Joṣua 5:10-15; 6:1-27

Lesson 155 - Senior

Memory Verse
“Tali o dabi iwọ, OLUWA, ninu awọn alagbara? tali o dabi iwọ, ologo ni mimọ, ẹlẹru ni iyìn, ti nṣe ohun iyanu?” (Ẹksodu 15:11).
Cross References

IGẹrẹ ti Wọn de Ilẹ Kenaani

1.Awọn Ọmọ Israẹli ṣe Ajọ Irekọja kẹta ni pẹtẹlẹ Jẹriko, Joṣua 5:10; Numeri 9:4, 5; Ẹksodu 12:7-11

2.Manna, ti i ṣe ounjẹ awọn Ọmọ Israẹli fun ogoji ọdun, dá nigbà ti Israẹli bẹrẹ si jẹ ounjẹ ni ilẹ Kenaani, Joṣua 5:10-12

IIOlori–Ogun Oluwa

1.Joṣua pade Olori-ogun Oluwa, Joṣua 5:13-15; Ẹksodu 23:20-23; Isaiah 55:4; Heberu 2:10; Ifihan 19:11-16

2.Joṣua wolẹ sin Oluwa, Joṣua 5:14, 15; Ẹksodu 3:5

IIIIṣẹgun Ilu Jẹriko

1.Ilu Jẹriko, ọba rẹ, awọn olugbe inu rẹ ni a ti fi le Israẹli lọwọ nipa aṣẹ Ọlọrun, Joṣua 6:2; 2:9, 24; 8:12; 11:6-12; 2 Samuẹli 5:19; Daniẹli 2:21

2.Ọlọrun fi eto pataki ni kinnikinni le Joṣua lọwọ nipa bi wọn yoo ṣe kọlu Jẹriko, Joṣua 6:3-5; Awọn Onidajọ 7:16-18

3.A fi ilana ti o dabi ẹni pe kò ni laari dán igbagbọ awọn Ọmọ Israẹli ninu Ọlọrun wò ki wọn to le lọ kọlu Jẹriko, Joṣua 6:6, 7; Awọn Onidajọ 7:4-7; 2 Awọn Ọba 3:16-20

4.Israẹli gbọran si aṣẹ Ọlọrun, eyi si yọri si odi Jẹriko ti o wó lulẹ, Joṣua 6:8-20; Heberu 11:30

5.A kilọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe ki wọn pa gbogbo ẹda alaaye ti ó wà nibẹ run, ati eniyan ati ẹranko, yatọ si Rahabu ati awọn eniyan rẹ, wọn si ṣe bẹẹ gẹgẹ, Joṣua 6:17, 21-25

6.A sọ fun Israẹli pe ifibu ni gbogbo ohun ti ó wà ninu ilu naa jẹ ayafi wura ati fadaka, ati awọn ohun-elo idẹ ati irin, eyi ti yoo jẹ ti Oluwa, Joṣua 6:17-19, 24

7.Joṣua gégun fun ẹnikẹni ti o ba dawọ le lati tun ilu Jẹriko kọ, Joṣua 6:26-27; 1 Awọn Ọba 16:34

Notes
ALAYE

Pipa Ajọ Irekọja Mọ

“Awọn ọmọ Israẹli si dó ni Gilgali; nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ kẹrinla oṣù li ọjọ alẹ ni pẹtẹlẹ Jẹriko.” Eyi yii pere ni ohun ti Bibeli sọ fun ni nipa irekọja kin-in-ni ti awọn Ọmọ Israẹli ṣe ni ilẹ Kenaani.

O ni lati jẹ akoko ayọ fun Israẹli. Ooru ati oorùn gbigbona janjan irinkiri aginju kò si mọ. Ifojusọna fun ọdún pupọ ki wọn to wọ ilẹ ileri ti kọja. Igbà kan ṣoṣo pere ni awọn Ọmọ Israẹli pa Ajọ Irekọja mọ ṣiwaju eyi lati igba ti wọn ti kuro ni Egipti. Eyi yii ni loke Sinai, oke ina, nigbà ti Ọlọrun sọkalẹ ti O fun awọn Ọmọ Israẹli ni Ofin ati Majẹmu Rẹ. Nibẹ ni wọn gbe pa Ajọ Irekọja mọ ni iranti alẹ ọjọ ti kò-ni-gbagbe ti Ọlọrun gba awọn eniyan Rẹ là kuro ni oko-ẹru Egipti (Numeri 9:4, 5).

“Ọjọ oni ni yio ma ṣe ọjọ iranti fun nyin” (Ẹksodu 12:14); o si ni lati jẹ ọjọ ti o dapọ mọ imi-ẹdun ati iranti ohun pupọ ti o ti ṣẹlẹ fun awọn iran keji wọnyii bi wọn ti n pa Ajọ Irekọja yii mọ nisisiyii ti o kù diẹ ki wọn gba ilẹ ileri.

