Orin Dafidi 17:1-15

Lesson 135 - Junior

Memory Verse
“Ni igba ipọnju on o pa mi mó ninu agọ rẹ” (Orin Dafidi 27:5).
Notes

Owu Saulu

A ti fi ororo yàn Dafidi lati jẹ ọba Israẹli ni igba ti o ṣi jẹ ọdọmọkunrin ti o kere pupọ: ṣugbọn Ọlọrun ko gbà a laye lati gba ijọba titi di nnkan bi ọdun meje lẹyin naa. Saulu ni o ṣi n jọba ni akoko naa; ṣugbọn bi o tilẹ jẹ pe nigba kan ri o ti jẹ onirẹlẹ iranṣẹ Ọlọrun, o ti sọ ifẹ Ọlọrun nù kuro ninu ọkàn rẹ, o ti wa di eniyan buburu rekọja bayii. O jowu Dafidi nitori iwa rere Dafidi, o fẹ lati pa a.

Dafidi ti fi han pe oun jẹ akọni jagunjagun, Saulu si ti fi i jẹ olori awọn ọmọ-ogun rẹ, o si ti sọ fun un pe ki o maa gbe ninu aafin ọba. Ni ọjọ kan nigba ti Dafidi n bọ lati ibi ti o ti ṣẹgun awọn Filistini, awọn eniyan jade lọ lati pade Saulu, wọn si kọrin pe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun tirẹ,” ogunlọgọ awọn agberin si dahun pe Dafidi si pa ẹgbẹgbarun tirẹ.” Eyi bí Saulu ninu gidigidi lati ri pe awọn eniyan ti ri i pe Dafidi gba iyin pupọ ju oun lọ, o si tun gbiyanju lati pa a.

Jonatani, ọmọ ọba, jẹ ọkan ninu awọn ọrẹ pupọ ti Dafidi ni. O fẹran Dafidi to bẹẹ ti o fi yọọda lati jẹ ki o jọba ni ipo oun. Oun kọ jowu, ṣugbọn o ṣe gbogbo nnkan ti o le ṣe lati ran ọrẹ rẹ lọwọ; o si ṣeleri lati fẹran rẹ titi de oju iku.

Ẹgbẹ Ogun Dafidi

Nigba ti Dafidi fi aafin ọba silẹ ọpọ ninu awọn ọmọ-ogun ni wọn ba a lọ. Wọn fẹ lati doju ija kọ ọba Saulu wọn si fẹ ki Dafidi gbe ijọba ti rẹ kalẹ lẹsẹkẹsẹ, ṣugbọn nigba gbogbo ni Dafidi n duro de Oluwa ti o si n wi fun Un pe ki O tó iṣisẹ oun. Saulu tilẹ kó ogun rẹ jade lati kọju ija si ogun ti Dafidi, ṣugbọn Ọlọrun ko jẹ ki o bori. Ni akoko kan Dafidi i ba pa Saulu; o sun mọ tosi to bẹẹ ti o fi gé iṣẹti aṣọ rẹ kuro. Ṣugbọn Dafidi rọ pe bi o tilẹ jẹ pe nisisiyii Saulu ti di ẹlẹṣẹ, Ọlọrun ni O ti fi ororo yan an ṣe ọba, oun o si duro titi Ọlọrun yoo fi mu un kuro ki oun to gba ijọba.

Ogun Oluwa

Ninu gbogbo ọdun ti Saulu fi doju ija kọ Dafidi, Dafidi gbadura si Ọlọrun fun iranwọ. Nitori bẹẹ ni Ọlọrun ko fi jẹ ki Saulu bori. Lai ṣe aniani Dafidi ti kà nipa awọn ogun awọn Ọmọ Israẹli ti Ọlọrun ti ṣé fun wọn, o si mọ pe Ọlọrun yoo ṣe bakan naa fun oun. Nigba ti o tilẹ jẹ ọdọmọde darandaran lasan, pẹlu kiki okuta ati kànnakannà lọwọ rẹ, ẹru ko ba a lati bá omiran naa jà. O ti mọ Ọlọrun nigba naa, bi o si ti n jade lọ lati pade Goliati, o wi pe “Gbogbo ijọ enia yio si mọ daju pe, OLUWA kọ fi ida on ọkọ gbà ni la: nitoripe ogun na ti OLUWA ni, yio si fi ọ le wa lọwọ” (1 Samuẹli 17:47).

