Luku 15:1-32

Lesson 150 - Senior

Memory Verse
“Ayọ mbẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada” (Luku 15:10).
Cross References

IOwe Jesu nipa Agutan ti o Sọnu

1.Awọn agbowode ati ẹlẹṣẹ sun mọ Ọn, awọn Farisi ati akọwe si n kùn, Luku 15:1, 2; 19:7

2.Jesu sọ nipa agutan ti o sọnu, a si fi awọn mọkandinlọgọrun ti o kù silẹ lati wa a ri, Luku 15:3, 4; 19:10

3.Awọn ọrẹ ati aladugbo ba oluṣọ-agutan yọ nigba ti o pada pẹlu agutan naa ni ejika rẹ, Luku 15:5, 6; Orin Dafidi 126:6

4.Bẹẹ gẹgẹ ni ayọ wà ni Ọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ba ronupiwada ju lori mọkandinlọgọrun eniyan ti o jẹ oloootọ, Luku 15:7

IIOwe Jesu nipa Fadaka ti Sọnu

1.Obirin kan ti o ni owo fadaka mẹwaa, sọ ọkan nù, o si wa a titi o fi ri i, Luku 15:8

2.O yọ ayọ naa pẹlu awọn ọrẹ ati awọn aladugbo rẹ, o si wi pe, “Mo ri fadakà ti mo ti sọnù,” Luku 15:9

3.Bẹẹ gẹgẹ ni ayọ wà laaarin awọn angẹli Ọlọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada, Luku 15:10; Ifihan 7:11, 12

IIIỌmọ Oninakuna ni ilẹ Okeere

1.O beere ini ti o kan an ninu ogún wọn, baba rẹ si pín ohun-ini rẹ fun awọn ọmọ rẹ, Luku 15:11,12

2.O lọ si ilẹ okeere o si fi iwa wọbia ná ohun-ini rẹ ni inakuna, Luku 15:13; Isaiah 53:6

3.O na gbogbo rẹ tan; iyan wá mú; o si di alaini; o ni lati maa tọju awọn ẹlẹdẹ ki o ba le ri ounjẹ oojẹ rẹ, Luku 15:14, 15

4.Tayọtayọ ni i ba fi maa jẹ ounjẹ ti awọn ẹlẹdẹ n jẹ, ṣugbọn ẹnikẹni kò si fi fun un, Luku 15:16

IVIpinnu Rẹ lati Pada si Ile Baba Rẹ

1.Oju rẹ walẹ o si bẹrẹ si ronu nipa awọn alagbaṣe baba rẹ ti wọn n jẹ ajẹyo ati ajẹti ounjẹ, Luku 15:17

2.O ṣe ipinnu lati pada lọ jẹwọ pe oun ti ṣẹ si Ọrun ati niwaju baba rẹ, Luku 15:18

3.Yoo jẹwọ pe oun ko yẹ ni ẹni ti a ba maa pe ni ọmọ mọ, oun yoo si beere pe ki a sa fi oun ṣe alagbaṣe, Luku 15:19

VIfẹ ti Baba fi Hàn fun Un

1.O dide o lọ, nigba ti ọmọ naa ṣi wa lọna jijin rere, baba rẹ sare lọ rọ mọ ọn lọrun, o si fi ẹnu ko o ni ẹnu, Luku 15:20

2.O jẹwọ ẹṣẹ rẹ ati bi oun kò ti yẹ ni ẹni ti a bá pe ni ọmọ mọ ṣugbọn a dá ọrọ mọ ọn lẹnu bi o ti n ṣe “ijẹwọ” rẹ, Luku 15:21; 1 Johannu 3:1

3.Baba rẹ paṣẹ ki wọn mu aayo aṣọ wa lati fi wọ ọ, ki wọn fi oruka bọ ọ lọwọ, ki wọn si wọ bata fun un, Luku 15:22; 1 Johannu 1:9

4.O paṣẹ ki wọn pa ẹgbọrọ maluu abọpa, “Nitori ọmọ mi yi ti kú, o si tún yẹ,” Luku 15:23, 24; Johannu 11:25

VIIbinu Ẹgbọn

1.O gbọ orin ati ijo, o si pe ọmọ-ọdọ kan o wadii lẹnu rẹ ohun ti o ṣẹlẹ, Luku 15:25, 26

