Lesson 132 - Junior
Memory Verse
“Ohun kan li a kọ le ṣe alaini: Maria si ti yàn ipa rere na, ti a kọ le gbà lọwọ rẹ.” (Luku 10:42).Notes
Alejo Kan
Jesu wọ ileto Bẹtani nibi ti Maria ati Marta n gbé (Johannu 11:1). A pẹ e lati jẹ alejo ninu ile wọn. Jesu fẹran ẹbi yii (Johannu 11:5), O si maa n bẹ wọn wọ nigbakuugba. Lai ṣe aniani inu Jesu dùn lati ri ile nibi ti a gbe tẹwọgba A. Nigba naa Oun kọ ni ile ti i ṣe ti Rẹ nihin ninu aye. Boya lẹẹkan ṣoṣo yii ni wọn pe E. Awọn eniyan ti wọn n fẹ Jesu ko pọ. A tun kà nipa akoko miiran ti Jesu wà ni Bẹtani nigba ti o wọ si ile Simoni adẹtẹ (Marku 14:3).
Ki i ṣe ọpọ eniyan lonii ni wọn n fẹ Jesu ninu igbesi-aye wọn ati ni inu ile wọn. Nigba ti Jesu ba wọ inu aye eniyan, ile rẹ a yipada pẹlu. Orire ẹni ti o wa ninu ile ti a ti gba Jesu ni alejo ti pọ to! Ninu awọn ile miiran a so akọle si oke ti o ka bayii pe,
“Kristi ni Olori ni ile yii,
Alejo airi nibi ounjẹ gbogbo,
Olufeti si gbogbo ọrọ ti a n sọ.”
Alabukunfun ni ọkan ati ile ti a pe Jesu si. Jesu ha wà ninu ọkàn ati aye rẹ? A ha ti pe Jesu lati jẹ Alejo ninu ile rẹ?Maria ati Marta ni awọn arabinrin Lasaru (Johannu 11:1, 2). Lai ṣe aniani inu wọn dùn lati gba Jesu si ile wọn. Wọn ko huwa bakan naa ṣá, nigba ti Jesu jẹ ipe wọn. Jẹ ki a wo ile yii ki a si wo bi wọn ti ṣe si Jesu.
Jijoko lẹba Ẹsẹ Jesu
Arabinrin kan, Maria, dabi ẹni ti o ro pe anfaani kan niyii lati gbọ ọrọ lẹnu Olukọni. Lai ṣe aniani Jesu mọ aniyan rẹ lati gbọ ẹkọ Rẹ. “Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo: nitori nwọn ó yo” (Matteu 5:6). O dabi ẹni pe Maria gbagbe gbogbo nnkan miiran yatọ si anfaani rẹ lati gbọ ẹkọ lati ẹnu Olukọni Nla naa.
“Ki n jokoo nib’ẹsẹ Jesu,
Ọrọ t’O sọ ti dun to!
Ib’ayọ! tó ṣe ’yebiye!
A ha le ba mi nibẹ.
Ki n jokoo nib’ẹsẹ Jesu,
N o bojuwo ẹyin mi;
Ifẹ Rẹ si mi ti pọ to!
O ti sọ mi di ti Rẹ.
“Ki n jokoo nib’ẹsẹ Jesu,
Mo ri ‘bukun kikun gbà;
Mo f’ẹru ẹṣẹ, aniyan,
Ati aarẹ mi sibẹ.
Ki n jokoo nib’ẹsẹ Jesu,
Ki n sọkun ki n gbadura
Or’ọfẹ ati ’tunu
“Bukun mi, Olugbala mi,
Mo wolẹ ni ẹsẹ Rẹ;
Ninu ’fẹ, jọ bojuwo mi,
Jẹ ki n roju Rẹ didan.
Jẹ kemi dabi Rẹ Jesu,
Sọ mi di mimó bi Rẹ;
Ki n fihan pe ti Rẹ lemi,
Wọ ti ’ṣe ododo mi.”
