Deuteronomi 31:14, 15; 32:48-52; 34:1-12

Lesson 143 - Senior

Memory Verse
“Iyebiye ni ikú awọn ayanfẹ rẹ li oju OLUWA (Orin Dafidi 116:15).
Cross References

IMose Ẹni Kiku

1.Mose gẹgẹ bi ẹni kikú pari igbesi aye rẹ pẹlu ipin ti a ti yàn fun gbogbo eniyan – ikú, Deuteronomi 32:48-52; 2 Samuẹli 14:14; Jobu 30:23; Heberu 9:27

2.Mose gẹgẹ bi ẹlẹran-ara ko le sọ akoko ti oun yoo ku, tabi iru iku ti oun yoo ku, tabi ibi ti oun yoo ku si, Deuteronomi 31:14, 15; 32:48-50; 34:1-12

3.Abuku ti Mose ni fun igba diẹ nipasẹ ẹṣẹ awọn Ọmọ Israẹli, eyi ti I ṣe aigbagbọ jẹ ohun pataki ti o fa iku rẹ, Numeri 20:12, 24-28; 27:12-14; Ofin Dafidi 106:32, 33

4.Mose, bi o tilẹ jẹ pe o ni ipo giga, wa ni abẹ akoso ati idajọ Ọlọrun gẹgẹ bi gbogbo eniyan, o si jiya nitori aiṣedeedee rẹ, Deuteronomi 32:48-52; Daniẹli 4:33-37; 5:22, 23, 30; Jobu 36:5-12; Kolosse 3:25

IIMose Eniyan Mimó Ọlọrun

1.Mose ri ilẹ ileri naa ṣugbọn ko dé bẹbẹ rẹ, bakan naa ni awọn agbaagba Israẹli ati Miriamu ati Aaroni, Deuteronomi 32:52; Numeri 20:1, 28; Joṣua 5:6, 7

2.Mose nipasẹ ipe rẹ bi olukọ ati wolii fun awọn eniyan Ọlọrun, jẹ apẹẹrẹ Kristi, Ẹksodu 4:15; 24:12; Deuteronomi 4:1, 14; 18:15; 34:10; Iṣe Awọn Apọsteli 3:22; 7:37-44

3.A pe Mose lọ si ipo ti o ga ju, ani kuro ninu iṣẹ ti aye, eyi ti i ṣe fifi Ofin fun ni, ati igbekalẹ isin agọ ajọ ti i ṣe ojiji agọ ajọ ti Ọrun, Ẹksodu 31:18; Johannu 1:17; 7:19; Heberu 8:5; 10:1; Romu 8:3

4.Joṣua, arọpo Mose, jẹ apẹẹrẹ Kristi gẹgẹ bi olori ogun ti Oluwa, ati nitori eyi oun ni o n ba iṣẹ Ọlọrun lọ nibi ti Mose ti fi i silẹ, Deuteronomi 34:9; Ẹksodu 17:9; 24:13; 33:11; Joṣua 1:2; Sẹkariah 3:1-10

IIIMose Ẹni-aiku

1.Mose, ninu iku rẹ jẹ apẹẹrẹ awọn eniyan mimọ Ọlọrun ti o ku ninu ireti iye ainipẹkun ti wọn ko i ti ri gba, Deuteronomi 34:5, 6; Heberu 11:13, 27, 39, 40; 1 Tẹssalonika 4:14-17

2.Ọlọrun funra Rẹ jẹri si ipo giga ti Mose wa, O si tun fi eyi hàn nigba ti Mose fara han lọdọ Kristi lori Oke Ipalarada, Deuteronomi 34:10-12; Numeri 12:7, 8; Matteu 17:3

3.A ri ifẹ nlá nlà ti Ọlọrun ni si Mose ninu eyi pe ko si ẹda kan ti o ṣe iranwọ kankan fun un ni wakati ikẹyin rẹ. Ọlọrun ni Ọrẹ ati Alabarin rẹ ni gbogbo igbesi aye rẹ, Oun si ni itunu rẹ lakoko iku, Ọlọrun funra Rẹ ni o si ṣe isinku rẹ, Deuteronomi 34:5, 6; 2 Kọrinti 1:7