2.Ọmọ-ọdọ naa ṣe àlàyé pé aburo rẹ ti de, wọn ti pa ẹgbọrọ maluu abọpa, wọn si n ṣe ariya, Luku 15:27

3.O binu, kò si jẹ wọle, baba rẹ jade lati wá ṣipẹ fun un, Luku 15:28; Matteu 22:4

4.O wijọ pe oun ti n sin baba oun ti pẹ, oun si n pa aṣẹ rẹ mọ, sibẹ baba oun kò ṣe ariya bẹẹ fun oun ri, Luku 15:29

5.Ṣugbọn gẹrẹ ti ọmọ rẹ ti o ti fi ohun-ini rẹ ṣofo, ninu iwa ẹṣẹ de, o pa ẹgbọrọ maluu fun un, Luku 15:30; Owe 30:12

6.“O yẹ ki a ṣe ariyá ki a si yọ, … nitori aburo rẹ yi ti kú, o si tún yẹ,” Luku 15:31, 32; Orin Dafidi 133:1

Notes
ALAYE

Ibi mẹta ni wọn yoo ti mọ nigba ti ẹlẹṣẹ kan ba kaanu fun ẹṣẹ rẹ, ti o ronupiwada, ti o bẹbẹ fun aanu ti o si ri idahun adura rẹ gbà pe, “Ọmọ, a dari ẹṣẹ rẹ ti o pọ jì ọ.” Ọrun yoo mọ ohun ti o ṣẹlẹ, awọn angẹli Ọlọrun yoo yọ; ihin naa yoo tàn kalẹ, awọn ẹni irapada laye yoo yọ; awọn ẹmi eṣu ni ọrun apaadi yoo maa payín keke. Ọkàn kan bọ kuro labẹ ajaga Satani!

Agutan ti O Sọnu

Jesu pa owe agutan ti sọnù lati fi ayọ ti ó wà lọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ba ronupiwada hàn: “Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹẹli ayọ mbẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada.” Bayii ni inu awọn angẹli Ọlọrun dùn to nipa ọkàn kan. “Ẹmi ti njiṣẹ ki gbogbo wọn iṣe, ti a nran lọ lati mã jọsin nitori awọn ti yio jogun igbala?” (Heberu 1:14). Awọn angẹli paapaa ni ipin ninu gbigba ẹni irapada si Ijọba Ọrun. Ki i ṣe pe wọn n mọ nipa ọkàn kọọkan ti o ronupiwada nikan, ṣugbọn igbala ọkàn awọn ti o wà ni aye jẹ aniyan ọkàn wọn pẹlu. Niwọn iba oye ti a ni, a le sọ pe awọn pẹlu yoo jẹ ẹgbẹ kan pataki ninu “awọsanma ti o kún to bayi fun awọn ẹlẹri” ti a fi yí iran Onigbagbọ ká (Heberu 12:1).

Agutan ti sọnu jẹ apẹẹrẹ ti o tọ fun ọkàn ti o n ṣegbe, “Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹle ọna ara rẹ” (Isaiah 53:6). Agutan ti o ba ṣako kuro ninu agbo jẹ alailagbara lati ṣe ohunkohun ju eyikeyi ninu awọn ẹranko miran lọ. Kò le da mọ ọna pada sinu agbo. Kò le ran ara rẹ lọwọ rara, yoo si di ijẹ fun gunnugun ati awọn ẹranko buburu ninu aṣalẹ, a fi bi ẹni kan ba dide fun iranlọwọ rẹ. Oluṣọ-agutan paapaa mọ bẹẹ. Nitori naa o fi mọkandinlọgọrun silẹ o bẹrẹ si wá inu aginju kiri titi o fi gbọ igbe agutan ti o nù; bi o si ti n tọ gẹrẹgẹrẹ oke lọ, o fi ọpa darandaran rẹ gbe agutan ti o n daku lọ ti gunnugun kan n fò yi i ka. O gbe ẹranko iyebiye yii le ejika rẹ, oluṣọ-agutan yii pada si agbo pẹlu ayọ.

