Numeri 27:15-23; Deuteronomi 34:9; Joṣua 1:1-18

Lesson 152 - Senior

Memory Verse
“Emi kò ha paṣẹ fun ọ bi? Ṣe giri ki o si mu àiya le; máṣe bẹru, bẹẹni ki àiya ki o máṣe fò ọ: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ ba nlọ” (Joṣua 1:9).
Cross References

IIgbega Joṣua si Ipo Alakoso

1.A kò yọnda fun Mose lati wọ Ilẹ Ileri, Numeri 27:15-17; Deuteronomi 31:14

2.Ọlọrun paṣẹ fun Mose pe ki o yan Joṣua ni alakoso, Numeri 27:18, 19; Deuteronomi 31:7, 23

3.Ẹmi Ọlọrun ti o tayọ, ọgbọn ati ọlá ni a fi fun Joṣua, awọn Ọmọ Israẹli si gbà ohùn rẹ gbọ, Numeri 27:20-23; Deuteronomi 34:9; Iṣẹ Awọn Apọsteli 6:6; 1 Timoteu 4:14

IIwọn Ileri Ọlọrun fun Joṣua

1.Lẹyin iku Mose, Oluwa paṣẹ fun Joṣua ki o mu awọn eniyan rekọja Jọrdani si Ilẹ Ileri, Joṣua 1:1, 2

2.Ọlọrun ṣeleri lati fi gbogbo ibi ti atẹlẹsẹ awọn Ọmọ Israẹli ba tẹ fun wọn, Joṣua 1:3, 4; 14:9; Deuteronomi 11:24

3.A ki Joṣua láyà pe ki o jẹ akọni ki o si ni igboya, Joṣua 1:5, 6; Romu 8:31, 37; Heberu 13:5

4.Ọna Joṣua gbogbo ni o n dara, o si n ṣe aṣeyọri bi o ti n pa Ofin Ọlọrun mọ ti o si n ṣe aṣaro ninu rẹ, Joṣua 1:7-9; Deuteronomi 29:9; Orin Dafidi 1:1-3

IIIImurasilẹ lati Rekọja Odo Jọrdani

1.Laaarin ọjọ mẹta lẹyin ti Joṣua ti gba gbogbo aṣẹ Ọlọrun, awọn Ọmọ Israẹli ti mura silẹ tan lati goke Jọrdani, Joṣua 1:10, 11; 3:2

2.A rán awọn ẹya Reubẹni, ati Gadi ati aabọ ẹya Manasse leti nipa ẹjẹ wọn, Joṣua 1:12-15; Numeri 32:20-22

3.Awọn ẹya wọnyii si jẹ oloootọ si Joṣua gẹgẹ bi wọn ti ṣe si Mose, Joṣua 1:16-18; Romu 13:1-5

Notes
ALAYE

Bi a ti n kà nipa igbẹyin igbesi ayé Mose, Iwe Mimọ tun fun ni ni anfaani lati mọ ohun kan si i nipa bi eniyan Ọlọrun yii ti jẹ alagbara to ninu ẹmi. Mose mọ pe awọn Ọmọ Israẹli kò ni pẹ de Ilẹ Ileri ati pe oun ki yoo ba wọn lọ. Gẹgẹ bi oluṣọ-agutan rere fun awọn eniyan naa, ohun ti o jẹ Mose lọkàn ju lọ ni pe ki Ọlọrun gbe ẹni kan dide fun ijọ eniyan, “Ti yio ma ṣaju wọn jade lọ, ti yio si ma ṣaju wọn wọle wá, ti yio si ma sin wọn lọ, ti yio si ma mú wọn bọ; ki ijọ enia OLUWA ki o máṣe dabi agutan ti kò li oluṣọ” (Numeri 27:17). Ọkàn Mose kò gba pe ki awọn Ọmọ Israẹli maa rin kiri lai si ẹni kan ti yoo ṣe aṣiwaju wọn, ti yoo si maa tọ wọn.

