Luku 13:23-30; Matteu 7:13, 14

Lesson 147 - Senior

Memory Verse
“Nitori ọpọlọpọ li a pẹ, ṣugbọn diẹ li a yàn” (Matteu 22:14).
Cross References

IẸnu-ọna Hiha ti O Lọ si Ijọba Ọrun

1.Ọkan ninu awọn eniyan beere pe, “Oluwa, diẹ ha li awọn ti a o gbalà?” Luku 13:23

2.Jesu dahun bayii pe ki gbogbo eniyan làkàkà lati wọ oju-ọna koto, Luku 13:24; Matteu 7:13, 14; Johannu 6:27; 2 Peteru 1:10

3.Akoko kan n bọ nigba ti a o ti ilẹkun ọna hiha ati tooro yii, Luku 13:24, 25; Matteu 25:10-12

IILẹyin Ilẹkun Lode

1.Awọn oniṣẹ ẹṣẹ ni a o tì mọ ẹyin ode ni Ijọba Ọlọrun, Luku 13:26, 27; Romu 9:31-33; 10:3; 2 Timoteu 3:1-5; Titus 1:16

2.Iya ti yoo jẹ awọn eniyan buburu yoo tubọ pọ si i nigba ti wọn ba ri awọn ti o wà ninu Ijọba, ti a si ti awọn si ode, Luku 13:28; 16:23; Ifihan 21:8

IIIIpe Si Gbogbo Agbaye

1.Ọpọ ni yoo gbọ ipe Ọlọrun kaakiri gbogbo aye ti wọn yoo si wá jokoo ninu Ijọba naa, Luku 13:29; Isaiah 43:5-7; Ifihan 7:9, 10

2.“Awọn ẹni-ẹhin mbẹ ti yio di ẹni-iwaju, awọn ẹni-iwaju mbẹ ti yio di ẹni-ẹhin,” Luku 13:30; Matteu 3:9; 8:11, 12

Notes
ALAYE

Ibugbe Ọlọrun ati Awọn Ẹni Irapada

Ibi giga ati ibi mimọ ni Ọrun i ṣe – ibi ti Ọlọrun n gbe. Bibeli royin ẹwà rẹ niwọn bi ẹdẹ awa ẹdá ti mọ. Wura ni a ṣe Ilu Mimọ naa, o mọ gaara to bẹẹ ti o fi dabi awojiji, wura ni a fi ṣe ita rẹ pẹlu. Pearli ni a fi ṣe ẹnu ibode rẹ mejila, awọn okuta iyebiye ni a si fi ṣe ipilẹ rẹ. Oòrùn tabi oṣupa ki yoo si nibẹ, nitori ogo Ọlọrun yoo tan imọlẹ si Ilu naa, Ọdọ-Agutan si ni Imọlẹ rẹ.

Pẹlu apejuwe meremere yii, sibẹ Iwe Mimọ sọ fun ni pe, “Ohun ti oju kò ri, ati ti eti kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni ti Ọlọrun ti pẹse silẹ fun awọn ti o fẹ ẹ” (1 Kọrinti 2:9). Ibi meremere yii ni yoo jẹ ibugbe Ọlọrun ati awọn eniyan mimọ Rẹ titi ayé ainipẹkun. Ẹni kan ha wà ti kò fẹ lati fi Ilu daradara yii ṣe ibugbe lẹyin ti ayé yii ba pin? Kò ṣanfaani ki ẹnikẹni kùnà lati de Ọrun nitori a ti san gbese irapada fun gbogbo aye; ẹnikẹni ti o ba si fi otitọ wá igbala ọkàn rẹ, ti o si ronupiwada ẹṣẹ rẹ tọkantọkan, yoo ri igbala.