Jesu ni Oluṣọ-agutan rere. “Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là.” Iṣẹ iranṣẹ nla ti O wá ṣe ni aye ẹṣẹ yii ni lati gba ẹlẹṣẹ là. Ọpọlọpọ ẹlẹṣẹ ti n tọ ipa ọna ara wọn rò pe wọn ti to tan, ṣugbọn ko si ẹni ti o fẹ gba ara rẹ là ti o ti i wọ inu agbo ri. Gẹgẹ bi agutan ti o sọnu, oun naa ti ṣako jinna ninu aṣalẹ. A fi igba ti o ba mọ ipo ẹgbé ati ailagbara ti oun wà, ti o si bẹbẹ fun aanu nikan ni Oluṣọ-agutan le dide fun igbala rẹ ki O si mu un pada sinu agbo ni alaafia.

Oluṣọ-agutan rere yii fara da idojukọ awọn ẹlẹṣẹ ati inunibini awọn ọta; nigbooṣe O fi ẹmi Rẹ lelẹ ni ori Agbelebu Kalfari lati pese agbo alaafia fun awọn agutan Rẹ ki O si kó wọn wá sinu agbo yii. O sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe, “Má bẹru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin” (Luku 12:32).

“Ko s’ẹni irapada t’o mọ

Jijin omi t’o la kọja;

Tab’ago kikoro t’Olugba mu

K’O to r’agutan rẹ t’o nù.

Ó gbọ igbe rẹ nin’aṣalẹ --

T’ojojo mú, ti o si n ku lọ.”

Owo Fadaka ti o Sọnu

Owe owo ti o sọnu tun fi han fun ni bi ayọ ti pọ to ni Ọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada. Bi owo yii ti niye lori to tubọ ye ni si i nipa itumọ ti awọn akẹkọọ Bibeli fi fun owe yii. Ni igba laelae, wọn a maa fun wundia ti o ba yege ni iye owo kan fun ẹri pe kò ba ara rẹ jẹ. Oun yoo si pa a mọ bi ọṣọ iyebiye. Eyi fi han fun ni bi oun yoo ti wá gbogbo ile rẹ pẹlu itara fun owo ti o sọnu yii, ti yoo si gbá gbogbo kọrọ iyara rẹ titi yoo fi ri owo naa; ti yoo si yọ pẹlu awọn ọrẹ ati ẹbi rẹ nigba ti o ba ri i. Owo yii pẹlu si jẹ apẹẹrẹ ọkàn ti o sọnu, nitori bi o ba pẹ diẹ, owo ti sọnu yoo dipẹta, aworan ati akọlé ti o wà lara rẹ yoo parẹ. Bakan naa ni aworan Ọlọrun sọnu nipasẹ ẹṣẹ ninu Ọgbà Edẹni, ninu ọkunrin ti Ọlọrun dá. Ireti ẹlẹṣẹ lati mu aworan yii pada wà ninu igbala nipasẹ Jesu Kristi, Ẹni ti i ṣe “itanṣán ogo rẹ, ati aworan on tikararẹ” (Heberu 1:3).

Ọmọ Oninakuna

Olubori ẹkọ ti o wa ni ori iwe yii ni o wa ninu itan ọmọ oninakuna. “Ọkọnrin kan li ọmọkọnrin meji: Eyi aburo ninu wọn wi fun baba rẹ pe, Baba, fun mi ni ini rẹ ti o kàn mi. O si pin ohun ini rẹ fun wọn.” Niwọn igbà ti a kò ti sọ fun ni pe owe ni akọsilẹ yii, o ni lati jẹ ohun ti o ṣẹlẹ gan an ni, gẹgẹ bi ti Lasaru ati ọlọrọ. Bi o ti wu ki o ri, o fi awọn otitọ pupọ ti o wà ninu Ihinrere hàn.

Ni Ilẹ Okeere

Kò si ofin ilu yii ti o kan an nipá fun baba yii lati pin ohun-ini rẹ. Ni igba naa, aṣẹ baalẹ ni o ga ju lọ. Ṣugbọn o gbà fun ọmọ rẹ, “o si pin ohun ini rẹ fun wọn.” “Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọna àjo rẹ pọn lọ si ilẹ òkere.” Ọmọkunrin yii fi baba ati ile rẹ silẹ, ki i ṣe nitori o ṣe alaini ohun kan, nitori awọn alagbaṣe paapaa n jẹ “onjẹ ajẹyó, ati ajẹtì”; ṣugbọn oun, gẹgẹ bi ọpọ ẹwe ode-oni, kò fara mọ itọni ati ibawi abẹ ile, o fẹ “lọ gbadun ilu okeere.” Boya Egipti ni “ilu okeere” yii, eyi ti i ṣe apẹẹrẹ aye. Nipa ti ẹmi ati nipa ẹkọ ti ìtẹdó (geography). “Egipti jinna sile baba rẹ, o si kún fun ẹṣẹ ninu eyi ti ọmọ oninakuna yii mookùn, nitori nibẹ ni “o gbé fi iwa wọbia na ohun ini rẹ ni inákuna.”

