Lesson 138 - Junior
Memory Verse
“Ẹ dán awọn ẹmí wọ bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ ti jade lọ sinu aiye” (1 Johannu 4:1).Notes
Asọtẹlẹ
Wo o bi ọkàn awọn eniyan ṣe maa n tagiri pupọ to lọjọ oni nigba ti ẹni kan ba sọ asọtẹlẹ nipa iṣẹlẹ nla kan, ti o ba si ṣẹ! Yoo jẹ akọle pataki ninu awọn iwe iroyin jake-jado orilẹ-ede, awọn eniyan yoo si fi ọkàn si asọtẹlẹ rẹ titun nigba ti wọn ba kà bayii: “Ọkunrin ti o sọ asọtẹlẹ ogun ajakaye kin-in-ni ati ekeji ti o si ri bẹẹ, nisisiyii tun n sọtẹlẹ bayii pe . . . . . . .” Ṣugbọn bi eniyan tilẹ le sọ asọtẹlẹ nnkan ti o si ri bẹẹ, kọ sọ pe eniyan Ọlọrun ni iru ẹni bẹẹ i ṣe.
Awọn alasọtẹlẹ nigba miiran le sọ asọtẹlẹ nipa ọjọ iwaju ki eyi si ṣẹ perepere ṣugbọn pẹlu agbara Satani ni. Eṣu le ṣe iṣẹ iyanu, o tilẹ le mu nnkan rere wá fun awọn ti o ba gbà a gbọ, ki o ba tan wọn jẹ lati maa tẹle e. Ṣugbọn ikú ni ẹre ẹṣẹ, iya ainipẹkun si n duro de olukuluku ẹni ti o ba tẹle okunfa Satani.
Iṣina
Ani ninu ẹsin ti a ro pe o jẹ ti Kristi paapaa Satani yoo wọle yoo si tan awọn eniyan jẹ bi wọn kọ ba jẹ oloootọ. Bi a ba fẹran Oluwa pẹlu gbogbo ọkàn wa a ko ni bẹru pe a o mu wa ṣina; ṣugbọn bi o ba jẹ pe alafarawe ẹsin ni a n fẹ ti a ko si fẹ pa gbogbo Ọrọ Ọlọrun mó, o yẹ ki a kiyesara. Ọlọrun yoo rán ohun ti n ṣiṣẹ iṣina si awọn wọnni ti kọ fẹran otitọ, “ki nwọn ki o le gbà eke gbó: ki a le ṣe idajọ gbogbo awọn ti kọ gbà otitọ gbó, ṣugbọn ti nwọn ni inu didùn ninu aiṣododo” (2 Tẹssalonika 2:11, 12).
Alala
Awọn ẹlẹsin eke ti wà nigba ti awọn Ọmọ Israẹli n lọ si Ilẹ Ileri. Ọlọrun ti kilọ fun awọn eniyan Rẹ ki wọn má ṣe sin ere igi tabi okuta, eyi ti kọ le riran, ti kọ si le gbọran, bẹẹ ni kọ le ṣe ohun kankan fun wọn. Ninu ẹkọ oni a kọ nipa ewu titun: awọn wolii yoo wá, wọn o si sọ itan didun didun nipa awọn ọlọrun miiran, ohun ti wọn fi lala tabi ti wọn ri ninu iran. Ọlọrun sọ pe laaarin awọn eniyan naa ni awọn eniyan yoo ti maa la ala ti wọn o si maa riran eke, Oun o si dan awọn Ọmọ Israẹli wọ lati ri boya wọn o gbọran si aṣẹ Ọlọrun tabi wọn o gba itan asan ti wọn ba gbó, boya otitọ tabi irọ ni.
Boya ẹni kan le lá ala alarinrin eyi ti yoo mu eniyan gbero pe yoo dùn lati lọ yẹ igbó ti awọn keferi ti n sin awọn oriṣa wọn wọ. O tilẹ le ro pe Ọlọrun ni O ti rán ala naa, nitori Ọlọrun ti ṣe bẹẹ sọrọ fun awọn wolii ninu Majẹmu Laelae (Numeri 12:6). Ọna ti awọn Ọmọ Israẹli fi le mọ boya iṣẹ naa jẹ eke tabi otitọ ni lati fi diwọn ofin Ọlọrun. Ofin naa ni pe: “Iwọ kọ gbọdọ yá ere fun ara rẹ,. . . . . iwọ kọ gbọdọ tẹ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹẹni iwọ kọ gbọdọ sin wọn” (Ẹksodu 20:4, 5), nitori naa, dajudaju ẹnikẹni ti o ba fẹran Oluwa yoo mọ pe iru alá bayii kọ ti Ọrun wá.
