Deuteronomi 11:26-32; 27:11-26; 28:1-68

Lesson 136 - Junior

Memory Verse
“Ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sìn li oni” (Joṣua 24:15).
Notes

Pẹpẹ Iranti

Rire kọja ti awọn Ọmọ Israẹli yoo ré Odo Jordani kọja yoo fi opin si irin kiri wọn ni aginju fun ogoji ọdun. Wọn o wà ni Kenaani, nibi ti a ti kọ ile silẹ fun wọn, ati ọgba eleso ati ọgba ajara ti a ti gbin lati fi eso fun wọn.

Nigba ti wọn ba de Kenaani, awọn Ọmọ Israẹli ni lati tẹ pẹpẹ kan, lori Oke Ebali, pẹlu okuta ti a kọ gbé. Wọn o ru ẹbọ iyin ati imoore si Ọlọrun fun mimu ti O mu wọn wá si ilẹ rere yii. Pẹpẹ yii yoo wà fun iranti fun ifẹ Ọlọrun ni titọju ti O tọju wọn gẹgẹ bi baba rere ti i maa ṣe itọju awọn ọmọ rẹ. Lara ogiri ti o wa ni ẹgbẹ pẹpẹ yii ni a o kọ Ofin Mẹwaa si.

Nihin lori oke yii nibi ti igi ko si ni Ofin wọnyii yoo wà nibi ti olukuluku wọn le ri i, to bẹẹ ti ki yoo fi si ẹni kan ti yoo wi pe oun ko mọ ifẹ Ọlọrun. Boya awọn ọmọde yoo ri pẹpẹ ti a kọ yii lori oke ni okeere, ni ọjọ daradara kan lẹyin ti wọn ba jẹun ọsan tan wọn le gun Oke Ebali lati ka awọn nnkan ti a kọ si ẹgbẹ rẹ.

A ti paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati kọ Ofin sara ilẹkun ẹnu ọna wọn, ati opo ile wọn, ati sara idẹ ọwó ati ọja-iweri wọn; wọn si ni lati maa sọ nipa rẹ nigba ti wọn ba jokoo ninu ile wọn, ati nigba ti wọn ba n rin lọ ni ọna. Oun ni o gbọdọ ṣe ọrọ ikẹyin ni alẹ ati ọrọ kin-in-ni ni owurọ, nipa bayii wọn o mọ ifẹ Ọlọrun, wọn o si maa ṣe e nigba gbogbo.

Njẹ bi awọn obi ba jẹ alai bikita ti wọn ko si sọ fun awọn ọmọ wọn nipa Ofin Ọlọrun n kó? Njẹ bi awọn baba ati iya ko ba n gbadura pẹlu awọn ọmọ wọn ki wọn to lọ sùn, tabi nigba ti wọn ba ji ni owurọ n kọ? A o ha sọ pe ki i ṣe ẹjọ awọn ọmọ bi wọn ko ba mọ Ofin Ọlọrun? Bẹẹ kọ, nitori ni gbangba ni ori Oke Ebali, nibi ti olukuluku ni anfaani lati ri i ni Ofin naa wa fun olukuluku ẹni ti o le ka a. Wọn si le ka a jade gbọnmọgbọnmọ ki awọn ọmọde le gbó ki wọn si le mọ ohun ti Ọlọrun palaṣẹ. Ko si awawi fun ẹnikẹni fun aimọ ifẹ Ọlọrun.

Bibeli Amọna Wa

Ni akoko yii a ti kọ ifẹ Ọlọrun sinu Bibeli. Ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe ni o wa ninu Iwe Mimọ yii. A kọ ọ ni ọna ti o rọrun lati yé eniyan to bẹẹ ti ọpọlọpọ ninu rẹ le yé ọmọde. Ọpọlọpọ igba ni o jẹ ohun irọrun fun awọn ọmọde lati gbadura pẹlu igbagbọ ti o pọ ki wọn si ri idahun gbà si adura wọn ṣaaju awọn agba. Awọn ki i gbiyanju lati fi ọgbọn wọn ro ileri Ọlọrun wọ, ṣugbọn wọn a kan gba a gbó, wọn a si wi pe, “Ọlọrun, Iwọ ti wi pe Iwọ yoo ṣe e, mo si mó pe Iwọ yoo ṣe e.” Jesu fẹ igbagbọ bi ti ọmọ kekere, O si wi bayii nipa awọn ọmọde, “Irú wọn ni ijọba ọrun” (Matteu 19:14). “Bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin ki yio le wọle ijọba ọrun” (Matteu 18:3).