Wo bi iwa aye ọmọkunrin yii ati ti ọpọ eniyan ti ṣe deedee pẹlu ọrọ ti wolii nì sọ: “Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹle ọna ara rẹ”! Wo bi iwa aye rẹ ti yatọ si ti awọn eniyan diẹ bi ti Mose ti o yàn lati “bá awọn enia Ọlọrun jìya, jù lati jẹ fãji ẹṣẹ fun igba diẹ”! “Ẹ ba ẹnu-ọna hihá wọle; gbòro li ẹnu-ọna na, ati onibú li oju-ọna na ti o lọ si ibi iparun; ọpọlọpọ li awọn ẹniti nma ibẹ wọle: Nitori bi hihá ti ni ẹnu-ọna na, ati toro li oju-ọna na, ti o lọ si ibi iye, diẹ li awọn ẹniti o nrin i” (Matteu 7:13, 14).

Ìyàn Mú ni Ilẹ Naa

Ọmọ oninakuna le ti gbadun faaji ẹṣẹ, ṣugbọn fun “igba diẹ” ni. “Nigbati o si bà gbogbo rẹ jẹ tan, iyan nla wá imu ni ilẹ na.” Bi oun naa ti wa mọ nigbooṣe, “ẹsan” wa fun ẹṣẹ.” Nitori ni aipẹ ọjọ, o bẹrẹ si ṣe alaini; nigba ti kò ri ọna gbe e gba mọ, ni o lọ dara pọ mọ ọlọtọ kan ni ilu naa ki o ba le ri iṣẹ ṣe. Ọga rẹ ran an lọ si pápá lati lọ maa bọ agbo ẹlẹdẹ - iṣẹ ti o jẹ iwọsi ju lọ loju awọn Ju. Sibẹ nitori ebi ti o n pa a, tayọtayọ ni oun i ba fi jẹ ounjẹ ẹlẹdẹ ṣugbọn ẹnikẹni kò fun un jẹ.

Abuku ti o kan ọmọkunrin yii ni ilẹ okeere jẹ apẹẹrẹ ipo iwọsi ti ẹnikẹni wà bi o ba kọ itọni ati ẹkọ Onigbagbọ, ti kò si naani iwà mimọ ati ododo, tabi ki o fi ti Ọlọrun pẹ. Ni aye yii ni o ti bẹrẹ si kore ohun ti o gbìn, ṣugbọn apẹẹrẹ ohun ti o n bọ wa gbà ni ayérayé ni eyi jẹ, bi kò ba pada lọna ibi yii, “Ki a máṣe tàn nyin jẹ a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká. Nitori ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti ara rẹ, nipa ti ara ni yio ká idibajẹ; ṣugbọn ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti Ẹmí, nipa ti Ẹmí ni yio ká iye ainipẹkun” (Galatia 6:7, 8).

Oju Rẹ Wálẹ

Iyà jẹ ọmọkunrin yii. O dara ti iyà jẹ ẹ. Dafidi Onisaamu sọ pe, “Ki a to pọn mi loju emi ti ṣina … O dara fun mi ti a pọn mi loju” (Orin Dafidi 119:67, 71). Nigba ti ó wà ni papa awọn ẹlẹdẹ, ti ebi fẹrẹ pa á kú, “oju rẹ walẹ.” Ọrọ kekere yii ni itumọ ti o jinlẹ -- itumọ rẹ ni pe iye rẹ sọji. “Ohùn kẹkẹlẹ ni” ti o ti fi ayé ijẹkujẹ pa lẹnu mọ tun bẹrẹ si ba a sọrọ nisisiyii. Ẹri ọkàn ni i ṣe; akọwe iranti ninu ookan aya ọmọ eniyan, nipasẹ eyi ti Ọlọrun maa n ba ni sọrọ. O le sé le, nipa wiwà ninu ẹṣẹ ati isọtẹ fun ọdun pupọ to bẹẹ ti ẹni naa kò ni gbọ ohùn Ọlọrun mọ. O lewu lọpọlọpọ lati dé iru ipo bayii. Ṣugbọn sibẹ ninu iru ipo bẹẹ bi otitọ diẹ kinun ba wà ninu ọkàn naa, oloootọ ati alaanu ni Ọlọrun, O le ran iṣoro tabi aisan – tabi ohunkohun ti yoo sún un de ibi ti yoo gbe mọ ipo egbe ati oṣi ti o wá, ati pe oun ni lati wá Ọlọrun.