Diẹ Ni A Gbàla

O dabi ẹni pe ẹni ti o tọ Jesu wa ti o si beere pe, “Oluwa, diẹ ha li awọn ti a o gbalà?” ni ọkàn ti o n rò nipa ayeraye. Lai si aniani, Ju ni ọkunrin naa i ṣe, awọn amofin Ju si ti sọ pe gbogbo Israẹli ni yoo ni ipin ni Ijọba Ọlọrun. Awọn ọmọ Abrahamu fi ireti igbala wọn si ori ijolootọ obi wọn. Wọn gbẹkẹle ìbí wọn nipasẹ Abrahamu pe yoo mu wọn de Ọrun lailewu, ṣugbọn ireti asán ni eyi, o si dabi ẹni pe ọkunrin yii mọ bẹẹ. Iru ohun kan naa wà lode oni. Awọn ọmọ ti o jẹ pe adura baba tabi iya wọn ti i ṣe Onigbagbọ nikan ni wọn gbẹkẹle fun igbala kò jinna si abamọ, nitori olukuluku ni o ni lati gbadura fun igbala ọkàn ara rẹ. Ọlọrun sọ pe nigba ti Oun yoo bá mu idajọ wá sori aye, “bi Noa, Daniẹli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn ki yio gba ọmọkọnrin tabi ọmọbirin là; kiki ọkàn ara wọn ni awọn o fi ododo wọn gbàla” (Esekiẹli 14:20).

Ọna kan ni o lọ si Ọdọ Ọlọrun ati Ọrun, eyi ni ọna tooro, ti i ṣe Jesu Kristi. Jesu wi pe, “Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là” (Johannu 10:9). “Emi li ọna, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi” (Johannu 14:6). A ta Ẹjẹ Jesu silẹ fun ẹṣẹ araye, nibikibi ti o wu ki wọn wà, ṣugbọn a ni lati fi Ẹjẹ yii wẹ ọkàn eniyan ki o to le mu ẹṣẹ rẹ kuro.

Ẹnu-Ọna Hiha

Jesu kò da onibeere naa lohun taara. Sibẹ, idahun Jesu fi hàn gbangba pe ẹni ti o ba fẹ ni igbala ni ohun kan lati ṣe, diẹ si ni awọn ti o fẹ ṣe e. Lati de Ọrun gbà ju pe ki a kan sa ipá wa nipa ààbọ ọkàn ati ilọwọwọ niwọn iba ti a le ṣe. Jesu wi pe “Ẹ làkaka lati wọ oju-ọna koto.” Eyi ni pe ki a gbiyanju gidigidi. Lọna miiran a tun le wi pe, ki a wọ iwa-yá-ijà lati gba ọna tooro wọle, bi o ba gbà bẹẹ. Ọna kan ṣoṣo yii ni “o lọ si ibi iye.” Gbogbo awọn ti a gbala ni yoo si gba ọna yii. Ѐre ti awọn ti o ba fi tọkantọkan rin ọna yii yoo ri gbà yoo tayọ inirakinira ti o wù ki wọn ba pade, itumọ kan naa ni gbigbà ọna tooro wọle jẹ pẹlu ohun ti Jesu sọ fun Nikodemu. “Bikoṣepe a tun enia bi, on kò le ri ijọba Ọlọrun” (Johannu 3:3). A o yi ẹni naa pada patapata: yoo kọ ẹṣẹ rẹ silẹ; Ọlọrun yoo dariji i, yoo si mu gbogbo ẹṣẹ rẹ kuro; ẹni naa yoo si di ẹdá titun. “Nitorina bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun” (2 Kọrinti 5:17).

Oju-ọna Tooro

Jesu ni Ọna Hiha naa. Ọna tooro nigbà naa ni ọna iwà mimọ. Ọna naa ati ibode rẹ mọ bakan naa, ekinni kò si fẹ ju ekeji. Ki í ṣe nitori ọna naa nira tabi pe kò larinrin ni a ṣe n pe e ni ọna tooro. Awọn ti wọn n rin lọna yii ni o layọ ju lọ layé. Wọn mọ pe wọn kò wá laye ṣá, ṣugbọn wọn ni opin kan ti wọn n lepa. Aye yii kò dá Onigbagbọ níjì, oró ikú si ti sọ oró rẹ nu. Ki ni ṣe ti inu rẹ ki yoo fi dùn?