Bibeli pọ pupọ ni aye ni akoko yii ju iwekiwe lọ. Gbogbo wa ni a ni anfaani lati mọ ifẹ Ọlọrun. Bi awọn obi kọ ba n ka Bibeli fun awọn ọmọ wọn, wọn o jiyin fun Ọlọrun idi rẹ ti wọn kọ fi ṣe bẹẹ, yoo si binu si wọn lọpọlọpọ. Ṣugbọn awọn ọmọde le ka Bibeli tikara wọn, nigba ti wọn ba dagba to lati ṣe bẹẹ.

Awọn ọmọde miiran ti wọn ti gbe nibi ti iwe ṣoro lati ri ni wọn ti kọ bi a ti n kawe nipa kika Bibeli. Abrahamu Lincoln, ọkan ninu awọn olori ti o ga ju lọ ninu ijọba ilu Amẹrika, fi ina oju àarọ ka Bibeli. Lẹyin ti o tilẹ di olokiki eniyan ti o si ni iṣẹ pupọ lati ṣe, o fẹran lati maa fi awọn ọrọ inu Bibeli ṣe ọrọ sọ.

Iyatọ laaarin Rere ati Buburu

Oke kan wa ni tosi Oke Ebali, afonifoji tooro kan ti o si jin ni o là wọn laaarin, a si n pe oke keji yii ni Oke Gerisimu. A n pe awọn oke meji yii ni oke ibukun ati oke egun. Ọlọrun a maa fi ohun ti a le fi oju ri kọ awọn eniyan Rẹ ni ẹkó; O si n fẹ fi iyatọ nla ti o wà laaarin rere ati buburu, laaarin igbọran ati aigbọran hàn wọn. A ko le reti ibukun Ọlọrun bi a ba ṣe aigbọran si I ninu ohun kan. A ko le jẹ Onigbagbọ ti n dẹṣẹ. Yala ki a gbọran si aṣẹ Ọlọrun ki a si ṣe ohun ti O palaṣẹ fun wa, tabi ki a yàn lati ṣaigbọran ki a si jẹbi ijiya ayeraye. Ninu Episteli Jakọbu a kà pe: “Nitori ẹnikẹni ti o ba pa gbogbo ofin mó, ti o si rú ọkan, o jẹbi gbogbo rẹ” (Jakọbu 2:10).

Oke Ebali ni oke egun, ni ẹba rẹ ni awọn ẹya Reubẹni, Gadi, Aṣeri, Sebuluni, Dani ati Naftali pejọ si. Ni ori Oke Gerisimu, ni apa keji ọna tooro ni ni awọn ẹya Simeoni, Lefi, Juda, Issakari, Josẹfu ati Bẹnjamini, ri àyẹ lati tẹti si ọrọ ti awọn ọmọ Lefi ni lati sọ. Olukuluku ni anfaani lati gbó ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn ti o ṣe aigbọran si Ọlọrun ati ibukun ti a o dà lu awọn ti o ba gbọran.

Idanwo Ini Pupọ

Awọn Ọmọ Israẹli ti kọ ẹkọ laaarin ogoji ọdun ninu aginju nipa iyiriwo ati wahala nla, wọn si ti wo Ọlọrun fun iranwọ. Nisisiyii wọn n lọ si ilẹ ọrọ, pẹlu idanwo ti o tun tobi ju lọ, eyi ni gbigbagbe Ọlọrun. A o fun wọn ni ikilọ titun lati gbọran si “bayi li OLUWA wi.” Akọsilẹ ibukun ati egun pupọ ni a kà jade kikan ki wọn ba le gbó; “Amin” ti awọn eniyan naa si n fi dahun fi han pe awọn eniyan naa mọ ewu ti o wà ninu ṣiṣe aigbọran si ifẹ Ọlọrun.

