Luku 11:1-13; Matteu 6:9-13

Lesson 133 - Junior

Memory Verse
“Ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura, ki ẹnyin ki o má ba bọ sinu idẹwọ” (Matteu 26:41).
Notes

Ifẹ Ọkan Awọn Ọmọ-ẹyin

Awọn ọmọ-ẹyin Jesu ti fi ohun gbogbo silẹ lati tọ Ọ lẹyin, wọn ti lọ yika agbegbe ilẹ naa fun igba diẹ, wọn si ti n ṣe iṣẹ-iyanu ni orukọ Rẹ. Wọn n yọ ninu iṣẹ nla ti wọn n ṣe ninu iṣẹ-iranṣẹ wọn. Ni ọjọ kan ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin tilẹ sọ bayii fun Jesu, “Oluwa, kó wa bi ãti igbadura.”

Iru adura ti gbogbo wa ni lati gbà niyii. Boya a ti n sin Ọlọrun fun ọpọ ọdun, ti O si ti n dahun awọn adura wa ni ọna iyanu. Eyi kọ fi han pe a ti kó gbogbo ohun ti Ọlọrun n fẹ ki a mọ. Bi a ba ti ri idahun si adura wa to, ni a maa n kó nipa agbara ti o wà ninu adura to, bẹẹ ni yoo si maa mu wa rin ni irẹlẹ niwaju Jesu to bẹẹ ti a o fi maa kigbe si i pe “Oluwa wa ọwọn, kó wa bi a ti i gbadura!”

Jesu ni Ọmọ Ọlọrun, O si sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pe, “Ọkan li emi ati Baba mi jasi” (Johannu 10:30). Sibẹ Jesu mọ pe Oun ni lati gbadura, a si maa gbadura ni gbogbo oru nigba miiran. Bi Oun ba ni lati gbadura, melomelo ni o jẹ ọranyan fun wa lati gbadura!

Baba Wa

Jesu só fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe ki wọn maa pe Ọlọrun ni “Baba wa.” Nigba ti a ba ri idariji gba lọdọ Ọlọrun a ti bi wa sinu ẹbi Rẹ. “Emi o si gbà nyin, emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbinrin mi, li Oluwa Olodumare wi” (2 Kọrinti 6:17, 18).

Wo iru iyọnú ti baba tootọ maa n ni si ọmọ rẹ! Inu rẹ a maa dùn pupọ nigba ti a ba bi ọmọkunrin kan sinu ẹbi rẹ, a si ṣe ọpọlọpọ iséra rẹ lati fun ọmọde naa ni gbogbo anfaani ni aye. Dajudaju, a ni lati jẹ ọmọde naa ni iya bi o ba ṣe ohun ti kọ tó, ṣugbọn baba rẹ n ṣe bẹẹ nitori ki ọmọ naa ba le jẹ ọmọkunrin ti yoo le ba awọn ẹlọmiran gbe pọ ni alaafia ki o si jẹ iranlọwọ ni aye.

Ọlọrun fẹran awọn ọmọ Rẹ ju bi awọn baba aye yii ti fẹran wa. Njẹ inu wa kọ dun pe Oun n fẹ pe ki a jẹ ọmọ Rẹ, paapaa pe Oun tilẹ jẹ ki a maa pe Oun ni Baba nigba ti a ba n gbadura?

Nigba ti a ba n gbadura a n ba Ọlọrun sọrọ. O n fẹ ki a maa sọ gbogbo ayó wa ati gbogbo ibanujẹ wa fun Oun. Nigba ti ohun iyanu kan ba ṣẹlẹ si ọmọde, oun a fi iru idunnu bẹẹ lọ sọ fun awọn obi rẹ. Iwọ ha n sọ fun Jesu bẹẹ? Iwọ ha n dupẹ lọwọ Rẹ fun awọn ibukun ti o n ri gba? O n fẹ gbó adura rẹ -- ki iṣe kiki nigba ti o ba n bẹ Ẹ pe ki O fun ọ ni ohun kan, ṣugbọn nigba ti kọ si ohun miiran ninu ọkàn rẹ ju iyin lọ. Jesu n wi pe, “Jẹ ki emi ri oju rẹ, jẹ ki emi gbó ohùn rẹ; nitori didùn ni ohùn rẹ, oju rẹ si li ẹwà” (Orin Sọlomọni 2:14).

