Joṣua 2:1-24

Lesson 153 - Senior

Memory Verse
“Ẹjẹ na ni yio si ṣe àmi fun nyin lara ile ti ẹnyin gbé wà: nigbati emi ba ri ẹjẹ na, emi o ré nyin kọja” (Ẹksodu 12:13).
Cross References

IA Fi Awọn Ami Meji Naa Pamọ ni Ile Rahabu

1.Joṣua rán ọkunrin meji lati yọ lọ ṣe ami ilu Jẹriko, wọn si de ile Rahabu, Joṣua 2:1

2.A sọ fun ọba, o si ranṣẹ si Rahabu pe ki o mu awọn ọkunrin naa wa, Joṣua 2:2, 3

3.Rahabu fi wọn pamọ o si sọ fun awọn iranṣẹ ọba pe wọn ti lọ ni oru, ki wọn sare lepa wọn, Joṣua 2:4, 5

4.O fi wọn pamọ si oke àjà, lasan ni awọn eniyan naa si wá wọn lọ titi de odo Jọrdani, Joṣua 2:6, 7

IIMajẹmu Rahabu pẹlu Awọn Ami Meji Naa

1.Rahabu bẹru Oluwa, nitori awọn olugbe ilu naa ti gbọ okiki iṣẹgun ti Ọlọrun fi fun Israẹli, Joṣua 2:8-10

2.Ẹrù nlá nlà ba awọn eniyan naa, Rahabu si mọ pe Ọlọrun Israẹli ni Ọlọrun Ọrun ati aye, Joṣua 2:11

3.Lẹyin ti o ti ṣe oore fun awọn ami naa, o bẹ wọn nipa ibura ati àmi kan pe ki wọn dá oun ati gbogbo ile oun sí, Joṣua 2:12, 13

4.Awọn ami naa si gba lati ṣe inu rere si i, bi kò ba fi ọran ti wọn bá wá hàn fun ẹnikẹni, Joṣua 2:14

IIIÀmì fun Igbala Rahabu ati awọn Ara Ile Rẹ

1.Lẹyin ti o ti fi “okùn” kan sọ wọn kalẹ si ẹyin odi, o rọ wọn lati yara sá lọ sori oke, Joṣua 2:15, 16

2.Awọn ọkunrin naa sọ fun un pe ki o so okùn ododó naa mọ oju ferese rẹ gẹgẹ bi àmì fun igbala wọn, Joṣua 2:17, 18; Ẹksodu 12:13

3.“Ẹnikeni ti o ba jade lati inu ilẹkun ile rẹ … ẹjẹ rẹ yio wà li ori ara rẹ”, Joṣua 2:19, 20; Ẹksodu 12:22

IVIpadabọ Awọn Ọkunrin Naa si Ibudo Israẹli

1.Rahabu rán wọn lọ o si so okùn ododo mọ ferese rẹ gẹgẹ bi wọn ti jọ ṣe adehun, Joṣua 2:21

2.Wọn fara pamọ lori oke titi awọn alépa fi pada, Joṣua 2:22

3.Wọn pada tọ Joṣua lọ, wọn si sọ gbogbo ohun ti o ṣẹlẹ ni irin-ajo wọn fun un, ati bi awọn olugbe ilu naa ti kun fun ibẹru pupọ nitori Israẹli, Joṣua 2:23, 24

Notes
ALAYE

Awọn ara Kenaani ni wọn n gbe ni Jẹriko, awọn ẹni ti wọn kún fun ibọriṣa ati iwa buburu eyi ti i ṣe iwa gbogbo awọn ẹya ti o n gbé ilẹ ti a ṣeleri fun Israẹli. Awọn eniyan wọnyii ti gbọ nipa Ọlọrun Israẹli nitori ihin yii de ilẹ pupọ. Wọn mọ bi Ọlọrun ṣe gba Israẹli kuro ni oko ẹru Egipti, bi O ti mu Okun Pupa gbẹ, ti O si ṣe amọnà wọn ni aginju, ti O si fi awọn ọba awọn ọmọ Amori meji le wọn lọwọ. Ẹrù bẹrẹ si ba wọn nisisiyii nitori Israẹli tẹdó si odi keji Jẹriko ni ihà ila-oorun Jọrdani. Ṣugbọn gbogbo iṣẹ iyanu wọnyii kò rú ifẹ ọkàn wọn soke lati sin Ọlọrun. Wọn taku sinu ibọriṣa ati aigbagbọ (Heberu 11:31).

