Luku 14:25-33

Lesson 149 - Senior

Memory Verse
“Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ, ki o si gbé agbelebu rẹ, ki o si mã tọ mi lẹhin” (Matteu 16:24).
Cross References

IOhun ti Yoo Gbà Lati Jẹ Ọmọ-Ẹyin

1.A kilọ fun ọpọ eniyan ti n wọ tọ Jesu lẹyin pe isin ti ko ti ọkàn wa, kò ṣe itẹwọgba niwaju Ọlọrun, Luku 14:25-33; Deuteronomi 13:6-10; Ẹksodu 32:26-28; Ifihan 3:15, 16; Owe 24:27, 30-34; Matteu 10:37, 38

2.Iṣẹ isin wa si Ọlọrun kò gbọdọ já bi o ti wu ki a ni idojukọ tó, Luku 14:27; 9:23-26; Marku 10:21; Johannu 19:17; 2 Timoteu 3:12; Iṣe Awọn Apọsteli 14:2; Matteu 13:21

3.Ifara rubọ ni lati jẹ eyi ti o ti ọkàn wá, Matteu 8:19-22; Luku 9:57-62; 1 Awọn Ọba 19:19-21

IIIṣẹ-Isin ti a Gbe Iṣiro Lé

1.Jesu kọ awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe wọn ni lati ṣiro ohun ti jijẹ ọmọ-ẹyin Oun yoo gbà wọn, Luku 14:28-33; Matteu 10:37, 38; 1 Kọrinti 3:9; Iṣe Awọn Apọsteli 7:39; Luku 17:31, 32

2.Igbesi aye ti a fi ji fun iṣẹ-isin Ọlọrun nikan ni o n fun ni ni idaniloju pe a o rin irin-ajo naa de opin rere, Luku 14:33; Romu 12:1; Marku 10:28-30; Heberu 10:4-10

3.Majẹmu Laelae sọ oniruuru igbà ti awọn kan jẹ ẹjẹ wọn, lati fi ṣe apẹẹrẹ ifara-rubọ patapata ti Oluwa n fẹ, 2 Samuẹli 24: 17- 25; 1 Samuẹli 1:11-15, 24-28; Orin Dafidi 50:6-15

Notes
ALAYE

Titọ Jesu Lẹyin

Jesu paṣẹ fun awọn ti o ba fẹ tọ Ọ lẹyin pe, “Bi ẹnikan ba tọ mi wá, ti ko si korira baba rẹ, ati iya; ati aya, ati ọmọ, ati arakọnrin, ati arabirin, ani ati ẹmí ara rẹ pẹlu, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi.” Awọn miiran ti gbọ ti a ka ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii ni ipade Ihinrere ti wọn si kọ ijẹwọ igbagbọ wọn silẹ lẹsẹkẹsẹ pe wọn ki yoo tọ Kristi lẹyin mọ.

O ha tọ ki a korira awọn ẹbi wa ati awọn ará wa? Itumọ ohun ti Jesu wi ki i ṣe pe ki a ni inu buburu tabi ẹtanu ninu ọkàn wa si awọn ẹbi wa. Itumọ “ikorira” ti o wà ninu ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii ni pe ki ifẹ si Ọlọrun leke ifẹ ti a ni si awọn ẹbi wa.

Ifẹ wa si Ọlọrun ni lati jẹ eyi ti o pé ti o si ga ju lọ ninu igbesi aye wa. Eyi ko wi pe ki a ṣe alai naani ẹbi ati ará wa tabi ki a kuna lati fẹran wọn. Ṣugbọn ifẹ yii kò gbọdọ tayọ ifẹ ti o jinlẹ ati isin ailabula ti o jẹ ti Ọlọrun, ani Ọlọrun nikan ṣoṣo. Nigba ti ifẹ wa si awọn ẹbi wa ba pọ to bẹẹ ti a fi n bọ wọn, eyi ti di ibọriṣa, nitori ifẹ si ẹbi ti gba ipo Ọlọrun ninu ọkàn. Ni ọna bayii ni ifẹ wa si Ọlọrun ni lati leke ifẹ ti a ni si ẹbi ati ará wa (Ka Matteu 10:37).

Aṣẹ ti Jesu pa nihin yi kò fun ẹnikẹni ni ẹtọ lati ṣe alai naani ẹbi rẹ tabi ki o kuna lati ṣe ojuṣe ti o yẹ ki o ṣe, ni ero pe oun n sin Ọlọrun. Ẹnikẹni ti o ba n sin Ọlọrun lotitọ a maa ṣe itọju awọn ẹbi rẹ, nipa aini wọn ti ara ati ti ẹmi.