Bi o ti jẹ akoko ọkà barli, o ṣe e ṣe ki Israẹli mu ọrẹ ọkà barli wa fun Ọlọrun ki wọn to jẹ ninu eso ikore ilẹ titun yii (Wo Lefitiku 23:14).

Ọlọrun ti fi manna bọ Israẹli. O n sọkalẹ ni owurọ ati ni aṣaalẹ lojoojumọ, a fi ni Ọjọ Isinmi, o si n mu ẹmi wà laaye. Kò dẹkun, bẹẹ ni o si pọ to lati bọ ẹgbaagbeje eniyan fun ogoji ọdun. Bi a ba fẹ mọ pe ifẹ Ọlọrun ni lati ṣe iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu nitori awọn eniyan Rẹ, akọsilẹ yii nipa bi Ọlọrun ti pese ounjẹ ati omi fun Israẹli ni akoko irin-kiri wọn ni aginju tó fun ẹri.

Ọlọrun a maa ṣiṣẹ iyanu sibẹ nigbà ti ọna gbogbo ba pin. Nigba ti Israẹli kò ni ounjẹ ati omi, Ọlọrun pese. Nigba ti wọn de ilẹ ti o mu eso wa, ti ounjẹ ati omi si wà lọpọlọpọ, lẹsẹkẹsẹ ni manna dásẹ, Israẹli ti ni eso oko ati àjàrà.

Olori-Ogun

Nigba ti Joṣua n wo ibi ti wọn yoo gbe jagun, Alejo kan pade rẹ. Alejo yii ni idà fifayọ ni ọwọ Rẹ, nitori naa Joṣua beere ni ọwọ Rẹ pẹlu igboya ti ẹni ti Oun i ṣe. Alejo naa dá Joṣua lohun pe Oun wá gẹgẹ bi Olori-ogun ti Oluwa.

Daju-daju, nigba yii ni Joṣua mọ pe Alejo lati Ọrun wa ni o bẹ oun wò, ki i si iṣe eniyan ẹlẹran ara. Bẹẹ ni, O tilẹ ju Alejo atọrunwa nikan! Oluwa ni Olubẹwo yii i ṣe! Oun ni Olori-ogun ti Oluwa, nitori Olori-ogun kan wà, a ni Jesu Kristi.

Joṣua doju bolẹ o si juba Rẹ, nigba naa ni a si sọ fun Joṣua pe ki o bọ bata ẹsẹ rẹ nitori o wà lori ilẹ mimọ. Mose ni iru iriri kan naa nigba ti o ri igbẹ ti n jo ti ina kò si run ún. Mose yẹra sapa kan lati ri ohun iyanu yii, Ọlọrun si sọ fun un lati bọ bata ẹsẹ rẹ nitori ori ilẹ mimọ ni o gbé wà. Nigba naa ni Mose gba aṣẹ lati mu awọn Ọmọ Israẹli jade kuro ni oko-ẹru Egipti.

Joṣua pẹlu pade Oluwa lori ilẹ mimọ a si fun un ni itọni ati imisi fun ogun ti o wà niwaju. Ọlọrun a maa ki awọn eniyan Rẹ laya nigbakigba ti eyi ba tọ, akoko yii si jẹ iru akoko bẹẹ. Ki ni o tun le jẹ ikiya fun Joṣua bi ibẹwo ti Oluwa bẹ wò lati ki i laya fun iṣẹ ti ó wà niwaju rẹ?

Iwewe Ogun

A fun Joṣua ni aṣẹ kinnikinni nipa bi ogun Jẹriko yoo ti lọ si. Bi i ti atẹyinwa, a kò fi ohunkohun silẹ fun oribande.

Isin Ọlọrun ni ẹtò, a si ni lati tẹle e letoleto lai si rudurudu. Bakan naa ni ohun miiran gbogbo ri ni igbesi aye awọn Ọmọ Israẹli.

Labẹ akoso Ọlọrun, Israẹli ki i ṣe ẹgbẹ oluṣọ-agutan tabi darandaran kan ṣá, ti kò ni akoso. Ẹgbẹ ọmọ-ogun ti o lakoso ni wọn i ṣe, aṣẹgun lori awọn jagunjagun ti o jafafa nigba nì. Loju wọn ni Farao ati awọn ọmọ-ogun rẹ rì sinu Okun Pupa, bakan naa ni wọn si la ilẹ awọn ọta wọn kọja gẹgẹ bi aṣẹgun. Israẹli jẹ apẹẹrẹ fun awọn orilẹ-ede Keferi wọnni lati fi hàn bi agbara Ọlọrun ti pọ to.