Notes
ALAYE

Opin Ayé Eniyan

Ẹkọ nipa igbesi aye Mose ko ni i pé lai jẹ pe a mẹnu kan iku ologo ti o kú. Iku ologo ni o kú lai fi iwa aikiyesara ti o hu pẹ nipa lilu apata nigba meji ni Meriba (Numeri 20:11). Aigbọran Mose si aṣẹ Ọlọrun ni o ṣe okunfa iku rẹ. Mose jiya nitori aigbọran yii. Nitori bẹẹ ni a ko ṣe jẹ ki o wọ Ilẹ Ileri. Sibẹ ẹri igbesi aye rẹ n ràn bi imọlẹ ninu itan Ijọ Ọlọrun.

Bi a ba jẹ ọmọ Ọlọrun awa yoo jẹ ohun elo amọ ti o kun fun ogo Ọlọrun; bayii ni o ri ni ti Mose. Ki i ṣe ara aiku ni o gbe wọ, ẹlẹran-ara bi awa ni oun naa i ṣe. Iṣẹgun ti o ni lori ara rẹ, nipa jijọwọ ara rẹ patapata fun akoso Ọlọrun ni o mu ki igbesi aye rẹ kun fun ẹkọ ti o ni imisi fun wa lati tẹle. Niwọn igba ti a ba gbe ara erupẹ yii wọ, a ni lati wa labẹ itọni ati ibawi Ọlọrun ki a ba le ṣe wa yẹ fun iye ainipẹkun. Bayii ni o ri fun Mose, o jagun o si ṣẹgun.

Itunu Onigbagbọ

Eyi ni idaniloju awọn Onigbagbọ lati ibẹrẹ wa pe nipa igbagbọ ninu Jesu wọn yoo bọ lọwọ iku ẹmi ati iya ainipẹkun. Mose ni imọ nipa Kristi ati ireti ajinde, nitori o mẹnu kan Wolii kan bi oun tikara rẹ ti yoo dide, ẹni ti awọn eniyan ni lati gbọ ti Rẹ, eyi si n tọka si Kristi (Iṣe Awọn Apọsteli 3:22).

Mose ni ẹtọ ti o daju lati ni ireti ninu ohun ti a n pe ni ajinde; nitori Enoku, ẹni keje si Adamu, ni a palarada ki oun ki o má ṣe tó iku wọ (Gẹnẹsisi 5:24; Heberu 11:5). Mose ni akoko iku rẹ ri ileri naa, ṣugbọn ti ọwọ rẹ ko si tẹ ẹ jẹ apẹẹrẹ awọn eniyan Ọlọrun ti o kú ni akoko Ofin ninu ireti kan naa.

Nigba ti Paulu n sọrọ awọn akọni nipa igbagbó, o wi pe: “Gbogbo awọn wọnyi li o kú ni igbagbó, lai ri ileri wọnni gbà, ṣugbọn ti wọn ri wọn li ọkere rere, ti nwọn si gbá nwọn mú. . . . . Gbogbo awọn wọnyi ti a jẹri rere si nipa igbagbó, nwọn kọ si ri ileri na gbà: nitori Ọlọrun ti pẹse ohun ti o dara jù silẹ fun wa, pe li aisi wa, ki a má ṣe wọn pé” (Heberu 11:13, 39, 40).

Mose ko ku lai ni ireti. Ko ku lai ni itunu ati itura iku rẹ. Bi o tilẹ jẹ pe Onigbagbọ ati alaiwa-bi-Ọlọrun a maa jẹ irora ninu ara lakoko iku, ẹlẹṣẹ ku lai ni itunu ati itura ni akoko iṣoro, eyi ti o buru ju ni pe o ku lai ni ireti iye ni aye ti n bọ. Ẹlẹṣẹ ti o ku n lọ sinu iya ayeraye ati ọrun apaadi titi lae, ti a ṣe fun eṣu ati awọn angẹli rẹ. Kọ ri bẹẹ fun ọmọ Ọlọrun. Ọlọrun ni itunu rẹ, awọn angẹli si wà lati ran an lọwọ ninu irin-ajo rẹ si ayeraye.

