Joṣua 3:1-17; 4:1-24

Lesson 154 - Senior

Memory Verse
“Ki gbogbo aiye ki o bẹru OLUWA: ki gbogbo araiye ki o ma wà ninu ẹru rẹ” (Orin Dafidi 33:8).
Cross References

IPipin Jọrdani Niya

1.Joṣua de bẹbẹ odo Jọrdani, Joṣua 3:1-6

2.Oluwa mu Joṣua ni ọkàn le, Joṣua 3:7, 8

3.Joṣua mu awọn eniyan lọkàn le, Joṣua 3:9-13

4.A pin omi Jọrdani niya, Joṣua 3:14-17; Orin Dafidi 114:5-7

IIAwọn Ohun Iranti Meji

1.A gbé okuta mejila jade lati inu odo Jọrdani fun iranti, Joṣua 4:1-8

2.A to okuta mejila jọ si aarin odo Jọrdani, Joṣua 4:9

3.Awọn eniyan rekọja Jọrdani, Joṣua 4:10-13

4.Oluwa gbé Joṣua ga, Joṣua 4:14-18

5.A gbé okuta iranti kan kalẹ ni Gilgali, Joṣua 4:19-24

Notes
ALAYE

Tẹsiwaju Laṣẹ Oluwa

Nigba ti Joṣua wà ni ọdọmọkunrin, o wà ni bebe Okun Pupa o si tẹti lelẹ si ọrọ Mose pe, “Ẹ má bẹru, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri igbala OLUWA”. O ri i ti Mose mu ọpa rẹ ti o si na an si oju òkun. Joṣua ti rin lori iyangbẹ ilẹ ti Ọlọrun là silẹ ni aarin òkun.

Ogoji ọdun ti kọja, Mose si ti kú; Ọlọrun si ṣeleri fun Joṣua pe, “Bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹẹli emi o wà pẹlu rẹ.” Ọrọ Ọlọrun wọnyii mu Joṣua lọkan le lati kó awọn eniyan rẹ de bebe Jọrdani, o si wi fun wọn pe, “Nigbati ẹnyin ba ri apoti majẹmu … ẹnyin o si ma tọ ọ lẹhin.” Wọn ni lati tẹju mọ Apoti naa, ki i ṣe ẹni ti o wà lẹgbẹ tabi ayika wọn. “Tẹju mọ Apoti” majẹmu Oluwa Ọlọrun rẹ; apoti naa ni yoo ṣe amọna yin. Ọmọ-eniyan kò pẹ ṣako lọ, ṣugbọn Apoti-ẹri Ọlọrun yoo maa ṣe amọna yin. Maa tọ ọ lẹyin!

Paulu kọ wa lati maa wo “Jesu olupilẹṣẹ ati alaṣepe igbagbọ wa.” A ni lati tọ Ọ wa ki O gbà wa là; a ni lati maa gbe inu Rẹ ki a ba le wa lọna naa. Oun ni Olupilẹṣẹ ati Alaṣepe igbagbọ wa – Alfa ati Omega -- ibẹrẹ ati opin. Bi a ba tọ Ọ wa ti a si n gbe inu Rẹ, ti a si foriti i titi de opin, a o gbà wá là.

Ilẹ Titun

A sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe, “Ẹnyin kò gbà ọnà yi rí.” Ilẹ titun kan wà niwaju wọn ti wọn ni lati gbà. Kò si ẹni kan laye yii ti o mọ giga, tabi jijin Ihinrere Jesu Kristi Oluwa. Bi a ba tẹju mọ Ọn ti a si n tẹle E, Oun yoo ṣamọna wa de ilu kan ti a ko ti i de ri.

Jọrdani ti a Pin Niya

Nipa aṣẹ Joṣua, awọn alufaa gbe Apoti-ẹri Ọlọrun, wọn n lọ taara sinu odo Jọrdani. Nigba ti atẹlẹsẹ wọn ti wọ omi, iṣẹ iyanu nla kan ṣẹlẹ. Nigba pupọ, awa naa pẹlu ni lati tẹ ẹsẹ wa bọ eti omi nipa igbagbọ ki Ọlọrun to dide fun iranwọ wa. Nigba pupọ, a ni lati tẹ siwaju nipa igbagbọ si ibi ti oju ara yii kò tó. Ṣugbọn gẹgẹ bi odo ṣe pinya ti isalẹ rẹ si gbẹ niwaju awọn ti o ru Apoti-ẹri, bakan naa ni Ọlọrun maa n lana silẹ fun awọn ti o gbẹkẹle E. “Nigbati iwọ ba nlà omi kọja, emi o pẹlu rẹ; ati lãrin odò, nwọn ki yio bò ọ mọlẹ” (Isaiah 43:2).

