Matteu 2:1-23; Luku 2:1-20

Lesson 156 - Senior

Memory Verse
“Jesu ni iwọ o pẹ orukọ rẹ; nitori on ni yio gbà awọn enia rẹ là kuro ninu ẹṣẹ wọn” (Matteu 1:21).
Cross References

IIbi Kristi

1.A bi Jesu ni Bẹtlẹhẹmu, Ilu Dafidi, Matteu 2:1, 5, 6; Luku 2:1-7; Johannu 7:42; Mika 5:2

2.Ajogunba Jesu ni aye jẹ ti otoṣi ati irẹlẹ; ibujẹ-ẹran ni a si bi I si, Luku 2:7, 12; Orin Dafidi 2:7; Isaiah 9:6, 7

IIIbẹwo Awọn Oluṣọ-Agutan

1.Ogo Oluwa fara hàn, awọn angẹli si mu Ihinrere tọ awọn oluṣọ-agutan wá, Luku 2:8-12; Iṣẹ Awọn Apọsteli 5:31; Isaiah 52:7

2.Ọpọ Ogun-ọrun dara pọ ni iyin Ọlọrun, Luku 2:13, 14; Ifihan 19:6

3.Nigba ti awọn angẹli naa si ti pada si Ọrun, awọn oluṣọ-agutan naa lọ taara si Bẹtlẹhẹmu, Luku 2:15

4.Wọn ri Maria ati Josẹfu ati Ọmọ titun naa ti a tẹ si ibujẹ-ẹran, Luku 2:16

5.Awọn oluṣọ-agutan naa tan iroyin iyanu ti wọn ri ti wọn si gbọ kaakiri, Luku 2:17-20

IIIAwọn Amoye ati Irawọ

1.Nipa titẹle irawọ Jesu, awọn amoye lati Ila-oorun de Jerusalẹmu, Matteu 2:1-7; Numeri 24:17

2.Nigba ti awọn amoye naa ri i pe ni Bẹtlẹhẹmu ni a ti bi Jesu, wọn lọ si ilu naa, wọn si tun ri irawọ Rẹ lẹẹkan si i, Matteu 2:8-10

3.Jesu Olugbala ni Ẹni ti awọn amoye juba, Matteu 2:11; 14:33; Orin Dafidi 95:6

4.Awọn amoye naa ba ọna miran lọ si ile, nitori Ọlọrun ti kilọ fun wọn, Josẹfu si mu Maria ati Ọmọ ọwọ naa, Jesu, lọ si Egipti, Matteu 2:12-15; Hosea 11:1

5.Hẹrọdu ranṣẹ lọ lati pa gbogbo awọn ọmọ ti o wà ni ẹkùn Bẹtlẹhẹmu, lati awọn ọmọ ọdun meji lọ silẹ, Matteu 2:16-18; Jeremiah 31:15

6.Awọn Ẹbi Mimọ naa si pada si ilẹ Israẹli ati Nasarẹti lẹyin ikú Hẹrọdu, Matteu 2:19-23; Johannu 1:45, 46

Notes
ALAYE

Ileri Olugbala

Bi a ti n ṣe Keresimesi alarinrin yii, o yẹ ki a ṣe aṣaro nipa ohun ti o mu ki Keresimesi ṣe e ṣe. Rò nipa Ẹbùn alai lẹgbẹ ti Ọlọrun fi fun eniyan. “Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹẹ gẹ, ti o fi Ọmọ bibi rẹ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun” (Johannu 3:16).

Lati ọdun pupọ ni ileri Messia ti jẹ ireti awọn eniyan Ọlọrun. Nisisiyii, ni alẹ Keresimesi kin-in-ni yii, ileri naa ṣẹ; pẹlu ogo ti o tọ si Ọmọ Ọlọrun, Jesu wa si ayé ni awọ eniyan lati ba eniyan gbe. Lootọ Jesu ni Ẹbùn ti Ọlọrun fi fun arayé, ṣugbọn Oun tikara Rẹ ni O yọnda lati wa san gbese ti irapada eniyan. Jesu mọ pe agbalebu wà ni opin irin-ajo Oun laye yii, ṣugbọn ipinnu kan ti O ní ni lati ṣe ifẹ Baba Rẹ. Ohun kan ni Ọlọrun n beere lọwọ wa fun ifẹ ti O fi han; O fẹ ki a sin Oun ki a si fẹ Ẹ. Jesu fi ẹmi Rẹ lelẹ fun wa. Ko ha yẹ ki awa naa fi aye wa fun Un ni imoore si I?