Lati ọjọ naa wa Dafidi ko jẹ gbagbe lati gbadura. Ko ṣe aika Ọlọrun si ki o si gbẹkẹle pe nitori a ti ran oun lọwọ nigba kan, a o tun ran oun lọwọ lai beere. Ninu ọkan ninu awọn adura rẹ o wi pe, “Li alẹ, li owurọ, ati li ọsan, li emi o ma gbadura, ti emi o si ma kigbe kikan: on o si gbohùn mi” (Orin Dafidi 55:17). O sọ nipa ohun ti awọn eniyan buburu n ṣe; ṣugbọn, o wi pe, Bi o ṣe ti emi ni, emi o kepẹ Ọlọrun; OLUWA yio si gbà mi” (Orin Dafidi 55:16).

Bawo ni inu wa yoo ti dun to bi a ba le gbẹkẹle Ọlọrun lati ràn wa lọwọ nigba gbogbo! Nigba ti iṣoro ba de a ni lati sọ fun Ọlọrun ki a si bẹ Ẹ pe ki O ràn wa lọwọ. Kaka bẹẹ ọpọ a maa sọ fun awọn ọrẹ wọn, wọn tilẹ le maa kùn nipa pe nnkan há fun wọn. Jesu fẹ ki a ko gbogbo aniyan wa le Oun, “nitoripe on ṣe aniyan” fun wa. Yoo tù wa ninu, ninu ibanujẹ wa, yoo si ran wa lọwọ lati ri ire fáyọ ninu rẹ. Nigba ti a ba n yọ O n fẹ ba wa yọ pẹlu. Bi a ti n yin In fun ibukun ti O ti fi fun wa, Oun yoo tun fun wa ni eyi ti o ju bẹẹ lọ.

Jesu ti gbe aye ri gẹgẹ bi eniyan O si mọ ayọ ati ibanujẹ wa, irora ati laalaa wa. O fẹ ki a rin sun mọ Oun. Nigba naa Oun yoo tẹti silẹ gbọ ohun ti a o wi. “Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọrọ mi ba si ngbé inu nyin, ẹ ó bẹre ohunkohun ti ẹ ba fẹ, a o si ṣe e fun nyin” (Johannu 15:7). “Ati nisisiyi, ẹnyin ọmọ mi, ẹ mã gbe inu rẹ; pe, nigbati o ba farahàn, ki a le ni igboya niwaju rẹ, ki oju má si ti wa niwaju rẹ ni igba wiwá rẹ” (1 Johannu 2:28).

Ete Aiṣẹtan

Ni ibẹrẹ adura ti a n yẹwo lonii, Dafidi fi hàn wa pe oun mọ pe Ọlọrun le ri ọkàn oun ati pe kọ ṣe e ṣe fun oun lati dibọn. O wi pe adura oun kọ ti “ẹte ẹtan” jade. Eyi ni pe oun ko fi ẹte oun sọ nnkan kan, nigba ti ọkàn oun n sọ nnkan miiran.

Jesu bá awọn akọwe ati awọn Farisi wí fun adura gigun wọn nigba ti wọn ba duro ni ọja nibi ti awọn eniyan ti le gbọ bi wọn ti n gbadura. O wi pe fun agabagebe ni wọn ṣe n gba adura gigun, wọn n fi han pe awọn n sin Ọlọrun nigba ti ọkàn wọn kun fun ẹṣẹ. Jesu le wo inu ọkàn wọn ki O si ri i pe adura wọnni ko ti inu ọkan wá rara. N ṣe ni wọn n ka adura wọn dipo ki wọn gbà a lati inu ọkàn.

Bi Jesu ba tilẹ le wo inu ọkàn wa ki O si ri ohun ti a n fẹ, bi O si ti mọ ohun ti a n fẹ, sibẹ O fẹ ki a beere lọwọ Oun. A kà pe, “Ẹ ko ni, nitoriti ẹnyin kọ bẹre” (Jakọbu 4:2). Paulu Apọsteli kọwe si awọn ara Filippi pe, “Ẹ máṣe aniyan ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ mã fi ibere nyin hàn fun Ọlọrun” (Filippi 4:6). Ṣugbọn adura wa ni lati ti inu ẹte ailẹtan wá ki o si jẹ gẹgẹ bi ifẹ Rẹ bi a ba n reti lati ri idahun gbà. A tun ka lati Jakọbu pe, “Ẹnyin bẹre, ẹ kọ si ri gbà, nitoriti ẹnyin ṣì i bẹre, ki ẹnyin ki o le lọ o fun ifẹkufẹ ara nyin” (Jakọbu 4:3).

