Johannu 9:1-41; 10:19-21

Lesson 134 - Junior

Memory Verse
“On sá ti là mi loju” (Johannu 9:30).
Notes

Fun Ogo Ọlọrun

Jesu n lọ kaakiri, O si n ṣe rere. Oun ki i kuna lati ran awọn alaini lọwọ. Jesu ti fi Tẹmpili silẹ nitori awọn eniyan kọ fẹ ẹkó Rẹ, wọn si gbe okuta lati sọ lu U (Johannu 8:59). Bi Jesu ti n rin kọja laaarin ọpọ eniyan wọnyii, O ri ọkunrin kan ti o n fẹ iranlọwọ. Awọn ọmọ-ẹyin Jesu pẹlu, ri ọkunrin afọju yii. Ọkàn wọn kọ kaanu fun ọkunrin yii gẹgẹ bi Jesu ti kaanu fun un. Awọn ọmọ-ẹyin dá ọkunrin yii lẹbi, wọn si ro pe iyà ẹṣẹ rẹ ni o n jẹ. Wọn beere lọwọ Jesu ẹni ti o dẹṣẹ, ọkunrin yii ni, tabi awọn obi rẹ?

Ọpọlọpọ igba ni ẹṣẹ awọn obi maa n mu ijiya wá sori awọn ọmọ wọn, o si maa n jẹ ki a dù wọn ni awọn ohun ti o dara. Bi o ba tilẹ jẹ bẹẹ, ki i ṣe igba gbogbo ni aisan maa n wá nitori ẹṣẹ. Awọn ẹlẹṣẹ miiran wà ti wọn ki saba ṣaisan, nigba ti o jẹ pe awọn eniyan Ọlọrun miiran si maa n ṣaisan nigba pupọ. “Ọpọlọpọ ni ipọnju olododo; ṣugbọn OLUWA gbà a ninu wọn gbogbo” (Orin Dafidi 34:19). Nipa ti ọkunrin afọju yii, ipọnju rẹ le jẹ fun ogo Ọlọrun . A fi oówo pón Jobu loju kikankikan, sibẹ ki i ṣe ẹṣẹ ni o fa a, nitori Oluwa wi pe o jẹ “olõtọ ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹru Ọlọrun” (Jobu 2:3). Nigba ti a sọ fun Jesu pe ara Lasaru kọ dá, O wi pe, “Aisan yi ki iṣe si ikú, ṣugbọn fun ogo Ọlọrun, ki a le yin Ọmọ Ọlọrun logo nipasẹ rẹ” (Johannu 11:4).

Imọlẹ Ayé

Jesu wá lati ṣe ifẹ Ọlọrun, ati lati pari iṣẹ ti a ti pinnu fun Un (Johannu 4:34). Nigba ti Jesu wà ni ọmọ ọdun mejila pere, O wi pe Oun kọ le ṣaima wà nibi iṣẹ Baba Oun (Luku 2:49). Lẹyin naa, nigba ti O jade lọ waasu, Jesu wi pe, “Emi kọ le ṣaima wasu ijọba Ọlọrun. . . . . nitorina li a sá ṣe rán mi” (Luku 4:43). Jesu fun wa ni apẹẹrẹ nipa igbesi-aye Rẹ ati nipa iwaasu Rẹ. Nigba ti O wi pe, “Emi ni imọlẹ aiye,” (Johannu 8:12) ohun ti Jesu n sọ ni pe Oun yoo kó awọn eniyan ni ohun ti ẹmi -- ọna iye ati ọna si iye. Igbesi-aye Jesu ati ọrọ Rẹ ni Amọna wa. “Ọrọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ mi, ati imọlẹ si ipa ọna mi” (Orin Dafidi 119:105). Njẹ iwọ ha n tẹle Amọna naa?

Nigba Ti I ṣe Ọsan

Akoko Jesu ninu ayé kuru. O maa n lọ gbogbo anfaani ti o bá ti ṣi silẹ lati fi ṣe iṣẹ Oluwa ati lati tan Ihinrere kalẹ. Igba kan maa n wà ni igbesi-ayé eniyan nigba ti Ọlọrun maa n fi opin si iṣé ẹni naa Oni ni akoko lati ṣiṣẹ fun Oluwa. “Kiyesi i, nisisiyi ni akokọ itẹwọgbà; kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala” (2 Kọrinti 6:2). Oru n bọ nigba ti ẹni kan ki yoo le ṣiṣẹ mó. Akoko yii yoo de ni igbesi-aye rẹ. Bawo ni o ṣe n lo akoko rẹ? “Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tọbẹẹ niwaju enia, ki nwọn ki o le mã ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yin Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo” (Matteu 5:16).

