Lesson 131 - Junior
Memory Verse
“Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ” (Matteu 22:39).Notes
Ibeere
Awọn eniyan ki i fi igba gbogbo beere ọrọ nitori wọn kàn fẹ ni imọ nipa ohun kan. Ọkunrin yii, ti o beere lọwọ Jesu ohun ti oun yoo ṣe ki oun ba le jogun iye ainipẹkun mọ idahun rẹ ki o tilẹ to beere. O kó Ofin, o si mọ ọn. O n fẹ dan Jesu wọ. Lai si aniani oun jẹ ọkan ninu awọn Farisi ti wọn n gbimọ pe ki awọn alaṣẹ mu Jesu. Wọn ko fẹ Oluwa ati awọn ẹkọ Rẹ.
Nipa ibeere amofin yii, o fi han pe oun fẹ gbọ ohun ti Jesu yoo sọ. Ipinnu ọkan rẹ ni lati dẹkùn mu Jesu. O beere ni ireti pe Jesu yoo sọ ọrọ ti o lodi si Ofin. Jesu mọ bi Oun yoo ti ba ọkunrin yii lọ, gẹgẹ bi O ti mọ bi Oun yoo ti ba gbogbo awọn ti n beere ọrọ lọwọ Rẹ lọ. Ibeere ni Jesu fi dahun: “Kili a kọ sinu iwe ofin?” Ọkunrin yii mọ Ofin daradara, o si sọ Ofin ti a kọ sinu Majẹmu Laelae (Deuteronomi 6:5; Lefitiku 19:18). Idahun Jesu wa ninu Ofin pẹlu, eyi ti ọkunrin yii mọ. “Ẹnyin o si ma pa ilana mi mó, ati ofin mi: eyiti bi enia ba ṣe, on o ma yẹ ninu wọn.” (Lefitiku 18:5).
“Ṣe Eyi”
Ọna si iye ainipẹkun jẹ ọkan naa fun gbogbo eniyan. Jesu wi pe, “Emi li ọna, ati otitọ, ati iye” (Johannu 14:6). Kọ si ọna kan si Ọrun fun eniyan kan ti o yatọ si ti awọn ẹlomiran. Jesu wi pe, “Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là” (Johannu 10:9).
Ṣe eyi! Eyi gan an ni iṣoro ti o wà ni igbesi aye ọkunrin yii. Oun kọ le ṣe ohun ti o yẹ ki o ṣe. Oun kọ ṣe ohun ti Ofin n beere lọwọ rẹ. Jesu kọ wá lati pa Ofun run: dipo eyi O wá lati mu un ṣẹ (Matteu 5:17).
Ihinrere ti Jesu mu wá ki i ṣe ohun kan ti o ṣe ajeji patapata, ti kọ si si ninu Majẹmu Laelae. Jesu kó ni ni Ihinrere ti ifẹ ti o le mu iyipada wá si igbesi-aye eniyan. “Bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun” (2 Kọrinti 5:17). Ihinrere Jesu n yi ọkàn pada, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ fun Esekiẹli lati sọtẹlẹ pe: “Emi o si fun wọn li ọkàn kan, emi o si fi ẹmi titun sinu nyin; emi o si mu ọkàn okuta kuro lara wọn, emi o si fun wọn li ọkàn ẹran” (Esekiẹli 11:19).
Ko si ifẹ ninu ọkàn awọn Farisi, ti i ṣe “oludaabo bo Ofin.” Ni igba kan Jesu wi pe, “Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi agabagebe; nitoriti ẹnyin nsan idamẹwa minti, ati anise, ati kumini, ẹnyin si ti fi ọran ti o tobiju ninu ofin silẹ laiṣe, idajọ, ãnu, ati igbagbó: wọnyi li o tó ti ẹnyin iba ṣe, ẹnyin kì ba si fi wọnni silẹ laiṣe” (Matteu 23:23).
Kọ Ni Ifẹ
Ifẹ Jesu ninu ọkàn ni agbara ti o n fun ni ni ipá lati ṣe ohun ti o tó. Amofin yii fi han pe ifẹ yii kọ si ninu aye oun; bi o ba ṣe pe o ti mọ ifẹ Ọlọrun yii, oun ki ba ti beere ibeere yii. O bẹrẹ si da ara rẹ lare nipa bibeere pe: “Tani ha si li ẹnikeji mi?” Ọrọ oun tikara rẹ da a lẹbi. Onigbagbọ ki i ṣe awawi fun ara rẹ. Nigba kan, Jesu wi fun awọn Farisi pe, “Ẹnyin li awọn ti ndare fun ara nyin niwaju enia; ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn nyin” (Luku 16:15).
