Johannu 10:1-18, 22-42

Lesson 144 - Senior

Memory Verse
“Nigbati o si mu awọn agutan tirẹ jade, o ṣiwaju wọn, awọn agutan si ntọ ọ lẹhin: nitoriti nwọn mọ ohun rẹ” (Johannu 10:4).
Cross References

IOluṣọ-Agutan Rere

1.Oluwa tẹnu mọ ọn pe a ni lati gba ẹnu-ọna wọ agbo-agutan bi a fẹ là; awọn olẹ ati ọlọṣà n gba ibomiran wọle, Johannu 10:1; Jeremiah 23:21

2.Oluṣọna a ṣi ilẹkun fun Oluṣọ-Agutan, Oun a si pe awọn agutan ti Rẹ ni orukọ, Johannu 10:2, 3; Isaiah 43:1; Iṣe Awọn Apọsteli 20:28

3.Awọn agutan mọ ohùn Oluṣọ-Agutan, wọn kò si jẹ tẹlé ohùn awọn alejo, Johannu 10:4, 5; 2 Samuẹli 7:8; Jeremiah 17:16; Matteu 25:32; Galatia 1:8

4.Jesu sọ fun wọn gbangba pe, “Emi ni ilẹkun awọn agutan”; gbogbo awọn ti o wá ṣiwaju Rẹ jẹ olẹ ati ọlọṣa, Johannu 10:7, 8; 14:6

5.Gbogbo ẹni ti o bá bá ọdọ Rẹ wọle ni a o gbalà, Johannu 10:9; Efesu 2:18

6.Olẹ wá lati jalẹ ati lati parun; Jesu wá ki wọn ba le ni iye, Johannu 10:10; Esekieli 34:2

7.Jesu ni Oluṣọ-Agutan rere, O si fi ẹmi Rẹ lélẹ fun awọn agutan, Johannu 10:11, 14, 15; Esekiẹli 34:12; Heberu 13:20; 1 Peter 2:25; 2 Timoteu 2:19

8.Alagbaṣe a sá lọ nigba ti ikookò ba n bọ, nitori kò naani awọn agutan, Johannu 10:12, 13; Sekariah 11:16, 17

IIAwọn Agutan Miiran

1.Jesu ni awọn agutan miiran ti wọn ki i ṣe ti agbo yii, yoo mu wọn wá, wọn yoo si jẹ agbo kan ati Oluṣọ-Agutan kan, Johannu 10:16; Isaiah 56:8; Esekiẹli 34:23; Efesu 2:14

2.Baba fẹran Jesu nitori O fi ẹmi Rẹ lelẹ fun awọn agutan. O ni agbara lati fi lelẹ ati lati tun gbà á pada, Johannu 10:17, 18; Isaiah 53:7, 8; Heberu 2:9; Johannu 21:9

IIIAwọn Ju Alaigbagbọ

1.A pa owe yii fun wọn nigba ajọ ọdun Iyasi-mimọ, awọn ọpọ eniyan duro yika, wọn si wi pe, “Bi iwọ ni iṣe Kristi na, wi fun wa gbangba,” Johannu 10:22, 24

2.Jesu dahun pe, “Emi ti wi fun nyin, ẹnyin kò si gbagbọ; iṣẹ ti emi nṣe li orukọ Baba mi, awọn ni njẹri mi. Ṣugbọn ẹnyin kò gbagbọ, nitori ẹnyin kò si ninu awọn agutan mi,” Johannu 10:25, 26; 3:2; 8:47; 1 Johannu 4:6

3.Jesu ati Baba Rẹ jẹ ọkan, kò si ẹni ti o le já awọn agutan kuro ọwọ wọn, Johannu 10:28, 29; 6:37; 17:11, 12; 18:9

4.Awọn Ju n wá ọna ati sọ Jesu ni okuta nitori O mu ara Rẹ bá Ọlọrun dọgba, Johannu 10:31-33; 5:18

Notes
ALAYE

Jesu fi aworan ara Rẹ hàn ninu owe yii, nipa fifi oluṣọ-agutan tootọ ṣe apejuwe. Apejuwe ti kò ṣajeji si wọn ni O lò. Wọn mọ iru ifẹ ati itọju ti oluṣọ-agutan tootọ fún awọn agutan rẹ. Jesu n fi ye awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe Oun ni Ọna sinu agbo agutan. Iṣẹ Ofin kò to fun igbala wọn, ṣugbọn wọn ni lati wọ inu agbo nipasẹ Rẹ.

