Luku 14:1-24

Lesson 148 - Senior

Memory Verse
“Nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ ga, li a o rẹ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ ara rẹ silẹ, li a o si gbéga”(Luku 14:11).
Cross References

INi Ile Farisi

1.Jesu mu ọkunrin kan lara dá ni Ọjọ Isinmi, Luku 14:1-6

2.Jesu n kọ wọn ni ẹkọ bi a ti ṣe i fi irẹlẹ yan ijoko, Luku 14:7-11

3.Jesu kọ Farisi naa ni iru awọn eniyan ti o ni lati maa pẹ si ibi ase rẹ, Luku 14:12-14

IIAwọn ti a Pe si Ase Ihinrere Kọ Ipe Naa

1.A pese ase nla kan silẹ a si nawọ ipe kaakiri, Luku 14:15-17

2.Wọn fi aniyan aye ṣiwaju ipe mimọ naa,

(a)“Ilẹ kan” jẹ ohun pataki loju ẹni kin-in-ni ju “Ilẹ Ileri lọ”, Luku 14:18

(b)“Ajaga malu marun” jẹ ohun ti o niye lori ju iṣura ti Ọrun lọ, Luku 14:19

(d)“Iyawo” jẹ ohun ribiribi loju ẹni kẹta ju awọn ohun ti i ṣe ti Ọlọrun, Luku 14:20

IIIIpe si Awọn Talaka, awọn Alabuku arùn, awọn Amukun ati awọn Afọju

1.Ipe naa jade lọ si igboro ati abuja ọna ni gbogbo ilu, Luku 14:21

2.A tun rán ipe yii jade lọ si ọna oko, ki ile naa ba le kún, Luku 14:22, 23

3.A ṣe gafara fun awọn ti a kọ pe, a kò si jẹ ki wọn tọwo ninu ase naa, Luku 14:24

Notes
ALAYE

Ọjọ Isinmi ati Ọjọ Oluwa

Awọn Farisi ni itara gbigbona fun Ọjọ isinmi wọn. Oluwa ti paṣẹ pe ki wọn ranti Ọjọ Isinmi lati lo o ni mimọ, ṣugbọn wọn ti rekọja awọn ofin Ọlọrun nipa ofin atọwọdọwọ wọn nipasẹ ohun ti a le ṣe ati ohun ti a kò gbọdọ ṣe ni Ọjọ Isinmi. Bi Jesu ti wọle Farisi kan lọ ni Ọjọ Isinmi, wọn n ṣọ Jesu finnifinni bi yoo ba pa ofin atọwọdọwọ wọn mọ nipa Ọjọ Isinmi yii. Jesu kò jẹ ki wọn gbe ibeere wọn jade, ṣugbọn, nitori O mọ ọkàn wọn, O bi wọn leere pe, “O ha tọ lati mu-ni larada li ọjọ isimi, tabi kò tọ?”

Igba gbogbo ni ibeere yii maa n jade ninu iṣẹ iranṣẹ Jesu. Nigba kan ri olori sinagọgu kilọ fun awọn eniyan ki wọn ma ṣe wá fun imularada ni Ọjọ Isinmi (Luku 13:14). Nigba kan ti ọrọ yii de lẹ, Jesu wi pe, “Nitorina li o ṣe tọ lati mã ṣe rere li ọjọ isimi” (Matteu 12:12). O wi fun wọn pe, “A dá ọjọ isimi nitori enia, a kò dá enia nitori ọjọ isimi: nitorina Ọmọ-enia li oluwa ọjọ isimi pẹlu” (Marku 2:27, 28). Ofin beere pe ki a pa Ọjọ Isinmi mọ. Awọn Onigbagbọ kò si labẹ Ofin lọjọ oni bi kò ṣe labẹ Oore-ọfẹ. A kò pa Ọjọ Isinmi awọn Ju ti i ṣe Satide mọ, bi ko ṣe Ọjọ Oluwa ti i ṣe ọjọ Ọsẹ, ọjọ ti Jesu jinde kuro ninu oku, fun idalare wa. Kristi ni “akọso” ti ajinde. Ofin Mose tọka si ọjọ yii nigba ti o paṣẹ pe ki a mu akọso eso wa “ni ijọ keji lẹhin Ọjọ Isimi” fun irubọ, eyi ni Ọjọ Ọsẹ ti wa. “Ọjọ kini ọsẹ” ni Jesu jinde, ọjọ naa ni O fara hàn nigba pupọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ lẹyin ti O jinde; ni ọjọ yii ni agbara Ẹmi Mimọ sọkalẹ (Iṣe Awọn Apọsteli 2), ti Jesu fi idi Ijọ Rẹ mulẹ; o jẹ ọjọ ti awọn ọmọ-ẹyin maa n pade lati bu akara ni iranti Ounjẹ-Alẹ Oluwa, ti wọn si n mú ọrẹ wọn wa fun Oluwa; ọjọ yii ni awọn ọmọ ijọ ti igba nì n pamọ lati nnkan bi aadọrin ọdun titi de nnkan bi ọọdunrun ọdun o le mẹrinlelogun lẹyin iku Oluwa, gẹgẹ bi ẹri awọn baba wa nipa igbagbọ lati ọdọ Ignatiusi (Ignatius) titi o fi de ọdọ Eusebiusi (Eusebius).