Ẹni ti Ọlọrun Yàn

Iṣẹ ti o ṣoro ni lati jẹ alakoso Israẹli ati lati ṣẹgun awọn ara Kenaani; nitori naa ẹni kan ni lati wà ti yoo rọpọ Mose -- ẹni ti o mọ Ọlọrun ti yoo si maa tẹle itọni Rẹ kinnikinni. Iru ẹni bayii wà ni ibudo -- ẹni ti o ti fi igboya rẹ hàn ni akoko ogun Amaleki, o si ti fi iwa irẹlẹ rẹ hàn gẹgẹ bi iranṣẹ Mose, o si ti fi iwà otitọ rẹ hàn nigba ti o tako iroyin buburu awọn ami mẹwaa wọnni -- Joṣua ni ọkunrin naa. Bi a ti n kà itan igbesi aye Joṣua, o dabi ẹni pe Ọlọrun ti ṣeto tẹlẹ pe ọkunrin yii ni yoo dipo Mose nigba ti akoko ba to lati yan ẹlomiran.

Ẹkọ ati itọni fun nnkan bi ogoji ọdun jẹ iranwọ ti o fun Joṣua ni agbara lati le jẹ alakoso awọn Ọmọ Israẹli lẹyin iku Mose. Ẹkọ yii ki i ṣe iru eyi ti olukọ n kọ ni gẹgẹ bi ọmọ ile iwe; ki i ṣe gbogbo eniyan Israẹli ni o ṣakiyesi ẹkọ yii, a kò fi kọ Joṣua nikan aafo yii ṣilẹ fun gbogbo Israẹli. Ṣugbọn Joṣua nikan ni o gba ẹkọ Ọlọrun si ọkàn rẹ ti o si jere nibẹ. O gba awọn oyẹ ti o ga ju lọ ni ile-ẹkọ iriri nitori o ni irẹlẹ to bẹẹ ti o le ṣe iṣẹ ti o rẹlẹ ju lọ, sibẹ o ni ọkàn ati ẹmi lati ṣe aṣeyọri awọn iṣẹ ribiribi ti a ba yàn fun un. Nitori naa nigba ti awọn eniyan Ọlọrun fẹ alakoso miiran lati maa bá iṣẹ naa lọ, Joṣua ni ẹni ti Ọlọrun yàn.

Yíyan Joṣua

Gẹrẹ ti Mose mọ inu Ọlọrun nipa ọrọ naa, Mose bẹrẹ si ṣe ohun ti Ọlọrun sọ fun un. A mu Joṣua wa siwaju Eleasari alufaa ati gbogbo ijọ eniyan Israẹli. Nibẹ ni Mose gbe ọwọ rẹ le Joṣua ti o si fun un ni aṣẹ lati maa ṣe akoso awọn eniyan naa.

Oluwa wi fun Mose pe, “Ki iwọ ki o si fi ninu ọlá rẹ si i lara.” Joṣua ti ni Ẹmi Ọlọrun tẹlẹ, ati nisisiyii, a fun un ni diẹ ninu ọlá Mose, ati ọlá lati jẹ alakoso awọn eniyan Ọlọrun. Mose fi Joṣua hàn ni gbangba bi ẹni ti yoo rọpo rẹ, awọn eniyan gbọ, wọn si fara mọ ẹni ti a yàn yii, ṣugbọn Mose kò le ṣe ju eyi lọ. Nigba ti a yan Joṣua, kò tó Mose lọna pupọ, ṣugbọn nipa iranlọwọ Ọlọrun, Joṣua kò fi anfaani ti a fi fun un wọlẹ, to bẹẹ ti a fi mọ Joṣua gẹgẹ bi ọkan ninu awọn alakoso pataki ni Israẹli.

