Deuteronomi 12:1-32; Johannu 4:19-24

Lesson 137 - Junior

Memory Verse
“Ẹmi li Ọlọrun: awọn ẹniti nsin i ko le ṣe alaisin i li ẹmi ati li otitọ” (Johannu 4:24).
Notes

Awọn Ibi Giga

Awọn oke ati ibi giga jẹ ohun pataki fun awọn ará igbaani. Ọpọ ilu ni a tẹdo si ori oke, ti a si mọ odi nla yi wọn ká, lati fi mú irẹwẹsi bá awọn ọtá ti o ba fẹ gbogun ti wọn.

Bi o ba ṣe pe a ti rin Ilẹ Kenaani wọ ki awọn Ọmọ Israẹli to gbà a, a o ti ri awọn ọgbà nlá nlá ti o lẹwa pupọ lori awọn ibi giga wọnyii. Njẹ iwọ mọ ohun ti a fi pamọ saarin awọn igi wọnni? Oriṣa ni. Oriṣiriṣi oriṣa! Awọn keferi wọnyii kọ sin Ọlọrun otitọ, bakan naa ni ki i ṣe ọlọrun eke kan ṣoṣo ni wọn n sin. Wọn ni awọn ọlọrun pupọ; ninu igbo oriṣa kọọkan ni a si le ri awọn oriṣa ti o yatọ si ara wọn. Awọn eniyan maa n rubọ si oriṣa wọnyii, awọn ọlọrun ti kọ le riran, ti wọn kọ le gbọran, ti wọn ko si le mọ nnkan kan ti awọn eniyan n ṣe.

Ọlọrun kọ fẹ ki a tàn awọn eniyan Rẹ jẹ lati rọ pe awọn ọlọrun igi ati okuta wọnyi ti o wa lori oke ni le dahun adura wọn. Wolii ni wi pe, “Lotitọ asan ni eyi ti o ti oke wá, ani ọpọlọpọ oke giga, lõtọ ninu OLUWA Ọlọrun wa ni igbala Israẹli wà” (Jeremiah 3:23). Awọn oke wọnyii kọ le ran awọn eniyan lọwọ nigba ti idajọ ba dé. A sọ fun ni pe awọn ẹlẹṣẹ yoo kigbe pe apata ati ọke lati wo lu wọn, nigba ti wọn ba duro niwaju Onidajọ gbogbo aye.

Wolii Nahumu sọ fun wa bi Ọlọrun ti tobi ju agbara awọn oke ni lọ: “Awọn oke nla mì nitori rẹ, ati awọn oke kékẹké di yiyó, ilẹ aiye si joná niwaju rẹ, ani aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ” (Nahumu 1:5).

Ilu Mimó Ni

Ọlọrun yoo gbé Ilu daradara ti Jerusalẹmu kalẹ gẹgẹ bi ibi ti awọn eniyan Rẹ yoo pejọ pọ lati jọsin. A o kó Tẹmpili kan sibẹ, eyi ti yoo dara ju gbogbo nnkan ti wọn ti kọ ṣaaju akoko naa. Apoti Majẹmu ti awọn ọmọ Lefi ti n rù lori ejika wọn ni irin-ajo wọn si Kenaani yoo wa ninu Ibi Mimó Ju lọ. Gbogbo awọn Ọmọ Israẹli yoo si lọ si Tẹmpili yii lati sin Ọlọrun.

Fun ogoji ọdun ti wọn wà ninu aginju ni Apoti Ẹri yii ti wà pẹlu wọn, wọn si n sin nibikibi ti a ba pa Agọ si. O ṣoro lati ṣe ofin ti o fẹsẹ mulẹ fun ọpọ eniyan bayii ti wọn kọ duro ni ibi kan. Ṣugbọn nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ba dé Kenaani, Ọlọrun yoo beere jù bẹẹ lọ lọwọ wọn.