O Pada Sile Baba

Iru isọji ọkàn bayii ni ọmọ oninakuna ni. Nigba ti o n ṣe aṣaro ninu papa, o wi pe, “Awọn alagbaṣe baba mi melomelo li o ni onjẹ ajẹyó, ati ajẹtì, emi si nkú fun ebi nihin! Emi o dide, emi o si tọ baba mi lọ, emi o si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ; Emi kò si yẹ, li ẹniti a ba ma pẹ li ọmọ rẹ mọ; fi mi ṣe bi ọkan ninu awọn alagbaṣe rẹ.” O ṣe bi o ti pinnu, o mú ọna ile pọn, pẹlu ẹsẹ riro ati aṣọ akisa, o la oke wọnni kọja, boya nibi ti o gbà lọ ni ọdun diẹ sẹyin pẹlu ọpọlọpọ rakunmi, bi o ti n lọ lati “jẹ aye” ni Egipti.

“Ṣugbọn nigbati o ṣi wà li òkere, baba rẹ ri i, ãnu ṣe e, o si sure, o rọmọ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu.” Njẹ iwọ mọ bi ifẹ baba yii ti jinlẹ to? Bakan naa ni ifẹ Baba wa ti n bẹ ni Ọrun. Nigba ti ẹlẹṣẹ wà ni okeere sibẹ, Oun a rin ko o lọna pẹlu ọkan iyọnu yoo si fi ẹnu ko o ni ẹnu, yoo si dariji i. Oun ki yoo ṣe e ni alagbaṣe. Oun yoo paṣẹ ki a fi aṣọ ọba wọ ọ, ki a si fi oruka aṣẹ bọ ọ lọwọ, ki a si wọ ẹsẹ rẹ ni bata Ihinrere Alaafia. Oun yoo si pa abọpa ẹran, yoo si wi pe, “Ki a mã jẹ, ki a si mã ṣe ariya: Nitori ọmọ mi yi ti kú, o si tún yẹ”. Gbogbo awọn ti n bẹ ni Ọrun yoo si maa yọ.

“Ẹ wo irú ifẹ ti Baba fi fẹ wa, ti a fi npẹ wa ni ọmọ Ọlọrun; bẹ li a sa jẹ. Nitori eyi li aiye kò ṣe mọ wa, nitoriti kò mọ ọ.

“Olufẹ, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe nisisiyi, a kò si ti ifihàn bi awa ó ti ri: awa mọ pe, nigbati a bá fihàn, a ó dabi rẹ; nitori awa o ri i ani bi on ti ri” (1 Johannu 3:1, 2).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Lọna wo ni gbogbo wa gbe dabi agutan? Fi Ọrọ Ọlọrun gbe idahun rẹ lẹsẹ.
  2. Nibo ni ayọ gbe wà nigba ti ẹlẹṣẹ kan ba ni igbala?
  3. Lọna wo ni owo ti o nù fi dabi ọkàn ti o ti sọnu?
  4. Ki ni ohun ti o pilẹ ọkàn eyi aburo lati fi ile baba rẹ silẹ nigba ti anito ati aniṣẹku wà nibẹ?
  5. Ilu wo ni a le pe ni ilu okeere ti o lọ? Apẹẹrẹ ki ni ilu yii jẹ?
  6. Apẹẹrẹ ta ni ọmọ yii i ṣe? Apẹẹrẹ ta ni baba duro fun? Apẹẹrẹ ta ni ẹgbọn rẹ agba i ṣe?
  7. Apẹẹrẹ ki ni iwọ ro pe olubori ẹkọ ti o wà ninu itan ọmọ oninakuna duro fun?
  8. Apẹẹrẹ ta ni ẹgbọn rẹ duro fun nigba ti o binu ti o si kọ lati wọle?
  9. Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ ni ori kẹẹdogun Luku ti o mu ki Jesu fi ẹgbọn yii ṣe apẹẹrẹ?