Isaiah 12:1-6; Habakkuku 3:17-19

Lesson 151 - Senior

Memory Verse
“Ẹ ma yìn OLUWA. Emi o ma yin OLUWA tinutinu mi, ninu ijọ awọn ẹni diduro-ṣinṣin, ati ni ijọ enia” (Orin Dafidi 111:1).
Cross References

IIdupẹ Awọn Oloootọ

1.Ni ọjọ naa awọn eniyan yoo yin Oluwa nitori O ti yí binu Rẹ kuro lọdọ wọn, O si tù wọn ninu, Isaiah 12:1

2.Awọn eniyan ki yoo bẹru; nitori Oluwa ni agbara, orin, ati igbala awọn eniyan Rẹ, Isaiah 12:2; Ẹksodu 15:2; Orin Dafidi 83:18

3.Pẹlu ayọ ni wọn yoo fa omi jade lati inu kanga igbala wá, Isaiah 12:3; Johannu 4:10, 14; 7:37, 38

4.Wọn yoo gbe orukọ Oluwa ga, wọn yoo si sọ nipa iṣẹ Rẹ laaarin awọn eniyan, Isaiah 12:4; 1 Kronika 16: 8; Orin Dafidi 105:1; 34:3

5.Awọn olugbe Sion yoo kigbe, wọn yoo hó, wọn yoo si kọrin nitori titobi ni Ẹni-Mimọ Israẹli ni aarin wọn, Isaiah 12:5, 6; Ẹksodu 15:1; Orin Dafidi 68:32; 98:1

IIAyọ Laaarin Ipọnju tabi Wahala

1.Awọn eniyan mimọ yoo yọ ninu Ọlọrun igbala wọn, bi o tilẹ jẹ pe eso kò si fun jijẹ, ti a si ke agbo¬-ẹran kuro, Habakkuku 3:17,18; Jobu 13:15; Isaiah 41:15-17; 61:10

2.Ni igba iṣoro wọnyii, Oluwa Ọlọrun ni yoo jẹ agbara wọn, Habakkuku 3:19; 2 Samuẹli 22:34; Orin Dafidi 27:1; 18:33; 46:2

Notes
ALAYE

Ninu ori iwe eyi ti o ṣiwaju ibi ti ẹkọ wa oni gbe wà, Isaiah ṣe apejuwe agbayanu nipa Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun ti Kristi. O ṣe apẹẹrẹ bi alaafia, ododo ati ayọ yoo ti wa layé nihin, nibi ti ki yoo si idibajẹ tabi ohun ti yoo dá ẹnikẹni niji. Iru igbesi ayé ti gbogbo eniyan layé nihin n fẹ ni yoo jẹ, nigba ti imọ Ọlọrun yoo bori ayé bi omi ti bo oju okun. Iran Isaiah fun wa ni imọ diẹ nipa ohun ti awọn eniyan yoo maa ṣe ati ohun ti wọn o ma sọ ni akoko daradara yii.

Orin Ọpẹ

Orin iwe yii jẹ orin iyin ati ọpẹ fun ọjọ iṣẹgun ti o layọ nigba ti a o tẹ gbogbo awọn ọta mọlẹ. A sọ fun ni wi pe eyi jẹ ọkan ninu awọn orin ti o wa ninu Iwe Orin Ọrun ti a o kọ nigba ti a ba de ọhun.

Ọpẹ ati iyin wa lọkan ọmọ Ọlọrun lojoojumọ fun aanu ati ibukun Ọlọrun ti o n ri gbà lọjọọjọ yipo ọdun. Awọn Ijọba Amẹrika tilẹ ya ọjọ kan lọdun sọtọ fun akanṣe ọpẹ si Ọlọrun fun gbogbo oore ti O ṣe fun wọn.

Lati iṣẹdalẹ aye ni o ti jẹ aṣa awọn eniyan lati maa kọrin ọpẹ si Ọlọrun, nigba ti O ba ti mu wọn la iṣoro já, ti iṣẹgun si ti jẹ ti wọn. Akoko ti Oluwa mu awọn Ọmọ Israẹli la Okun Pupa já, ti omi duro gbọnin bi odi lọtun losi ti wọn si kọja ni iyangbẹ ilẹ, ti awọn ara Egipti ti o fẹ ṣe bẹẹ si ri sinu omi, jẹ apẹẹrẹ ohun ti a n sọ yii. Lakoko naa ni Miriamu mu ilù lọwọ rẹ, o n le orin iyin si Ọlọrun, awọn eniyan si n gbẹ é.