Ala ati Iran Lode Oni
Ọpọ eniyan lonii ni wọn ni igbẹkẹle lile ninu alá ati iran. Wọn gbagbọ pe Ọlọrun n fun wọn ni itọni O si n sọtẹlẹ nipa ọjọ-iwaju wọn nipa alá. Lootọ nigba miiran Ọlọrun a maa tọ ni a si maa ki awọn eniyan Rẹ laya lọna bayii. Ṣugbọn alá tabi iran naa ni lati ṣe deedee pẹlu Ọrọ Ọlọrun bi bẹẹ kọ Oun kó ni O rán an. Ọlọrun kọ ni ṣe iṣipaya kankan ti yoo lodi si Ọrọ Rẹ.
Bibeli ni amọna wa ti o daju si Ọrun, o si ni gbogbo itọni ti o yẹ fun ni lati le mura silẹ lati pade Jesu. Ofin ati aṣẹ Ọlọrun fun awọn Ọmọ Israẹli pé, O si kilọ pe, “Iwọ kọ gbọdọ bukún u, bẹẹni iwọ kọ gbọdọ bù kuro ninu rẹ” (Deuteronomi 12:32). Johannu Ayanfẹ pẹlu gbọ Ohùn Jesu pe: “Bi ẹnikẹni ba fi kún wọn, Ọlọrun yio fi kún awọn iyọnu ti a kọ sinu iwe yi fun u. Bi ẹnikẹni ba si mu kuro ninu ọrọ iwe isọtẹlẹ yi, Ọlọrun yio si mu ipa tirẹ kuro ninu iwe iye, ati kuro ninu ilu mimó nì, ati kuro ninu awọn ohun ti a kọ sinu iwe yi” (Ifihan 22:18, 19). Eyi n sọ fun wa pe awọn ti o ti fi igba kan jẹ Onigbagbọ ri paapaa yoo gbiyanju lati yọ kuro ninu Ọrọ naa. Jesu wi pe orukọ iru ẹni bẹẹ ni a o yọ kuro ninu Iwe Iye; kọ si le si ninu rẹ bi ko ba ṣe pe o ti jé Onigbagbọ.
Wolii Eke
Ni akoko kan ninu itan igbesi-aye awọn Ọmọ Israẹli, ọba wọn, Jeroboamu, ti yá ẹgbọrọ maluu wura meji kan fun awọn eniyan naa lati maa sin. Ọlọrun sọ fun wolii ododo kan lati fi pẹpẹ Jeroboamu bú, wolii naa si gbọran. Ọrọ ti o sọtẹlẹ si ṣẹ. Inu bi ọba si ọrọ rẹ, o si na ọwọ rẹ jade lati di i mú, ṣugbọn Ọlọrun mu ki ọwọ Jeroboamu gan ti kọ fi le mu un pada. O ni ki wolii naa gbadura fun oun, Ọlọrun si dahun, O wo apa naa sàn. Ọba naa mọ oore to bẹẹ ti o fi rọ wolii naa lati wá si aafin rẹ ki oun ba le da a lọla. Ṣugbọn Ọlọrun ti sọ fun wolii naa pe gẹrẹ ti iṣẹ rẹ ba ti pari ni ki o pada sile, nipa ọna miiran, ki o má si ṣe duro lati jẹ tabi lati mu. Wolii naa gbọ ti Ọlọrun ju ti ọba lọ, o si bẹrẹ si lọ sile.
Ṣugbọn itara rẹ kọ duro pẹ. O fi ẹsẹ palẹ ni ọna; bi o si ti jokoo labẹ igi, wolii eke kan le e bá pẹlu ọrọ pe lati ọdọ angẹli kan ni oun ti wá, ẹni ti o wi pe ki a pe e lọ si ile wolii eke naa lati jẹun. Eyi yatọ si iṣẹ ti Ọlọrun ti rán tẹlẹ; ṣugbọn niwọn bi eniyan Ọlọrun naa ti ṣaigbọran nipa diduro lati sinmi labẹ igi oaku, iye rẹ ti ra si ati mọ ohun ti i ṣe eke, o si bá wolii eke naa pada. O ha mọ ki ni ṣẹlẹ si i? Ọrọ ti Ọlọrun rán si i ni yii: “Niwọn bi iwọ ti ṣe aigbọran si ẹnu OLUWA, ti iwọ kọ si pa aṣẹ na mọ ti OLUWA Ọlọrun rẹ pa fun ọ. . . . . okú rẹ ki yio wá sinu iboji awọn baba rẹ” (1 Awọn Ọba 13:21, 22). Lẹyin ti o tun bẹrẹ si i lọ si ile kiniun kan pade rẹ o si pa a. Eyi ni idajọ Ọlọrun lori ọkunrin afasẹyin yii ti o tẹti si wolii ẹké.
