Johannu 11:47-54; Luku 13:10-17

Lesson 146 - Senior

Memory Verse
“O ṣànfani fun wa, ki enia kan kú fun awọn enia, ki gbogbo orilẹ-ẹde ki o má bà ṣegbé” (Johannu 11:50).
Cross References

IImularada Obirin Alailera Kan

1.Eṣu de obirin yii to bẹẹ ti kò fi le rin ni inaro, Luku 13:10, 11, 16

2.Jesu mu un lara dá, O si fi agbara ti O ni lori Eṣu hàn, Luku 13:12, 13; Heberu 2:14; 1 Johannu 3:8

3.Obirin naa yin Ọlọrun logo, Luku 13:13; Johannu 9:35-38

4.Olori sinagọgu kò yin Ọlọrun logo, ṣugbọn o fi irunu ṣe ariwisi si Jesu, Luku 13:14; Johannu 9:13-16

5.Olori sinagọgu kò gbà pe Jesu ni agbara Ọlọrun, nitori o ka iwosan ti Jesu ṣe si iṣẹ kan lasan dipo iṣẹ iyanu ti o ti ọwọ agbara Ọlọrun ṣẹlẹ, Luku 13:14; Matteu 12:24

6.Jesu ba agabagebe naa wi, O si doju ti gbogbo awọn ọta Rẹ nitori wọn ṣe alailaanu, Luku 13:15-17; Matteu 12:10-12

IIAwọn Igbimọ kọ lati Gba kristi

1.Asọtẹle nipa Messia ti fi hàn pe a o kọ Kristi lati ọwọ awọn eniyan Rẹ, Isaiah 53:3, 7-9; Orin Dafidi 2:2; 27:12; 35:11-15; 41:9; 69:4; 109:3-5; Sekariah 11:12

2.Asọtẹlẹ yii ṣẹ si Jesu ni gbogbo igbà ti O lò ni ayé, Matteu 2:12-15; 13:53-58; Johannu 1:11

3.Awọn ti o n ṣe inunibini si Jesu gbà pe O ni agbara lati ṣe iṣẹ iyanu nigba ti wọn fẹ bẹrẹ igbogun wọn, Johannu 11:47, 48

4.Ọlọrun lo olori alufaa igbà naa, ti i ṣe Kaiafa, lati sọ asọtẹlẹ nlá kan nipasẹ Etutu fun ẹṣẹ nigba ti o n fẹ lati dá iṣẹ buburu wọn lare, Johannu 11:49, 50; 18:14; 3:17; Galatia 3:13; 1 Kọrinti 15:22; 1 Peteru 2:21-25; 3:18

5.Ọrọ Ọlọrun fi ye wa pe Etutu naa wà fun ẹṣẹ gbogbo ayé, Johannu 11:51, 52; Heberu 2:9; 9:28; 2 Kọrinti 5:15; Romu 5:18; Iṣẹ Awọn Apọsteli 10:43; Ifihan 22:17

6.Jesu kò le rin ni gbangba laaarin awọn Ju mọ nitori inunibini ti o dide si I lakoko yii, Johannu 11:53, 54; Matteu 12:14-16

Notes
ALAYE

Iṣesi Wa Si Ọlọrun Lakoko Isin

Nipa ẹkọ yii, a le ri i pe iṣesi wa ṣe pataki, paapaa ju lọ nigba ti a ba wá lati sin Ọlọrun. Bi Jesu ti n kọ ni ninu ọkan ninu awọn sinagọgu awọn Ju, oniruuru ati oniwaiwa eniyan ni o wà nibẹ. Diẹ ninu wọn kò gba A, ṣugbọn bi o ti wu ki o ri, a mọ nipa ẹni kan ti o gba A gbọ ni ọjọ Isinmi yii, ati awọn miiran ti o yin In logo. Awọn ti o kọ Ọ kò ri ibukún gbà lọjọ naa, ṣugbọn obirin yii ri ibukún gbà fun igbagbọ ati ọkàn otitọ rẹ.