Ẹwa ifẹ nla Ọlọrun si awọn ti Ọlọrun fẹran, fara han ninu iku Mose. Mose lọ si ori oke lati lọ kú lai si ẹda alaaye kan ti o ba a lọ. Ọlọrun ti jẹ ohun gbogbo ni igbesi aye rẹ, ohun ti o si leke ọkan rẹ ni lati mọ Ọlọrun ju ohunkohun lọ ninu aye yi. Iṣẹ Ọlọrun ni Mose gbaju mọ. Mose ko beere ohun kan ju pe ki o mọ Ọlọrun ki o si sun mọ Ọn. Miriamu ati Aarọni, wolii obinrin ati wolii ọkunrin, arabinrin ati arakunrin Mose ti ja a tilẹ nigba kan ri, wọn si doju kọ ọ. Mose, ni igbesi aye rẹ wà fun Ọlọrun o si kú fun Ọlọrun; a ya a nipa kuro lọdọ awọn ara rẹ lati nikan rin lọna ti gbogbo eniyan ko le ṣe alai rin. Ṣugbọn Ọlọrun ba Mose lọ. Eniyan ko ni wa ni adado bi Ọlọrun ba wa pẹlu rẹ. Awọn Olukọni Ju sọ fun ni pe aṣiri ti ó wà nibi iku Mose ni pe Ọlọrun gbé ẹmi rẹ relé. Inu ẹnikẹni ha le bajẹ pe iru opin bayii ni o de ba oun?

Ọlọrun sin Mose si ilẹ Moabu (Deuteronomi 34:6). Ohun ti o wú ni lori ni lati ṣe aṣaro nipa ogo ati ọla ti o jẹ ti Mose ni akoko yii ti Ọlọrun ati awọn angẹli Rẹ tẹ oku eniyan Ọlọrun yii si iboji. Bayii ni awọn eniyan Ọlọrun ṣe n ku. A le ti ọwọ eniyan gbe ara amọ yii si iboji, ṣugbọn ọwọ Ọlọrun ati awọn angẹli Rẹ ni o n tẹwọgba ọkàn ati ẹmi.

“Lori adado oke Nebo

Niha ihin Jordani,

Ni afonifoji ilẹ Moabu

Ni boji kan wa,

Ko si ẹni m’oju oori naa,

Ko s’ẹni t’o ti i ri i;

Tor’ awọn angẹli Ọlọrun lo gbẹ ẹ,

Wọn sinku naa sibẹ.

“Nibi t’ o dara julọ

Ni a n sin ọjọgbọn si,

A si n ṣe ‘boji wọn lọṣọ,

Pẹl’ okuta ‘yebiye,

N’nu ile-isin nlá

Ti’mọlẹ didan ntan,

Ti duru n dun, t’olorin didun n kọ

Lẹba ogiri ọlọna.

“Ọlọla kọ ha l’ẹni -

To f’ ori oke ṣe iboji,

Oku ẹni t’angẹli n ṣọ

Irawọ ṣe ‘mọlẹ wọn,

Igi n mì lẹgbẹ lori oke,

Nibi posi rẹ wa,

T’ ọw’ Ọlọrun kpaapaa tẹ si ‘boji,

Ni ‘lẹ adado yii?’

Ireti Ajinde

Eniyan Ọlọrun ku ni alaafia pẹlu ireti ninu ọkan rẹ. O mọ pe ni ọjọ ajinde, nigba ti ara ti ọkan yoo pade ti wọn yoo si ji dide ni ara aiku, oun ni yoo kọ ji dide, awọn ti o wa laaye yoo si tẹle wọn (1 Tẹssalonika 4:13-17).

Akọsilẹ Ipalarada Kristi, ti Matteu Onihinrere kọ fi han wa pe Mose ati Elijah fara han. Mose ni aṣoju awọn eniyan mimọ ti o ti sùn, ti wọn n reti ajinde, Elijah si jẹ aṣoju awọn eniyan mimọ ti ó wà laaye ti wọn n wọna fun ipalarada ti wọn. Juda tọka si Mose, eyi ti o fi han dajudaju pe a ti ji Mose dide o si ti gbe ara ologo wọ nigba ti o fara han pẹlu Kristi. “Ṣugbọn Mikaẹli, olori awọn angẹli, nigbati o mba Ѐṣu jà, ti o nṣe ọpẹ alaiye nitori okú Mose, kọ si gbọdọ sọ ọrọ-odi si i, ṣugbọn o wipe, Oluwa ni yio ba ọ wi” (Juda 9).