Gbogbo Ọrọ Ọlọrun Ṣe Pataki
Kọ si ohun kan ninu Ofin ti Ọmọ Israẹli kan le sọ nipa rẹ pe “Eyi kọ ṣe pataki. Mo ni lati sọra lati pa eyi ti o ṣe danindanin mó, ṣugbọn awọn kan ki i ṣe dandan.” Gbogbo ọrọ ti Ọlọrun sọ ni o ṣe pataki.
Nigba ti Ọlọrun sọ fun awọn Ọmọ Israẹli, ki wọn to jade ni Egipti, lati mu ọdọ-agutan ọlọdun kan, alailabuku, ki wọn pa a ki wọn si fi ẹjẹ rẹ sori ilẹkun wọn ati si ara awọn ọpó rẹ ki wọn ba le bó lọwọ iku, o ṣe danindanin fun wọn lati mu ọdọ-agutan ọlọdun kan, ti kọ ni abuku, ki wọn pa a ki wọn si fi ẹjẹ rẹ sori ilẹkun wọn ati si ara awọn ọpó rẹ. Ọlọrun wi pe, “Nigbati emi ba ri ẹjẹ na, emi o ré nyin kọja.” Oun yoo gba olukuluku ẹni ti o wà ninu ile naa là laaye. Ni ile awọn iyoku akọbi ọmọ yoo kú ni oru naa.
Ọdọ-agutan ni jẹ apẹẹrẹ Jesu, ti O ta Ẹjẹ Rẹ silẹ fun ẹlẹṣẹ. I ba ṣe pe ọdọ-agutan naa ni abawọn kan lara rẹ, ki ba ti jẹ apẹẹrẹ Jesu alailẹṣẹ ti O mó ti O si jẹ pipe. Bi awọn Ọmọ Israẹli ba ti fi ọdọ-agutan alailabawọn naa pamọ ninu ile wọn lai pa a, sibẹ ki ba ti jẹ apẹẹrẹ Jesu, nitori pe Jesu ta Ẹjẹ Rẹ silẹ. Bi wọn ba fi ẹjẹ ọdọ-agutan naa pamọ sinu awo ti wọn ko si fi i sara ilẹkun, ki ba ti ṣiṣẹ bi apẹẹrẹ Ẹjẹ Jesu eyi ti a ni lati fi wón ọkàn ẹni kọọkan wa ki o le ko ẹṣẹ wa lọ. Aṣẹ kọọkan ti Ọlọrun fi fun wọn fun pipa ati jijẹ Ọdọ-agutan irekọja ni o ṣe pataki, fifi eyi keyi ninu rẹ silẹ lai ṣe i ba mu iku wá sori ẹni kan ninu idile naa.
Bi ọkọọkan ninu aṣẹ Ọlọrun ti ṣe pataki to ni yii. Jesu wi pe, “A kọ le ṣe alaitún nyin bí.” Itumọ eyi ni pe a ni lati ronupiwada ẹṣẹ wa ki a si gbadura titi a o fi mọ pe a ti ri idariji gbà fun wọn. Ki a kan wi pe a gba Jesu gbọ ati pe a gbà A gẹgẹ bi Olugbala wa kọ tó. A ni lati mọ pe awọn ẹṣẹ wa atijọ ti rekọja lọ; nigba naa a o ni agbara lati maa lọ ki a ma si dẹṣẹ mó.
Isọdimimọ
Ọpọlọpọ ni wọn gbagbọ pe a ni lati tun eniyan bi, ṣugbọn pe isọdimimọ kọ ṣe danindanin. Ṣugbọn Bibeli wi pe, “Eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimó nyin” (1 Tẹssalonika 4:3). Jesu n fẹ ki gbogbo awọn ọmọ Rẹ jẹ ọkan; O n fẹ ki wọn gba ohun kan naa gbó. Isọdimimọ a maa wẹ ọkàn mó a si maa mu isọkan wá. Jesu gbadura fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe, “Baba mimó, pa awọn ti o ti fifun mi mó, li orukọ rẹ, ki nwọn ki o le jẹ ọkan, ani gẹgẹ bi awa. . . . . Nwọn ki iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi ki ti iṣe ti aiye. Sọ wọn di mimó ninu otitọ: otitọ li ọrọ rẹ” (Johannu 17:11, 16, 17). Eyi ki i ṣe fun awọn ọmọ-ẹyin Jesu nigba ti O wà ni aye nikan. O sọ siwaju pe, “Ki si iṣe kiki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yio gbà mi gbó nipa ọrọ wọn” (Johannu 17:20).