Dafidi wi pe, “Ohun kan li emi ntọrọ li ọdọ OLUWA, on na li emi o ma wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile OLUWA li ọjọ aiye mi gbogbo, ki emi ki o le ma wọ ẹwà OLUWA, ki emi ki o si ma fi inu- didùn wọ tẹmpili rẹ” (Orin Dafidi 27:4). O ni lati jẹ pe eyi ni ero Maria pẹlu. O n ṣafẹri ododo ti o wà ninu Ihinrere ki o ba le maa gbe inu Ile Oluwa laelae. Dajudaju o fẹ lati maa wo ẹwà inu awọn ẹkọ Jesu ati lati lọ jinlẹ ninu wọn. Boya o ni ibeere lati beere, tabi o kan fẹ gbọ awọn owe Rẹ. “O si fi owe ba wọn sọrọ ohun pipọ” (Matteu 13:3).
Maria gbọ ọrọ Rẹ. O feti silẹ lọna ti kọ fi padanu gbogbo rẹ. O fi eti inu ati ti ode gbọ Ọrọ naa. Awọn ẹlomiran a maa fi eti ti ara gbọ Ọrọ Ọlọrun ṣugbọn kọ ju bẹẹ lọ. Wọn a gbagbe ohun ti wọn ti gbọ kiakia. Wọn ki i ṣe oluṣe Ọrọ naa bi wọn ti jẹ olugbọ (Jakọbu 1:22). “Ọrọ rẹ ni mo pamó li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ si ọ” (Orin Dafidi 119:11).
Ó Kún Fún Aniyan ati Laalaa
Arabinrin keji, Marta, ti gba Jesu sinu ile rẹ. Lẹyin naa o wá n ṣaniyan nipa ohun ti ara. Boya o yara jade ni ireti pe oun yoo wá ounjẹ ki oun naa si jokoo lẹsẹ Jesu pẹlu. Nnkan kan ni o kọkọ gba akoko rẹ, lẹyin eyi nnkan miiran, titi ero ti rẹ ko fi jẹ ti Jesu mọ. Ounjẹ ti o n pese fun Un gba akoko rẹ ati ero rẹ. Ninu aniyan rẹ lati ṣe itọju Jesu o fún ẹkó Rẹ ati ọrọ Rẹ pa. Ohun ti o kan ni pe o mura tan lati fi arabinrin rẹ sùn. O ri ariwisi nitori Maria n ṣe ohun ti Marta ti ṣainaani, ohun kan ti a ko le ṣe alaini – jijoko lẹba ẹsẹ Jesu ati gbigbọ ọrọ Rẹ.
A le ro pe Maria kọ ṣe ojuṣe rẹ ninu iṣẹ naa. Jesu ki ba ti yin in bi o ba ri bẹẹ. O ṣe e ṣe fun eniyan lati fi iṣẹ rẹ si eto, ki o si làna rẹ ki o ba le ni àyẹ fun ohun ti ẹmi ati fun iṣẹ ti rẹ pẹlu. “Ẹ mã ṣe ohun gbogbo tẹyẹtẹyẹ ati lẹsẹlẹsẹ” (1 Kọrinti 14:40).
Maria nikan kó ni a fi sùn pe o “joko lẹba ẹsẹ Jesu.” Awọn olufisun Daniẹli kọ le ri nnkan kan lodi si i bi ko ṣe ijolootọ rẹ si Ọlọrun (Daniẹli 6:5, 6). A ti ni iru ariwisi kan naa si awọn Onigbagbọ miiran. O ti dara to pe ki awọn eniyan dá ọ lẹbi fun iha ti o kọ si Ọlọrun ju pe ki Ọlọrun dá ọ lẹbi fun ọna ti kọ tọ ti o fi n ba awọn eniyan ẹlẹgbẹ rẹ lọ. Ni akoko kan Jesu wi pe,” Awọn ara-ile enia si li ọta rẹ” (Matteu 10:36).
