Lesson 145 - Senior
Memory Verse
“Emi kò ti wi fun ọ pe, bi iwọ ba gbagbọ, iwọ o ri ogo Ọlọrun?” (Johannu 11:40).Cross References
IIku Lasaru
1.Lẹyin ti Jesu ti gba iṣẹ ti a rán si I nipa aisan Lasaru, O fi ipada lọ si Bẹtani falẹ fun ọjọ pupọ si i ki O ba le ṣe iṣẹ iyanu kan, Johannu 11:1-6, 15
2.Ifilọ ti Jesu ṣe pe Oun yoo pada si Bẹtani mu ki idaamu bá ọkàn awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe ki O má lọ fi ẹmi Rẹ wewu Johannu 11:7-10, 16; 10:31; 8:59
3.Wíwà lai lewu Jesu wà lọwọ agbara Ọlọrun ti O n daabo bo O niwọn igba ti ko i ti pari iṣẹ Rẹ ni ayé, Johannu 11:9, 10; Luku 13:31-33; Johannu 13:30; Orin Dafidi 91:11, 12; Matteu 10:29, 30
4.Ki Jesu ba le mu aṣiro awọn ọmọ-ẹyin nipasẹ ipò ti Lasaru wà kuro, O sọ fun wọn gbangba pe, “Lasaru kú”, Johannu 11:11-14
IIOniṣegun Lati Ọrun
1.Marta ni ẹni kin-in-ni ti o kọ pade Jesu nigba ti o de si Bẹtani, Johannu 11:20
2.Ẹri kan naa ni Marta ati Maria jẹ, wọn wi pe “Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakọnrin mi kì ba kú”, Johannu 11:21, 22, 32
3.Nigba ti Maria lọ pade Jesu, ọpọ awọn ti n ṣofọ tẹle e, wọn rò pé o n lọ sọkun ni iboji Lasaru, Johannu 11:28-33
4.Jesu n fẹ lati bù si igbagbọ Marta ati Maria ki wọn ba le gbagbọ pe Oun ni Ajinde ati Iyẹ, Johannu 11:23-27, 40; 1 Kọrinti 15:54-58
5.Ẹkún ti Jesu sun fi ẹmi ibakẹdun Rẹ hàn, Johannu 11:33-38; Luku 19:41; Heberu 5:7; Isaiah 53:3
6.O jẹ ohun ti o rú awọn ti n woran loju pe Jesu kò si nibẹ lati wo Lasaru sàn nigba ti o n ṣaisan, Johannu 11:37, 4, 15
IIIAgbara Ajinde
1.Ọrọ ti o ti ẹnu Jesu jade pe Oun ni Ajinde ati Iye jẹ ọkan ninu ohun ti O tẹnu mọ pupọ lati fi hàn pe Ọlọrun ni Oun, Johannu 11:25, 26; 1:4; 5:26; 2 Timoteu 1:10; 1 Johannu 5:12
2.Jesu fi hàn daju pe Ọlọrun ni oun nigba ti O pe Lasaru jade wá lati inu iboji, Johannu 11:38-44
3.Ọpọ ti o ri iṣẹ iyanu ajinde Lasaru gba Kristi gbọ, nigba ti awọn miiran si pada lọ royin fun awọn Farisi ohun ti o ṣẹlẹ; Johannu 11:45, 46; 12:9, 17-19; Luku 16:31
Notes
ALAYEAwọn Ọjọ Idojukọ
Johannu nikan ni Onihinrere ti ó sọ nipa ọran iku Lasaru. Diẹ ninu awọn akẹkọọ Bibeli gba pe awọn Onihinrere iyoku kó mẹnu kan Lasaru nitori Lasaru wà laaye sibẹ nigba ti wọn kọ akọsilẹ ti wọn. Iṣẹ iyanu jiji i dide fa ibinu ati ikorira wa ba Jesu ati Lasaru lati ọdọ awọn Farisi; boya nitori eyi, awọn ọmọ-ẹyin miiran kò mẹnu kan an ki o ma ba pokiki ti o le kó wahala bá Lasaru. Nitori Lasaru jẹ eri ti kò le parun si agbara Ọlọrun, awọn Farisi fẹ lati pa a, (Ka Johannu 12:9-11, 17-19).