Obirin yii ni arun ti o mu ki o tẹ ki o si kákò pẹlu irora nlánlà. Iṣẹ eṣu ni aisan rẹ i ṣe gẹgẹ bi aisan miiran gbogbo ati ẹṣẹ ti jẹ iṣẹ eṣu pẹlu. Ṣugbọn o mọ daju pe Olukọni ti oun gbọrọ lẹnu Rẹ ni ọjọ naa ki i ṣe eniyan kan lasan. O ka iwe Ofin, o si ṣe àlàyé rẹ gẹgẹ bi wọn ti i maa ṣe nibẹ, ṣugbọn O n sọrọ taṣẹ-taṣẹ yatọ si awọn ẹlomiran ti obirin yii ti ba pade ri tabi ti o ti gbọrọ lẹnu rẹ. O wá si aye lati pa iṣẹ eṣu run, arun ara rẹ si jẹ ọkan ninu awọn ohun ti O wá lati fi agbara iyanu Rẹ mú kuro.

O ke si i, oun naa si dahun. O sọrọ itunu ti o mu ki ọlẹ ayọ sọ ninu rẹ, O sọ fun un pe a tu u silẹ kuro ninu ailera rẹ. Ọkan rẹ rọ mọ ohùn aṣẹ Rẹ. O gba A gbọ. O gbe ọwọ le e, O si na ẹyin ti o ti kákò, O si sọ ọ di alara dida ṣáṣá. Awọn egungun ti o ti kákò nà, wọn si bọ sipo. Lai si aniani, awọn egungun ti o ti di wọgunwọgun ni a mu pada bọ sipo daradara. Eyi ṣẹlẹ ni iṣẹju kan pere!

A wò ó sàn! Oun naa le rìn bi awọn ẹlomiran, o si le gbé oju rẹ soke ọrun lati wò ogo Ọlọrun, tabi ki o wohin-wọhun lọsan tabi loru lati gbadun awọn ohun meremere ti Ọlọrun dá. O ti gbagbe gbogbo ìṣẹ ati iya atẹyinwa! Nisisiyii o le bá ẹgbẹ ati ọgbà rìn lai jẹ pe wọn n fi i ṣẹfẹ tabi ki wọn maa kaanu fun un.

Ṣugbọn ẹ wo bi iṣesi rẹ, ki a to wo o san ati lẹyin ti a wo osan, ti yatọ si ti awọn miiran ti o wà nibẹ. A kò mọ bi eyi mú iyipada ba awọn ti o pejọ nibẹ. Ṣugbọn a mọ eyi pe o wólẹ lati sin Ọlọrun lẹyin ti a wo o san. A mọ pe kò le ri iwosan bi ko bá kọkọ gba Jesu gbọ ki o si tẹle Ọrọ Rẹ. O ni ọkàn igbagbọ; nitori eyi, Jesu le ṣiṣẹ iyanu nipasẹ rẹ lati doju ti awọn alaigbagbọ ati agabagebe ti o wà nibẹ.

Inu bi olori sinagọgu nipa ohun ti o ṣẹlẹ yii, o si fi ìkannú wi pe ọjọ miiran wà lẹyin Ọjọ Isinmi ti awọn eniyan le wá fun iwosan. Ero ọkàn rẹ ni pe iṣẹ agbara ni iwosan i ṣe, ati pe Jesu ki i ṣe Ọlọrun bi ko ṣe eniyan kan ṣakalá ti o fi agbara ẹran-ara ṣe iṣẹ iwosan.

Idande obirin yii kuro ninu igbekun eṣu ti o ti wà kò ja mọ nnkan kan loju agabagebe alaṣẹ yii. Kò tilẹ si ibakẹdun kinun ninu ọkàn ọkunrin yii fun ẹni ti o ti n ṣíṣẹ bi obirin yii lati nnkan bi ọdun mejidinlogun wá. Irora ti o ti fun un ni inira, itiju ti o ti fara dà, hila-hilo ti o ti n bá kiri nipa ipo ti o wà ti ireti rẹ gẹgẹ bi ẹdá pin, kò ja mọ nnkan kan fun ọkunrin yii.

Jesu bá a wí, O pe e ni agabagebe loju gbogbo ijọ eniyan. Ọmọ Ọlọrun fi ye wọn pe ẹnikẹni ninu wọn ni o n tú ohun ọsin rẹ silẹ ni Ọjọ Isinmi lati fun wọn ni omi mu. Ki ni ṣe ti Oun ki yoo tú obirin yii silẹ kuro ninu igbekun eṣu ni Ọjọ Isinmi?