Igbagbọ Rahabu ninu Ọlọrun Israẹli

Ni iru ayika bayii ni Rahabu dagba si – a ni laaarin ibọriṣa ati iwà buburu awọn ara ilu rẹ. Kò si ẹni iwa-bi-Ọlọrun kan laaarin wọn, oun naa kò si ni imọ ẹsin miiran yatọ si ibọriṣa ati iwa buburu ti o wà ni tẹmpili wọn, nibi ti o daju pe a ti n mu un lọ jọsin lati igbà ewe rẹ.

Sibẹ Rahabu ẹni ti a tọ dagbà sinu aimọkan ati okunkun yii, ti kò ni ọrẹ tabi ẹbi lati ran an lọwọ, nipa gbigbọ nipa iṣẹ iyanu Ọlọrun Israẹli ati ibukun Ọrun ti o jẹ ti awọn eniyan Rẹ, itanṣan igbagbọ ati ireti wọ inu ọkàn aibalẹ rẹ. Dajudaju Ọlọrun alagbara kan wà nibi kan, ti O ga rekọja ọlọrun asán ti awọn eniyan rẹ n sìn! Isin aimọ wọn kò ṣe e ni ire kan. Ebi n pa ọkàn rẹ fun ohun ti o dara ju bẹẹ lọ. Nigba ti awọn alejo meji wọnyii wọ inu ile rẹ, ireti sọji ninu ọkàn rẹ.

Awọn Alejo lati Ibudo Israẹli

Joṣua rán ọkunrin meji lati ṣe ami ilẹ naa, nitori ilu olódi ni Jẹriko ti o wà ni afonifoji Jọrdani, oun ni idenà kin-in-ni ti o wà loju ọna wọn si Ilẹ Ileri. Awọn eniyan wọnyii fẹrẹ maa ti i wọ ile-ero ti o wà lori odi, eyi ti Rahabu n boju to ti ihin ti kan ọba lara. O si rán onṣẹ lati mu wọn, awọn onṣẹ dé, wọn si wi pe, “Mú awọn ọkunrin nì ti o tọ ọ wá, ti o wọ inu ile rẹ jade wá: nitori nwọn wá lati rin gbogbo ilẹ yi wò.” Ṣugbọn Rahabu ṣe iranwọ fun wọn o si fi wọn pamọ, o si rọ awọn onṣẹ naa lati lepa wọn titi de odo Jọrdani.

Nigba ti awọn onṣẹ ti lọ tan, Rahabu gun oke lọ nibi ti o gbe fi wọn pamọ si, o si wi pe, “Emi mọ pe OLUWA ti fun nyin ni ilẹ yi, ati pe ẹru nyin bà ni, ati pe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori nyin.” Awọn ọrọ yii fi iwa igbagbọ ti o ya ni lẹnu hàn nipa ẹni ti o jẹ pe aigbagbọ ni o yi i ká ni gbogbo ọjọ aye rẹ. Iṣẹ iyanu ti Ọlọrun ṣe fun awọn Ọmọ Israẹli ninu irin-ajo wọn mu ki ibẹru-bojo bá awọn olugbe ilẹ naa. Ki eyi tilẹ to ṣẹlẹ ni Oluwa ti ṣeleri pe Oun yoo rán ẹru wọn si ọkàn orilẹ-ede wọnyii: “Li oni yi li emi o bẹrẹsi fi ifoya rẹ, ati ẹru rẹ sara awọn orilẹ-ẹde ti mbẹ ni gbogbo abẹ ọrun, ti yio gburó rẹ, ti yio si wariri, ti yio si ṣe ipàiya nitori rẹ” (Deuteronomi 2:25). Ni akoko oore-ọfẹ yii paapaa, ẹrù wà lara awọn eniyan Ọlọrun. A kọ ọ pe, “Ẹru nla si ba gbogbo ijọ, ati gbogbo awọn ti o gbọ nkan wọnyi … Ninu awọn iyokù ẹnikan kò daṣà ati dapọ mọ wọn” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:11-13). Bayii ni a ri i pe, ni imuṣẹ Ọrọ Ọlọrun, ipaya ba awọn olugbe Kenaani, bi Israẹli ti fẹrẹ ti wọ ilẹ wọn, ki i ṣe nitori wọn pọ ni iye, tabi nitori wọn lagbara ju awọn orilẹ-ẹde miiran lọ, ṣugbọn nitori Ọlọrun wọn ni Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu. Ṣugbọn sibẹ laaarin awọn ogunlọgọ eniyan wọnyii ti ọkàn wọn ti domi fun ẹrù ni ọkàn kàn wà -- Rahabu, onile-erò -- ti o yi pada si Ọlọrun Israẹli fun aabo.

