi O si ti n sure fun wọn, a gba Jesu kuro lọdọ wọn, a si gbe E lọ si Ọrun (Luku 24:51). Wo bi ibukun ti O fi fun awọn eniyan Rẹ ti dara pọ to: “Emi ó si bẹre lọwọ Baba, on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mã ba nyin gbé titi lailai” (Johannu 14:16). A mu ileri ibukun yii ṣẹ ninu Ihinrere ti Arọkuro Ojo, ti o wà ni aye lonii. Jesu tun sọ ọjọ ti o logo ti o wà niwaju fun Ijọ Rẹ: “Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbó lọ; Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi ẹṣu jade; nwọn o si ma fi ẹde titun sọrọ; nwọn o si ma gbé ejọ lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, ki yio pa wọn lara rara: nwọn o gbé ọwó le awọn olokunrun, ara wọn ó da” (Marku 16:17, 18). Gbogbo ọmọ-ogun tootọ ti Jesu ni wọn n ṣe alabapin ibukun iyanu yii. Olubori ibukun ṣi n bọ lẹyin. Awọn angẹli sọ bayii nigba ti Jesu goke re Ọrun, “Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bẹẹ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:11).

Ibukun ti Ẹmi

Iyatọ kan wà laaarin ire ti Jakọbu sú fun awọn ọmọ rẹ, ati ire ti Mose sú fun awọn ẹya Israẹli mejila. Asọtẹlẹ ti Jakọbu sọ nipa ọjọ iwaju jẹ mọ ohun ti ara pupọ, o jẹ mọ ipo wọn bi orilẹ-ede, ṣugbọn Mose sọ nipa ti ẹmi ati ibukun nipa ti ara ti wọn yoo ni ni ilẹ Kenaani. Ọlọrun fẹ fun awọn eniyan Rẹ ti igbà ni ni ohun ti o dara ju lọ nipa ti ẹmi ati nipa ti ara bi Oun ti maa n ṣe lonii. Ibukun ti ẹmi ti a fi fun Israẹli wa fun wa lonii pẹlu; a le ri apẹẹrẹ ibukun ti o tobi ju lọ ti a n tu jade sori awọn ọkàn ti ebi n pa ati awọn arinrin ajo lọna Ihinrere bakan naa ninu ibukun ti ara ti o wà ni Kenaani.

Ọlọrun pe Mose lati jẹ alakoso ninu Ijọ ni aginju. Ko si ẹni ti o ri iran ti o mọlẹ gaara tabi oye kikun nipa ẹwa ati anfaani Ijọ Ọlọrun bi Mose. Gẹgẹ bi oluṣọ-agutan Israẹli tootọ, Mose sa gbogbo ipá rẹ lati gbe iran naa kalẹ ni ọna ti yoo wú awọn eniyan naa lori lati fara mọ Ọlọrun timọtimọ.

Eyi ni anfaani ati iṣẹ Onigbagbọ lode oni. Nitori eniyan di otitọ Ihinrere mu ni a ṣe n pe e ni Onigbagbọ. Igba ti Ẹmi Ọlọrun ba ṣiṣẹ lọkan rẹ ti Ọlọrun Baba si fi ara han an pe “Kristi, Ọmọ Ọlọrun alãye ni iwọ iṣe” (Matteu 16:16), ni yoo ṣe e ṣe fun un lati gba Jesu gbọ. Nigba ti Jesu ba fi ara han ọkàn kan, yoo fun un ni aṣẹ lati lọ sọ nipa oore-ọfẹ ti oun ti ri gbà fun awọn ẹlomiran. Bi ifarahan yii ba ti pọ to ni ẹni naa yoo ni ifẹ pọ to lati lọ sọ Itan naa fun ẹlomiran. Eyi ni ẹri Paulu, “Nitorina, Agrippa ọba, emi kọ ṣe aigbọran si iran ọrun na. Ṣugbọn mo kó sọ fun awọn ti o wà ni Damasku, ati ni Jerusalẹmu, ati já gbogbo ilẹ Judea, ati fun awọn Keferi, ki nwọn ki o ronupiwada, ki nwọn si yipada si Ọlọrun, ki nwọn mã ṣe iṣẹ ti o yẹ si ironupiwada” (Iṣe Awọn Apọsteli 26:19, 20). Njẹ awa ko ha gbọ ti ọrọ Jesu n lu agogo lọkan wa pe, “Lọ, ki iwọ ki o si ṣe bẹẹ gẹgẹ” (Luku 10:37)?

Reubẹni, Juda ati Lefi

Mose sure fun awọn ẹya Reubẹni pe wọn o wà titi, wọn ki yoo kú. Boya Mose ri ijakadi wọn lati sin Ọlọrun ni odi keji Odo Jordani ti i ṣe idena laaarin wọn ati pẹpẹ Ọlọrun. Jakọbu ti sọ tẹlẹ nigba ti o n sure fun Reubẹni pe ẹni riru bi omi ni, ki yoo si tayọ (Gẹnẹsisi 49:4). Bi o tilẹ jẹ pe nnkan bi igba ọdun ti kọja lẹyin eyi, igbesi aye ẹya Rẹubẹni ko yipada to bẹẹ.