Ẹni ti o kọ Orin Sọlomọni sọ nipa ẹwà, ipa ati agbara Iyawo Kristi ati ti Ijọ ni ede owe bayii pe, “Iwọ yanju, olufẹ mi, bi Tirsa, o li ẹwà bi Jerusalẹmu, ṣugbọn o li ẹru bi ogun pẹlu ọpagun.” O tun tẹ siwaju lati sọ pe, “Tali ẹniti ntàn jade bi owurọ, ti o li ẹwà bi oṣupa, ti o mọ bi õrun, ti o si li ẹru bi ogun pẹlu ọpagun?” (Orin Sọlomọni 6:4, 10).

Balaamu, ọkunrin ti o ni agbara lati sure tabi fi ẹni ti o ba fẹ bú, ni Ọlọrun mi si lati sọ asọtẹlẹ nipa Israẹli, o si sọ bayii nipa awọn ọpọ eniyan wọnyii: “Ọlọrun mú wọn lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere. Nitõtọ, kò si ifaiya si Jakọbu, bẹẹni kò si afọṣẹ si Israẹli: nisisiyi li a o ma wi niti Jakọbu ati niti Israẹli, Ohun ti Ọlọrun ṣe! Kiyesi i, awọn enia na yio dide bi abokiniun, yio si gbé ara rẹ soke bi kiniun: on ki yio dubulẹ titi yio fi jẹ ohun ọdẹ, titi yio si fi mu ninu ẹjẹ ohun pipa” (Numeri 23:22-24).

Awọn ọmọ-ogun Isarẹli dara ni wiwò, iroyin pe ẹnikẹni kò le ṣẹgun wọn ti tan kaakiri ilẹ naa, titi ẹru fi ba awọn orilẹ-ede lati kọjuja si Israẹli lati ba wọn jagun.

Rahabu sọ fun awọn ami meji wọnni pe ọkàn awọn eniyan ti di omi ninu wọn nitori Israẹli, kò si si okun ninu ẹnikẹni, nitori Ọlọrun ti Israẹli n sin (Joṣua 2:9-11). Bayii ni awọn ara Jẹriko ri i pe ogun nla awọn ti n sin Ọlọrun Ọrun dó ti wọn.

Iṣẹgun nipa Igbagbọ

Ogun Jẹriko jẹ eyi ti a ni lati ṣẹ nipa igbagbọ ninu Ọlọrun. Oluwa ti sọ fun Joṣua pe a ti fi ilu yii, ọba rẹ, ati awọn olugbe rẹ le Israẹli lọwọ; nitori naa Israẹli yi Jẹriko ká pẹlu igbagbọ pe Ọlọrun yoo ṣe gbogbo eyi ti O ti ṣeleri (Romu 4:21).

Ọpọlọpọ ọna ti Israẹli gbà lati ṣe eto ogun jija wọn ni lati jẹ eyi ti kò mọgbọn wá loju awon orilẹ-ede Keferi wọnyii. Ṣugbọn iyọrisi ọnà ọtọ ti wọn gbà n ṣe ohun gbogbo kò ni ariwisi rara, nitori ọna ọtọ wọnyii jẹ ọgbọn Ọlọrun (Ka 1 Peteru 2:9; 1 Kọrinti 1:18-29). Irinkiri Israẹli fun ogoji ọdun ni aginju ti kọ wọn lati gbọran si Ọlọrun lẹnu bi ohun ti O palaṣẹ kò tilẹ yé wọn yekeyeke. Nitori naa, irin wọn yiká Jẹriko fun ọjọ meje le ṣe ajeji loju awọn olugbe Jẹriko, ṣugbọn fun Israẹli, irin igbọran ati igbagbọ ni.

Awọn ẹhanna eniyan kan wà sibẹ ti wọn a maa ke yányán, wọn a maa fò soke, wọn a si maa já balẹ, ki wọn to lọ si ogun, ni ireti pe nipa ṣiṣe bẹẹ wọn yoo tubọ ni igboya, wọn yoo si dá awọn ọta wọn ni iji. Ẹṣẹ ati aṣerege ni ohun ti o pilẹ iru aṣehan bẹẹ (Ka 1 Awọn Ọba 18:26-29).

Yiyi ti Israẹli yí odi Jẹriko ká ki i ṣe pẹlu igbona ara gẹgẹ bi aṣa awọn abọriṣa bi ko ṣe ni igbọran si aṣẹ Ọlọrun. Wọn n lọ lai sọrọ, ipe nikan ni wọn n fun. Boya idi rẹ ti Ọlọrun kò fẹ ki wọn fọhùn ni lati fi iyatọ si hihan ati igbe bi ẹlẹmi eṣu ti awọn Keferi ati ẹhanna maa n ke bi wọn ti n lọ si ogun ati adura idakẹjẹjẹ ti awọn eniyan Ọlọrun. Idakẹjẹjẹ jẹ apẹẹrẹ ọwọ; idakẹjẹjẹ Israẹli ki ha i ṣe lati bọwọ fun Ọlọrun ti n bẹ laaarin wọn bi wọn ti n lọ?