Jesu kọ sọ itumọ ẹni keji gẹgẹ bi iwe itumọ, tabi ki O ṣe apejuwe ti kọ le ye ni. Jesu ṣe àlàyé ti o rọrun ti o si yé ni daradara ki a má ba le tete gbagbe ẹkọ yii.
Jà Lólẹ
Jesu dahun ibeere yii, “Tani ha si li ẹnikeji mi? pẹlu apejuwe. Ọna kan wà laarin Jerusalẹmu ati Jeriko. Ọkunrin kan, boya Ju, ti o n rin lọ lọna yïi, bó si ọwọ awọn ọlọṣa. Wọn gba ohun ini rẹ, wọn si fi i silẹ si ẹba ọna ni a-pa-ipatan.
Awọn Arinrin-ajo Miiran
Awọn arinrin-ajo miiran n rin loju ọna yii lati Jerusalemu lọ si Jẹriko. Ọkan ninu wọn jẹ alufaa, ẹni ti o jẹ pe, boya, o ti n ṣe iṣẹ alufaa rẹ ninu Tẹmpili ni Jẹrusalẹmu. Dajudaju, o ti ṣe eto isin gẹgẹ bi Ofin. Boya o ro pe lati fi ọwọ kan ẹni ti o gbọgbẹ yii yoo sọ oun di alaimó. O kọja lọ niha keji lai si ọrọ itunu kan rara tabi ki o gbiyanju lati ṣe iranwọ. Isin ti ode ara ni gbogbo isin rẹ. Oun kọ ni ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn rẹ. “Ẹnikẹni ti o ba di eti rẹ si igbe olupọnju, ontikararẹ yio ke pẹlu: ṣugbọn a kì yio gbó” (Owe 21:13).
Ẹni keji ti o kọja lọ ni ọmọ Lefi kan, ti o n ṣe iranṣẹ fun awọn alufaa ninu Tẹmpili. Boya o ro pe oun ti ṣe ojuṣe oun niwaju Oluwa. Iṣẹ rẹ fi han pe oun kọ ni ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn rẹ. O wo ọkunrin ti o gbọgbẹ yii, o si ba ọna ti rẹ lọ. Ofin beere pe ki a huwa ti o dara ju bẹẹ lọ si ẹranko, i baa tilẹ jẹ ti ọta ẹni paapaa (Ẹksodu 23:4, 5).
Alaanu Ara Samaria
Arinrin-ajo miiran ti o tẹle wọn ni ara Samaria kan. Awọn Ju kọ ni nnkan kan ṣe pẹlu awọn eniyan wọnyii (Johannu 4:9). Ṣugbọn ifẹ ọmọnikeji, eyi ti kọ si ninu ọkàn alufaa ati ọmọ Lefi, wà ninu ọkan ara Samaria yii. Ọwọ rẹ kọ di pupọ ju, bẹẹ ni kọ di isin rẹ lọwọ, lati ran alaini kan lọwọ. Oun kọ duro ki ẹni ti o gbọgbẹ yii wá beere iranwọ. Ara Samaria yii lọ si ọdọ ẹni ti o n fẹ iranlọwọ.
Ninu 1 Johannu 3:18, a ka pe “Ẹ máṣe jẹ ki a fi ọrọ ẹnu tabi ahọn fẹran, bikoṣe ni iṣe ati li otitọ.” Ara Samaria yii ṣe eyi, nitori oun ko wo ọkunrin naa nikan, ṣugbọn o fi aanu han nipa riran an lọwọ. O di ọgbẹ naa lẹyin ti o da ọti-waini ati ororo si i, boya lati wẹ ẹ mó ati ki o le tu u lara. Awọn miiran ti le rọ pe awọn ti ṣe ohun nlá nlà. Ara Samaria yii kọ lọ, lẹyin ti o ti di ọgbẹ naa paapaa. O gbé ọkunrin ti o gbọgbẹ yii sori ẹranko ti oun tikara rẹ, o si gbe e lọ si ile-ero. A sọ fun ni pe kọbọ meji ni owó ọyà ọjọ meji, yoo si to ná fun ọjọ pupọ. Ara Samaria yii san owo itọju ọkunrin ti wón ṣá lọgbẹ yii, o si ṣeleri lati pada wa san ohunkohun ti onile-ero naa ba ná kun un.