Ifọju

Ọrọ nikan kó ni Jesu sọ; O tẹ siwaju lati fi ogo fun Ọlọrun nipa iṣẹ Rẹ. Oun i ba ti sọ fun afọju naa pe, “Oju, iwọ là”; oju rẹ i ba si ti là. Jesu ní ọna miiran lakoko yii. O fi amọ si oju ọkunrin afọju yii. A le rọ pe, lati fi amọ si oju rẹ yoo fó ọ loju si i ju pe ki o la oju rẹ lọ. Jesu maa n ṣe nnkan ni ọna miiran yatọ si eyi ti a ro pe Oun yoo ṣe. Nigba naa ni Jesu paṣẹ fun ọkunrin afọju naa lati lọ si adagun Siloamu, ki o si wẹ.

Igbọran

Ẹkọ yii fi han wa ohun ti o maa n ṣẹlẹ nigba ti eniyan ba gbọran si Jesu lẹnu. Ohun idiwọ pupọ ni o wà ni ọna ọkunrin afọju yii, ṣugbọn o gbọran. Kọ beere ọna ti oun yoo gba de adagun naa, tabi ibi ti o wà, tabi eredi ti oun yoo fi lọ wẹ nibẹ. O gbọran si Jesu, o “si de, o nriran” Fun igba kin-in-ni ni igbesi-aye rẹ o ri imọlẹ oorun. Agbara Oluwa ti fun un ni iriran. Ki i ṣe amọ ni o mu un iriran, bẹẹ ni ki i ṣe omi inu adagun Siloamu, ṣugbọn igbọran rẹ ni. Eyi ni iṣẹ Ọlọrun. Ọpọlọpọ afọju ni o wà, ọpọ amọ ni o wà a si sọ fun ni pe Adagun Siloamu wà sibẹ. Bi a ti mọ mọ, kọ tun si ẹlomiran ti o riran ni ọna bayii. Eyi jẹ iṣẹ-iyanu Jesu.

Afọju nipa ti Ẹmi

Ọpọlọpọ eniyan ni oju wọn fọ si ohun ti ẹmi. Wọn kọ ti i ri ẹwà Ọlọrun ri lati igbà ti a ti bi wọn, nitori oju ẹmi wọn ti fó. Oju wọn kọ fọ nipa jamba mọto tabi aisan: a bi wọn ni afọju ni. Gẹgẹ bi ẹdá, oju eniyan fó si ohun ti i ṣe ti ẹmi. “Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun” (Romu 3:23).

Boya ọkunrin afọju yii ti gbiyanju ọnà miiran lati ri iwosan, ṣugbọn kọ si eyi ti o bó si i. Ireti kan ṣoṣo fun gbogbo eniyan wà ninu Jesu. O wá “lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu ọkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹṣẹ” (Iṣe Awọn Apọsteli 26:18; Luku 4:7-21). Eniyan le gbiyanju ọnà miiran lati le riran nipa ti ẹmi, ṣugbọn ki o má ṣe e ṣe. “Wẹ mi, emi o si fún jù ẹgbọn-owu lọ” (Orin Dafidi 51:7). Ẹniti o fẹ wa, ti o si wẹ wa ninu ẹjẹ rẹ kuro ninu ẹṣẹ wa, . . . . . tirẹ li ogo ati ijọba lai ati lailai” (Ifihan 1:5, 6). Njẹ Ẹjẹ Jesu ti wẹ ẹṣẹ rẹ nù bi? Njẹ o ti jẹ ki Jesu ṣí oju rẹ si ohun ti ẹmi?

Nibi Agbelebu ni mo kọ ri ’mọlẹ

Nibẹ, ẹru ọkàn mi si fo lọ,

Nibẹ, nipa igbagbọ, mo riran

Nisi, mo wa l’alafia titi!”