Àmi fun Aabo Rahabu

Ni akoko yii, Rahabu fẹ ba awọn ọkunrin meji ti o ti ṣe iranwọ fun yii dá majẹmu, pe ki a le dá oun ati awọn ẹbi oun si nigbà ti Israẹli ba dide si Jẹriko. O jẹwọ pe, “OLUWA Ọlọrun nyin, on li Ọlọrun loke ọrun, ati nisalẹ aiye. Njẹ nitorina, emi bẹ nyin, ẹ fi OLUWA bura fun mi, bi mo ti ṣe nyin li ore, ẹnyin o ṣe ore pẹlu fun ile baba mi, ẹnyin o si fun mi li àmi otitọ: ati pe ẹnyin o pa baba mi mọ lãye, ati iya mi, ati awọn arakọnrin mi, ati awọn arabirin mi, ati ohun gbogbo ti nwọn ni, ki ẹnyin si gbà ẹmi wa lọwọ ikú.” Nigba ti wọn si ri i pe Rahabu ṣe rere fun wọn, awọn ọkunrin wọnyii fara mọ ọrọ rẹ, lori adehun yii pe, “bi ẹnyin kò ba fi ọran wa yi hàn.”

O ti di ọjọ alẹ; okunkun bolẹ, a si ti se ilẹkun odi, ṣugbọn Rahabu sọ wọn kalẹ sẹyin odi pẹlu okùn lati oju ferese, o si sọ fun wọn lati tara ṣaṣa, o si wi pe “Ẹ bọ sori òke, ki awọn alepa ki o má ba le nyin bá; ki ẹnyin si fara nyin pamọ nibẹ ni ijọ mẹta, titi awọn alepa yio fi pada: lẹhin na ẹ ma ba ọna ti nyin lọ.” Fun “àmi otitọ” awọn ọkunrin wọnyii mu ọjá ododo ti a fi sọ wọn kalẹ, wọn si sọ fun un lati so o mọ oju ferese, nigba ti wọn ba de ilẹ naa, ki o kó awọn ẹbi rẹ sinu ile nibi ti wọn ni lati wà. Nipa bayii awọn Ọmọ Israẹli yoo mọ pe gbogbo ọkàn ti o ba wà labẹ orule yii ni a ni lati dasi laayẹ.

Àmi Tootọ fun Awọn Eniyan Ọlọrun

Ọja ododo ti a ti ta si oju ferese Rahabu jẹ apẹẹrẹ daradara ti ipese ti a kò le gbagbe ti Oluwa ṣe fun idande awọn Ọmọ Israẹli kuro ni oko-ẹru Egipti. Ni alẹ ọjọ idande wọn, a paṣẹ fun wọn lati fi ẹjẹ ọdọ-agutan ti wọn pa sara òpó ati atẹrigbà ile wọn, ninu eyi ti wọn ni lati wà. Oluwa si wi pe, “Emi o là ilẹ Egipti já li oru na, emi o si kọlù gbogbo awọn akọbi ni ilẹ Egipti, ti enia ati ẹran; ati lara gbogbo oriṣa Egipti li emi o ṣe idajọ: emi li OLUWA. Ẹjẹ na ni yio si ṣe àmi fun nyin lara ile ti ẹnyin gbé wà: nigbati emi ba ri ẹjẹ na, emi o ré nyin kọja” (Ẹksodu 12:12, 13).

Ni ọjọ kan, ni ọdun pupọ lẹyin eyi, nigba ti Johannu Baptisti wà laaarin ọpọ eniyan ni tosi Jọrdani, Ẹni kan n tọ wọn bọ. Bi Johannu si ti tọka si I, o kigbe pe, “Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó ẹṣẹ aiye lọ.” Nigba ti Paulu Apọsteli n kọwe si awọn ara Kọrinti, o wi pe “Nitorina ẹ mu iwukarà atijọ kuro ninu nyin, ki ẹnyin ki o le jẹ iyẹfun titun, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ aiwukara. Nitori a ti fi irekọja wa, ani Kristi, rubọ fun wa” (1 Kọrinti 5:7). Ẹjẹ Ọdọ-agutan “ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye” ni i ṣe imuṣẹ “àmi otitọ” ti irapada wa.

“Kristi, pa mi mọ lọjọjọ,

Lab’Ẹjẹ iyebiye nì;

Ẹjẹ ’wosan on ’wẹnumọ,

Lab’Ẹjẹ ’yebiye.”