Iran Isaiah sọ ti igba ikẹyin nigba ti a o gbe eṣu dẹ, ti a o mu egún kuro lori aye, ti a o si gba awọn eniyan kuro lọwọ ọta nì. “Bi o tilẹ ti binu si mi, ibinu rẹ ti yi kuro, iwọ si tù mi ninu.” Ọrọ wọnyii fi ohun ti o wà ninu ọkàn kọọkan ti a ti dari ẹṣẹ ji, ti ayọ Ọlọrun si wọ inu ọkàn naa hàn. A ti mu ibawi ati ẹbi ẹṣẹ kuro ninu ọkàn naa, alaafia Ọrun si bo ọkàn naa.

Ayọ ati Agbára awọn Eniyan Naa

Ninu ẹkọ yii, a fi Oluwa, Jehofa hàn gẹgẹ bi ayọ ati agbara awọn eniyan Rẹ. Ọrọ, dukia tabi ibukun ti ara kọ ni i ṣe ibukun pataki ti awọn eniyan Ọlọrun, ṣugbọn Ọlọrun tikara Rẹ ni ayọ ati agbara wọn, O si ti di igbala wọn.

Nigba ti a ba pejọ ni Ọjọ Idupẹ lati yin Ọlọrun fun ọpọ ìtí ti a rù sinu àká ninu ọdun ti o kọja, ki i ṣe ọpọ ibukun ti a ni yii ni o n mu wa yọ, bi ko ṣe pe Ọlọrun ni o fi fun wa. A yin In nitori gbogbo ibukun n ṣàn lati ọdọ Rẹ wa.

Awọn Kanga Igbala

“Ẹnyin o si fi ayọ fà omi jade lati inu kanga igbala wá.” O n sọrọ nipa awọn kanga nihin. O n fi ye ni pe ọpọ ibukun ti Ẹmi Mimọ ti ki i tan ti a n ri gba dabi kanga omi. Wọn a maa lo kanga ti wọn wà ni aye atijọ fun ọpọlọpọ ọgọrun ọdun. Orisun ibukun ti ki i gbẹ ni wọn jẹ fun awọn eniyan. A ranti pe ni igbà aye Jesu, obirin Samaria kan lọ fa omi ninu kanga Jakọbu. Kanga naa ti wà nibẹ fun nnkan bi ẹgbẹwa (2,000) ọdun. O wa pọn omi mimu, ṣugbọn ni ọjọ naa, ni ibi kanga yii, o ri kanga Omi Iye ti n sun si iye ainipẹkun. Kanga yii ta kanga Jakọbu yọ, nitori naa o fi ladugbo rẹ silẹ, o sure lọ saarin ilu lati sọ fun wọn pe oun ti ri kanga Omi Iye. Ọlọrun ni O gbẹ kanga yii silẹ, ṣugbọn awa tikara wa ni lati fa omi rẹ. Nipa igbagbọ ni a fi le fa omi rẹ jade. Bi a ba ti lo igbagbọ to ni a o ri omi naa pọn to. Igbagbọ ti ẹlomiran n lo kere to bẹẹ ti ohun ti o tẹ wọn lọwọ kere.

Ọjọ Ikẹyin Ajọ

Ni ọjọ ti o keyin Ajọ Agọ, awọn eniyan a saba maa fi ladugbo wura wọn pọn omi wa lati orisun odo Salome, wọn a si lu u pọ pẹlu waini lati tu u sori ẹbọ lori pẹpẹ, pẹlu ayọ nlá. Itujade omi yii fi ironupiwada hàn. A kò fi aṣa yii lelẹ ninu Ofin Mose ṣugbọn a da a silẹ gẹgẹ bi apẹẹrẹ ibukun ti o n bọ wa, o n sọ tẹlẹ ohun ti yoo ṣẹlẹ ni akoko ti Messiah ba de.