Wo ohun iyanu nla ti o maa n ṣẹlẹ nigba ti oju ẹmi ẹni kan bá là! Iyipada ẹlẹṣẹ ti a fi oore-ọfẹ gbala jẹ ohun ti o daju gẹgẹ bi iyipada ti o ṣẹlẹ lara ọkunrin afọju yii. Eniyan maa n ri awọn ẹdá Ọlọrun ati iṣẹ ọwọ Rẹ ni ọtun. Igbesi-aye ti o n gbe a si yi pada. O ti riran, o si bọ si igbesi-aye kikún. Idalẹbi ati itiju ti o wa ni igbesi-aye rẹ atijọ ti rekọja lọ. O mó, o si lagbara nipa agbara Jesu. Iriri rẹ daju gẹgẹ bi ti ọkunrin afọju ni. Oun pẹlu, le wi pe, “Ohun kan ni mo mọ, pe mo ti fọju ri, mo riran nisisiyi” (Johannu 9:25).

Aigbagbọ

Awọn aladugbo ati awọn Farisi mọ pe iyipada de si igbesi-aye ọkunrin afọju yii. Ninu ọfintoto wọn, wọn beere bawo ati nibo ni o ti riran. Lẹyin ti wọn ti gbó bi o ti jẹ gan an, wọn kọ gbagbó, ṣugbọn wọn gbiyanju lati sé iṣẹ-iyanu naa. Awọn obi rẹ ṣọra pupọ ki a ma ba le wọn kuro ninu sinagọgu-ile isin wọn. Jesu ti gbà wọn lọwọ ibanujẹ, iwuwo ọkàn, ati wahala ti ifọju ọmọ wọn mú ba wọn. Sibẹ, ẹrù ba wọn, wọn si kuna ojuṣe wọn lati fi ọpẹ fun Jesu. Olukuluku eniyan ni o le wà yala fun Jesu tabi lodi si I (Luku 11:23). Kọ si ilẹ àdádó. “Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọrọ mi, . . . . . on na pẹlu li Ọmọ-enia yio tiju rẹ, nigbati o ba de ninu ogo Baba rẹ” (Marku 8:38).

Igbagbọ ati Ijọsin

Ọkunrin ti a wosan yii sọ ẹri ati ijẹwọ rẹ nipa Jesu: “Ibaṣepe ọkunrin yi ko ti ọdọ Ọlọrun wá, ki ba ti le ṣe ohunkohun” (Johannu 9:33). Awọn eniyan gbiyanju lati yi i lọkàn pada, wọn si n fi ye e pe iwosan naa ti ọna miiran wá. Ọkunrin yii mọ pe Jesu ti wọ oun sàn, ko si jẹ fara mọ ijiyan wọn. Awọn Farisi kọ fẹ fi eti si ẹri rẹ; dipo eyi wọn ti i jade kuro ninu ile isin wọn.

Jesu maa n duro ti awọn ẹlẹri Rẹ. O tọ ọkunrin yii lọ, o si fi ara Rẹ hàn án bi Ọmọ Ọlọrun, ọkunrin naa si sin In pe, “Oluwa, mo gbagbó.”

Alabukun-fun tabi Ẹni Ti A Dá Lẹbi

Ẹkọ yii fi hàn wa bi iṣesi awọn eniyan si Jesu ti yatọ si ara wọn. Ọkunrin yii kọ le ri Jesu. O mọ ipo rẹ, o si n fẹ ki Jesu mú okunkun kuro ki oun ba le riran. O gbọran, a si mu un lara dá.

Awọn Farisi le ri Jesu, sibẹ oju wọn fó si ipo ti wón wà. Lẹyin ti wọn ti ri iṣẹ-iyanu naa paapaa, wọn kọ gbagbó. Lai si aniani, wọn “fẹ ọkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru.” (Johannu 3:19). Jesu bá wọn wi, O si wi pe ẹṣẹ wọn wà sibẹ. Ni ọjọ naa, ọpọlọpọ kọ lati gba Jesu gbó, a si dá wọn lẹbi. Ọkunrin kan ri ibukun gbà nitori o gbàgbó. Ninu awọn oriṣi eniyan meji wọnyii, ewo ni iwọ fé jé?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni o ti pẹ tó ti ọkunrin yii ti jé afọju?
  2. Bawo ni o ṣe ri iriran gbà?
  3. Ki ni ẹri rẹ?
  4. Iha wo ni awọn obi rẹ kọ si iṣẹ-iyanu yii?
  5. Ki ni awọn Farisi ṣe si ọkunrin naa?
  6. Ki ni ṣe ti wón ti i jade kuro ninu sinagọgu?
  7. Iṣẹ wo ni Jesu wá ṣe?
  8. Ki ni ṣe ti a kọ la awọn eniyan wọnyii ni oju ẹmi?