Ọna ti o lọwọ pupọ ni O gba bẹrẹ ọrọ yii: “Lõtọ, lõtọ …” (eyi ni pe “Otitọ ni! Otitọ ni!) lati fi ye wọn bi ohun ti O fẹ sọ ti ṣe pataki tó. Jesu wi pe, ẹni ti o bá gba ibomiran wọle, oun naa ni olẹ ati ọlọṣà. Awọn agutan oluṣọ-agutan ni ẹtọ lati wọ inu agbo rẹ. Ṣugbọn awọn ti o fẹ wọ inu agbo Ọlọrun lai ni ironupiwada tootọ ati lai di atunbi, ni o n gba ọnà miiran wọlé, Oluwa pe wọn ni olẹ ati ọlọṣà. Ọpọlọpọ fẹ lọ si Ọrun nipa iṣẹ rere ati itọrẹ-aanu ti wọn n ṣe, lai naani Ẹjẹ etùtù nì ati igbagbọ ninu Jesu Kristi Oluwa wa.

Oluṣọ-Agutan Kekere

A ri apejuwe oluṣọ-agutan rere ni igbesi aye Dafidi Ọba. Nigba ti o wà ni ẹwe, oun ni a fi itọju agbo ẹran baba rẹ le lọwọ. Ni ọjọ kan, kiniun kan ati beari wọ inu agbo wá, wọn gbe ọdọ-agutan meji ni kọọkan. Dafidi kò salọ nigba ti o ri kiniun ati beari yii, ṣugbọn ifẹ rẹ si awọn agutan ati ojuṣe rẹ lati daabo bo wọn mu ki o dide fun igbala wọn. Igbagbọ ati agbara lati ọdọ Ọlọrun rẹ ran an lọwọ lati já awọn agutan wọnyii gbà lẹnu kiniun ati kuro lọwọ beari. A gbagbọ pe Ọlọrun fun un ni iriri wọnyii lati kọ ọ bi oun yoo ti ṣe ṣe itọju Israẹli, eniyan Rẹ. Ọlọrun mọ pe Oun le fi ọkàn tán an gẹgẹ bi oluṣọ-agutan rere. “Ẹ kiyesara nyin, ati si gbogbo agbo ti Ẹmi Mimọ fi nyin ṣe alabojuto rẹ, lati mã tọju ijọ Ọlọrun, ti o ti fi ẹjẹ ara rẹ rà” (Iṣe Awọn Apọsteli 20:28).

Ẹmi ti Kò Gba Ọjẹgẹ

Paulu mọ bi o ti ṣe pataki tó lati jẹ oluṣọ-agutan tootọ, nitori naa o wi pe, “Nitori emi kò fà sẹhin lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun nyin” (Iṣe Awọn Apọsteli 20:27). Kò si aye fun ẹkọ ti kò yẹ kooro ninu iṣẹ-iranṣẹ Paulu. “Ṣugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọrun wá, li o ba wasu ihinrere miran fun nyin ju eyiti a ti wasu fun nyin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu” (Galatia 1:8).

Paulu kiye sara gidigidi, lati ri i pe a kò gba ikookò ti o gbe awọ agutan wọ (Matteu 7:15) láyẹ rará ninu agbo Ọlọrun. O ṣe e ṣe ki a má tete fi ojú ẹmi ri wọn bi Daidi ti le fi oju ara ri kiniun ati beari, ṣugbọn Ẹmi Ọlọrun kò ni jẹ ki wọn rin jinnà ninu agbo ti irú eniyan ti wọn jẹ yoo fi fara hàn fun wa. Oluṣọ-agutan tootọ kò ni jọgọ silẹ tabi ki o sá nigba ti o ba ri i ti ikookò n bọ wa, ṣugbọn pẹlu ida ati apata ni oun yoo jade lọ lati kò ó loju bi ọta. Paulu wi pe, “Nitoriti emi mọ pe, lẹhin lilọ mi, ikõkò buburu yio wọ ãrin nyin, li aidá agbo si” (Iṣe Awọn Apọsteli 20:29). O wi pe “lẹhin lilọ mi.” O pinnu pe wọn ki yoo wọle niwọn igbà ti oun wa laayé.