Ariwo Ogun

Nigba ti Israẹli yi ilu naa ka ni igba keje ni ọjọ keje, Joṣua paṣẹ ki awọn eniyan naa ho yẹẹ; nitori Ọlọrun ti fi ilu naa le wọn lọwọ. Awọn alufaa fun ipe, awọn eniyan si ho yee; odi Jẹriko si wó lulẹ. Israẹli si goke lọ lati gba ilu naa.

Itan nipa ogun jija fi ye ni pe ilu olodi ṣoro lati ṣẹgun, nigba pupọ ni kò tilẹ ṣe e ṣe rara. Igbagbọ ninu Ọlọrun ni agbara Israẹli; bi o ti wu ki odi Jẹriko lagbara to, nipa ogun ti aye yii, kò gbe Jẹriko ró, Onisaamu wi pe “Bikoṣepe OLUWA ba kọ ile na, awọn ti nkọ ọ nṣiṣẹ lasan: bikoṣepe OLUWA ba pa ilu mọ, oluṣọ ji lasan” (Orin Dafidi 127:1).

Bakan naa ni o si tun wi pe, “Kò si ọba kan ti a ti ọwọ ọpọ ogun gba silẹ; kò si alagbara kan ti a fi agbara pupọ gba silẹ: Ohun asan li ẹṣin fun igbala: bẹẹni ki yio fi agbara nla rẹ gbàni silẹ” (Orin Dafidi 33:16, 17).

Awọn abọriṣa Kenaani kunà lati ri gbese ifẹ ati ijuba ti wọn jẹ Ọlọrun Ọrun, nitori naa, wọn bọ sinu idajọ ododo lati ọdọ Ọlọrun wá eyi ti a mu ṣẹ nipasẹ awọn Ọmọ Israẹli. Wọn ni anfaani lati ronupiwada ṣugbọn wọn kò ṣe bẹẹ. Akoko ironupiwada wọn dopin nigbooṣe, a si pa wọn run nitori ẹṣẹ wọn. I ba ṣe wọn ni ire bi wọn ba ti feti si Ọrọ Ọlọrun ti o wi pe, “Ẹ fi fun OLUWA, ẹnyin ibatan enia, fi ogo ati ipá fun OLUWA. Ẹ fi ogo fun orukọ OLUWA: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá si agbala rẹ. Ẹ ma sin OLUWA ninu ẹwà iwa-mimọ: ẹ wariri niwaju rẹ, gbogbo aiye. Ẹ wi lãrin awọn keferi pe, OLUWA jọba” (Orin Dafidi 96:7-10).

“Nipa igbagbọ li awọn odi Jẹriko wó lulẹ, lẹhin igbati a yi wọn ká ni ijọ meje” (Heberu 11:30). Ni kukuru, eyi ni aworan awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun Ọlọrun ti yoo yi gbogbo odi iwa buburu ati ẹṣẹ ká nikẹhin, ati pe nikẹhin, nipa igbagbọ, Olori-ogun nla ti Oluwa yoo ni iṣẹgun pipe, yoo si maa jọba titi lae ni alaafia, iwa mimọ, aiṣegbe ati ni ododo.

“Wọ ha gbọ ẹsẹ wọn

Bi wọn ti n bọ n’nu ’mọlẹ

Ti wọn wọ’ṣọ ogo, didan

Aṣọ ’gbọ t’a f’ẹjẹ fọ?

“Iwọ ha gbọ iro orin

T’o gb’aye at’ọrun kan?

Ti ẹgbẹ ogun aṣẹgun

T’asia rẹ n fẹ lẹlẹ.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ajọ Irekọja meloo ni awọn Ọmọ Ọlọrun Israẹli ti ṣe ni akoko yii? Nibo ni wọn si ti ṣe wọn?
  2. Iru ounjẹ wo ni Israẹli jẹ ni ilẹ Kenaani?
  3. Ta ni Olori-ogun ẹgbẹ ogun ti Oluwa?
  4. Ki ni ṣe ti Israẹli fi yi Jẹriko ká ni igba meje?
  5. Njẹ ẹte ogun kankan wà ninu irin wọn yii?
  6. Ki ni ṣe ti ẹru awọn Ọmọ Israẹli fi ba awọn ara Kenaani?
  7. Ki ni agbara awọn Ọmọ Israẹli ti a kò fi le ṣẹgun wọn?
  8. Lọna wo ni a o gbà tun mu itan yii ṣẹ?