Ẹran fun Ounjẹ

Ẹran jijẹ ṣọwọn ninu irinkiri wọn ni aginju, awọn Ọmọ Israẹli si n pa maluu ati agutan wọn fun ẹbọ nikan, ninu eyi ti wọn n jẹ ninu Agọ gẹgẹ bi apa kan iṣẹ-isin wọn. Awọn ọmọ kékẹké ti wọn dagba laaarin akoko ogoji ọdun yii kọ mọ igba miiran ti wọn jẹ ẹran. Ọlọrun sọ fun wọn pe ẹran yoo pọ pupọ ni Kenaani, bi ebi ẹran ba si n pa awọn Ọmọ Israẹli, àye wà fun wọn lati jẹ gbogbo eyi ti wọn ba fẹ gẹgẹ bi awa naa ti n jẹ ẹran ninu ounjẹ wa. Ṣugbọn, akọbi agbo ẹran wọn ati eyi ti a yà sọtọ fun irubọ si Oluwa ni wọn ni lati mú lọ si ile Ọlọrun ki wọn si fi ṣe irubọ nibẹ.

Iparun Igbo Oriṣa

Lẹyin gbogbo nnkan nlá nlà ti Ọlọrun ti ṣe fun awọn eniyan Rẹ, a le rọ pe wọn kọ tilẹ ni gbero ati sin eyikeyi ninu awọn oriṣa okuta ati igi wọnni, ṣugbọn Ọlọrun mọ pe wọn yoo ṣe bẹẹ. Nitori eyi ni O ṣe kilọ fun wọn leralera lati ṣọra ki wọn má tilẹ gbadun ọgbà nla wọnni nibi ti a fi awọn oriṣa wọnyii pamọ si. “Bayi li ẹnyin o fi wọn ṣe; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn, ẹ o si bi ọwọn wọn lulẹ, ẹ o si ke igbo oriṣa wọn lulẹ, ẹ o si fi iná jó gbogbo ere finfin wọn” (Deuteronomi 7:5). Ọlọrun tilẹ sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe wọn kọ gbọdọ gbin igi si tosi pẹpẹ Ọlọrun ti yoo jẹ ki o jọ pẹpẹ awọn keferi ni ọnakọna (Deuteronomi 16:21).

Isin Eṣu

Njẹ iwọ mọ ohun ti awọn eniyan yii n sin dipo Ọlọrun? Wọn n sin oorun, oṣupa, irawọ; wọn n fori balẹ niwaju ere Aṣtarotu, Baali, Dagoni ati Diana; wọn n bu ọlá fun ẹgbọrọ maluu wura; wọn si n sin ẹṣu paapaa. Ki i ṣe ẹran nikan ni wọn fi n rubọ si awọn ọlọrun ajeji wọnyii, ṣugbọn nigba miiran wọn maa n fi ọmọ wọn rubọ. Nitori awọn Ọmọ Israẹli ṣe afarawe awọn keferi, wọn si n ṣe awọn nnkan wọnyi, pẹlu, Ọlọrun mú ki a kọ ẹya mẹwaa ninu wọn lọ si igbekun si ilẹ Assiria (2 Awọn Ọba 17).

Lẹyin naa, a kó awọn ẹya Juda ati Benjamini lọ si igbekun, a si fi agbara mu wọn gbé ni Babiloni fun aadọrun (70) ọdun. A kọ gbọ pe wọn tun sin ọlọrun ajeji mó. Dipo eyi, wọn pada di olufọkansin, wọn si gbiyanju pupọ lati tẹle ọrọ Ofin ni kinnikinni. Ṣugbọn kọ si ifẹ lọkan pupọ ninu wọn, igbekalẹ ati ẹto isin wọn jẹ kiki ohun irira niwaju oluwa. Eyi gan an ni ipo ti Kenaani (tabi Palestini, gẹgẹ bi a ti n pe e lẹyin naa) wà nigba ti Jesu wà ni aye. O n ba awọn akọwe ati awọn Farisi wi leralera fun ọkàn buburu wọn, nigba ti wọn n fara hàn bi ẹni ti o n tẹle aṣẹ Ọlọrun. Wọn ṣọra gidigidi lati ri pe wọn sin ni Jerusalẹmu: wọn si rọ pe kọ si ẹni ti a o gbala ayafi ti o bá pada di Ju ti o si gbọran si aṣẹ awọn olukọni ti i ṣe awọn agbaagba Ju. Lọjọ kan, Jesu sọ fun wọn pe: “Ẹnyin nyi okun ati ilẹ ká lati sọ enia kan di alawọṣe; nigbati o ba si di bẹẹ tan, ẹnyin a sọ ọ di ọmọ ọrun apadi nigba meji ju ara nyin lọ” (Matteu 23:15). Alawọṣe ni ẹni ti a yipada lati inu ẹsin kan si omiran, nihin yii si ẹsin awọn Ju.