Jesu ti sọ fun awọn ẹlomiran nigba kan ri pe a dá Ọjọ Isinmi nitori eniyan, a kò dá eniyan nitori Ọjọ Isinmi. O fun wọn ni apẹẹrẹ rere ṣiṣe ni Ọjọ Isinmi ki i ṣe riru Ofin bi kò ṣe ofin atọwọdọwọ wọn ti awọn tikara wọn ti so pọ mọ Ofin Ọlọrun. Ọjọ yii wà fun iyin Ọlọrun logo, lati sin In ati lati gbé orukọ Rẹ ga. Ọna kan ha wa ti o dara ju eyi lọ lati fi agbara Ọlọrun hàn nipa dida ẹni kan ti eṣu ti dẹ nigbekun silẹ, eyi ti yoo mú ki a yin Olufunni ni gbogbo ẹbun rere ati ẹbun pipe?

Olori sinagọgu fi ikannú sọrọ, boya ki i ṣe nitori biba Ọjọ Isinmi jẹ bi kò ṣe nitori a yin Jesu logo. “Kò si ẹniti o ti isọrọ bi ọkọnrin yi ri” (Johannu 7:46) abuku si kan awọn ti o n ṣe atako Otitọ, oju tì wọn, kẹkẹ si pa mọ wọn lẹnu niwaju Ẹni ti O sọrọ ti ayé si wà -- Ẹni ti wọn sẹ ti wọn kò si gbà! Ṣugbọn “iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ gbọ; awọn ẹniti a bí, ki iṣe nipa ẹjẹ, tabi nipa ifẹ ara, bẹẹni ki iṣe nipa ifẹ ti enia, bikoṣe nipa ifẹ ti Ọlọrun” (Johannu 1:11-13).

Atako N Pọ Si i

Ọjọ n lọ. Akoko Ẹbọ Nla nì n sún mọle. Ninu gbogbo awọn ti o ṣe alabapin ohun ti o ṣẹlẹ lati mu akoko oore-ọfẹ wọle yii, Jesu nikan ni O mọ iwuwo Rẹ. Nitori eyi ni O ṣe wá si aye. Ki i ṣe lati kọ ni nikan ni O ṣe wá. Kò fi Ọrun silẹ lati wá gbe ni ode ayé lati jẹ apẹẹrẹ nikan, O wa lati jiya! O wa lati kú! O wa lati ji ara Rẹ dide kuro ninu oku!

Awọn ti kò gba Jesu mọọmọ ṣe bẹẹ ni. Nipa ṣiṣe eyi, wọn dimọ lù pẹlu awọn wọnni ti wọn mu etò Ọlọrun fun igbala ẹda ṣẹ lai mọ pe ohun ti wọn n ṣe ni eyi. Iṣẹ ibi wọn bẹrẹ nipa kikọ ipe Ọmọ Ọlọrun ti O duro laaarin wọn – ipe ti o mu ni lọkan to bẹẹ. Ki i ṣe igbà kin-in-ni ti wọn ri Jesu tabi ti O ba wọn sọrọ ni wọn kan An mọ agbelebu. Ohun ti wọn kọ ṣe ni pe wọn kọ ẹkọ Rẹ; ni opin gbogbo rẹ, wọn kọ Oun paapaa! Lẹyin gbogbo eyi, wọn wi pe, awọn kò ni ipin tabi ipa ninu Ijọba Rẹ, nitori wọn wi pe, “Awa kò li ọba bikoṣe Kesari” (Johannu 19:16).

Diẹdiẹ ni atako n pọ sii. Bi o tilẹ jẹ pe wọn kọkọ kọ Ọ pẹlẹpẹlẹ, ṣugbọn nigbooṣe wọn tẹ ipá bọ ọ. Ninu ẹsùn wọn, wọn tilẹ jẹwọ pe Jesu ṣe iṣẹ iyanu, nipa eyi wọn jẹri si I pe O ni agbara ti o rekọja ti ẹdá. Niwọn bi o ti jẹ pe ninu ọkàn wọn lọhun wọn ti yan ohun ti o wu wọn pẹlu ipinnu ti kò le yi pada, wọn kò le tipasẹ iṣẹ iyanu wọnni mọ pe Ọlọrun ni o wà laaarin wọn yii. Wọn kò mọ pe wọn doju kọ Ẹni ti i ṣe Olori ohun gbogbo, ani Ẹni ti o tobi ju awọn alaṣẹ Romu lọ.