Awọn Iyipada Pataki

Ọpọlọpọ ohun pataki ninu eto igbala ti Ọlọrun ṣe ni o fi ara han fun ni ni akoko iku Mose. Mose ni ohun elo ti Ọlọrun lo lati fi ofin Rẹ han fun araye, Ofin irubọ awọn ọmọ Lefi, ati ti iṣẹ isin awọn alufaa. Igbekalẹ agọ ajọ ni lati kọ awọn eniyan bi a ṣe le sin Ọlọrun. Ofin jẹ olukọni lati mu wa wá sọdọ Kristi: irubọ ti awọn ọmọ Lefi n ṣe ni lati fi han eniyan pe irubọ ati itajẹ-silẹ fun etutu fun ẹṣẹ ṣe dandan; iṣe isin awọn alufaa jẹ apẹẹrẹ daradara ti Ẹni ti yoo jẹ Olori Alufaa wa ti yoo maa bẹbẹ fun wa lọdọ Ọlọrun Baba. Iṣẹ Mose ni lati gbe awọn nnkan wọnyii kalẹ, lati kó awọn eniyan ni Ofin ati isin Ọlọrun. Olukọni, oluṣọ-agutan ati wolii pataki ni oun i ṣe.

Igbà kan ninu itan igbesi aye awọn Ọmọ Israẹli dopin, iṣẹ alakoso yii si pari pẹlu rẹ. Nigba ti o ba to loju Ọlọrun lati mu ọkan ninu awọn ojiṣẹ Rẹ pataki bi Mose kuro, iṣẹ naa maa n falẹ; ṣugbọn iṣẹ Oluwa ni, Oun yoo si ṣe itọju rẹ daradara. Nigba miiran Ọlọrun ko le ṣe bi O ti fẹ nitori ailera ati aile fi ara rubọ awọn eniyan ti O fẹ lọ.

Ọlọrun ki i fi iru ẹni kan naa gan an ṣe paṣi-pààrọ awọn oṣiṣẹ Rẹ. Israẹli ṣe orire pe Joṣua ti fi ara rẹ rubọ patapata fun ifẹ Ọlọrun ati ire Israẹli.

Joṣua, arọpo Mose jẹ ẹni ọtọ patapata, eniyan miiran ni, ipe rẹ si yatọ. A pe Mose lati kó ni, lati fi nnkan lelẹ, lati kó ati lati so ṣọkan; a pe Joṣua lati maa ba iṣẹ lọ, lati maa kede eyi ti a ti fi lelẹ, ati lati maa mọ lé ohun ti a ti pilẹ rẹ. Joṣua ni olori ogun awọn ẹgbẹ ọmọ ogun Israẹli, nipa bayii oun naa jẹ apẹẹrẹ Jesu, Ẹni ti i ṣe Ọgagun igbala wa, Olori ogun ti Oluwa, Kiniun Juda. Joṣua ni o ṣe aṣaaju Israẹli lọ si ogun nigba ti Mose duro ti o si n gbadura fun iṣẹgun (Ẹksodu 17:9).

Bi Israẹli ti fẹrẹ wọ Ilẹ Ileri, àfo ṣi silẹ fun ẹni kan ti Ọlọrun pe lati jẹ aṣiwaju wọn ninu ogun ti wọn yoo gbe ti awọn ọta wọn. Eto igbala Ọlọrun to fun gbogbo aini wa. A ko le gboju fo talẹnti ati ẹbun oore-ọfẹ ti awọn ojiṣẹ Ọlọrun ati awọn oluṣọ-agutan ni lati ni lati le kó ati lati le tó agbo Ọlọrun daradara. A ko gboju fo o da ninu Mose; Joṣua ti o si jẹ arọpo Mose wa labẹ ẹkọ fun ọdun pupọ titi di igba ti oun naa di alakoso. Nigba ti Ọlọrun ninu ọgbọn ti Rẹ mu Mose kuro, ẹni ti yoo rọpo rẹ ti mura tan.