Ki i ṣe Kọnstantine (Constantine) tabi Poopu (Pope) awọn Aguda, tabi ẹlomiran ni o gbe ọjọ ekinni ọsẹ kalẹ gẹgẹ bi “Ọjọ Oluwa.” Gẹrẹ ti Jesu ti jinde ni ọjọ yi ti di ọjọ ijọsin gbogbo awọn Onigbagbọ otitọ labẹ Majẹmu Titun; lati igba ní titi di oni-oloni ni a si ti n pa ọjọ yi mọ. Gẹgẹ bi Onigbagọ, lọjọ oni, awa pẹlu gbọdọ pa Ọjọ Oluwa mọ, a kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ tabi ki a maa tà tabi ki a maa rà tabi ki a ṣe ohunkohun ti kò ni laari ni Ọjọ Oluwa (Wo Nehemiah 13:15-23; Isaiah 58:13, 14).

Yiyan Ipo Giga

Jesu n ṣọ awọn ti a pẹ wá si ibi ase pẹlu Rẹ ni ile ọkunrin Farisi nì. O ri i bi wọn ti n yan awọn ipo ọlá. Eyi lodi si ofin wọn. Sọlomọni sọ fun wọn pe, “Máṣe ṣefefe niwaju ọba, má si ṣe duro ni ipò awọn enia nla. Nitoripe, o san ki a wi fun ọ pe, wá soke nihin, jù ki a fà ọ tì sẹhin niwaju ọmọ-alade ti oju rẹ ti ri” (Owe 25:6, 7).

A sọ fun ni ki a “máṣe fi ija tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ lọ” (Filippi 2:3). A ni lati rẹ ara wa silẹ “labẹ ọwọ agbara Ọlọrun” ki Oun le gbé wa ga ni akoko ti o wọ. Ẹnikẹni ti o ba gbe ara rẹ ga ni a o rẹ silẹ. O sàn ki a tikara wa rẹ ara wa silẹ ju pe ki Oluwa rẹ wá silẹ lọ. Oun yoo ṣe bẹẹ, bi o ba yẹ lati ṣe e, ṣugbọn ó le ni wa lara lati gba a. Jesu rẹ ara Rẹ silẹ. “Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ: pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo kun ki o mã kunlẹ.” Ọlọrun ti pese ohun nlá fun wa, bi a ba rin ni irẹlẹ niwaju Ọlọrun ni ayé nihin.

Awọn ti O Yẹ Lati Pẹ

Nigba ti a ba se ase, “awọn talakà, ati awọn alabùkù arùn, ati awọn amọkun, ati awọn afọju” ni o yẹ ki a pẹ. Ifẹ wa kò ni lati pin si ọdọ awọn ara ile wa, awọn ọrẹ wa, ẹbi wa tabi awọn ọlọla ni adugbo wa nikan. “Bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ kili ẹnyin ni?” (Matteu 5:46). Jesu kú fun ẹlẹṣẹ. Ọlọrun fẹ wa nigba ti awa jẹ ẹlẹṣẹ sibẹ. A kọ ni pe, “Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti wọn nṣe inunibini si nyin; ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun” (Matteu 5:44, 45). Bi awa ba jẹ ọmọ Ọlọrun, iru ifẹ ti Oun fi fẹ wa ni lati fi ara hàn ninu wa si awọn ẹlomiran. O dara lati ṣoore fun awọn ọrẹ wa nitori a jẹ ọrẹ, ṣugbọn Ọlọrun ti ṣeleri pe bi a ba kaanu “awọn talakà, ati awọn alabùkù arùn, amọkun ati afọju,” Oun yoo fun wa ni ibukun rẹ ni Ọjọ Ajinde.