Tooro ni ọna naa nitori kò gba ni gba ẹṣẹ. “Opopo kan yio si wà nibẹ, ati ọna kan, a o si ma pẹ e ni, Ọna iwà-mimọ; alaimọ ki yio kọja nibẹ; nitori on o wà pẹlu wọn: awọn ẹro ọna na, bi wọn tilẹ jẹ òpe, nwọn ki yio ṣì i. Kiniun ki yio si nibẹ, bẹẹni ẹranko buburu ki yio gùn u, a ki yio ri i nibẹ; ṣugbọn awọn ti a ti ràpada ni yio ma rìn nibẹ” (Isaiah 35:8, 9). Ọna naa kò di titẹju si i bi o ti n lọ si ode Ọrun. Bi a ba le sọ ohunkohun nipa rẹ rárá, n ṣe ni ọna naa n di tooro siwaju si i bi o ti n sun mọ Ita Wura naa, ṣugbọn òye ọna yii ti ye arinrin-ajo daradara, o si n fi ayọ rin lọ ni oju ọna tooro naa.

Kò Jinlẹ Tó

Awọn ti Jesu sọ pe wọn “yio wá ọna ati wọ ọ, nwọn ki yio si le wọle”, ni awọn ti wọn gbiyanju diẹ lati ni igbala, ṣugbọn ti wọn yoo ṣegbe nitori wọn kò walẹ jìn tó. Boya wọn tilẹ ri ẹnu ibode naa, wọn si yẹ ọna naa sí, ṣugbọn wọn kunà oore-ọfẹ ati ogo Ọlọrun nitori lẹẹkọọkan ni wọn n wá ohun ti a ko le ni bi ko ṣe pe a ba lakaka gidigidi. Ọpọlọpọ ni o gbẹkẹle pe orukọ wọn wà ninu iwe ijọ, ṣugbọn Jesu sọ pe a ni lati kọ orukọ wọn sinu Iwe Iye ti Ọdọ -Agutan. Ohun kan daju: Awọn wọnyii kò làkaka tọkantọkan lati sọ ipẹ ati yiyan wọn di dajudaju nigba ti ilẹkun aanu wà ni ṣiṣi-silẹ. Lẹẹkan ti Oluwa ti dide ti O si se ilẹkun, awọn eniyan yii bẹrẹ si làkàkà lati wá ọna lati wọle. Akoko ti wọn fi n ṣe dakudaji ti kọja. Wọn fi tọkantọkan tẹra mọ adura gbigba, ṣugbọn wọn kò le wọle nisisiyii, nitori adura wọn ti pẹ jù.

“Oluwa, Oluwa”

Ẹbẹ awọn eniyan yii fi hàn pe wọn kò ṣalai ni imọ nipa Jesu ati ọna Rẹ. “Awa ti jẹ, awa si ti mu niwaju rẹ, iwọ si kọni ni igboro ilu wa.” Wọn jẹwọ pe wọn ti gbọ itan Ihinrere ati ipẹ Jesu ninu ọkàn wọn; ṣugbọn wọn ti kunà lati jẹ ipe naa tọkantọkan. “Ki iṣe gbogbo ẹniti npẹ mi li Oluwa, Oluwa, ni yio wọle ijọba ọrun: bikoṣe ẹniti nṣe ifẹ ti Baba mi ti mbẹ li ọrun” (Matteu 7:21). Ni gbogbo igbà ti wọn fi n fi ara ṣe igbagbọ, wọn kò kuro lọna gbooro, nitori Jesu wi pe, “Ẹ lọ kuro lọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ ẹṣẹ.” Olukuluku eniyan ni lati kiye sara gidigidi lati bá ẹnu-ọna hihá wọle, ki o si maa rin lọna tooro pẹlu otitọ ọkàn titi yoo fi lọ si Ọrun rere ti ilẹkun yoo si ti lẹyin ti o ti wọle tan!

Wo bi ibanujẹ awọn ti a sé ilẹkun Ijọba Ọrun mọ si ẹyin ode ti pọ tó. “Ẹkún ati ipahinkeke yio wà nibẹ.” A o gba awọn eniyan mimọ ati awọn wolii ti igba Majẹmu Laelae si Ijọba Ọlọrun lati gbadun ire ti o wà nibẹ, nitori pe wọn ri Ọjọ Kristi lokeere nipa igbagbọ wọn si ri itoye Ẹjẹ Rẹ ti O ta silẹ. Ibanujẹ awọn ti o ṣegbe yoo tubọ pọ si i nigba ti wọn ba ri awọn eniyan mimọ ati awọn wolii ti o ti dide lati irandiran ti wọn n gbadun ibukun ti o wà ni Ọrun ti a si ti awọn paapaa si ode.