Ihin Ayọ

Ọran naa ṣe pataki to bẹẹ gẹẹ nigbà ti a bi Olugbala ti Ọlọrun fi ran angẹli kan lati Ọrun lati kede ihin ayọ naa. Ki i ṣe awọn ilu Ju ti o kún fọfọ fun ero ni a rán angẹli naa si; awọn oluṣọ-agutan ti n ṣọ agbo-ẹran wọn lori oke Judea ni a ran an si. Lai si aniani, awọn eniyan ti ọkàn wọn ṣipaya wọnyii ti n foju sọna fun imuṣẹ Ọrọ Ọlọrun. Lojiji ogo Ọlọrun tan loju ọrun ni iṣọ oru. Ẹru ba awọn oluṣọ-agutan bi wọn ti ri iran ologo yii, ṣugbọn angẹli naa fi wọn lọkàn balẹ o si tù wọn ninu. Ihin ti angẹli naa mu wa ki i ṣe ti ẹru; ihin ayọ nla ni i ṣe; “Nitori a bí Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa” (Luku 2:11). Bi o tilẹ jẹ pe awọn oluṣọ-agutan ni a kede rẹ fun, gbogbo agbayé, ani gbogbo eniyan, ni ihin yii wà fun. Eyi ni ipinnu Ọlọrun. O sọ fun awọn diẹ, O si fun wọn ni aṣẹ lati lọ maa sọ ohun ti wọn gbọ ti wọn si ti ri fun awọn ẹlomiran.

Oru Iyanu

Dajudaju, oru ọjọ yii jẹ iyanu fun aye, Keresimesi kin-in-ni, oru ọjọ ti a bi Jesu! Awọn angẹli Ọlọrun ni lati mọ bi oru ọjọ naa ti ṣe pataki to, nitori gẹrẹ ti a sọ ihin yii di mimọ, ọpọ Ogun ọrun si dara pọ lati juba. Iyin wọn lọ deede pẹlu eyi ti angẹli ti akọkọ mu wá: “Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun, ati li aiye alafia, ifẹ inu rere si enia” (Luku 2:14).

Awọn oluṣọ-agutan kò ṣiyemeji ihin iyanu naa, nitori wọn ri ogo ti o tẹle e. Lẹyin ti awọn angẹli pada lọ si Ọrun, awọn oluṣọ-agutan ba ara wọn sọ pe, “Ẹ jẹ ki a lọ tàra si Bẹtlẹhẹmu, ki a le ri ohun ti o ṣẹ, ti Oluwa fihàn fun wa.” Wọn si wá si ilu lọgan, wọn ri Maria, Josẹfu ati Ọmọ-ọwọ naa ti o dubulẹ ni ibujẹ ẹran, gẹgẹ bi angẹli Oluwa ti wí. Ipo irẹlẹ ti wọn ba A yii kò mi igbagbọ wọn lọnakọna; “Nigbati nwọn si ti ri i, nwọn sọ ohun ti a ti wi fun wọn nipa ti ọmọ yi. Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ si nkan wọnyi, ti a ti wi fun wọn lati ọdọ awọn oluṣọ-agutan wá.” Awọn eniyan i ba jẹ le ni ọkàn lati ri Jesu lonii gẹgẹ bi awọn oluṣọ-agutan wọnyii, wọn yoo si le lọ si opopo ayé lati lọ sọ ti iran ti oju wọn ti ri!

Ilu Dafidi

Ni ilu Bẹtlẹhẹmu ni a gbe bi Jesu, gẹgẹ bi wolii nì ti sọ tẹlẹ ni nnkan bi ẹẹdẹgbẹrin ọdun ṣiwaju eyi. Bẹtlẹhẹmu ni a gbe bi Dafidi Ọba pẹlu, lẹyin naa ni a si n pe e ni Ilu Dafidi. Nihin ni Dafidi gbe dagba ti o si n tọju agbo-ẹran baba rẹ ki a to fi jọba Israẹli. Bawo ni o ti dara to pe nibẹ ni a gbe bi Jesu, Ọmọ Dafidi, gẹgẹ bi itan iran lati di Oluṣọ-agutan Nla fun gbogbo agutan Ọlọrun, ati Ọba ti n bọ wa fun awọn ẹni irapada. Itumọ Bẹtlẹhẹmu ni “Ile Ounjẹ”. Eyi ki ha ṣe ibi ti o yẹ ki a gbe bi I -- Ẹni ti I ṣe “Onjẹ iye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá?” (Johannu 6:51).