A Ti Ọwọ Ọlọrun Danwo

Ẹru ko bà Dafidi lati jẹ ki Ọlọrun dan aya oun wọ lati ri I tikara Rẹ pe ohun ti Dafidi sọ jẹ ododo. O ni agbara lati wà lai dẹṣẹ; nitori pe ọkàn rẹ mó, o mọ pe Ọlọrun yoo dá oun lohun. O wi pe, “Iwọ ti wadi mi, iwọ kọ ri nkan” – ko si nnkan buburu, ko si ẹtan ti a fi bọ nibẹ, ko si igberaga ti a fi pamọ. Ayọ ti a maa n ni ninu ọkàn wa ti pọ to nigba ti a ba le fi ẹri-ọkàn gaara gbadura, ti a mọ pe ko si alebu kankan ninu igbesi-aye wa fun Jesu lati rí! “Bi ọkàn wa kọ ba dá wa lẹbi, njẹ awa ni igboiya niwaju Ọlọrun. Ati ohunkohun ti awa ba bẹre, awa nri gbà lọdọ rẹ, nitoriti awa npa ofin rẹ mó, awa si nṣe nkan wọnni ti o dara loju rẹ” (1 Johannu 3:21, 22).

Dafidi ti pa ara rẹ mó kuro lọdọ awọn eniyan buburu. Ko ba awọn ẹlẹṣẹ gbọjẹgẹ. O yan awọn eniyan ti o fẹran Ọlọrun ṣe ọrẹ rẹ. Awọn ọmọ ogun wọnni ti wọn ti wá dara pọ mọ ọn lẹyin ti o fi aafin Ọba Saulu silẹ fẹ ri pe ẹtó ni o bori. Awọn naa fẹran Ọlọrun ti Dafidi n sìn.

Labẹ Iyẹ-apa Rẹ

Ọlọrun ti ṣeleri lati tọju awọn ọmọ Rẹ daradara. O wi fun awọn Ọmọ Israẹli ni akoko kan bayii: “Ẹnyin ti ri ohun ti mo ti ṣe si awọn ara Egipti, ati bi mo ti rù nyin li apa-iyé idì, ti mo si mú nyin tọ ara mi wá” (Ẹksodu 19:4). O le jẹ aworan yii gan an ni o wà ninu ọkàn Dafidi nigba ti o gbadura pe, “Ni igba ipọnju on o pa mi mó ninu agọ rẹ: ni ibi ikọkọ agọ rẹ ni yio pa mi mó” (Orin Dafidi 27:5).

Itunu naa ti larinrin to fun Onigbagbọ lati ni idaniloju wiwà lai lewu ni akoko wahala! Ki i ṣe nisisiyii nikan ni a o maa rin labẹ aabo ṣugbọn nigba nigba ti Ipọnju Nla ni ba de sori aye a o gbe awọn ayanfẹ eniyan Ọlọrun leke gbogbo iyọnu naa, wọn o si maa gbadun pẹlu Oluwa. Nipa akoko naa ni Isaiah sọtẹlẹ nigba ti o wi pe “Wá, enia mi, wọ inu iyẹwu rẹ lọ, si se ilẹkun rẹ mọ ara rẹ: fi ara rẹ pamọ bi ẹnipe ni iṣéju kan, titi ibinu na fi rekọja” (Isaiah 26:20).

Ẹgbẹ ogun Saulu jẹ eyi ti a wọ ni ihamọra daradara, a si bó awọn ọmọ ogun rẹ yó. Wọn ni ẹbi ni ile, ati awọn ọmọ ti wọn ni ohun gbogbo ti wọn n fẹ. Iba agbo kekere ni awọn ọkunrin Dafidi jẹ, ko si ni nnkan kan lati fi bó wọn. Wọn n sá pamó lori oke ati ninu ihọ. Ohun ti wọn ba ri ko ni ogun ni wọn si n jẹ. Nigba miiran wọn a lọ ba awọn abọriṣa jà, wọn a tọju ikogun ti wọn ba ri lati fi tọju ara wọn.

Dafidi ro pe bi kiniun ti n ṣe iwọra si ohun ọdẹ rẹ, bẹẹ ni awọn ogun Saulu yi oun kaakiri ti wọn si n gbaradi lati kọlu awọn eniyan oun. Ṣugbọn ni iha ti rẹ ni Ọlọrun wà, o si gbadura pe, “Dide, OLUWA, ṣaju rẹ, rẹ ẹ silẹ.” A mọ pe Ọlọrun gbọ adura rẹ, nitori Dafidi fẹ lati wù Oluwa.

Dafidi ko bikita fun ọrọ aye rara, tabi ọlá ti aye yii. Lẹyin ti o sọrọ nipa ọrọ awọn ọta rẹ, o wi pe, “Bi o ṣe ti emi ni emi o ma wo oju rẹ li ododo: àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba ji.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni o ti ṣẹlẹ ti Dafidi fi n bá Saulu jà?
  2. Ta ni Dafidi gbagbọ pe o ni ogun naa?
  3. Awọn ogun wo ni Dafidi kókó jà gẹgẹ bi ọdọmọkunrin?
  4. Bawo ni o ti ṣe ṣẹgun?
  5. Ki ni ifẹ Dafidi nigba ti o ba kú?