Ofin kin-in-ni ni pe ki wọn fẹran Oluwa tayọ ohun gbogbo ti o kù; egun kin-in-ni ti o si jade wa si ori ẹni ti o ba sin ọlọrun miiran, iṣẹ ọwó eniyan.

Ọlọrun yoo ri i bi oun tilẹ sin ọlọrun ajeji ni ni ikọkọ. Ọlọrun ri gbogbo ẹṣẹ ikọkọ.

Egun keji wá sori awọn ọmọde ti o ṣaigbọran si obi wọn. Aṣẹ Ọlọrun ni, “Bọwọ fun baba on iya rẹ: ki ọjó rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ” (Ẹksodu 20:12).

A ṣe akiyesi pe fun ibukun kọọkan ti a sọ ninu Deuteronomi ori kejidinlọgbọn fun igbọran, ni egun wà ni idakeji fun aigbọran, “Ibukún ni fun ọ ni ilu, ibukún ni fun ọ li oko;” “Egún ni fun ọ ni ilu, egún ni fun ọ li oko.” Bi a ba gbọran si aṣẹ Ọlọrun ibukun Rẹ yoo maa ba wa lọ ni ibikibi ti a ba n lọ; ṣugbọn bi a ba ṣe aigbọran, a ki yoo le bọ lọwọ egun naa. Dafidi wi pe: “Bi emi ba gọke lọ si ọrun, iwọ wà nibẹ: bi emi ba si té ẹni mi ni ipọ okú, kiyesi i, iwọ wà nibẹ. Emi iba mu iyẹ-apa owurọ, ki emi si lọ joko niha opin okun; ani nibẹ na li ọwọ rẹ yio fà mi, ọwọ ọtún rẹ yio si dì mi mu” (Orin Dafidi 139:8-10).

Jijẹ Ori

Ere Ọlọrun fun igbọran ni pe awọn Ọmọ Israẹli yoo maa jẹ ori, awọn orilẹ-ẹde iyoku yoo si maa jẹ irù; ṣugbọn fun aigbọran, wọn o maa jẹ irù, awọn orilẹ-ẹde iyoku yoo maa jẹ ori. Nigba miiran ti awọn ọmọde ba fẹ ṣire, olukuluku wọn yoo wi pe, “Emi ni yoo ṣe e: tabi “Emi ni mo fẹ wa ni ipo kin-in-ni.” Ọla ti Ọlọrun n fẹ fun awọn ọmọ Rẹ ni aye ni eyi -- awọn ni yoo jẹ ipo kin-in-ni. Ṣugbọn bi wọn ba ṣe aigbọran si Ọlọrun, awọn orilẹ-ẹde iyoku yoo gba ọlá yii.

Ọlọrun n fẹ sọ awọn ọmọ Rẹ di ọlórọ, pẹlu, ki wọn ba le maa wín awọn orilẹ-ẹde miiran; ṣugbọn bi wọn ba ṣe aigbọran wọn o talaka to bẹẹ ti wọn o maa tọrọ. A o tilẹ ko awọn ọmọ wọn ni igbekun lọ, nikẹyin gbogbo rẹ, Israẹli yoo lọ si oko ẹrú.

Idajọ

Ọlọrun kilọ fun awọn Ọmọ Israẹli nipa idajọ buburu ti yoo wa sori wọn to bẹẹ ti eti eniyan yoo ma hó lati gbó wọn. Akoko naa yoo de ti awọn ọtá yoo dó ti awọn ilu olodi wọn, iyan naa yoo si le to bẹẹ ti wọn o fi maa jẹ awọn ọmọ wọn. Wọn ki yoo ni ifẹ fun ara wọn mó, ọkọ ati aya yoo maa ṣe onikupani fun ara wọn. Awọn arakunrin yoo kẹyin si ara wọn. Arun buburu ati ajakalẹ arun, ti wọn bẹru rẹ, yoo wá sori wọn, ọpọlọpọ wọn yoo si kú. Awọn eniyan diẹ ti o kù ni a o tuka si gbogbo aye, wọn ki yoo si jẹ orilẹ-ẹde mọ titi yoo fi di igba ikẹyin.