Maria, iya Jesu, jẹ ara Nasarẹti, ilu kan ni Galili ni iha ariwa Bẹtlẹhẹmu. Ki ni ṣe ti o fi jẹ pe Bẹtlẹhẹmu ni a gbe bi Jesu? O dabi ẹni pe Ọlọrun n mi gbogbo aye lati mu asọtẹlẹ Rẹ ṣẹ. Aṣẹ wá lati ọdọ Kesari Augustu pe ki a kọ orukọ gbogbo aye sinu iwe, olukuluku ni ilu ti rẹ. Josẹfu ati Maria fi Nasarẹti silẹ lati lọ si Bẹtlẹhẹmu (nitoripe iran ati idile Dafidi ni oun iṣe) “lati kọ orukọ rẹ, pẹlu Maria aya rẹ afẹsọna.” Oluwa si fi ẹsẹ rẹ mulẹ lai si aniani pe lati iran ati idile Dafidi ni Jesu yoo ti wá gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti sọ tẹlẹ.

Simeoni ati Anna

Awọn oluṣọ-agutan ni o kọkọ gbọ ti wọn si ri iran ologo nipa Kristi. Ni ogoji ọjọ lẹyin eyi ninu Tẹmpili, Simeoni ati Anna sọ lati ọwọ Ẹmi, fun gbogbo awọn ti yoo ba feti si i, nipa idande ati igbala Ọlọrun ti o fara hàn ninu Ọmọ-ọwọ naa. A le ro pe o yẹ ki awọn ọrọ wọnyii ṣi iyẹ diẹ ninu awọn olugbe Jerusalẹmu lati ri ohun ti ó wà niwaju wọn; ṣugbọn lai si aniani, kò si ohun ti o le mi awọn eniyan yii, nitori nigba ti awọn amoye dé kò si ninu awọn eniyan wọnyii ti o dabi ẹni pe wọn fura si ibi Jesu.

Ibẹwo Awọn Amoye

O pẹ diẹ lẹyin ti a ti bi Jesu ki awọn amoye lati ila-oorun to wá si Jerusalẹmu lati wo Ọba ti a bí. Wọn ri Irawọ ti Bẹtlẹhẹmu ni oru ọjọ kan naa ti a bi Jesu, lai si aniani wọn mu ọna ajo wọn pọn lai jafara. O dabi ẹni pe wọn mọ ohun ti irawọ naa wi, boya nitori asọtẹlẹ ti Balaamu sọ fun ọba Moabu ni nnkan bi egbeje (1,400) ọdun sẹhin, “Irawọ kan yio ti inu Jakọbu jade wá, ọpa-alade kan yio si ti inu Israẹli dide” (Numeri 24:17).

O dabi ẹni pe Keferi ni awọn amoye wọnyii, wọn ki i ṣe ọlọtọ Israẹli. Ibi ti wọn n gbe jinna si ibi ti a gbe bi Jesu, wọn si le ṣe awawi pe, “Bi a ba bi Ọmọ-alade ati Olugbala, a o gbọ ihin yii ni ilẹ wa lai pẹ jọjọ, nigbà naa ni awa yoo lọ juba Rẹ.” Ṣugbọn awọn amoye wọnyii kò jafara lati lọ ri Jesu, nitori oju wọn ti wà lọna lati juba Rẹ; wọn si rin fun ọjọ pupọ lọ si ilẹ Israẹli lati ri Ọba ti a bi ati lati ta A lọrẹ.

Titẹle Irawọ Naa

Amoye tootọ ni awọn ọkunrin wọnyii i ṣe. Wọn ri irawọ Jesu, wọn dide, wọn si tẹle e titi wọn fi de ibi ti o gbé yọ. Awọn ti o ba fẹ ri Jesu ki wọn si mọ Ọn, kò ni jokoo kawọ gbenú titi Jesu yoo fi maa kọja, ṣugbọn wọn yoo dide lati wá A. Awọn ti o ba fi tọkantọkan wá Ọba Ogo yoo ri Imọlẹ lati fi ibi ti wọn n lọ hàn wọn.

Lai si aniani, awọn amoye wọnyii ni ireti lati ba gbogbo awọn ará Jerusalẹmu ki wọn maa juba Ọba wọn ti a bi, ṣugbọn ibeere wọn pe, “Nibo li ẹniti a bí ti iṣe ọba awọn Ju wà?” mu ki Hẹrọdu ati gbogbo Jerusalẹmu pẹlu rẹ daamu. Hẹrọdu pe awọn olori alufaa ati awọn akọwe lati beere ibi ti a o gbe bi Kristi. Lọgan ni awọn olori alufaa ati awọn akọwe dahùn ibeere yii, nitori wọn mọ asọtẹlẹ wolii Mika: “Ati iwọ Bẹtlẹhẹmu Efrata; bi iwọ ti jẹ kekere lãrin awọn ẹgbẹgbẹrun Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israẹli yio ti jade tọ mi wá; ijade lọ rẹ si jẹ lati igbãni, lati aiyeraiye” (Mika 5:2).