Bi awọn alufaa ti n tẹ siwaju titi de agbedemeji odo yii, omi gbara jọ pọ bi okiti ni iha oke nibi ti omi ti n ṣàn wá. Omi ti n bẹ nisalẹ kò pada sẹyin, ṣugbọn o ṣàn lọ sinu òkun. Laaarin agbedemeji odò yii ni awọn alufaa duro si titi awọn Ọmọ Israẹli fi ré Jọrdani kọja si Kenaani. Awọn alufaa duro ṣinṣin laaarin omi ti o duro gidigbi bi okiti titi ẹni kọọkan ti a yàn lati inu ẹya kọọkan fi gbe okuta kọọkan lati ibi ti Apoti-ẹri wà, ti o si gbe e lọ si ibi ti Israẹli yoo tẹdo si ni alẹ ọjọ naa. Joṣua si to okuta mejila si ọgangan ibi ti awọn alufaa ti wọn gbe Apoti-ẹri duro si ni agbedemeji Jọrdani. Bi awọn alufaa ti n jade kuro ninu Jọrdani, ti wọn si de bẹbẹ odo naa, omi rẹ ya lu ilẹ, o si bẹrẹ si ṣàn gẹgẹ bi iṣe rẹ atẹyinwa.

Awọn Ohun Iranti

Nibi ti awọn Ọmọ Israẹli kọkọ tẹdo si ni Kenaani ni wọn to okuta mejila wọnni jọ si, awọn okuta ti wọn gbe jade lati inu odo Jọrdani, gẹgẹ bi ohun iranti – ohun iranti ti o sọ nipa iṣẹ iyanu nla yii ti Ọlọrun ṣe. Onisaamu sọ bayii ninu akọsilẹ rẹ nipa iṣelẹ nla naa: “Kili o ṣe ọ, … iwọ Jọrdani ti iwọ fi pada sẹhin? Ẹnyin òke nla, ti ẹ fi nfò bi àgbo; ati ẹnyin òke kekẹke bi ọdọ-agutan? Warìri, iwọ ilẹ, … niwaju Ọlọrun Jakọbu” (Orin Dafidi 114:5-7). Ọlọrun n fẹ ki orukọ Rẹ jẹ ayinlogo ni Israẹli, to bẹẹ ni ọjọ iwaju nigba ti awọn ọmọ ba beere lọwọ awọn baba wọn, “Eredi okuta wọnyi?” awọn baba wọn yoo dahùn pe, “Israẹli là Jọrdani yi kọja ni ilẹ gbigbẹ. Nitoriti OLUWA Ọlọrun nyin mu Jọrdani gbẹ kuro niwaju nyin, titi ẹnyin fi là a kọja, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si Okun Pupa, ti o mu gbẹ kuro niwaju wa, titi awa fi là a kọja: ki gbogbo enia aiye ki o le mọ ọwọ OLUWA, pe o lagbara; ki nwọn ki o le ma bẹru OLUWA Ọlọrun nyin lailai.”

Ohun iranti meji ni a gbe kalẹ nigbà ti Israẹli ré Jọrdani kọja: ekinni ni bebe Jọrdani ti o wà ni Kenaani, ekeji ni aarin Jọrdani. Eyi ti o wà ni bebe odò n sọ nipa idande nla ati bi Ọlọrun ṣe kó awọn eniyan Rẹ yọ nigbà ti O dá omi Jọrdani duro. Eyi ti o wà ni aarin odò n sọ nipa Jesu Kristi, Ẹni ti kò ja àjàbọ. O kú nitori ẹṣẹ wa. Oun ni Oludande wa. Onisaamu ke pe, “Gbogbo riru omi ati bibì omi rẹ bò mi mọlẹ.” Jesu kú ki ibukún Kenaani nipa ti ẹmi le jẹ ti wa. Ohun iranti kan wà ni eti ebute nibi ti awọn ọmọ gbe le beere pe, “Eredi okuta wọnyi?” Ekeji ni a bo mọlẹ si aarin odo nibi ti o jẹ pe oju Ọlọrun nikan ni o le ri i. Kò si ẹni ti o mọ bi irora Jesu ti pọ to lati ra idariji fun wa. A bo okuta mejila mọlẹ sinu odo nibi ti kò si ọmọ ti o le beere, ti kò si si baba kan ti o ṣe àlàyé, “Eredi okuta wọnyi?”

Iṣẹ iyanu nla ni a ṣe nigba ti Ọlọrun pin Okun Pupa niya ti O si mu awọn eniyan Rẹ jade lati Egipti wa, ṣugbọn a kò gbe ohun iranti kalẹ si ibẹ. Ọlọrun kò fẹ ki awọn eniyan Rẹ gbe ni aginju tabi ki wọn pada si Egipti. Kò si ọmọ Jakọbu ti yoo wà nibẹ lati beere pe, “Eredi okuta wọnyi?” Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan Rẹ gbe ni ilẹ Kenaani. Eyi ni ilẹ ti O ti fi fun wọn, ifẹ Rẹ si ni pe ki wọn goke lọ lati gba a. Eyi ni ilẹ rere ti Ọlọrun ti ṣeleri, “ilẹ odò omi, ti orisun ati ti abẹ-ilẹ, ti nrú soke lati afonifoji òke jade wa.” “Ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ nṣe itọju; oju OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lara rẹ nigbagbogbo, lati ibẹrẹ ọdún dé opin ọdún” (Deuteronomi 11:12). Nihin yii ni Ọlọrun ṣeleri lati “fun nyin li òjo ilẹ nyin li akokò rẹ, òjo akọrọ ati òjo àrọkuro, ki iwọ ki o le ma kó ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ ati oróro rẹ sinu ile” (Deuteronomi 11:14).