Awọn Ọré

O ṣe e ṣe nigba ti ọmọde ba n dagba diẹ si i oun a fẹ lati pa ara mó diẹ kuro lọdọ awọn obi rẹ, yoo si fẹ lati fi ọkàn tán ọrẹ rẹ ti o jẹ korikosun fun un. Jesu fẹ fi ara Rẹ ṣe ọrẹ yii. “Ọré mi li ẹnyin iṣe, bi ẹ ba ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun nyin” (Johannu 15:14). Iwọ ha n huwa si Jesu gẹgẹ bi ọré? Njẹ iwọ maa n gbadun biba Jesu sọrọ gẹgẹ bi o ṣe maa n gbadun bibẹ awọn ọrẹ rẹ ni ile-ẹkọ wọ?

Nigba ti iwọ ba ji ni owurọ, iwọ ha n ranti pe Jesu ni Ọrẹ rẹ ti o dara ju lọ; iwọ ha n fi Oun ṣe ẹni akọkọ ti o n ba sọrọ, ki gbogbo aniyan aye yii to ṣú bo ọkàn rẹ?

Arakunrin Agba

Ni igba miiran Jesu pe ara Rẹ ni Arakunrin wa (Matteu 12:50). Bi a kọ ba gbadura si I, a dabi ẹni pe a ko ba arakunrin wa sọrọ. Njẹ ki i ṣe ohun ti o ba ni ninu jẹ bi ẹni kan ba wà ninu ile wa ti ki i fẹ sọrọ? Jesu wà ni tosi nigba gbogbo O si n gbọ, O si n ri awọn nnkan ti a n ṣe; ro o wo bi ọkàn Rẹ yoo ti ri nigba ti a ba ṣe aibikita lati ba A sọrọ ninu adura!

Nigba miiran awọn eniyan kọ fẹ lati yọ Oluwa lẹnu nitori “awọn ohun kekere.” Jesu kọ ka eyi si iyọlẹnu. Oun a maa kiyesi awọn nnkan kekere wọnni O si n fẹ mọ nipa wọn. Awa ki i maa ṣe akiyesi awọn ẹyẹ kékẹké wọnni lọ titi, ṣugbọn Jesu n ṣe akiyesi wọn. Ọkan kọ le bó silẹ ki Oun ki o má mọ nipa rẹ.

Lai Sinmi

Jesu n fẹ ki a maa gbadura ni aisinmi. Eyi yii ki i ṣe pe a ni lati wà lori eekun wa ni gbogbo akoko, ṣugbọn itumọ rẹ ni pe a ni lati maa ranti Jesu ninu ohun gbogbo ti a n ṣe. A ti gba adura owurọ ninu ile wa ki a to jade, bi a si ti n lọ a o tun maa fi ọkan gbadura pe ki Ọlọrun daabo wa ni gbogbo ọjọ naa, ki a ba le sọda opopo ọna ni ailewu ki jamba ma ba ṣẹlẹ si wa ni ọna miiran pẹlu. Bi idanwo ba de si wa a o sọ fun Jesu bayii, “Iwọ mọ nipa eleyi ju mi lọ, Oluwa. O ki yoo ha ràn mi lọwọ?” Yoo ran wa lọwọ bi O ba ri i pe a n gbiyanju lati wu Oun.