Nigba ti Olugbala wa dide duro ni ọjọ ikẹyin ajọ, ti o si kigbe pe, “Bi òrùngbẹ ba ngbẹ ẹnikẹni, ki o tọ mi wá, ki o si mu,” O fi ye wọn pe aṣa atọwọdọwọ wọn n tọka si Oun ati Ẹmi Mimọ ti Oun yoo fi fun ni.

Riroyin Awọn Iṣẹ Rẹ

Nigba ti eniyan ba n yọ nitori ohun kan, oun yoo fẹ sọ nipa ohun naa. Ihin naa yoo ṣàn jade lati inu ọkàn wá. “Li ọjọ na li ẹnyin o si wipe, Yin OLUWA, kepe orukọ rẹ, sọ iṣe rẹ lãrin awọn enia, mu u wá si iranti pe, orukọ rẹ li a gbe leke.” Awọn ẹri ti a n jẹ ni akoko isin wa mu ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii ṣẹ ju ohunkohun miiran lọ. Awọn ẹni irapada le yin Ọlọrun. Wọn le gbe orukọ Rẹ ga. Wọn le royin awọn iṣe Rẹ ni awujọ eniyan. Bi eniyan ti gbẹkẹle Ọlọrun to ti o si ri ibukun gbà lati ọwọ Rẹ wá ni o jẹ gbese lati maa kede rẹ tó, “Ẹnyin li ẹlẹri mi, ni OLUWA wi” (Isaiah 43:10).

Ifọkantan Habakkuku

Lẹyin ti Wolii Habakkuku pari iroyin rẹ nipa awọn iṣẹ iyanu ti Jehofa ṣe nipa mimu awọn baba wọn lati Egipti wá si Ilẹ Ileri, o ri isọdahoro ti yoo de ba ilẹ naa. O mọ pe oloore ati alaanu ni Ọlọrun, pẹlu igbagbọ ni o fi gbẹkẹle ileri Ọlọrun ti ki i tase ti o si wi pe, “Bi igi ọpọtọ ki yio tilẹ tanná, ti eso kò si ninu àjara; iṣẹ igi-olifi yio jẹ aṣedanù, awọn oko ki yio si mu onjẹ wá; a o ke agbo-ẹran kuro ninu agbo, ọwọ ẹran ki yio si si ni ibùso mọ: Ṣugbọn emi o ma yọ ninu OLUWA, emi o ma yọ ninu Ọlọrun igbàla mi.”

Eyi ni ijẹwọ aiṣẹtan ti i ṣe ti Habakkuku pe, bi gbogbo ohun ọgbin kò tilẹ mu eso wa, ti awọn ẹran ọsin si kú, sibẹ oun yoo maa yọ ninu Ọlọrun igbala ati agbára oun, Ẹni ti yoo mu oun rìn ni ibi giga. O ni ayọ ti i ṣe ti ẹni ti o gbẹkẹle Ọlọrun, ireti ti ayida aye kò le parun. Pẹlu iwariri ni o fi bẹrẹ adura rẹ; ṣugbọn o fi orin iṣẹgun pari rẹ! O bẹrẹ pẹlu ẹbẹ pe ki Ọlọrun tun ṣe awọn iṣe iyanu Rẹ bi ti igba nì, pẹlu ifọkantan ati ifayabalẹ ninu aabo awọn eniyan Ọlọrun. Ẹkọ igbagbọ ni eyi i ṣe. Igbagbọ ni i ṣe ifayabalẹ ninu Ọlọrun bi o ti wu ki ọna ṣokunkun to, lai foya ohunkohun ti o le de.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nigba wo ni a kọ orin yii?
  2. Bawo ni a ṣe ni lati yin Oluwa pọ to?
  3. Ta ni ayọ ati agbara awọn eniyan mimọ?
  4. Ki ni ṣe ti Oluwa fi igbala wé kanga omi?
  5. Lọna wo ni a gbà n fa omi igbala jade lati inu kanga?
  6. Darukọ ọna diẹ ti a gbà le kede awọn iṣẹ iyanu Ọlọrun laaarin awujọ eniyan.
  7. Ki ni ifọkantan ti Habakkuku ni ninu Ọlọrun?
  8. Ki ni ifọkantan ti awa ti ode oni ni ninu Ọlọrun?