Ipe Kristi

Ipe Ihinrere yoo dún jakejado gbogbo agbaye, awọn eniyan yoo wá lati Ila-oorun, Iwọ-oorun, Guusu ati Ariwa, wọn o si jokoo ni Ijọba Ọlọrun. Ipe Kristi n dún titi de opin ilẹ ayé lọjọ oni. Jesu wi pe, “A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ẹde; nigbana li opin yio si de” (Matteu 24:14). A ti ṣe itumọ awọn apa kan ninu Bibeli si ede ti o lé ni ẹẹdẹgbẹfa (1,100), a si ti n waasu Ihinrere ni ibi gbogbo ti a le mọ ni orilẹ-ẹde ayé. Opin ko ha sun mọ tosi?

Ohun ti o ya ni lẹnu ninu gbogbo ọran yii ni pe awọn ti a n pe ni Keferi, ti wọn ti wà ninu okunkun biribiri ati isin atọwọdọwọ lati iran-diran n tẹwọ gba ẹkọ Ihinrere kánkán ju awọn ti wọn sọ pe wọn wa ni ilẹ Onigbagbọ. Eyi jẹ ẹri si ẹsẹ Ọrọ yii, “Si wo o, awọn ẹni-ẹhin mbẹ ti yoo di ẹni-iwaju, awọn ẹni-iwaju mbẹ ti yoo di ẹni-ẹhin.” Awọn ti o ti ni imọlẹ Ihinrere fun ọdun pupọ ti wọn kò si jara mọ ọn ni a o kọ ti a o si ti si ẹyin ode. Awọn ẹlomiran ti kò ni anfaani yii ti o si dabi ẹni pe wọn ṣegbe lati ibẹrẹ wá ṣugbọn ti wọn si tẹwọ gba ọna irapada nigba ti o di mimọ fun wọn, yoo jẹ ẹni-iwaju ni Ijọba Ọlọrun.

Awọn Ọna ti O Lodi si Ara Wọn

Lọna bayii, a ri ẹwa ati iwuri ti o wa ni ẹnu ọna hiha ati oju ọna tooro. A ri opin rere ti o wà ni igbẹyin ọna yii, a si mọ pe nipa lilàkàkà nikan ni ọwọ wa le fi tẹ ẹ. Ẹnikẹni ti kò ba rin ni ọna tooro, o wà ni oju ọna gbooro ti Jesu sọ nipa rẹ.

Ronu ni iṣẹju kan nipa ọna gbooro ati onibu yii, ọna ẹṣẹ ati iwa buburu. O le dabi ẹni pe ọna naa rọrùn lati rin, nitori ẹni kan sọ fun ni pe ọna ọrun apaadi kún fun ero rere gbogbo ti a kò mu ṣẹ; ṣugbọn iparun ni opin ọna gbooro. Ikú, ikú ayeraye ati iya ainipẹkun ni o wà ni opin ọna yii.

Awọn ọna wọnyii kò dọgba; ekinni lodi si ekeji. O wà ni ipá ẹni kọọkan lati yan ọna ti oun yoo tọ. Ọrọ naa wà niwaju wa gbangba: ọna hiha, ọna tooro ati ìye; tabi ọna gbooro, ọna onibu ati iparun. Eyi ti o yẹ ki a yàn fara hàn gbangba lai si ariyanjiyan. “Ati Ẹmi ati iyawo wipe, Mã bọ. Ati ẹniti o ngbọ ki o wipe, Mã bọ. Ati ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o ba si fẹ, ki o gbà omi iye na lọfẹ” (Ifihan 22:17).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ohun ti ọkan ninu awọn ti wọn pejọ beere lọwọ Jesu?
  2. Ki ni Jesu fi dá a lohun?
  3. Ki ni ohun ti Jesu rò nigba ti O wi pe, “Ẹ bá ẹnu-ọna hiha wọle”?
  4. Ọpọlọpọ eniyan ha ni wọn n bá ẹnu-ọna hiha wọle?
  5. Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ti kò ba ẹnu ọna hiha wọle?
  6. Ibi daradara wo ni o wà ni opin ọna tooro?
  7. Nibo ni ọna gbooro ati onibu lọ sí?
  8. Ewo ni iwọ rò pe o dara ninu ọna meji yii? Iwọ ha wà loju ọna naa?