Ọpọlọpọ nnkan ni o yi wa ka nitori eyi ti a ni lati dupẹ lọwọ Rẹ. Boya a ri ikuuku ti afẹfẹ lile n gbá lọ, tabi wiwọ oorun ti o logo lati wọ, tabi awọn oke ti wọn fi ara kọra pẹlu eweko tutu minniminni lori wọn, tabi ẹwa titan itanṣan oorun lori yinyin ti o bo ori oke. Ọkan wa a sọji pẹlu ayọ fun ẹwa awọn ohun ti Ọlọrun dá wọnyii a o si dupẹ lọwọ Ọlọrun nitori O mu ki aye lẹwa to bẹẹ fun wa lati gbe inu rẹ. Ṣugbọn a le ri ẹni kan ti n jẹ irora aisan, tabi ọmọde kan ti o fara pa ni ibi iṣire, tabi ẹni kan ti ko ni ile ti o dara lati gbe. Inu wa yoo bajẹ a o si gbadura pe ki Ọlọrun ràn wón lọwọ.

Adura Ikọkọ

Ki a ba le maa wa lori ina adura nigba gbogbo, lati le mọ pe Jesu wa ni tosi lati gbọ adura ti a gba wuyẹwuyẹ nigbakigba, a ni lati gbadura pupọ lori eekun wa, pẹlu. Jesu n fẹ ki a kiyesara lati jẹ mimó, ki a gbadura ni ikọkọ ninu yara wa, tabi ninu ile-isin, ni ibi pẹpẹ adura. Bi a ba gbadura daradara nigba naa, ti a si fi ọkan ati ara wa rubọ fun Un, a o mọ pe Oun wà ni tosi wa nigba gbogbo. Ṣugbọn bi a ba ṣe alai bikita ati alafara, ti o jẹ pe adura iṣẹju diẹ ni a n gba nigba gbogbo, a o gbagbe Oluwa nigba ti a ba n ba iṣẹ oojọ wa lọ tabi ni ibi iṣire wa. Oun ki yoo dabi Ọrẹ korikosun tabi Arakunrin fun wa mọ, ẹni ti a le ba sọrọ nigbakugba.

Nigba ti a ba n gbadun irẹpọ timọtimọ bẹẹ pẹlu Jesu, kọ ni ṣoro fun wa lati bori idanwo ti o n wá si ọna wa ti o n fẹ mu wa ṣe ohun ti ko tó. Ṣugbọn bi a ba gbagbe Jesu fun igba diẹ, bi idanwo ba de a o ti fẹrẹ ṣubu sinu ẹṣẹ ki a to fura rara pe bẹẹ ni o ri. Adura ni aabo wa lọwọ ẹṣẹ. Bi idanwo ti o le ba tilẹ de, a le gbadura pe ki Jesu fi Ẹjẹ Rẹ bo wa lọtun, Oun yoo si fun wa ni agbara lati bori gbogbo ibi.

Ninu Ọgbà Nì

Nigba ti o ku diẹ ki a kan Jesu mọ agbelebu, O lọ sinu Ọgbà Getsemane lati gbadura. O mu Peteru, Jakọbu ati Johannu pẹlu ara Rẹ O si ni ireti pe wọn o ṣe iranlọwọ fun Oun lati gbadura. Dipo ki wọn ṣe bẹẹ, oorun ni wọn lọ sùn. Jesu fi han pe wọn n já Oun tilẹ nigba ti O wi pe, “Ẹnyin kọ le bá mi ṣóna ni wakati kan?” O kilọ fun wọn pe wọn ni lati maa ṣọna ki wọn si maa gbadura ki wọn maa ba bó sinu idẹwo. Bi wọn kọ ba le gbadura fun Un, bi o ti wu ki o ri wọn i ba tilẹ gbiyanju lati gbadura fun ara wọn. Ṣugbọn wọn tun pada lọ sùn; nigba ti awọn ọmọ ogun ati awọn olufihan Jesu de, awọn ọmọ-ẹyin kọ ni agbara lati duro fun Jesu, wọn si yipada wọn salọ.