Akoko iku Lasaru jẹ nnkan bi ọdun kan ṣiwaju igba ti a kan Jesu mọ agbelegbu. Nitori Jesu ba agabagebe ati eké ti o wà ninu isin ati ẹkọ awọn Ju wí, ọpọlọpọ idojukọ ni o dide lọtun losi. Ọpọlọpọ iṣẹ iyanu ti Jesu n ṣe tubọ n bu epo si ẹtù ati ina owú ti ilara ti o ti n jó tẹlẹ. Ọdun ti o kẹyin ninu iṣẹ iranṣẹ Jesu ni a saba maa n pe ni Ọdun idojukọ, otitọ si ni eyi. Jesu ni lati fi agabagebe Jerusalẹmu silẹ lati le bọ lọwọ inunibini. O wà ni ikọja Jọrdani, nibi ti Johannu Baptisti gbe kọ n ṣe iribọmi; nigba ti o gba iroyin pe ara Lasaru kò dá (Johannu 10:40).
Ìfoyà pupọ ni o wà lọkàn awọn ọmọ-ẹyin nigba ti Jesu sọ pe Oun fẹ pada si Judea. Wọn mọ bi igbi inunibini si Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin Rẹ ti pọ to. Wọn rán Jesu leti pe kò ṣe anfaani fun wọn lati pada nitori ni aipẹ jọjọ yii ni awọn Ju fẹ sọ Jesu ni okuta, o si ṣe wọn ni kayefi pe yoo tun pada sibẹ.
Jesu fi ọkàn awọn ọmọ-ẹyin Rẹ balẹ pe Oun wà lai lewu nipa riran wọn leti pe iṣẹ Oun ko i ti i pari. Niwọn igba ti iṣẹ Rẹ ko i ti i pari, aabo Ọlọrun wà lori Rẹ. Jesu beere lọwọ awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe, “Wakati mejila ki mbẹ ninu ọsán kan?” Itumọ ọrọ yii ni pe bi agogo ti n ka wakati lọjọọjọ, gẹgẹ bi ilana Ọlọrun, bakan naa ni ipinnu Ọlọrun kò le ṣai ṣẹ ninu igbesi aye Jesu Kristi – ohun gbogbo yoo lọ gẹgẹ bi a ti kọwe rẹ. Bi o tilẹ jẹ pe buburu ni awọn ọjọ, ti ọta si yí Jesu ká niha gbogbo, sibẹ Ọlọrun ṣe iranwọ fun Jesu lati pari iṣẹ ti O ran An wa ṣe, ati lati waasu ododo. Nigba pupọ ni Jesu n yẹra kuro lọdọ awọn eniyan, ki irukerudo ma ba bẹ silẹ, ati lati mu ki ibinu wọn rẹlẹ. Ṣugbọn lai si aniani Ọlọrun da ìmọ awọn apaniyan, ọta Kristi rú ju igba kan ṣoṣo lọ (Ka Matteu 26:55).
Gbogbo eniyan ni a fun ni aafo ati akoko lati ronupiwada, bakan naa ni Oluwa gba awọn eniyan ati awọn Farisi layẹ lati mọ daju bi iṣẹ ati iwaasu Kristi ba i ṣe ti Ọlọrun. Titi wọn yoo fi pinnu ati titi iṣẹ Kristi yoo fi pari, Jesu yoo ni anfaani lati maa ṣe iṣẹ iranṣẹ Rẹ. O dabi ẹni pe eyi kò fi awọn ọmọ-ẹyin lọkàn balẹ to bẹẹ nitori Tọmasi wi pe, “Ẹ jẹ ki awa na lọ, ki a le ba a kú pẹlu.”