Gbogbo aṣẹ Ọlọrun ni ododo ati otitọ. Kò si ohun ti o leke ifẹ Ọlọrun, nitori ifẹ Ọlọrun ṣe pataki to bẹẹ ti kò le si awawi kankan lati ṣe aigbọran si i. Ni abẹ ofin, Ọlọrun paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati pa ẹnikẹni ti o ba gbà ẹlomiran niyanju pe ki o má ṣe sin Ọlọrun, tabi ẹnikẹni ti o ba tan ẹlomiran lati lọ sin oriṣa. Bi ẹni kan ninu ẹbi ẹnikẹni ba hu iru iwa bẹẹ, a ni lati pa a (Deuteronomi 13:6-10). Labẹ Oore-Ofẹ, a paṣẹ fun wa lati ya ara wa ya ohunkohun ti o le dẹ wa lọna lati sin Ọlọrun.

Ṣiṣe Iṣiro

Jesu kilọ fun awọn ti o n tẹlẹ E lati ṣiro ohun ti yoo gbà wọn lati jẹ ọmọ-ẹyin. Itara igbà diẹ ati eyi ti kò ti ọkàn wa. Ipinnu lati fi ara ẹni jì fun Ọlọrun ni lati jẹ eyi ti o yanju gedegede gẹgẹ bi o ti le ri fun ẹni ti o fẹ kọ ile-iṣọ ti o si ṣiro iye ti yoo na an lati kọ ọ. Ki o to dawọ le e, o ni lati ṣiro iru ohun ti yoo fi kọ ọ, irin iṣẹ ti yoo lò, ati pe oun ni imọ to lati le lo wọn, ati pe oun ni owo to lati ra gbogbo ohun ti oun fẹ lo. Lati le kọle igbesi aye ti o kún fun iṣẹ isin fun Ọlọrun, gba pe ki a ni iriri idalare, isọdimimọ ati ifiwọni Ẹmi Mimọ. Nipa ọrọ adura ati ifararubọ ni a fi le ri wọn gbà.

Kristi ni ipilẹ igbala, ibẹrẹ igbala yii si ni idalare, eyi ti i ṣe idariji ẹṣẹ nipa itoye Ẹjẹ Kristi. A ni lati mọ le ipilẹ yii gẹgẹ bi ọlọgbọn ọmọle (Ka 1 Kọrinti 3:10-13).

Isọdimimọ, ti i ṣe iṣẹ oore-ọfẹ keji, nipasẹ eyi ti a fi n pa aworan Adamu run kuro lọkan Onigbagbọ ti a dalare, jẹ pataki lara ile yii. Ile naa kò ti i pari sibẹ. Ẹmi Mimọ ti o n ba ni gbe, eyi ti a n ri gba ni ẹkun rẹrẹ nigba ti a ba ni ifiwọni Ẹmi Mimọ, yoo pese ọkàn wa silẹ fun Ipalarada ati Ase Alẹ Igbeyawo Ọdọ-Agutan.

Ọmọ-ẹyin Jesu ni lati fi ara rẹ rubọ ki o ba le gbe igbesi aye aṣẹgun titi de opin. Lati pinnu pe a le tọ Jesu lẹyin lai ni awọn iriri wọnyii, tabi ki a kọ lati fi ara wa rubọ lati le ni iriri wọnyii, ni lati maa lepa lati tẹle Kristi lọna ti yoo mu aile ṣe aṣeyọri wá! Awọn aladugbo iru ẹni bẹẹ yoo ṣe ẹlẹya pe, “Ọkọnrin yi bẹrẹ si ile ikọ, kò si le pari rẹ.” Peteru sọ bayii nipa awọn ti wọn bẹrẹ ti wọn kò si le pari rẹ pe, “Iba san fun wọn, ki nwọn ki o má mọ ọna ododo, jù lẹhin ti nwọn mọ ọ tan, ki nwọn ki o yipada kuro ninu ofin mimọ ti a fi fun wọn” (2 Peteru 2:21).