Juda gba ire lati ẹnu Mose ati Jakọbu. Ire mejeeji jẹ mọ ti ẹmi pupọ, nitori lati inu ẹya yii ni Olugbala yoo ti jade wá. Mose sọ pe Juda yoo jẹ ẹni ti n gbadura, ati pe adura wọn yoo jẹ itẹwọgba, Ọlọrun yoo mu ki ẹya Juda pọ si i yoo si gbe wọn leke awọn ọta wọn.

Ẹbi Aarọni lati inu ẹya Lefi ni a fi iṣẹ isin fun. Ire ti ẹya yii jẹ ti ẹmi patapata. Nitori isin atọkan wa awọn Lefi si Ọlọrun nigba ti Israẹli dẹṣẹ ni Oke Sinai nibi ti wọn gbe yá ẹgbọrọ maluu ti yoo mu wọn pada si Egipti, Ọlọrun sọ pe, “Nitorina ni Lefi kọ ṣe ni ipín tabi iní pẹlu awọn arakunrin rẹ; OLUWA ni ini rẹ” (Deuteronomi 10:9). Ibukun wo ni o tayọ eyi fun ẹnikẹni?

Awọn Ẹya Miiran

A mọ Bẹnjamini gẹgẹ bi ayanfẹ Ọlọrun, lai si aniani eyi jẹ abajade ayẹ ti o wà lọdọ baba rẹ. Bakan naa pẹlu ni Oluwa ri i pe apa kan Ilu Jerusalẹmu yoo jẹ ipin Bẹnjamini, ilu ti Ọlọrun fẹ ti O si fi orukọ Rẹ si.

Ẹya Josẹfu pẹlu ri ibukun gbà. Ibukun rẹ jẹ mọ ti ara ati ti ẹmi. Mose tọrọ “ifé inurere ẹniti o gbé inu igbé” fun Josẹfu, eyi n tọka si ohun ti o ṣẹlẹ ni Oke Horebu nigba ti Ọlọrun fara han ninu igbé ti n jó (Ẹksodu 3:2, 3).

O dabi ẹni pe ibukun ti Sebuluni ati Issakari gba ni lati le maa ṣe iranwọ fun awọn aladugbo wọn lati sin Ọlọrun. Naftali pẹlu wà ninu awọn ti Ọlọrun pẹ. Nigbooṣe awọn wolii sọrọ nipa wọn lọna ti o yanju kedere; a si ri i pe ni akoko iṣẹ iranṣẹ Jesu ni aye, Kapernaumu ni ẹkun Sebuluni ati Naftali ni ibujoko Rẹ gan an gbé wà (Matteu 4:13-15). Ilẹ Galili nibi ti ọpọlọpọ gbe fi tayọtayọ gbọ ọrọ Jesu, ati nibi ti pupọ ninu awọn Apọsteli gbe ti jade wá, wà ninu ilẹ ini awọn ẹya wọnyii.

Ẹya Aṣeri ri ibukun ti ẹmi pataki gba. “Ati bi ọjó rẹ, bẹẹli agbara rẹ yio ri.” Eyi jẹ ileri lati fọkan wọn balẹ pe Ọlọrun yoo ràn wọn lọwọ ninu ipọnju ati wahala wọn gbogbo. Eyi pẹlu jẹ ileri ti o daju fun gbogbo iru-ọmọ Abrahamu nipa ti ẹmi pe Ọlọrun yoo fun wọn ni oore-ọfẹ ati agbara lati ṣe iṣẹ ti O ba pe awọn ọmọ Rẹ lati ṣe ati iṣoro ti O ba pe wọn lati là kọja.

Agbara bi Ọjọ Rẹ

Ọlọrun ko jẹ beere pe ki awọn ti Rẹ ṣe ohun ti ko ṣe e ṣe. O le dabi ẹni pe wọn ṣoro nigba miiran, lai si aniani wọn yoo ṣoro lati ṣe bi o ba jẹ pe agbara ti wọn ni wọn yoo fi ṣe e. Nihin yii ni ileri Ọlọrun gbe gba iṣẹ naa ṣe, “Bi ọjó rẹ, bẹẹli agbara rẹ yio ri.” Iṣọkan laaarin Ọlọrun ati eniyan ni o le mu agbara yii wá. Ti Ọlọrun ni lati yan iṣẹ tabi ojuṣe kan ti a ti fun eniyan ni agbara lati ṣe. Ti eniyan ni lati sa gbogbo ipá rẹ lati lo agbara ti a fun un lati tọ ọna ti o la silẹ niwaju rẹ lati ṣe iṣẹ ti a yàn fun un. Nigba ti agbara mejeeji yii ba papọ -- agbara Ọlọrun ati ipinnu eniyan -- otitọ ni pe ko ni si ohun ti yoo ṣoro.