O ṣe e ṣe ki Joṣua má le ṣe iṣẹ ti Mose ṣe. Igbesi aye Mose jẹ eyi ti o kun fun iṣẹ pataki pupọ, nigba ti awọn Ọmọ Israẹli si fẹrẹ wọ Ilẹ Ileri, iṣẹ kpupọ ṣi wà sibẹ lati ṣe. Ko si ẹni ti o le da nikan ṣe gbogbo iṣe Ọlọrun. Awọn ẹlomiran wà lati funrugbin, awọn miiran lati bomi rin, Ọlọrun yoo si mu ibisi wá (1 Kọrinti 3:6-8). Mose sọ ẹru rẹ kalẹ nitori o mọ pe iṣẹ Ọlọrun ko ni falẹ nitori aisi akoso. O ti pari iṣẹ rẹ a si ti fi ade ododo lelẹ fun un lọrún.

Ọpọlọpọ ifiwera ti o larinrin ni a le ri ninu awọn Iwe Marun-un ti Mose ati Iwe Joṣua, awọn iwe Ihinrere mẹrẹẹrin ati Iṣe Awọn Apọsteli. Awọn Iwe marun-un ti o ṣiwaju ninu Bibeli mu wa la ibẹrẹ ibalo Ọlọrun pẹlu eniyan já titi de gbigbe isin Ọlọrun kalẹ ni pato. Mose ni ẹni ti Ọlọrun lo lati gbe isin yii kalẹ, a si ri i pe iru eniyan bi ti rẹ ṣọwọn. Iwe Joṣua jẹ akọsilẹ nipa awọn Ọmọ Israẹli, nipa bi wọn ṣe n ba eto isin Ọlọrun lọ lẹyin ti a ti gbe e kalẹ tan.

Awọn Iwe Ihinrere mẹrẹẹrin sọ fun ni nipa igbesi aye Jesu ati iṣẹ-iranṣẹ Rẹ. Oun ni Olu ninu gbogbo awọn akọsilẹ wọnyii. Kristi gbe eto isin kalẹ ni ọna titun fun Israẹli ati fun gbogbo agbaye: isin Ọlọrun ni ẹmi ati ni otitọ ti a le fi we igbekalẹ Ofin pẹlu awọn eto irubọ rẹ ati iṣẹ isin awọn alufaa. Iṣe Awọn Apọsteli jẹ akọsilẹ nipa awọn ọmọ-ẹyin Kristi ati ọna ti wọn gba n ba iṣẹ isin Ọlọrun lọ gẹgẹ bi Kristi ti gbe e kalẹ.

Lẹyin iku Mose, iyipada wa lọna pupọ ninu igbesi aye awọn Ọmọ Israẹli. Bi o tilẹ jẹ pe iyipada yii ko kan eto isin wọn, sibẹ labẹ akoso Joṣua ni wọn de Ilẹ Ileri ti wọn si gbe isin agọ kalẹ nibi kan pato ani Ṣilo. Awọn ohun titun miiran ni a ni lati ṣe eto fun labẹ akoso titun yii.

Iku ati ajinde Kristi mu iyipada wa sinu isin. Iyipada naa si tobi jọjọ fun gbogbo eniyan. Isin Ọlọrun labẹ Ofin ká kuro. Akoko Oore-ọfẹ wọle de. Jesu ko si láyé mọ, Ẹmi Mimọ ni yoo maa jẹ Olukọni, Oun si ni Olukọni sibẹ. Mose, gẹgẹ bi alakoso jẹ apẹẹrẹ Jesu, Wolii nla ni, Ẹni ti Israẹli ni lati gbọ ti Rẹ ni ọdun pupọ lẹyin naa.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni fa iku Mose?
  2. Njẹ amuwa Ọlọrun le wà ninu iku awọn eniyan mimó Rẹ?
  3. Njẹ Mose kú ikú itiju?
  4. Ta ni ṣe iranwọ lati sin Mose?
  5. Lọna wo ni Mose fi jẹ apẹẹrẹ Kristi?
  6. Lọna wo ni Joṣua fi jẹ apẹẹrẹ Kristi?
  7. Ki ni iyipada ninu iṣakoso ti Israẹli ṣe lẹyin iku Mose?
  8. Lọna wo ni a le fi awọn Iwe Mose ati Joṣua wé awọn Ihinrere mẹrẹẹrin ati Iṣe Awọn Apọsteli?
  9. Ki ni ẹri idaniloju ti a ni pe Mose wà ni Ọrun?