Idahun Falẹ
Nigba ti Jesu gbọ pe Lasaru n ṣaisan, Oun kò tete lọ si Bẹtani. Jesu mọọmọ duro pẹ bẹẹ ni, O si sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe eredi ti Oun fi ṣe bẹẹ ni pe ki ogo Ọlọrun le hàn nigba ti Oun ba lọ. Jesu wi pe, Lasaru sùn ni, ṣugbọn kò ye awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe iku ni O n pe ni oorun (itumọ eyi ni pe, ara sùn ṣugbọn ẹmi wà pẹlu Ọlọrun). Jesu fi ye wọn gbangba pe “Lasaru kú.” Ẹnikẹni kò i ti i sọ fun Un nipa iku Lasaru, ṣugbọn Jesu mọ pe Lasaru ti kú, nitori Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe, O si mọ ohun gbogbo; ohun kan kò si pamọ fun Un.
Nipa akọsilẹ Iwe Mimọ, a mọ pe Lasaru ati awọn arabirin rẹ mejeeji, Marta ati Maria ṣọwọn fun Jesu lọpọlọpọ. Oun a saba maa de si ile wọn, Maria si ni ẹni naa ti o jokoo lati kẹkọọ lẹsẹ Jesu. Ẹnikẹni le ro pe o tọ o si yẹ ki Jesu ṣe aajo ẹni ti i ṣe ọrẹ Rẹ, nigba ti O mọ pe o ṣaisan titi de oju iku. O yẹ ki Jesu sọ gbolohun ọrọ kan, ara Lasaru yoo dá lẹsẹkẹsẹ bi o ti wu ki ọna jìn tó (Wo Matteu 8:8).
Ifẹ Kristi ju ohun ti ẹda le fẹnu sọ lọ. Jesu fẹran Lasaru, O si fẹ ki o wa layọ ati alaafia, ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, Jesu fẹ ki Lasaru ati gbogbo awọn ti o wà nibẹ mọ otitọ Ọlọrun, ki wọn si jẹ alabapin rẹ. Nibikibi ti o wu ki Jesu wa ninu igboke-gbodo oojọ, Oun kò kuna lati fi ohun ti o n ṣẹlẹ ni ayika wọn dari awọn eniyan si igbesi aye miiran, iye ainipẹkun! Oun kò kuna lati lo ohun ti o ṣẹlẹ ni akoko yii lati fi hàn ẹni ti Oun i ṣe, ati ki ni ẹkọ Rẹ jẹ. Bi o ti jẹ pe awọn otitọ ti Jesu fẹ fi hàn yatọ si ero ọkàn ọpọlọpọ eniyan patapata, Oun ni lati gbe wọn kalẹ lọna ti itumọ rẹ yoo fi ye awọn eniyan yekeyeke.
Nigba pupọ ni ọna ti Ọlọrun gba n dahun adura wa yatọ si ọna ti awa n reti. Jesu kò kọ lati ṣe iranwọ fun Lasaru, ṣugbọn O ṣe e ni akoko ti Rẹ ki a le ri ogo Ọlọrun. A lẹ mọ bi ogo Ọlọrun ti fara hàn to ninu iṣẹlẹ yii nitori ọpọlọpọ ni o gba Kristi gbọ lati igba naa lọ.
Igbagbọ
Jesu kò lọ si ile Lasaru nigba ti O de Bẹtani. O ṣe e ṣe ki o jẹ pe Jesu kò fẹ ki ohun-kohun di Oun lọwọ ti Oun yoo fi ṣe ohun ti Oun ni i ṣe. Marta ni o kọ pade Jesu lọna, ohun kan naa ti o sọ yii ni Maria sọ nigba ti o ba Jesu pade lẹyin naa: “Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakọnrin mi kì ba kú.” O dá Marta loju pe Jesu i ba wo Lasaru san bi O ba wà nibẹ.