Àwọ Agutan

Ninu Iwaasu lori Oke, Jesu wi pe, “Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu” (Matteu 7:15). Ni akoko yii, ọpọlọpọ wolii eke ni o ti dide, ti wọn si gbe ẹwu wọ bi ojiṣẹ Ọlọrun. Wọn ti wá ni awọ agutan lati gbe ẹkọ ti kò ye kooro kalẹ fun awọn eniyan, wọn si ti ṣi ọpọ alailera ati awọn ti kò duro deedee lọna kuro ninu otitọ.

Ọkan ninu awọn iṣina igbà ikẹyin yii ni ẹkọ ti o kọ ni pe a kò le sọ oore-ọfẹ Ọlọrun nù bi a bá tilẹ dẹṣẹ. Ẹkọ odi yii ni wọn gbe kalẹ lori ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti o wà ninu ẹkọ wa oni pẹlu awọn miiran ti wọn ṣi tumọ ti wọn si lọ lọrùn. “Awọn agutan mi ngbọ ohùn mi, emi si mọ wọn, nwọn a si ma tọ mi lẹhin: Emi si fun wọn ni iye ainipẹkun; nwọn ki o si ṣegbé lailai, kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ mi. Baba mi, ẹniti o fi wọn fun mi, pọ ju gbogbo wọn lọ, kò si si ẹniti o lẹ já wọn kuro li ọwọ Baba mi.”

Awọn wolii eke wọnyii sọ fun ni pe bi eniyan ba ti di ẹbi Ọlọrun, ọmọ Ọlọrun ni oun i ṣe nigba gbogbo. Ohunkohun ti o wu ki o ṣe tabi bi o ti wu ki o mokun ninu ẹṣẹ to, wọn gba pe ọmọ Ọlọrun ni oun i ṣe sibẹ -- bi o tilẹ jẹ ọmọ oninakuna -- wọn gba pe nijọ kan ṣá, yoo pada wá ilé. Wọn kunà lati gba ẹkọ Bibeli yii rò ti o kọ ni pe, a le ta ọmọ nù ati pe ẹṣẹ ti a kò ba ronupiwada rẹ yoo ta ọkàn nù kuro lọdọ Ọlọrun laelae. Ẹsẹ pupọ ni o wà ninu Ọrọ Ọlọrun ti o tako ẹkọ odi yii; ṣugbọn ẹyọ kan lati inu Esekiẹli ti tó lati bi ẹkọ yii wó. “Ṣugbọn nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ, ti o si huwà aiṣedede, ti o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo irira ti enia buburu nṣe, on o ha yẹ? gbogbo ododo rẹ ti o ti ṣe ni a ki yio ranti: ninu irekọja rẹ ti o ti ṣe, ati ninu ẹṣẹ rẹ ti o ti dá, ninu wọn ni yio kú” (Esekiẹli 18:24).

Nipa yiyẹ Ọrọ Ọlọrun miiran gbogbo wò lori ọran yii, a mọ daju pe, o ṣe e ṣe fun wa ki a kunà lati duro labẹ akoso Ọlọrun. Kò si agbara kan ni aye yii tabi ni ọrun apaadi ti o le já wa gbà, niwọn igbà ti a ba pa ara wa mọ ninu ọna ati ifẹ Ọlọrun. Awa tikara wa nikan ni a le já ara wa gbà kuro labẹ ikẹ ati aabò Ọlọrun – o wà ni ipá wa lati ṣe bẹẹ! Ọlọrun fun olukuluku ni ọkàn – lati dá yàn – lati yan ibi ti yoo gbé ni ayeraye. Ọlọrun kò gba eyi lọwọ rẹ nigba ti o di ẹbi Ọlọrun. Bi o ba si wu u nigbakigba lati tọ ọna ẹṣẹ, ki o si kọ ọna Ọlọrun silẹ ki o fẹ ohun ti aye yii ju Ọlọrun lọ, o le ṣe bẹẹ, ṣugbọn eyi yoo gbọn igbala rẹ sọnù.

Kò si ẹni ti o fẹ iye ainipẹkun ti yoo lọ sinu ẹṣẹ ki o si ni erò lati yi pada ki ó to kú. Ohun ti o ṣe e ṣe ni ki a tun mu eniyan bọ sinu oore-ọfẹ Ọlọrun lẹyin ti o bá ti sọ ọ nù (1 Johannu 2:1, 2); ṣugbọn bi eniyan ba kú sinu ẹṣẹ rẹ, oun yoo ṣegbe titi laelae. Ohun ewu ni lati fi aanu ati ifẹ Ọlọrun tafala. “Ẹniti o ba foriti i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà” (Matteu 10:22).