Joṣua di Alakoso

“Mose iranṣẹ mi kú.” Iku Mose ni lati dun awọn Ọmọ Israẹli pupọ. Adanu nla ni o jẹ, nitori ijọ eniyan Ọlọrun kò le ṣe alai mọ iku eniyan bi Mose lara ki wọn si ṣọfọ ẹni ti o kún fun igbagbọ ati otitọ inu ti o si tun fara mọ Ọlọrun bayii. Ṣugbọn itunu yii wa fun ni pe bi a tilẹ mu awọn ti o jafáfá ninu Ijọ lọ sile, sibẹ Ọlọrun ṣi ni Olupilẹṣẹ ati Eleto iṣẹ Rẹ, Oun yoo si wá ẹni kan lati di aafo ti o ṣi silẹ. Mose, iranṣẹ Oluwa le kú, ṣugbọn Ọlọrun, Ọba aṣẹda, ti O gbe iṣẹ Rẹ kalẹ, kò kú. O wa laaye titi lae, O si n kiyesi aini awọn eniyan Rẹ.

Ọgbọn ọjọ ti wọn fi ṣọfọ fun Mose fẹrẹ dopin nigba ti Ọlọrun kọ si Joṣua ti O si wi fun un pe ki o kó awọn Ọmọ Israẹli la Jọrdani já. Ọlọrun kò fẹ ki awọn Ọmọ Israẹli ṣọfọ Mose titi aye. Ilana Ọlọrun fun Israẹli ṣẹṣẹ bẹrẹ ni. Dajudaju, iku ẹni kò le da eto yii duro. Nigba ti a ba ṣi awọn eniyan Ọlọrun lọwọ lẹnu iṣẹ wọn, omije a maa gboju awọn ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ wọn ati awọn alabaṣiṣẹpọ wọn kan fun iwọn igba diẹ -- kò le ṣai ri bẹẹ, ṣugbọn ibanujẹ ati ẹkun kò gbọdọ di ifunrugbin lọwọ. Iṣẹ pupọ ni o wà lati ṣe sibẹ. Ihinrere ni lati maa tẹ siwaju ati siwaju, nigba gbogbo ati titi lae, titi Jesu yoo fi pada de ti yoo si pe awọn eniyan Rẹ soke Ọrun. “Ẹniti nfi ẹkun rin lọ, ti o si gbé irugbin lọwọ, lõtọ, yio fi ayọ pada wá, yio si rù iti rẹ” (Orin Dafidi 126:6).

Aṣeyọri Rere

Nigba ti Ọlọrun paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati tẹ siwaju, Ọlọrun ṣeleri fun Joṣua pe yoo ni iṣegun ti o daju nigba gbogbo, lori adehun kan ṣoṣo: “Sá ṣe giri ki o si mu àiya le gidigidi, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi ti palaṣẹ fun ọ; má ṣe yà kuro ninu rẹ si ọtún tabi si òsi, ki o le dara fun ọ nibikibi ti iwọ ba lọ” (Joṣua 1:7).

Eyi ni ọna iyanu ti ẹnikẹni ti i ṣe ọmọ Ọlọrun le gbà ṣe aṣeyọri! Joṣua ni lati tẹle Ofin Mose, nitori eyi ni iwọnba Ọrọ Ọlọrun ti wọn ni lọwọ nigba naa. Lọjọ oni, a ti mu gbogbo Ofin Mose ṣẹ ninu Jesu, Imọlẹ aye, Ẹni ti O tàn jade ninu gbogbo agbara ati ogo Rẹ. Gbogbo Bibeli, Ọrọ Ọlọrun ti o kun fun imisi, wà lọwọ wa; ki a ba le ni aṣeyọri ni igbesi aye wa bi Onigbagbọ, a ni lati fara mọ ilana kan naa – lati gba gbogbo Ọrọ Ọlọrun gbọ, ki a si maa tẹle E.