Ohun ti Maria tun sọ lẹyin eyi fi igbagbọ ti o ní ninu Jesu hàn “Ṣugbọn nisisiyi na, mo mọ pe, ohunkohun ti iwọ ba bẹre lọwọ Ọlọrun, Ọlọrun yio fifun Ọ.” O dabi ẹni pe igbagbọ Marta kò ti i doju ami, nitori Jesu fi i lọkan balẹ pe, arakunrin rẹ yoo yẹ. Idahun Marta pe oun mọ pe arakunrin oun yoo jinde ni Ọjọ Ajinde mu ki Jesu sọ ọkan ninu awọn ọrọ alarinrin ju lọ ti a ri ninu Iwe Mimọ nipa ara Rẹ, jijẹ Ọlọrun Rẹ ati agbara ajinde Rẹ: “Emi ni ajinde, ati iye: ẹniti o ba gbà mi gbọ, bi o tilẹ kú, yio yẹ: ẹnikẹni ti o mbẹ lãye, ti o si gbà mi gbọ, ki yio kú lailai.” Bi o tilẹ jẹ pe ohun ti Jesu sọ kò ti i ye Marta jinlẹ-jinlẹ, otitọ ọrọ wọnyii fun ọkàn rẹ layọ gidigidi, o si gbagbọ tọkantọkan. Ni idahun si Jesu, ọrọ yii bu jade lati inu odò ọkàn rẹ: “Bẹẹni, Oluwa, emi gbagbọ pe, iwọ ni Kristi na Ọmọ Ọlọrun.” Ijẹwọ igbagbọ ti o nilaari ti ẹnikẹni le ni!
Ko si ohun ti Maria le ṣe nigba ti o tọ Jesu wa ju pe ki o wolẹ lẹsẹ Jesu pẹlu omije ki o si wi pe: “Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakọnrin mi kì ba kú.” Nigba ti Jesu ri i ti Maria ati awọn Ju ti n tọ ọ lẹyin n sọkun, Oun naa sọkun pẹlu. Ọpọlọpọ arosọ ni awọn eniyan ti gbe kalẹ nipa ẹkún ti Jesu sun nibi iboji Lasaru ati ibanujẹ Maria. Lai si aniani, ẹkún ti Jesu sun yii tayọ ti ẹni ti ọfọ ṣẹ nipa ọrẹ rẹ ti o kú, bẹẹ ni o si tayọ omije lati bá Marta ati Maria kẹdun ninu ọfọ ti o ṣẹ wọn. Ibanujẹ Jesu eyi ti o rú jade lati inu odò ọkàn Ọmọ Ọlọrun, fi ifẹ ati aanu ti Ọlọrun ni si awọn ti o fẹ Ẹ hàn.
Itunu Onigbagbọ
Nihin yii nibi iboji ọrẹ ti o ṣọwọn, Jesu tun pade ọta ti Oun wá lati parun – ani ikú! Oro eyi ti i ṣe ẹṣẹ. Ati ẹlẹṣẹ ati eniyan Ọlọrun ni o n kú nipa bibọ agọ ti ara yii silẹ nitori egun Ọlọrun wà lori aye ẹṣẹ yii. Ki i ṣe ifẹ Ọlọrun ki awọn eniyan Rẹ maa joro ikú. Ki i ṣe ipinnu Ọlọrun ni ibẹrẹ pe ki a ya awọn ẹbi nipa tabi ki a si gba awọn ayanfẹ kuro lọwọ awọn olufẹ wọn. Ẹṣẹ ni o mú ọta yii ba eniyan - ikú!
Ọlọrun nikan ni o le tu awọn ti ọfọ ba ṣẹ ninu. Jesu gẹgẹ bi aworan Ọlọrun, lọ si iboji Lasaru lati lọ fi itunu Ọlọrun fun awọn onirobinujẹ nipa fifun ẹni ti o ti kú ni iye. Onisaamu sọ fun ni pe, “Bi ẹkun pẹ di alẹ kan, ṣugbọn ayọ mbọ li owurọ” (Orin Dafidi 30:5). Omije le gboju awọn eniyan Ọlọrun kan fun iwọn igba diẹ, ṣugbọn Ọlọrun yoo nu omije nù, wọn ki yoo si mọ (Ifihan 21:4).