Awọn olori alufaa ati awọn akọwe ti fi gbogbo ọjọ aye wọn kẹkọọ Ọrọ Ọlọrun; boya wọn tilẹ ti kọ ibi pupọ sori ninu rẹ, sibẹ wọn kunà lati mọ ọjọ ibẹwo Kristi; nitori naa gbogbo akitiyan ireti wọn fun ohun ti ọrun já si asán; “ Iwe a mã pani, ṣugbọn ẹmi a mã sọni di ãye: (2 Kọrinti 3:6). Ki a mọ Ọrọ Ọlọrun si agbari nikan kò le gba ẹnikẹni là. A ni lati kọ Ọrọ naa si wa lọkàn pẹlu, eyi ni Kristi wá lati ṣe.

Lilọ si Bẹtlẹhẹmu

Hẹrọdu rán awọn amoye si Bẹtlẹhẹmu pe, “Ẹ lọ iwadi ti ọmọ-ọwọ na lẹsọlẹsọ; nigbati ẹnyin ba si ri i, ẹ pada wá isọ fun mi, ki emi ki o le wá iforibalẹ fun u pẹlu.” Irawọ ti wọn ri ni Ila-oorun tun fara hàn, wọn si tẹle e lọ si ibi ti Ọmọ-ọwọ na wà. “Nigbati nwọn si wọ ile, nwọn ri ọmọ-ọwọ na pẹlu Maria iya rẹ, nwọn wolẹ, nwọn si foribalẹ fun u: nigbati nwọn si tú iṣura wọn, nwọn ta a lọrẹ wura, ati turari, ati ojia” (Matteu 2:11).

Awọn amoye ko pada si Jesuralẹmu gẹgẹ bi Hẹrọdu ti fẹ ki wọn ṣe, nitori Ọlọrun kilọ fun wọn ninu ala lati gba ọna miiran pada si ilu wọn. Lẹyin ti awọn eniyan wọnyii ti lọ tan, Ọlọrun fara han Josẹfu ninu ala lẹẹkan si i pe, “Dide, gbé ọmọ-ọwọ na pẹlu iya rẹ, ki o si sálọ si Egipti, ki iwọ ki o si gbé ibẹ titi emi o fi sọ fun ọ: nitori Hẹrọdu yio wá ọmọ-ọwọ na lati pa a” (Matteu 2:13). Hẹrọdu kò ni ọkàn lati juba Jesu, ohun ti o fẹ ṣe ni lati pa Ọmọ Ọlọrun nitori awọn amoye sọ pe Ọba awọn Ju ni.

Jesu ti Nasarẹti

Lẹyin iku Hẹrọdu, angẹli Oluwa fara hàn Josẹfu loju ala, ni Egipti lati sọ fun un pe kò si ewu mọ fun awọn Ẹbi Mimọ yii lati pada si Israẹli. Ẹru n ba Josẹfu lati pada si Judea, nitori Arkelau, ọmọ Hẹrọdu ni o n jọba nibẹ. Nipa itọni Ọlọrun, wọn lọ si Galili, wọn si lọ si ilu Nasarẹti.

Jesu ti Nasarẹti di okuta idigbolù fun awọn Ju, nitori ti wọn wi pe, “Ohun rere kan ha le ti Nasarẹti jade?” (Johannu 1:46). Idahun si eyi ni pe, “Wá wò o.” Iwọ ni lati ri Jesu ki o to mọ bi Ó ti dara to; o ni lati mọ Jesu ki o to le fẹ Ẹ. Awọn ti wọn mọ Ọn ti wọn si fẹ Ẹ ni wọn ni alumọni iyebiye ju lọ ni aye yii, wọn si ni ileri aye ti n bọ pẹlu.

“Gbat’ Onirẹlẹ Nasarẹt’

Dide fun ’ranlọwọ mi,

O f’alaafia f’ọkàn mi

Okùn lọ Imọlẹ de.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni kọ kede ihin ayọ ti ibi Jesu? Awọn ta ni o kọ gbọ ọ?
  2. Nibo ni Ọmọ Ọlọrun gbe dubulẹ si nigba ti awọn oluṣọ-agutan tọ Ọ wa? A kò ha le ri ibi ti o dara ju bayii lọ fun Jesu?
  3. Ni ilu wo ni a gbe bi Jesu? Sọ bi eyi ṣe ri bẹẹ.
  4. Ki ni itumọ “Bẹtlẹhẹmu”?
  5. Ta ni awọn amoye? Ọmọ Israẹli ha ni wọn i ṣe bi?
  6. Bawo ni wọn ṣe de Jerusalẹmu?
  7. Ki ni ṣe ti Josẹfu fi sá lọ si Egipti pẹlu Ẹbi Mimọ yii?
  8. Ilu Israẹli wo ni wọn yà si nigba ti wọn n pada bọ lati Egipti?
  9. Ki ni ẹbùn Keresimesi ti o tobi ju lọ ti a ti i fi fun ni?