Kiyesi i lati maa ṣe ohun ti a kọ sinu Rẹ. Didun inu ọmọ Ọlọrun ni lati ṣe ifẹ Baba rẹ, yoo si banujẹ bi o ba kuna lọnakọna. Bi a ba fẹ mọ ifẹ Ọlọrun, a ni lati ka Ọrọ Ọlọrun – ki i ṣe lẹẹkan lọsẹ tabi ẹẹkan loṣu, ṣugbọn nigba gbogbo. A paṣẹ fun Joṣua ki o maa ṣe aṣaro ninu Iwe Ofin naa ni ọsan ati ni oru. Iṣẹ pupọ wa fun un lati ṣe, alakoso ọgbọn ọkẹ ọmọ-ogun ati awọn ẹbi wọn, ati lati ṣẹgun orilẹ-ede meje ti o wà ni Kenaani, sibẹ o ni lati ni akoko lati ṣe aṣaro ninu Ọrọ Ọlọrun. Ọlọrun ha ṣe alai bikita fun itọju awọn ọmọ-ogun Rẹ ni ode-oni? Ki ha ṣe Ofin kan naa ni o n ṣakoso wọn sibẹ? Ofin kanna ni bi a ba fẹ ṣe aṣeyọri rere ninu Ihinrere yii.

Ṣise Gbogbo Rẹ

A ni lati ṣe ohun gbogbo ti a kọ sinu Ọrọ Ọlọrun bi a ba fẹ ṣe aṣeyọri rere. Kò to ki a kàn ka Ọrọ Ọlọrun, ki a gbọ ọ, ki a gbadùn rẹ, tabi ki a sọrọ rere nipa rẹ nikan; a ni lati jẹ oluṣe Ọrọ naa bi a ba fẹ ri ibukun gbà. “Ṣugbọn ẹniti o ba nwo inu ofin pipé, ofin ominira ni, ti o si duro ninu rẹ, ti on kò jẹ olugbọ ti ngbagbé; bikoṣe oluṣe iṣẹ, oluwarẹ yio jẹ alabukun ninu iṣẹ rẹ” (Jakọbu 1:25).

Ni igba mẹrin ni a gba Joṣua niyanju ninu ori iwe yii pe ki ó ṣe giri ki o si mu ayà le. O le ya ni lẹnu pe Joṣua ni a n fun ni iru imọran yii nitori a mọ ọn ni ogboju ati akọni ọkunrin tẹlẹ. Ṣugbọn, o ni lati jẹ pe Joṣua n wò ara rẹ bi alai lera ati alai lagbara fun iṣẹ nla ti o wà niwaju rẹ, paapaa ju lọ nigba ti o jẹ pe iru ẹni nla bi Mose ni oun yoo rọpo. Ọlọrun wi pe “Emi kò ha paṣẹ fun ọ bi?” Nigba ti Ọlọrun ba fi iṣẹ kan le ẹni kan lọwọ, Oun kò ni kuna lati gbe ẹni naa lọwọ soke ki O si ran an lọwọ titi iṣẹ naa yoo fi pari, bi oluwarẹ ba gbe igbagbọ ati igboya rẹ le Ọlọrun. Aini igbagbọ ninu Ọlọrun ati ileri Rẹ ni o n fa irẹwẹsi. Ki a ṣe giri ki a si jẹ alagbara ninu Oluwa, ki a si ni igbagbọ ninu Rẹ ni ọna ti o tọ ti a fi lẹ lé irẹwẹsi jinna.

Ileri Ọlọrun wa fun Joṣua pe, kò si ọkunrin ti yoo le duro niwaju rẹ; ati pe ibikibi ti atẹlẹsẹ rẹ bá tẹ ni yoo jẹ ti rẹ, ati pe Ọlọrun yoo wà pẹlu rẹ bi O ti wà pẹlu Mose. Ohun ti Joṣua ni lati ṣe lati tubọ mu aya rẹ le ni pe ki o tun ranti gbogbo ileri iyebiye wọnyii ki o si ni igbagbọ ninu Ọlọrun ti O ṣeleri wọnyii. Ọlọrun ni o gbe iṣẹ yii kalẹ, bi o si ti wu ki o dabi ẹni pe iṣoro ti o wà niwaju ga tó, wọn kò le duro niwaju agbara Rẹ.