Paulu Apọsteli sọ fun ni pe, “Nitorina Jesu pẹlu, ki o le fi ẹjẹ ara rẹ sọ awọn enia di mimó, o jiya lẹhin bode” (Heberu 13:12). Jesu mú apẹẹrẹ ẹbọ ẹṣẹ ṣẹ, eyi ti a fi rubọ ninu Agọ ni aginju nigba ti a sun ara ẹbọ naa lẹyin ibudo Israẹli, ti a si mú ẹjẹ rẹ wa si inu Agọ (Ibi Mimọ) ti a si fi wón pẹpẹ wura.
Ẹmi, Olukọni Wa
Bawo ni a ṣe le mọ ẹni ti o tọna ati ohun ti o yẹ ki a gbagbọ? Nipa kika Bibeli; bi a ba si jẹ oloootọ, Ẹmi yoo kó wa. Bi eniyan ba fẹ gbọran si Ọlọrun ni tootọ ki o si lọ si Ọrun, oun yoo fẹ ki a mú gbogbo ileri ti o wà ninu Ọrọ ni ṣẹ ninu ọkàn rẹ. Nigba ti o ba kà ninu Bibeli pe; “Eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimó nyin ,” kọ ni wi pe kọ si nnkan kan ninu eyi ati pe kọ ṣe danindanin, ki o to gbiyanju lati ri i. Ẹni ti o ba n tako Ọrọ Ọlọrun ko ni pé ninu igbala. Ṣe bi ẹnikẹni ti o ba fẹ wu Olugbala i ba tilẹ gbiyanju lati ri pe a mú awọn ileri Ọlọrun ṣẹ ninu ọkàn rẹ ki o to maa wi pe wọn kọ le ṣẹ rara fun oun tabi ẹlomiran!
Ojo Arọkuro
Nigba ti Ojo Arọkuro kọkọ rọ, ni 1906, a fi Agbara Ẹmi Mimọ wọ awọn eniyan ti a ti sọ di mimọ, ti ọkan wọn si jẹ mimọ, ti wọn si wà ni ọkàn kan. Ṣugbọn awọn olukọ eke wa saarin wọn, kọ si pẹ ki awọn miiran to maa lọ kuro ninu igbagbọ.
Ẹni ti o dá ijọ Apostolic Faith silẹ di ẹkọ naa mu gẹgẹ bi o ti wà ninu Bibeli ati bi a ti waasu rẹ nigba ti Ojo Arọkuro kọkọ rọ, paapaa lẹyin ti aṣiwaju rẹ tẹlẹ pinnu pe isọdimimọ kọ ṣe danindanin. Oniwaasu kan sọ fun un pe yoo yipada si ọna iwaasu ti wọn, nitori gbogbo awọn iyoku ni wọn ti “gba bẹẹ.” O dahun pe, “Rara! Agbẹdọ! ki i ṣe ọran gbigba bẹẹ. Ọran jijẹ oloootọ si Ọrọ naa ni. Bi o ba ka ẹmi rẹ si, ti o ba si ka ẹmi awọn wọnni ti iwọ yoo ba pade si, iwọ yoo waasu gbogbo Ọrọ naa.” Ọlọrun yé iduro rẹ si fun iṣẹ oore-ọfẹ keji ninu ọkàn, isọdimimọ, ọkan funfun, ninu eyi ti iwa ti ara maa n parun ti a si n ṣe awọn eniyan Ọlọrun ni ọkan ṣoṣo. Lonii ẹgbẹ nla awọn eniyan wà ti a pin kaakiri gbogbo agbaye ti n sin Ọlọrun ninu ẹwa iwa-mimọ, ni iṣọkan igbagbọ ti n tipasẹ isọdimimọ wa. Wọn si ti gba ẹbun Ẹmi Mimọ sinu ọkàn mimọ ati pipe.
Bi awọn eniyan kọ ba ni isọdimimọ, ti wọn ba si gba nnkan ti wọn n pe ni ifi Ẹmi Mimọ wọ ni, ki i ṣe lati ọdọ Ọlọrun wá nitori o lodi si Bibeli. Igbesi aye awọn ti o ni iru iriri bẹẹ fi han pe wọn ki i ṣe ti Ọlọrun.