Ẹni Keji
Nigba naa ni Jesu beere lọwọ amofin yii ta ni ó ro pe i ṣe ẹni keji ọkunrin ti o bó si ọwọ awọn ọlọṣa. Bawo ni eyi ti yatọ si idahun ti amofin yii n reti! O ṣe dandan fun un lati yin ẹni ti wọn korira, bi o tilẹ jẹ pe kọ darukọ “ara Samaria.” Jesu wi fun un ki o fi aanu hàn bẹẹ gẹgẹ.
Ọpọlọpọ ti n rin ni opopo aye dabi ọkunrin ti o gbọgbẹ yii. Wọn ti fi ile-isin Ọlọrun ati ibukun Rẹ silẹ. Ẹṣẹ ti jà wọn lole gbogbo ohun ti o dara. Wọn dubulẹ ni ẹbá ọna pẹlu ọgbé -- ni a-pa-ipatan (wọn wà laaye nipa ti ara ṣugbọn wọn ti kú iku ẹmi). Ko ha si ẹni ti o le ràn wón lọwọ?
Ifẹ ninu Ọkàn
Awọn eniyan Ọlọrun maa n wa anfaani lati ran awọn miiran lọwọ. Awọn ọmọde le ṣe iranwọ ni ọna pupọ -- wọn le sare lọ si ibi ti a ba rán wọn, wọn le ṣe itọju awọn ọmọ kekeke, wọn si le mú itanna lọ fun awọn alaisan. Ninu ile itọju awọn alaisan, loju ọna opopo, ninu tubu, ati ni ibikibi ni awọn eniyan Ọlọrun o jẹri ti wọn si n sọ nipa Jesu. Wọn n ran awọn ẹlomiran lọwọ, nitori wọn ni ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn wọn. Nigba ti ẹni kan ba ri igbala, ifẹ Ọlọrun yoo wá sinu ọkàn ati igbesi-aye ẹni naa. Iriri yii maa n mu ki eniyan ṣe gẹgẹ bi Oluwa ti paṣẹ. “Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ: ati ẹnikeji rẹ bi ara rẹ.” Ifẹ ninu ọkàn ni akoja Ofin (Romu 13:10).
Jesi wi pe, “Ofin titun kan ni mo fifun nyin, Ki ẹnyin ki o fẹ ọmọnikeji nyin; gẹgẹ bi emi ti fẹran nyin, ki ẹnyin ki o si le fẹran ọmọnikeji nyin. Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin” (Johannu 13:34, 35). Ọmọlẹyin Jesu maa n ni ifẹ si ọmọnikeji rẹ -- eyi ni ọna ti a le fi mọ Onigbagbó. Awọn miiran ni isin ti o dabi ti alufaa ati ọmọ Lefi ni. Bi ẹni kan ba fẹ jogun iye ainipẹkun, o gbọdọ ni isin ti o ju ti wọn lọ. O gbọdọ ni ju iṣẹ rere lọ, ki o ba le lọ si Ọrun. Ọpọ eniyan ni o maa n tọju ara wọn daradara, ti wọn si maa n ro nipa ti ara wọn ṣaaju ẹlomiran. Awọn ti yoo jogun iye ainipẹkun maa n ṣe bi wọn ti n fẹ ki ẹlomiran ṣe si wọn (Luku 6:31), -- ju eyi lọ pẹlu, wọn maa n ṣe si awọn ẹlomiran gẹgẹ bi wọn ti n ṣe si ara wọn. Ẹsin igbagbó ni pe ki a dabi Kristi, ki a si ni ifẹ si ọta wa pẹlu. “Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin kọ, ti nwọn si nṣe inunibini si nyin” (Matteu 5:44).
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti amofin yii fi ibeere yii siwaju Jesu?
- Bawo ni amofin yii ṣe le jogun iye ainipẹkun?
- Bawo ni eniyan ṣe le jogun iye ainipẹkun lonii?
- Ki ni ṣe ti Jesu sọ nipa Alaanu ara Samaria?
- Ẹkọ wo ni Jesu fẹ kọ ni nihin?
- Ewo ni o fi ifẹ han fun ẹni keji rẹ ninu awọn arinrin-ajo wọnyii?
- Ta ni ẹni keji rẹ?
- Bawo ni iwọ ṣe le jẹ ẹni keji fun awọn wọnni ti o ba ba pade?