N Tọka Si Jesu

Isin Agó ati isin Tempili ni ipo ti wọn ninu eto Ọlọrun fun irapada, ṣugbọn nigba ti Jesu dé, O fi ilana titun lelẹ. Akoko fifi ẹran rubọ ti kọja. Irubọ wọnni tọka si Jesu, nisisiyii Jesu yoo ta Ẹjẹ Rẹ silẹ lẹẹkan ṣoṣo, ati pe nipa Ẹjẹ naa gbogbo ẹlẹṣẹ ti wọn n fé ri igbala ni a le wẹ ẹṣẹ wọn nù.

Ni ọjọ ti Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin Rẹ rin kọja laaarin Samaria, ti wọn si pade obinrin ni nibi kanga, O sọ fun un pe wakati naa ti dé nigba ti awọn olusin tootọ ki yoo lọ si Jerusalẹmu tabi ibi pataki kan mó, ṣugbọn bi o ba ni ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn rẹ, o le sìn ni ibikibi.

Oke Gerisimu

A ti kọ ẹkó nipa awọn oke ibukun ati oke egún, Oke Gerisimu yii ni a yàn gẹgẹ bi oke ibukun. Lori oke yii ni awọn ara Samaria kó Tẹmpili si lẹyin ọdun pupọ, nibẹ ni wọn si n sin gẹgẹ bi awọn Ju ti n sin ni Jerusalẹmu. Ara Samaria ni obinrin ti o wà nibi kanga yii, o si woye pe Wolii ni Jesu I ṣe. Nitori naa o bi I leere Tẹmpili ti o tọ lati jọsin. Njẹ awọn ti o lọ si Jerusalẹmu lati sin yoo jẹ olododo ju awọn ti o gun ori Oke Gerisimu lati sin ninu tẹmpili awọn ara Samaria?

Isin Tootọ

Jesu sọ fun un pe iyatọ wà ninu ijọsin wọn nitori a ti fi ọna igbala kikun le awọn Ju lọwọ. Ọlọrun ti pe Abrahamu lati ilẹ Uri wá O si ti ṣe ileri pe lati ipasẹ rẹ ni a o ti bukun fun gbogbo idile aye. Awọn Ju ni a fun ni isin Agọ, wọn si ti jẹ ayanfé Rẹ fun ọpọlọpọ ọgọrun ọdun. Awọn ti wọn ba fẹ ri igbala n wá sọdọ awọn Ju lati kó nipa Ọlọrun.

Ṣugbọn a ti mu iyatọ ti o wà laaarin awọn Ju ati awọn Keferi kuro. Ni akoko oore-ọfẹ ti Jesu mu wá yii, olukuluku eniyan ni o ni anfaani kan naa lati ri igbala. Ni ọjọ nlá ti o kẹyin ajọ Jesu wi pe: “Bi ọrùngbẹ ba ngbẹ ẹnikẹni, ki o tọ mi wá, ki o si mu” (Johannu 7:37). Ẹnikẹni ni o le wá, ki i ṣe Ju nikan.

Akoko isin Agó kọja. Kọ ṣe anfaani lati ṣe irubọ mó, nitori Jesu ti fi ara Rẹ rubọ gẹgẹ bi Ọdọ-agutan Ọlọrun. Igbekalẹ ati eto isin nikan kọ gba awọn eniyan là. Olusin tootọ gbọdọ maa sin Ọlọrun ni ẹmi ati ni otitọ nigbakuugba.