A Dá Rahabu ati Ẹbi Rẹ Si Laaye

Nigba ti awọn ọkunrin wọnyii ti fun Rahabu ni àmì otitọ, o rán wọn lọ o si pada lọ lati ta ọjá ododo naa si oju ferese rẹ. “Bẹẹli awọn ọkunrin meji na pada, nwọn si sọkalẹ lori òke, nwọn si kọja, nwọn si tọ Joṣua ọmọ Nuni wá; nwọn si sọ ohun gbogbo ti o bá wọn fun u. Nwọn si wi fun Joṣua pe, Nitõtọ li OLUWA ti fi gbogbo ilẹ na lé wa lọwọ; nitoripe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori wa.” Nigba ti Israẹli si ré Jọrdani kọja, wọn ba Jẹriko jà gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ fun wọn. Ogiri wọnni wo lulẹ bẹẹrẹ, awọn Ọmọ Israẹli si pa ohun gbogbo ti n bẹ ni ilu naa run, ọkunrin ati obirin, ọmọde ati agbà, maluu, agutan ati kẹtẹkẹtẹ ni wọn fi oju ida kọlu. Wọn si fi iná kun ilu ati ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ, a fi wura ati fadaka ati irin ti a ni lati mu wa si ile iṣura Oluwa.

Ṣugbọn Joṣua sọ fun awọn ọkunrin meji wọnyii lati wọ inu ile ibi ti a gbe fi àmi sara ferese lọ, ki wọn si mu Rahabu jade ati ẹbi rẹ jade. “Awọn ọmọkunrin ti o ṣamí si wọle, nwọn si mú Rahabu jade, ati baba rẹ, ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ, ati ohun gbogbo ti o ni” (Joṣua 6:23). A si tun sọ fun ni ni ẹsẹ kẹẹdọgbọn pe “o si joko lãrin Israẹli titi di oni-oloni.” Bayii ni a gba Rahabu si “ẹbi” Israẹli; ninu Ihinrere Matteu, a darukọ rẹ gẹgẹ bi ọkan ninu iya nla Jesu Kristi Oluwa wa (Matteu 1:5).

A ka Rahabu mọ awọn “Akọni ninu Igbagbọ” ninu Heberu ori kọkanla, pe, nipa igbagbọ oun kò ṣegbé pẹlu awọn ti kò gbọran, nigbà ti o tẹwọ gba awọn ami ni alaafia (Heberu 11:31). Eyi fi hàn pe nígbà ti o beere “àmi otitọ” lọwọ awọn ọkunrin meji wọnni, o n wo Ọlọrun Israẹli fun idande rẹ nipa igbagbọ, ki i ṣe awọn amí wọnyii nikan. Ọlọrun si fun un ni àmì - ọjá òdòdó ti a ta soju ferese, eyi ti i ṣe iru ami ti Ọlọrun fun Israẹli – “fifi ẹjẹ sara opo ati atẹrigba,” nipasẹ eyi ti a sọ abọriṣa obirin Kenaani kan di ọmọ Ọlọrun, ti a gba a si ẹbi Rẹ.

“Ole nì l’or’agbelebu

Yọ lati ri ’sun na

Bi mo kun f’ẹṣẹ bi ti rẹ,

Mo le wẹ n’n’ẹjẹ na.”

Rahabu le bojuwo ẹyin wo ọjọ okùnkun wọnni ti oun jẹ ara Kenaani, alejo si ọlọtọ Israẹli, ati ajeji si majẹmu ileri wọnni, lai ni ireti ati Ọlọrun ni aye yii. Ṣugbọn, ha! Iyipada nla – o di ẹda titun nipa oore-ọfẹ!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Awọn ara ilu wo ni awọn olugbe Jẹriko?
  2. Ki ni ẹsin ati ihuwasi wọn ti ri si ti awọn orilẹ-ẹde miiran ti o wà ni ilẹ naa?
  3. Iroyin nipa Israẹli de ilu naa. Ki ni wọn gbọ? Ki ni eyi mu wa ba ọkàn awọn eniyan naa?
  4. Ki ni iyatọ ti ó wà laaarin Rahabu ati awọn ara ilu rẹ?
  5. Iṣẹlẹ wo ni ọjá ododo ti a ta si oju ferese jẹ apẹẹrẹ rẹ?
  6. Lọna wo ni awọn nnkan meji wọnyii fi jọ ara wọn?
  7. Ki ni ṣe ti Rahabu fi ran awọn ami meji ti o ti ibudo Israẹli wá lọwọ?
  8. Ki ni abayọrisi inu rere rẹ si wọn?
  9. Ki ni awọn iṣẹlẹ diẹ ninu igbesi aye rẹ ti ọjọ iwaju ti a ṣakiyesi lẹyin ti a da a si kuro ninu iparun Jẹriko?
  10. Ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wo ni o fi idi igbagbọ rẹ ninu Ọlọrun ati igbala rẹ mulẹ?