Iṣẹ-Isin ti O Tọna

A sọ fun ni pe Ọlọrun kò beere ju iṣẹ-isin wa ti o tọna lọ, a ni eyi ti o ṣe e ṣe fun wa lati ṣe. Otitọ ni eyi, ṣugbọn iṣẹ-iranṣẹ wa ti o tọna gba gbogbo ẹmi wa! “Nitorina mo fi iyọnu Ọlọrun bẹ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ ãye, mimọ, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isin nyin ti o tọna” (Romu 12:1). Eyi ni ohun ti a ni lati ṣe bi a ba fẹ ṣe iṣẹ-isin wa si Ọlọrun ni aṣeyọri. “Gẹgẹ bẹẹli ẹnyin pẹlu, nigbati ẹ ba ti ṣe ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun nyin tan, ẹ wipe, Alailere ọmọ-ọdọ ni wa: eyi ti iṣe iṣẹ wa lati ṣe, li awa ti ṣe” (Luku 17:10).

A ni lati jẹ oloootọ si Kristi pẹlu gbogbo ọkàn wa, a si ni lati fi gbogbo ọkàn wa sin Jesu. Fun idagbasoke Ijọba Ọlọrun ni ohun ti o dara ju lọ ti a le ṣe ninu iṣẹ ọwọ wa. Itara wa, ilera wa, ilepa wa laye ati agbara lati ṣiṣẹ jẹ ti Kristi pẹlu.

Iṣẹgun wà larọwọto wa. Bi a ba ṣe alai ni ọgbọn, agbara, ipa tabi ohunkohun ti o wu ki a ṣe alai ni, oore-ọfẹ Ọlọrun yoo tan aini yii, yoo fun ni ni anito ati aniṣẹku (Ka Jakọbu 1:5). Ifẹ ati ifararubọ lati ṣe ifẹ Ọlọrun ni aṣiiri titọ Jesu lẹyin. Ẹnikẹni ti o ba pinnu patapata, nisisiyii ati titi lae, pe nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, oun yoo maa sin Jesu ni gbogbo ọjọ aye rẹ, ti fi ẹsẹ le ọna rere si iṣẹgun aṣeyọri.

Ẹbọ Pipe

Ọpọlọpọ awọn eniyan Majẹmu Laelae ni ẹjẹ wọn si Ọlọrun jẹ apẹẹrẹ ifararubọ patapata ti Oluwa n beere lọwọ gbogbo awọn ti o n tọ Ọ lẹyin. Ifararubọ ti ode ara wà, eyi ti iṣẹ-isin tootọ jẹ apa kan rẹ, kò pari si iṣẹ-isin tootọ nikan. Eyi ti o ṣe pataki ju lọ ni ifararubọ ti inu ti a ṣe patapata lati odo ọkàn ati àyà wa fun Ọlọrun, iru eyi ni a kò le ṣe ayederu rẹ, bẹẹ ni kò si eyi ti o tayọ rẹ.

Nigba ti Hanna n wá ọmọ, o gbadura si Ọlọrun lati inu odò ọkàn rẹ wá, ki i ṣe lọna ti eti le gbọ ohun ti o sọ, ṣugbọn Eli alufaa ba a wi nitori o ro pe o mu ọti yó. Hanna ṣeleri pe bi Ọlọrun ba fun oun ni ọmọkunrin kan oun yoo fi i fun Oluwa ni gbogbo ọjọ aye rẹ. Ọlọrun gbọ adura rẹ o si bi ọmọkunrin kan. Hanna san ẹjẹ rẹ fun Ọlọrun, Samuẹli si sin Oluwa lati ewe titi di ọjọ iku rẹ.

Dafidi fẹ lo ibi ipaka Arauna lati rubọ si Oluwa. Arauna fi i fun Dafidi lọfẹẹ pẹlu maluu ati awọn ohun miiran ti o le fẹ lò, ṣugbọn Dafidi wi pe, “Bẹẹli emi ki yio fi eyiti emi kò nawo fun, rú ẹbọ sisun si OLUWA Ọlọrun mi” (2 Samuẹli 24:24). Ọlọrun tẹwọ gba ẹbọ Dafidi O si gbọ adura rẹ.

Wọnyii jẹ apẹẹrẹ ifararubọ patapata ti jijẹ ọmọ ẹyin Kristi beere. Awọn Ofin Ọlọrun lodi patapata si fifi ohun alaipé tabi alabuku rubọ si Ọlọrun. “Ati ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ alafia si OLUWA, lati san ẹjẹ, tabi ẹbọ ifẹ-atinuwá ni malu tabi agutan, ki o pé ki o ba le dà; ki o máṣe si abùkun kan ninu rẹ. Afọju, tabi fifàya, tabi eyiti a palara, tabi elegbo, elekuru, tabi oni-ipẹ, wọnyi li kò gbọdọ fi rubọ si OLUWA” (Lefitiku 22:21, 22).