Ipe Ihinrere

Owe ase nla ti aṣaalẹ yii fi iwa ọpọlọpọ ẹda si ipe Ọlọrun hàn lati igba ti ayé ti ṣẹ titi di isisiyii. Ni pataki, o fi hàn bi awọn Ju ti a pẹ ti kọ Jesu silẹ. Iru awawi ti kò ni laari bayii ti awọn ti a pẹ nigba nì ṣe ni ọpọ ninu awọn ti ode-oni n ṣe sibẹ.

Ounjẹ Alẹ Nla Kan

Ounjẹ alẹ nla ni eyi. Owo iyebiye ni a fi pese rẹ. Iye owo irapada wa kò ṣe ṣiro nipa idiwọn ohun ti isisiyii. Ẹmi Ọmọ Ọlọrun ni O fi tan an. Gbogbo ohun ti yoo gba ni Ọlọrun fi fun un lati ba araye laja sọdọ ara Rẹ. Ninu iṣẹ iranṣẹ Jesu laye, O wá sọdọ awọn ti Rẹ -- awọn Ju. O wi pe, “A kò rán mi, bikoṣe si awọn agutan ile Israẹli ti o nù” (Matteu 15:24). Israẹli kò kara mọ anfaani ti a fi fun wọn, wọn kọ Olugbala, wọn wi pe, “Ki ẹjẹ rẹ wà liori wa, ati li ori awọn ọmọ wa” (Matteu 27:25). Lonii, ipe ti jade si gbogbo agbaye pe, “Ẹ wá; nitori ohun gbogbo ṣe tan.”

Awawi

A sọ fun awọn ti a pe wa jẹun nipa ase ti o n bọ wa. Jesu sọ fun awọn Ju, “Ẹnyin nwá inu iwe-mimọ nitori ẹnyin rò pe ninu wọn li ẹnyin ni iyẹ ti kò nipẹkun; wọnyi si li awọn ti njẹri mi” (Johannu 5:39). Nigba ti akoko ounjẹ to, awọn iranṣẹ jade lọ lati pe awọn ti a ti pẹ. “Gbogbo wọn si bẹrẹ, li ohùn kan lati ṣe awawi.” Awawi ti kò ni laari! Ekinni ra ilẹ biiri kan, o si fẹ lọ wò ó. Lai si aniani o ti ra a lai yẹ ẹ wo, nisisiyii o fẹ lọ wo o ni akoko ounjẹ alẹ nigba ti ilẹ ṣú tán. Wọn ti ṣe gbogbo eto pari; ilẹ naa kò ni sá lọ, ṣugbọn kò le jẹ ki o di ẹyin ounjẹ alẹ ki o to lọ. O jẹ ki iṣẹ di oun lọwọ iyẹ ainipẹkun. Ọpọlọpọ eniyan lode oni ni ohun ayé yii ti dí lọwọ to bẹẹ ti wọn kò fi naani iyẹ ainipẹkun. O pa ọran iyẹ ainipẹkun tì si apakan fun ilepa awọn ohun ayé diẹ ti o n ṣegbe.

Oriṣiriṣi awawi ni awọn eniyan n ṣe lonii fun idi rẹ ti wọn kò fi gba ipe Ihinrere. Ọpọlọpọ ni kò fẹ kọ afẹ ayé ati irera ẹṣẹ silẹ. Wọn kò ronu jinlẹ bi o ti lewu to lati ṣe aibikita ni kikọ Ọlọrun silẹ. Ọlọrun wi pe, “Ẹnikẹni ninu awọn enia wọnyi ti a ti pẹ, ki yio tọwò ninu àse-alẹ mi.” Gbogbo awọn ti o n ṣe awawi ni a yọnda ifẹ wọn fun ti a si kọ fún lati wá si ibi ase naa.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Sọ awọn iṣẹ iwosan gbogbo ti Jesu ṣe ni Ọjọ Isinmi.
  2. Ki ni ṣe ti a fi n pa Ọjọ Oluwa mọ dipo Ọjọ Isinmi awọn Ju?
  3. Ki ni Jesu fi dahun ibeere yii, “o ha tọ lati mu-ni larada li ọjọ isimi”?
  4. Ki ni idaamu ti a le ba pade bi a ba yan ibi giga nibi ase?
  5. Ki ni yoo ṣẹlẹ si ẹni ti o ba gbé ara rẹ ga?
  6. Nigba wo ni a o san án fun wa bi a ba pe awọn talaka ati awọn amọkun si ibi ase?
  7. Ki ni itumọ owe ti àse-alẹ nla yii?
  8. Ki ni awawi ti awọn ti a pe sibi ase naa ṣe?
  9. Ki ni ṣẹlẹ si awọn ti o ṣe awawi?
  10. Ki ni awọn diẹ ninu awawi ti awọn eniyan n ṣe fun aisin Ọlọrun lọjọ oni?