Igba ti ipẹ lati lọ si Egipti, lati gba awọn Ọmọ Israẹli là kuro loko ẹrú kan Mose lara, o wi pe “Tali emi, ti emi o fi tọ Farao lọ, ati ti emi o fi le mú awọn ọmọ Israẹli jade lati Egipti wá?” (Ẹksodu 3:11). ṣO mọ pe alailagbara ni oun i ṣe lati ṣe iṣẹ ribiribi bayii. Oluwa dá Mose lohun pe, “Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ” (Ẹksodu 3:12); eyi ti to. Ifarahan Ọlọrun a maa fun alainilaari ni ọla, a maa sọ ope di ọlọgbọn, a maa fun alailera ni okun. Mose jade lọ bi alagbara ninu ipá ati agbara Ọlọrun, ta ni jẹ sọ pe ko ṣe aṣeyọri iṣẹ rẹ?

Agbara Jobu

Jobu ni iriri yii pe “bi ọjó rẹ, bẹẹli agbara rẹ yio ri” nigba ti eṣu ta ọfa tẹmbẹlẹkun rẹ si i. A mọ daju pe Ọlọrun fun un ni agbara nitori o la idanwo naa já lai dẹṣẹ. Boya Jobu ko tilẹ mọ agbara Ọlọrun lara rẹ rara; nitori oun a maa beere idi rẹ ti Ọlọrun fi pa oju Rẹ mọ lara oun (Jobu 13:24). Kọ di igba ti Onigbagbọ ba ri ọwó agbara Ọlọrun yii ni igbesi aye rẹ, ṣugbọn ipo ti o ni lati fi ara rẹ si ni pe ki o mọ daju pe oun ko le ṣe iṣẹ ti a pe oun sí lai si agbara Ọlọrun ki o si ni igbagbọ ààyẹ ninu Olufunni ni gbogbo ẹbun rere ati ẹbun pipe. Lẹyin naa, Ọlọrun le rán ohunkohun si oluwarẹ, iru eyi ti kọ ṣẹlẹ si ẹnikẹni rí, ṣugbọn Oun yoo fun un ni agbara ti o tó, yoo si mu ẹni naa là á já pẹlu orin iṣẹgun.

Ọrọ Ikẹyin Mose

Bi ire ti a su fun awọn ẹya Israẹli mejila ti n lọ si opin, ti imisi Ọlọrun si wa ninu rẹ sibẹ, Mose lẹẹkan si i gbe Ọlọrun Israẹli ati Israẹli Ọlọrun ga. Wọnyii ni ọrọ ikẹyin ti a kọ silẹ pe Mose sọ, nitori naa wọn ṣe pataki. Ọrọ ikẹyin eniyan, paapaa ju lọ eniyan Ọlọrun jẹ ọrọ afiyesi gidigidi.

Ko si ọlọrun ti a le fi wé Ọlọrun Israẹli, “ti ngùn ọrun fun iranlọwọ rẹ, ati ninu ọlanla rẹ li oju-ọrun. Ọlọrun aiyeraiye ni ibugbé rẹ, ati nisalẹ li apa aiyeraiye wà.” Aabo wà lori Israẹli ni iha gbogbo, loke ati ni isalẹ pẹlu.

Eyi kọ ha ni ipin ẹni kọọkan ti i ṣe ọmọ Ọlọrun? A ni Baba kan ti a ko le fi ẹnikẹni ṣe akawe Rẹ, ti O n daabo bo wa ni iha gbogbo, Oun ni O n ṣakoso awọn ọrun, nitori naa ko si ipọnju ti o le ti ibẹ wa ti yoo le bì wá ṣubu. Oun ni asa wa ni iha gbogbo, nitori naa “Iwọ ki yio bẹru nitori ẹru oru; tabi fun ọfa ti nfo li ọsán” (Orin Dafidi 91:5). Apa ayeraye ni o n gbé awọn ọmọ Ọlọrun ró lati isalẹ. Bi o ti wu ki a fi inunibini tabi idanwo, aini tabi ipọnju rẹ ọmọ Ọlọrun silẹ to, apa ayeraye wọnni wà nisalẹ ti ki yoo jẹ ki ọkàn rẹ daku, ti ki yoo si jẹ ki igbagbó rẹ yẹ, ti yoo si mu ọkàn rẹ pada bọ si ipo itura. Awa naa ko ha le wi pẹlu Paulu pe, “Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa?” (Romu 8:31).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Akoko wo ni igbesi aye Mose ni o sure fun awọn Ọmọ Israẹli?
  2. Ọna wo ni ire ti Mose sú fi yatọ si eyi ti Jakọbu sú fun awọn ọmọ rẹ?
  3. Ẹya wo ni Mose sọ pe yoo maa gbadura?
  4. Ki ni ṣe ti ẹya Lefi ri ibukun ti o dara bẹẹ gbà?
  5. Sọ diẹ ninu ire ti a sú fun Josẹfu. Njẹ Josẹfu ri ibukun ti ẹmi gbà lati ẹnu Mose?
  6. Ki ni itumọ ileri yii, “Bi ọjó rẹ, bẹẹli agbara rẹ yio ri?”
  7. Ta ni aabo awọn Ọmọ Israẹli?
  8. Ta ni aabo awọn ọmọ Ọlọrun lọjọ oni? Lọna wo?