Itunu Kristi, ti i ṣe ireti ajinde awọn oku ninu Kristi ni o ti n ṣe odi agbara awọn Onigbagbọ. Ajinde ni egungun-ẹyin Ihinrere. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe, “Ẹnyin o ma sọkun ẹ o si ma pohùnrere ẹkún, ṣugbọn awọn araiye yio ma yọ: inu nyin yio si bajẹ, ṣugbọn ibinujẹ nyin li yio si di ayọ … ọkàn nyin yio si yọ, kò si si ẹniti yio gbà ayọ nyin lọwọ nyin” (Johannu 16:20, 22; 1 Kọrinti 15:13-19).
Lasaru kú ki Ọlọrun ba le ji i dide bi ẹri nla fun awọn alaarẹ ọkàn ati awọn ti o ṣiyemeji si agbara Ọlọrun. Idahun kan naa ti Jesu fun Marta ati Maria ninu ibinujẹ wọn wà fun ọkàn kọọkan ti o ba fẹ gbọ ọ: “Bi o tilẹ kú, yio yẹ.” Otitọ ni ọrọ yii pe ikú kò le duro nibikibi ti Jesu Kristi orisun iye, bá wà. Ni aṣẹ Jesu si Lasaru pe “Jade wá,” o jade laaye ati ara lile.
Ihin ikú ati ajinde Lasaru tan kaakiri, nitori eyi, ọpọlọpọ gba Jesu gbọ. Ni gbogbo ọjọ aye rẹ, Lasaru jẹ ẹri nla si agbara ati oore-ọfẹ Ọlọrun.
Kò pẹ lẹyin eyi ni Jesu fi agbara Rẹ hàn, ati otitọ yii pe Oun ni Ajinde ati Iye, nipa ajinde Oun tikara Rẹ. Awọn Farisi rò pe wọn pa Jesu lẹnu mọ titi lae nipa ikú Rẹ. Kò pẹ ti ireti yii di asán, nitori ni ọjọ mẹta lẹyin eyi, isa oku kò le dá Olufunni ni Iye duro mọ, O si bú jade ninu ogo Rẹ. Nibi ti o ti jẹ pe ọpọlọpọ eniyan ni o gba Jesu gbọ nitori ajinde Lasaru, aimoye ọkẹ eniyan ni wọn ti gbagbọ nipasẹ ajinde Kristi.
Ogunlọgọ ọkẹ aimoye ti kú ikú Onigbagbọ, wọn ṣe bẹẹ tifẹtifẹ, pẹlu ifọkanbalẹ ti o ga pe ẹni ti o jí Jesu dide yoo jí awọn naa dide, yoo si jí gbogbo awọn ti wọn ba ké pe orukọ Rẹ dide(2 Kọrinti 4:14).
“Oun wà, Oun wà
Krist’ Jesu wà sibẹ!
O n ba mi sọrọ,
O pẹlu mi lọna ajo mi,
Oun wà, Oun wà,
Lati wa gba mi la! O ha fẹ mọ p’O wa laaye?
O n gbe ‘nu ọkàn mi.”
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti Jesu kò fi tete lọ si Bẹtani?
- Ki ni ṣe ti awọn ọmọ-ẹyin Rẹ kò fẹ ki O lọ?
- Ki ni Jesu sọ lati fi ọkàn ọmọ-ẹyin Rẹ balẹ pe Oun wà lai lewu?
- Iwuri wo ni Jesu fun Marta pe ohun gbogbo yoo lọ deedee pẹlu arakunrin rẹ?
- Ki ni ṣe ti Jesu sọkun nibi iboji Lasaru?