Ailagbara

Otitọ ni pe agutan le tete mọ ohùn oluṣọ-agutan ki o má si ṣe tẹle ẹlomiran. Jesu wi pe, “Nwọn kò jẹ tọ alejò lẹhin, … nitoriti nwọn kò mọ ohùn alejò” (Johannu 10:5). Agutan ti o sọnu kò le dá mọ ọnà ile funra rẹ. Nipa ti ẹmi kò si ẹni ti o jẹ alailagbara bi ẹni ti o wà ninu ẹṣẹ. Kò ṣe e ṣe fun un lati tikara rẹ bọ lọwọ ẹṣẹ. Kò lagbara lati ran ara rẹ lọwọ. “Ara Etiopia le yi àwọ rẹ pada, tabi ẹkùn le yi ilà ara rẹ pada? bẹẹni ẹnyin pẹlu iba le ṣe rere, ẹnyin ti a kọ ni iwà buburu” (Jeremiah 13:23). Eṣu ti gbiyanju lati fi iṣẹ rere dipo atunbi. Kò si ohun kan ti o le mú ẹṣẹ kuro lọkàn lẹyin Ẹjẹ Jesu.

Agbara Lati fi Ẹmi Rẹ Lelẹ

“Nitorina ni Baba mi ṣe fẹran mi, nitoriti mo fi ẹmi mi lelẹ; ki emi ki o le tún gbà a. Ẹnikẹni kò gbà a lọwọ mi, ṣugbọn fi i lelẹ fun ara mi. Mo li agbara lati fi i lelẹ, mo si li agbara lati tun gbà a. Aṣẹ yi ni mo ti gbà lati ọdọ Baba mi wá.” Nihin yii ni ògo ẹbọ ti Jesu fi ara Rẹ rú gbé wà, ni ti pe Oun tikara Rẹ ni o fi ẹmi Rẹ lelẹ fun awọn agutan. Ẹwà Ajinde si fara hàn ni eyi pe, O ni agbara lati tun gba ẹmi Rẹ pada.

Awọn Agutan Miiran

“Emi si ni awọn agutan miran, ti ki iṣe ti agbo yi.” I baa ṣe dudu tabi funfun, pupa tabi ofeefé, bakan naa ni wọn ri niwaju Ọlọrun, “Ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ẹde, ẹniti o ba bẹru rẹ, ti o si nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ” (Iṣe Awọn Apọsteli 10:35).

A le wo bi ọkàn oluṣọ-agutan yoo ti balẹ tó nigba ti gbogbo agutan rẹ ba ti wọle tán, ti wọn si wà labẹ ibugbe ni ailewu ni gbogbo oru. Bakan naa ni a le foju ẹmi wo bi ayọ naa yoo ti pọ tó nigba ti ọkàn ti o kẹyin ninu awọn ti a gbala yoo ba gba Ẹnu “bode ogo wọle ti Oluṣọ-Agutan awọn agutan yoo wi pe, “Gbogbo wọn n bẹ nihin, a ti pe orukọ, ko si si eyi ti o sọnu.”

“Má bẹru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin”(Luku 12:32).

Awọn agutan kan ni yoo wà – agbo kan -- Oluṣọ-Agutan kan.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni awọn orukọ ti a fi fun Jesu ninu owe yii?
  2. Bawo ni awọn oluṣọ-agutan ṣe n kó agutan wọn sinu agbo?
  3. Nipa ti ẹmi, bawo ni a ṣe le wọ agbo Ọlọrun?
  4. Nipasẹ ta ni a le wọle?
  5. Ki ni Jesu pe awọn ti o fẹ gba ibomiran wọle?
  6. Ta ni Oluṣọ-Agutan Nla, ta si ni awọn oluṣọ-agutan kékèké?
  7. Ki ni alagbaṣe ṣe nigba ti o ri ikooko ti o n bọ wá?
  8. Njẹ awọn Ju nikan ni o wà ninu agbo naa?
  9. Agbo meloo ati oluṣọ-agutan meloo ni yoo wà?