Marta ti bẹrẹ daradara boya o si ni ipinnu rere. Lati fẹ ṣe ohun kan fun Jesu ni ero ẹnikẹni ti o ba ti ri igbala. Ṣugbọn Marta ṣe laalaa nipa ṣiṣe iranṣẹ titi o fi ni idiwọ lati gbọ ọrọ Oluwa. Aniyan ati laalaa nipa iṣẹ wọ Marta lara to bẹẹ ti Oluwa fi ba a wi – ki i ṣe fun ṣiṣe iranṣẹ, ṣugbọn fun ṣiṣe laalaa nipa ṣiṣe iṣẹ pupọ.
Ohun Ti a Ko Le Ṣe Alaini
Awọn eniyan bi Marta pọ lonii. Wọn ti bẹrẹ daradara nipa gbigba Jesu sinu aye ati ile wọn. O dabi ẹni pe wọn gbagbe pe eniyan ni lati rin ninu Imọlẹ ki o ba le gbadun irẹpọ Jesu (Johannu 12:35). Aniyan iṣẹ wọn a kà wọn laya to bẹẹ ti wọn fi sọ itara nù nipa ohun ti ẹmi. Lai pẹ wọn o maa ṣe aniyan si i nipa aye yii, wọn ó si fà sẹyin ninu ilepa aye ti n bọ. Iṣẹ ile-iwe ati ere le gba ọkan awọn ọmọde to bẹẹ ti ti wọn kọ fi ni ṣọra lati ka Bibeli ki wọn si gbadura, nipa bẹẹ wọn a si sọ ohun kan naa ti a kọ le ṣe alaini nù – alaafia pipe ati otitọ ninu ọkàn.
Ọlọrun ko fẹ ki awọn eniyan Rẹ ṣe aniyan aye yii to bẹẹ ti wọn o fi kuna ohun kan ti a kọ le ṣe alaini – idaniloju idariji ẹṣẹ. Pupọ ninu awọn eniyan Ọlọrun ni wọn n ṣiṣẹ fun ounjẹ oojọ wọn. Wọn ni ojuṣe ti wọn ati ile wọn, ṣugbọn iwọnyi kọ di ẹrù pa wón. Olori ifẹ wọn jẹ fun ohun ti ẹmi ati iduro wọn niwaju Ọlọrun. “Ṣugbọn ẹ tẹte mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ” (Matteu 6:33).
Awọn kan n ṣe aniyan nipa ohun pipọ ṣugbọn ohun kan ni o yẹ ki wọn fi ọkan wọn fún. O dabi ẹni pe wọn n ṣe laalaa pupọ -- boya lori ọpọ ohun ti kọ ni laari dipo lori ohun kan ti a kọ le ṣe alaini. Wọn le ni ọpọlọpọ nnkan lati fi fun Oluwa, ṣugbọn ohun danindanin kan ni Oun n wọ -- ẹri-ọkàn ti o mó sipa ti Ọlọrun ati eniyan. Ọpọlọpọ ni wọn n fẹ lati ṣe iṣẹ rere ati lati ná owo wọn fun ile Ọlọrun; ṣugbọn bi wọn kọ ba ni ohun kan ti a ko le ṣe alaini, wọn kuna ohun gbogbo ti yoo ṣe wọn yẹ fun Ọrun. “Nitori nibiti iṣura nyin gbé wà, nibẹ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu” (Luku 12:34).
Maria yan ipa rere, ti ẹmi, -- ti o duro ti o si wà titi -- yatọ si awọn ohun ti ara ti kọ ni pẹ kọja lọ. Ewo ni iwọ yàn?
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti Jesu lọ si ile Maria ati Marta?
- Ki ni ipa rere ti Maria yàn?
- Ki ni ṣe ti Maria fẹ jokoo lẹba ẹsẹ Jesu?
- Ki ni Marta n ṣe?
- Ki ni ẹsun Marta?
- Ki ni ṣe ti Jesu bá Marta wi?
- Ninu awọn mejeeji, ewo ni iwọ fẹ jọ? Ki ni ṣe?
- Bawo ni o ṣe le dabi rẹ?