Adura pẹlu Omije

Jesu ni Oun o gbọ adura ti o ti inu ọkan irobinujẹ ati ironupiwada jade wa. Jesu ri omije wa nigba ti a ba gbadura, O si n ṣe akiyesi wọn. Nigba kan Israẹli ni ọba kan ti a n pe ni Hẹsekiah ẹni ti o ṣaisan pupọ. A rán wolii Isaiah si i pe ki o fi ile rẹ si eto ki o si mura silẹ lati kú. Hẹsekiah kọ oju rẹ si ogiri o si sọkun o si gbadura pe ki oun ba le sàn ninu aisan naa. Ọlọrun rán Isaiah si Hẹsekiah lẹẹkan si i pe, “Mo ti gbó adura rẹ, mo ti ri omije rẹ: kiyesi i emi o fi ọdun mẹẹdogun kún ọjọ rẹ” (Isaiah 38:5). Ọlọrun ti ṣe akiyesi omije rẹ. Nigba ti a ba gbadura ni irẹlẹ, ti a si fi ọkàn wa rubọ fun Oluwa, omije wa yoo maa ṣàn pẹlu adura wa.

Omije Hẹsekiah ki i ṣe ti ibanujẹ pe oun jẹ ẹlẹṣẹ, ti o wa ninu wahala. O rán Ọlọrun leti pe oun ti rin niwaju Oluwa pelu aya pipe, oun si ti ṣe eyi ti o tọ ni oju Rẹ. Omije kọ le mu ki a ri ibeere wa gba lọwọ Oluwa bi a ba gbiyanju lati bọ ẹṣẹ wa mọlẹ.

Adura fun Awọn ti n Ṣegbe

Ọlọrun n fẹ ki a gbadura fun awọn ti n ṣegbe, ki wọn ba le ri igbala ki wọn si bó ninu ijiya. O n fẹ ki a ké ki a si gbadura, “Ẹniti nfi ẹkun rìn lọ, ti o si gbé irugbin lọwọ, lõtọ, yio fi ayọ pada wá, yio si rù iti rẹ” (Orin Dafidi 126:6). Nigba ti a ba gbadura tẹduntẹdun fun awọn ti n ṣegbe, ti ọkàn wa si n fẹ gidigidi pe ki wọn le ri igbala, Jesu yoo dahun adura wa, inu wa yoo si dun lati kó “iti” ti o ṣe iyebiye wá si iwaju Oluwa. Ẹmi Ọlọrun yoo ràn wá lọwọ lati gbadura nigba ti a kọ ba mọ ohun ti a o sọ. “A kọ mọ bi ã ti igbadura gẹgẹ bi o ti yẹ; ṣugbọn Ẹmi tikararẹ nfi irora ti a kọ le fi ẹnu sọ bẹbẹ fun wa” (Romu 8:26).

Nigba ti awa tikara wa ba ti ri igbala, isọdimimọ, ati Ẹmi Mimọ gbà, ti a si n gbe igbesi-aye wa ni fifi ara mó Oluwa timọtimọ, a o maa fẹ pe ki O pada wa lati gbe ijọba Rẹ kalẹ ni aye yii fun ẹgbẹrun (1,000) ọdun ti alaafia. Nigba ti a ba gbe Ijọba Ọlọrun kalẹ ni aye yii, nigba naa ni awọn eniyan yoo maa ṣe ifẹ Rẹ. Ni akoko yii, Onigbagbọ ti o ni Ijọba ninu ọkàn rẹ a maa gbadura bayii; “Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹẹni li aiye.” Ṣugbọn adura yii ki yoo ṣe wa ni ire kan bi a ba n taku lati gba ọna ti wa.

Ounjẹ Oojọ

Jesu kó awọn ọmọ-ẹyin Rẹ lati gbadura bayii: “Fun wa li onjẹ õjọ wa loni.” Jesu sọ pe Baba wa ti n bẹ ni Ọrun mọ pe a ṣe alai ni nnkan wọnyii yoo si pese, ṣugbọn sibẹ Oun n fẹ ki awọn ọmọ Rẹ beere. Nigba ti a ba beere ti Oun ba si fi i fun wa, igbagbọ wa yoo maa pọ si i. Bi igbagbó wa ba ti pọ to pe Oun yoo dahun adura wa, ni a o tubọ maa gbadura pupọ si i.