Kristi Arọpo Wa

Kaiafa, olori alufaa, gbiyanju lati ṣe àlàyé ipo wọn. Nipa ṣiṣe bẹẹ, Ọlọrun lò o lati rán araye leti pe, bi o tilẹ jẹ pe ejo nì kò ni pẹ pa Iru-ọmọbirin nì ni gigisẹ, ṣugbọn idande wà fun ẹnikẹni ti o ba gba Ihinrere gbọ. A ni lati rú ẹbọ nla ni lai pẹ jọjọ, nipasẹ eyi ti a o bi Satan ati ijọba rẹ wó.

Asọtẹlẹ ti kò lẹgbẹ ha kọ eyi! “O ṣànfani fun wa, ki enia kan kú fun awọn enia.” Kò si ẹni ti o tọ bi ko ṣe Ọdọ-Agutan Ọlọrun ti kò dẹṣẹ ti kò si labawọn. Idajọ iku wà lori gbogbo eniyan nitori gbogbo eniyan dẹṣẹ, wọn si jẹbi niwaju Ọlọrun. Ẹni kan kò le duro fun ẹṣẹ ẹni keji, nitori a ti dá oun paapaa lẹbi iku nitori ẹṣẹ ti rẹ. Kò le ku ju igba kan ṣoṣo lọ.

Ṣugbọn Ọlọrun gbe ilana kan yọ gẹgẹ bi gbogbo ilana Rẹ, pipe ni. Jesu alai lẹṣẹ ni yoo gba iku gbogbo eniyan kú. Kò si ẹṣẹ lori Rẹ; ati nitori Ọlọrun Oun i ṣe, O le fi ẹmi Rẹ lelẹ fun gbogbo ẹda alaaye – lati irandiran, ni gbogbo igbà ati fun gbogbo orilẹ ati ẹde.

Oun ni Ẹbọ pipe ti gbogbo ẹgbẹrun irubọ agọ-ajọ n tọka si. Oun ni Ẹbọ pipe ti ẹbọ sisun gbogbo lati ayebaye n tọka si. O ku fun gbogbo wa, nigba ti O si n kú lọ, O sọrọ asọkẹyin ti o fi ọkàn wa balẹ pẹsẹpẹsẹ ti o si jẹ ki a mọ pe a ti san gbese naa paapaa. Ki O to mi eemi ikẹyin, O wi pe, “O pari.” Nipa Ẹjẹ Rẹ ti O ta silẹ, a le ri idariji gbogbo ẹṣẹ wa gbà, ki a si wà bi ti Rẹ ni mimọ laulau, ki a si pese ọkàn wa silẹ lati pade Rẹ ni alaafia lẹyin ti awa ti wà fun Un laye yii.

“A kò le mọ, a kò le sọ,

Bi ‘rora Rẹ ti to,

Ṣugbọn a mọ pe ’tori wa

L’O ṣe jiya nibẹ.

“O kú ka le ri dariji,

Ka le huwa rere,

Ka si le d’ọrun nikẹyin

Ni ’toye Ẹjẹ Rẹ.

“Ko s’ẹni rere miiran mọ

T’o le sanwo ẹṣẹ,

Oun lo le ṣilẹkun Ọrun,

K’o si gba wa sile.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni olupilẹṣẹ ẹṣẹ ati aisan?
  2. Tọka si ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun kan ti o fi hàn fun ni Ẹni ti o le pa olupilẹṣẹ ẹṣẹ ati aisan run ki o si ka a lati ori.
  3. Lẹyin ti a wo o san, ihà wo ni obirin alarun naa kọ si Ọlọrun?
  4. Lọna wo ni iwa rẹ gba fi yatọ si ti olori sinagọgu?
  5. Ọrọ pataki wo ni olori sinagọgu sọ lati sẹ pe Jesu jẹ Ọlọrun d’eniyan?
  6. Ta ni olori alufaa ni ọdun naa?
  7. Tọka si asọtẹlẹ ti Ọlọrun sọ lati ẹnu rẹ wa, ka eyi lati ori ki o si fi hàn lati inu Bibeli ẹtọ ti a ni lati sọ pe ọrọ naa jẹ mọ awa ti ode-oni.
  8. Ki ni ohun pataki ti o ṣẹlẹ ni akoko olori alufaa kan naa yii?
  9. Ki ni itilẹyin ti a ni lati inu Bibeli lati sọ pe Etutu yii wà fun gbogbo eniyan ti o ba yàn lati gbà anfaani ti ó wà ninu rẹ?
  10. Ki ni iyipada ti Jesu ṣe nipa igbesi aye Rẹ nitori idojukọ yii?