Lonii, ẹlẹṣẹ le wa sọdọ Ọlọrun pẹlu ironupiwada ninu ile rẹ, tabi ni ode gbangba, tabi bi o ti n rin lọ ni opopo ọna, ki o si ri idariji ẹṣẹ rẹ gbà nibẹ gẹgẹ bi o ti ṣe le ri i gbà ninu ile-isin. Ọkàn ni Jesu n wọ, nigba ti O bá si ri ironupiwada, ati ipinnu lati ṣe ohun ti o tó, Oun yoo dariji ẹlẹṣẹ naa, yoo si sọ ọ di Onigbagbọ. Ọpọlọpọ eniyan ni wọn ti kunlẹ lẹba ibusun wọn, ti wọn si ti ri igbala. A mọ nipa ọdọmọkunrin kan ti o gbadura ninu ile ijẹun titi Ọlọrun fi dariji i. Ọmọ-ogun kan ninu Ẹgbẹ ọmọ-ogun gbadura lẹba kukute igi kan ninu igbó, a si dari ẹṣẹ rẹ ji i. Wọn fi tọkantọkan gbadura si Ọlọrun, O si gbó adura wọn.

Bi o ba ṣe dandan lonii lati lọ si Jerusalẹmu lati lọ jọsin, ki i ṣe ọpọ wa ni i ba ṣe e ṣe fun lati di Onigbagbọ. Yoo ṣoro pupọ lati rin irin-ajo naa. Ṣugbọn Ọlọrun rán Olutunu sinu aye nigba ti Jesu pada lọ si Ọrun, Oun si n dari awọn eniyan nibi gbogbo si otitó. Jesu wi pe, “Nigbati on ba si de, yio fi ọye yé araiye niti ẹṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ” (Johannu 16:8). Oun yoo fi oye yé araye, ki i ṣe awọn Ju nikan. Nigba ti O bá fi hàn awọn eniyan pe ẹlẹṣẹ ni wọn, Oun yoo si tún kọ wọn bi wọn ṣe le ri igbala pẹlu.

Bi o tilẹ jẹ pe àyẹ wà fun wa lati sin Ọlọrun ni ibikibi, o gbọdọ dá wa loju pe a n sin In ninu ẹmi. Bi a ba gba ohunkohun ti o lodi si Ofin Ọlọrun láyẹ ninu ile-isin kan, a sọ fun wa pe, “Ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọtọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwó kàn ohun aimó; emi o si gbà nyin” (2 Kọrinti 6:17); Ọmọ Ọlọrun tootọ maa n fẹ idapọ pẹlu awọn eniyan mimó iyoku, oun yoo si ya ara rẹ kuro lọdọ awọn wọnni ti kọ gbe igbesi aye wọn lati fi wu Oluwa.

Kọ si ohun ti o dùn jù pe ki a sin Oluwa papọ ni iṣọkan igbagbó, nitori nibẹ ni Jesu tikara Rẹ yoo wá ba awọn eniyan ti Rẹ sọrọ. “Nitori nibiti ẹni meji tabi mẹta ba kó ara wọn jọ li orukọ mi, nibẹ li emi o wà li ãrin wọn” (Matteu 18:20).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni awọn Ọmọ Israẹli yoo ti maa sìn lẹyin ti wọn ba de Kenaaani?
  2. Nibo ni awọn keferi ti n sìn?
  3. Ki ni awọn Ọmọ Israẹli ni lati ṣe si ibi ti awọn keferi ti n jọsin?
  4. Nibo ni awọn ará Samaria ti n sìn ni igba aye Jesu?
  5. Nibo ni a ti gbó nipa oke yii nigba kan rí?
  6. Ki ohun ti obinrin ti o wà nibi kanga beere lọwọ Jesu?
  7. Ki ni idahun Rẹ?
  8. Bawo ni a ṣe ni lati sin Ọlọrun?