Adura Agbayọri

Njẹ bawo ni yoo ti ri bi a kọ ba dahun adura wa lẹsẹ kan naa? O ha yẹ ki eyi ni mu igbagbó wa rẹwẹsi bi? Jesu fun wa ni apẹẹrẹ lati fi ohun ti a o ṣe hàn wa bi a ko ba tete dahun adura wa. O sọ fun wa nipa ọkunrin kan ti ọrẹ rẹ de lai ro tẹlẹ ni oru, ko si si ounjẹ ninu ile rẹ lati fun un jẹ. O beere pe ki awọn aladugbo rẹ yá oun ni akara, ṣugbọn a kọ fun un nitori aladugbo rẹ ti wà lori ibusun rẹ. Ṣugbọn nigba ti ọkunrin naa ko sinmi lati maa beere, nikẹyin aladugbo rẹ wa fun un ki oun ba le dakẹ jẹẹ.

Inu bi aladugbo rẹ, kọ si fẹ ki a di oun lọwọ, ṣugbọn o dahun ibeere ẹni ti o n fẹ akara yii. Jesu ki i binu, Oun si n fẹ fi ẹbun rere fun awọn ọmọ Rẹ. Oun ko ha ni fẹ lati da wa lohun ju aladugbo ni lọ, bi o tilẹ jẹ pe Oun yoo mu ki a duro fun igba diẹ? “O yẹ ki a mã gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣãrẹ” (Luku 18:1).

Agbara Nipa Adura

Agbara lati sin Ọlọrun gẹgẹ bi O ti n fẹ ki a ṣe, a maa wá nipasẹ adura. Iṣẹ ti a n ṣe fun Ọlọrun ki yoo so eso afi bi a ba gbadura tọkantọkan fun Ẹmi Ọlọrun lati bukun un fun ogo Rẹ. Jesu wi pe: “Ẹmí ni isọni di ãye: ara kọ ni ẹre kan; ọrọ wọnni ti mo sọ fun nyin, ẹmi ni, iye si ni” (Johannu 6:53). O tun sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe lẹyin ti Oun ba lọ Oun o rán Olutunu, wọn o si gba agbara nigba ti Ẹmi Mimọ bá bà le wọn, “ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalẹmu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8).

Ẹmi Ọlọrun ni o n dá ẹṣẹ lẹbi ninu ọkàn ọkunrin ati obinrin, eto Ọlọrun si ni pe ki awọn ọmọ Rẹ ni Ẹmi yii ninu wọn pọ to bẹẹ ti ẹlẹṣẹ yoo fi moye bẹẹ ti yoo si yipada kuro ninu iwa buburu rẹ si Kristi.

Ọpọlọpọ awọn ẹlẹṣẹ ni wọn n rekọja lọ si ayeraye lai ni Ọlọrun. Awa ha n sa ipá ti wa lati ràn wón lọwọ? Awa ha ni Ẹmi Mimọ ninu ọkàn wa to bẹẹ ti wọn o fi ni idalẹbi ọkan fun ẹṣẹ wọn nigba ti wọn ba wa niwaju wa? Ẹmi Mimọ ha n sọrọ lati ẹnu wa sinu ọkàn awọn alaigbagbọ? Njẹ iwọ ko ri idi rẹ ti a fi ni lati ké pé, “Oluwa wa ọwón, kó wa bi a ti i gbadura?”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni awọn ọmọ-ẹyin beere lọwọ Jesu ninu ẹkọ yii?
  2. Iru ipo wo ni a wà si Ọlọrun?
  3. Ki ni a ni lati gbadura fun?
  4. Bawo ni a ṣe ni lati gbadura to?
  5. Ki ni a gbọdọ ṣe bi a ko ba ri idahun adura wa gbà lẹsẹkẹsẹ?
  6. Agbara wo ni Jesu fun wa nipasẹ adura?
  7. Kó adura Oluwa sori (Matteu 6:9-13).