A ka gbogbo ofin wọnyii si eti awọn Ọmọ Israẹli nibi ti wọn ti lẹ gbó. Njẹ wọn gbọran si aṣẹ Ọlọrun ki wọn si gbadun gbogbo ibukun ti O n fẹ fun wọn? Rara o. Lai pẹ lẹyin iku Mose, wọn tun di ọrẹ pẹlu awọn keferi ti o dán wọn wọ lati tẹle awọn ọlọrun miiran. (Awọn Onidajọ 3:7).

Njẹ idajọ ti Ọlọrun ṣeleri ṣẹlẹ bẹẹ bi? Dajudaju o ṣẹlẹ. O buru to bẹẹ gẹẹ ti wọn fi n jẹ eniyan paapaa, nigba ti ogun dó ti Samaria (2 Awọn Ọba 6:28, 29), ati nigba ti ogun dó ti Jerusalẹmu ni aadọrin ọdun lẹyin ibi Jesu (70 A.D). Nigba ti Titu dide pẹlu awọn ọmọ-ogun rẹ si Jerusalẹmu ijiya naa buru jai gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Mose sọtẹlẹ. Ikoro ọkan ati ikorira pọ laaarin awọn eniyan naa to bẹẹ ti wọn fi n ji ounjẹ ti o kere ju lọ ti wọn ba le ri ji mọ ara wọn lọwọ. Bi ẹni kan ba ni ounjẹ diẹ, ko ni le sẹ é jinná ki ẹlomiran ma ba gboorun rẹ ki o si wa gbà a lọ. Awọn eniyan n jẹ bata wọn ati igbanú wọn ti a fi awọ ṣe. Ija ati asọ ti o wa ninu odi ilu buburu to eyi ti awọn ara Romu gbé ti wọn lode. Alakọsilẹ itan ti a n pẹ ni Josephus sọ fun wa pe eebu ti Hẹrọdu bú awọn Ju buru to bẹẹ ti o jẹ pe eniyan bi ẹranko paapaa ko jẹ pón wọn loju bẹẹ.

Ipilẹṣẹ Ipọnju

Ibẹrẹ ijiya lasan ni eyi jẹ fun awọn Ju. Lati igba naa ni wọn ti n rin kiri gbogbo aye ti wọn n wá ibujoko. A sọ pe o kere tan o to ọọdunrun ọkẹ (6,000,000) ni awọn ti o kú ninu ogun ajakaye ti o kọja. Iwa ikà ti o buru ju lọ ati ti ailaanu ni awọn orilẹ-ede ti o doju kọ wọn hu si wọn, a n pa awọn Ju run ni akopọ nlá nlà. Sibẹ “ipilẹṣẹ ipọnju” ni eyi jẹ. Ko ṣe e ṣe fun wa lati rọ bi ijiya ti o ju eyi lọ yoo tun ṣe de ni igba Ipọnju Nla, ṣugbọn eyi ni ohun ti Ọlọrun ṣeleri fun awọn orilẹ-ẹde (tabi ẹni kọọkan) ti o ba gbagbe Rẹ.

Lonii a ni anfaani lati jọwọ ọkàn wa fun Oluwa ni ifẹ ati ninu iṣẹ-isin iyọọda atọkanwa, a si ni ileri ere ọrọ ti o pọ nihin, ati iye-ainipẹkun ni Ọrun. “Kọ si ẹniti o fi ile, tabi aya, tabi ará, tabi, obi tabi ọmọ silẹ, nitori ijọba Ọlọrun, ti ki yio gba ilọpo pipọ si i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ iye ainipẹkun” (Luku 18:29, 30).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Darukọ oke meji ti o ṣe pataki ninu ẹkọ yii.
  2. Ki ni orukọ miiran ti a fi n pe wọn?
  3. Ki ni ẹkọ ojukoju ti wọn n kọ ni?
  4. Ki ni amọna wa si Ọrun?
  5. Darukọ diẹ ninu awọn ibukun ati egun naa.
  6. Nigba wo ni idajọ Ọlọrun bẹrẹ si ṣẹlẹ lori awọn Ọmọ Israẹli? Bawo ni?
  7. Ni ọna wo ni egun wọnni fi n ṣẹlẹ sibẹ?
  8. Nigba wo ni yoo jé akoko ijiya nla?