Ajaṣẹgun

Lati le ṣẹgun ẹgbẹ ọmọ-ogun ni lati doju ija kọ ọta; kò gbọdọ maa fi igba gbogbo duro de igba ti ọta ba dojuja kọ ọ ki o to ja ki o si ni ero pe oun ni yoo ṣẹgun nikẹyin. Eyi ni Ọlọrun fẹ ki Joṣua ṣe, lati doju ija kọ ọta, nipa ti ẹmi ati nipa ti ara. Ogun ti Onigbagbọ ti ode-oni le má jẹ eyi ti oun yoo gbe ohun ija ti a fi oju ri, ṣugbọn oun ni lati dojuja kọ ọta ẹmi rẹ. “Ẹ jẹ alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipá rẹ. Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, ki ẹnyin ki o le kọ oju ija si arekereke Eṣu … Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ ni ki ẹ mã gbadura nigbagbogbo ninu Ẹmi, ki ẹ si mã ṣọra si i ninu iduroṣinṣin gbogbo, ati ẹbẹ fun gbogbo enia mimọ” (Efesu 6:10, 11, 18). “ Ẹ kọ oju ija si Ѐṣu on ó si sá kuro lọdọ nyin” (Jakọbu 4:7). Akoko ti o dara ju lọ lati kọ oju ija si eṣu ni igba ti o ba kọkọ fara hàn ki i ṣe igba ti o ba ti fi idi mulẹ ṣinṣin ninu ero ọkàn rẹ.

Apẹẹrẹ Kristi

A le ri agbayanu apẹẹrẹ Kristi ninu igbesi aye Joṣua. Joṣua ti fara mọ Mose gẹgẹ bi iranṣẹ rẹ fun ọjọ pipẹ ṣiwaju igba ti a gbe e ga si ipo alakoso Israẹli. Jesu Oluwa wa, “bọ ogo rẹ silẹ, o si mu awọ iranṣẹ, a si ṣe e ni awòran enia, … Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ” (Filippi 2:7, 9).

Joṣua jẹ olorukọ Olugbala wa. A tumọ “Joṣua” ni ede Heberu si “Jesu” ni ede Griki – eyi ti o tumọ si “Oun ni yoo gbala.” Joṣua gba awọn eniyan rẹ là kuro lọwọ awọn ọta wọn: Jesu gbà awọn eniyan Rẹ là kuro ninu ẹṣẹ wọn. Joṣua ni alakoso ati balogun awọn eniyan ninu ogun Kenaani eyi ti yoo mu ki Ilẹ Ileri jẹ ti wọn. Jesu ni Balogun igbala wa, yoo si tẹ Eṣu mọlẹ labẹ ẹsẹ Rẹ, yoo fun wa ni Kenaani ti ẹmi, ati isinmi ti Joṣua kò le fun awọn Ọmọ Israẹli nitori aigbagbọ wọn (Heberu 4:6, 8, 9). “Nitorina, ẹ jẹ ki a bẹru, bi a ti fi ileri ati wọ inu isimi rẹ silẹ fun wa, ki ẹnikẹni ninu nyin ki o má bã dabi ẹnipe o ti kùna rẹ” (Heberu 4:1).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Mose fi n ṣaniyan nipa ẹni ti yoo ṣe alakoso Israẹli lẹyin ikú rẹ?
  2. Darukọ awọn nnkan diẹ ti o mu ki Joṣua yẹ ni alakoso Israẹli nipo Mose?
  3. Ki ni ero awọn eniyan nipa Joṣua? O ha ti ṣe aṣiwaju wọn lọ si ogun ri?
  4. Ọlọrun fun Joṣua ni awọn ileri iyanu pupọ. Darukọ pupọ ninu wọn.
  5. Bawo ni a o ṣe maa dari Joṣua ninu iṣẹ ti o gbà yii?
  6. Bawo ni o ti pẹ to ti Joṣua ti di alakoso Israẹli ki awọn eniyan wọnyii to mura tan lati ré odo Jọrdani kọja?
  7. Awọn ẹya Israẹli wo ni ipin wọn ti tẹ lọwọ? Ki ni Joṣua si wi fun wọn?
  8. Ki ni idahun wọn?