Bayi ni a le ri otitọ yii di mu nipa apẹẹrẹ ti o wà ninu Lefitiku, pe Ọlọrun beere ẹbọ pipé. Jesu Kristi jẹ Ẹbọ pipe fun ẹṣẹ wa; ṣugbọn a ni lati mu ẹbọ pipe wá tabi ki a ṣe ifararubọ pipe si Ọlọrun ki Oun to le tẹwọ gbà wá patapata.

Ki ni ifararubọ pipé? A mọ ohun ti eyi jẹ nipa apẹẹrẹ Jesu. “Ẹbọ sisun ati ẹbọ fun ẹṣẹ ni iwọ kò ni inu didùn si. Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i, (ninu iwe-kiká nì li a gbé kọ ọ nipa ti emi) Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun” (Heberu 10:6, 7). Jesu wa si aye lati ṣe ifẹ Ọlọrun eyi ni i ṣe ẹbọ pipe (Ka Orin Dafidi 50:7-14). A ko le fi ohun miiran dipo rẹ, ohunkohun ti o ba si ti yẹ ni fifi-ara-ẹni rubọ lati ṣe ifẹ Ọlọrun jẹ ẹbọ elekuru, Ọlọrun ki yoo tẹwọ gba a. A le fi eyi wé ẹni ti o fẹ ṣẹgun ẹgbẹ ọmọ-ogun ọta lai ni ọmọ-ogun ti o pọ to ati lai mura silẹ. Eyi ni o fa iṣubu awọn Ọmọ Israẹli, ẹbọ alabuku. Ajambaku isin ati kikùn ni o dabi ohun ti o dara ju lọ ti o dabi ẹni pe Israẹli le mú wá.

Wọn jẹ “iran agidi ati ọlọtẹ; iran ti kò fi ọkàn wọn le otitọ, ati ẹmi ẹniti ko ba Ọlọrun duro ṣinṣin (Orin Dafidi 78:8). “Nwọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ, nwọn si kọ lati ma rin ninu ofin rẹ” (Orin Dafidi 78:10). Israẹli kò fi ara wọn rubọ patapata, eyi ti wọn ni lati ṣe ki wọn le ni iṣẹgun; abayọrisi rẹ ni pe wọn kò de opin ire ije wọn.

Nigba kan o dá Peteru loju pe bi o tilẹ di ati kú, oun yoo tẹle Jesu. Wakati diẹ lẹyin eyi ni Peteru sẹ Oluwa rẹ nigba mẹta. Eyi mu ki Peteru banujẹ lọpọlọpọ, to bẹẹ ti o ni lati yẹ ọkàn ara rẹ wò ki o si ronupiwada ki o si tun ẹjẹ rẹ jẹ fun Ọlọrun, ki o si fi ara rubọ lati sin Ọlọrun, ti kò si kuna mọ. Peteru di akọni ninu igbagbọ, o si sin Ọlọrun tọkantọkan titi di ojú ikú rẹ.

A kò gbọdọ gbagbe ọrọ iyanju Paulu si awọn ara Romu; “Bẹẹni ki ẹnyin ki o máṣe jọwọ awọn ẹya ara nyin lọwọ fun ẹṣẹ bi ohun elo aiṣododo, ṣugbọn ẹ jọwọ ara yin lọwọ fun Ọlọrun, bi alãye kuro ninu okú, ati awọn ẹya ara nyin bi ohun elo ododo fun Ọlọrun.”

Ọrọ Jesu ti O sọ ni pe, “Gẹgẹ bẹẹni, ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ninu nyin, ti kò ba kọ ohun gbogbo ti o ni silẹ, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi.” Ro ohun ti o le gbà ọ! A ni iye kan lati san; dandan gbọn ni pe ki a san an bi a ba fẹ gba gbogbo ibukun ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wa. Bi a ba san an, ere wa yoo pọ ni ayé yii ati ni ayé ti n bọ pẹlu.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Lọna wo ni a le gbà fi igbesi-aye Onigbagbọ we ẹni ti o n kọ ile-iṣọ?
  2. Ki ni awọn ohun ti a ni lati lò fun ile kikọ?
  3. Bawo ni a ṣe le ri awọn ohun elo wọn gbà? Lọdọ ta ni?
  4. Darukọ ọpọlọpọ awọn ti o fi ara wọn rubọ patapata.
  5. Ki ni ẹbọ pipé?
  6. Ọlọrun ha le gba ẹbọ elekuru lọwọ wa bi?
  7. Njẹ a ni ohunkohun lati san ti Ọlọrun n beere lọwọ wa?