Ilẹ Ileri

Nigba ti Israẹli bọ kuro ni oko-ẹru ni Egipti, wọn jẹ apẹẹrẹ ẹlẹṣẹ ti o kọ aye ẹṣẹ yii silẹ. Ni alẹ ọjọ ti wọn kuro nibẹ, wọn pa Ọdọ-agutan fun Irekọja, eyi ti i ṣe apẹẹrẹ Kristi gẹgẹ bi Ọdọ-Agutan ti Irekọja. Wọn bọ lọwọ iku nipa ẹjẹ ti wọn fi sara ile wọn nigba ti Oluwa la ilẹ naa kọja lati lu awọn ara Egipti pa. Lẹyin idande wọn, a ri wọn bọmi nigba ti wọn kọja labẹ awọsanma ati Okun Pupa -- apẹẹrẹ pipe iribọmi nipa riri sinu odo (1 Kọrinti 10:1, 2).

Ọlọrun tun mu awọn Ọmọ Israẹli lọ si Oke Sinai ki O le sọ wọn di mimọ patapata. O fẹ kọ Ofin Rẹ si ori tabili ẹran ọkàn wọn, ki i ṣe tabili okuta nikan. “Emi o fi ofin mi sinu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn” (Jeremiah 31:33).

Bi o tilẹ ṣe pe Israẹli fà sẹyin kuro lọdọ Ọlọrun nipa ìbẹrù ati aigbagbọ, nipasẹ eyi ti wọn fi ọdun pupọ ṣofo ninu irin kiri, sibẹ ohun ti o ṣẹlẹ ni Oke Sinai jẹ apẹẹrẹ iriri isọdimimọ ti Ọlọrun ti pese silẹ fun awọn ti kò fà sẹyin kuro ninu ifẹ Rẹ si wọn.

Ọlọrun mu awọn Ọmọ Israẹli ré Jọrdani kọja lọ si Kenaani, ilẹ ileri, eyi si jẹ apẹẹrẹ iṣisẹ kẹta ninu iriri Onigbagbọ ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wa, ifiwọni Ẹmi Mimọ. Lẹyin ti Onigbagbọ ba ni iriri igbala ati isọdimimọ, o ṣetan lati wọ ilẹ ti a ti ṣeleri fun un lọ, -- ilẹ ologo ti o kun fun ọpọlọpọ ibukun ti i ṣe ti rẹ nipa iriri ti gbigba agbara Ẹmi Mimọ.

Ọlọrun ti rọ akọrọ-òjo ati òjo arọkuro gẹgẹ bi asọtẹlẹ ti o wà ni Joẹli 2:23-29. Ni Ọjọ Pẹntikọsti, nigba ti akọrọ-ojo tu jade, Peteru wi pe, “Ṣugbọn eyi li ọrọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joẹli” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:16). O si tun wi pe, “Fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pẹ” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39). Ojo Arọkuro n tú jade lonii. Ipe lati lọ gba ibukun Kenaani ti ẹmi wà fun gbogbo awọn ti a ti gbala, ti a si ti sọ di mimọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni yoo lanà silẹ fun Israẹli ninu Jọrdani?
  2. Ikiyà wo ni Joṣua ri gbà lati ọdọ Ọlọrun?
  3. Nigbà wo ni omi Jọrdani bẹrẹ si i kojọ bi okiti?
  4. Ki ni ṣe ti a ṣa okuta mejila jade lati inu Jọrdani?
  5. Awọn iriri Onigbagbọ wo ni irin-ajo awọn Ọmọ Israẹli jẹ apẹẹrẹ rẹ?
  6. Fun anfaani ta ni awọn ohun iranti ti a gbe kalẹ ni Gilgali?
  7. A maa n fi Kenaani ṣe apẹẹrẹ Ọrun. Ki ni ṣe ti o fi jẹ apẹẹrẹ ti o gbamuṣe nipa igbesi ayé Onigbagbọ aṣẹgun layé yii?
  8. Igba meloo ni Odo Jọrdani pinya?
  9. Gbiyanju lati darukọ gbogbo awọn ohun ti o ṣẹlẹ ninu Bibeli ni Odo Jọrdani.
  10. Ki ni ṣe ti a mẹnu kan ẹya Reubẹni, Gadi ati Manasse lọtọ nihin?