Iran Eke
Ni akoko kan oniwaasu kan, ẹlẹgbẹ ẹni ti o dá ijọ wa silẹ, sọ fun un nipa iṣipaya nlá nlà kan ti oun ri. Imọlẹ arẹwa kan ti kun yara rẹ, o si ti sọ fun un pe ohun kan ti wọn ti n waasu rẹ kọ ṣe danindanin mó. Oun dahun pe: “Bi iṣipaya rẹ ba mú ohunkohun kuro ninu Ọrọ yii tabi ti o ba fi kun un, iran eke ni.” O beere pe “Imọlẹ agbayanu ni n kó?” Oun dahun pe; “Eṣu le tan imọlẹ nla. Kọ si imọlẹ tabi iran ti yoo yi wa kuro ninu Ọrọ Ọlọrun.”
Paulu Apọsteli sọ pe bi angẹli kan ba ti Ọrun wá pẹlu ihinrere miiran yatọ si eyi ti Kristi ti fi le awọn Apọsteli Rẹ lọwọ, ati Paulu pẹlu, “Jẹ ki o di ẹni ifibu.” Bi Paulu ba yi ọkan rẹ pada ti o ba si bẹrẹ si waasu ẹkọ miiran, jẹ ki o di ẹni ifibu (Galatia 1:6-9). Ọlọrun kọ ni yi Ọrọ Rẹ pada. “Titi ọrun on aiye yio fi kọja lọ, ohun kikini kan ninu ofin ki yio kọja, bi o ti wù ki o ri, titi gbogbo rẹ yio fi ṣẹ” (Matteu 5:18).
Ipinya
Ki ni eniyan ni lati ṣe si wolii eke, ọkunrin ti o mu ẹkọ miiran wa? Ọlọrun wi fun awọn Ọmọ Israẹli pe: “Wolĩ na, tabi alalá na, ni ki ẹnyin ki o pa; nitoriti o ti sọ isọtẹ si OLUWA Ọlọrun nyin. . . . . . lati tì ọ kuro li oju ọna ti OLUWA Ọlọrun rẹ filelẹ li aṣẹ fun ọ lati ma rìn ninu rẹ. Bẹẹni ki iwọ ki o si mú ibi kuro lãrin rẹ” (Deuteronomi 13:5). Bi o tilẹ jẹ ara ile wọn gan an – arakunrin, tabi ọmọkunrin, tabi iyawo, tabi ọrẹ timọtimọ ju lọ fun wọn -- awọn Ọmọ Israẹli kọ gbọdọ ṣaanu fun un, ṣugbọn wọn ni lati pa a run fun mimu ẹkó eke wa. Ọwọ ti wọn ni o ni lati kó wà lara ẹni naa, nigba naa ni ki gbogbo eniyan lọwọ si i lati sọ ọ ni okuta titi yoo fi kú.
Bi wọn ba gbọ pe ilu kan ti yipada si ibọriṣa, gbogbo ilu naa ni wọn gbọdọ parun: awọn ara ilu naa, awọn ohun ọsin; ati awọn ile ti o wa nibẹ ni a ni lati sun jona to bẹẹ ti ki yoo fi ku ohun kan ninu “ohun ifibu” naa.
Bi idajọ Ọlọrun ba wuwo bayii ni igba ni lori awọn eniyan ti o gbiyanju lati yi awọn ọmọ Rẹ kuro ni ọna otitọ, iwọ ha ro pe Oun yoo fẹ ki a feti si awọn eniyan ti n sọ fun ni pe kọ ṣe danindanin fun wa lati gba gbogbo Bibeli gbó? Ni akoko oore-ọfẹ a ki kúkú pa eniyan, ṣugbọn bi wọn ba wá si ile-isin wa ti wọn si mú ẹkọ eke wá, a paṣẹ fun ni pe: “Ẹ mã ṣọ awọn ti nṣe iyapa, ati awọn ti nmu ohun ikọsẹ wá lodi si ẹkó ti ẹnyin kó; ẹ si kuro ni isọ wọn” (Romu 16:17). “Olukuluku ẹniti o ba nru ofin ti kọ si duro ninu ẹkó Kristi, kọ gba Ọlọrun. Ẹniti o ba duro ninu ẹkó, on li o gbà ati Baba ati Ọmọ. Bi ẹnikẹni bá tọ nyin wá, ti kọ si mu ẹkó yi wá, ẹ máṣe gbà a si ile, ki ẹ má si ṣe kí i. Nitori ẹniti o ba ki i, o ni ọwó ninu iṣẹ buburu rẹ” (2 Johannu 9-11).
Itumọ eyi ni pe bi ẹni kan ba tọ wa wá ti o wi pe oun jẹ ọmọ Ọlọrun ti o si fẹ kọ wa pe lara awọn ẹkọ ti Jesu ki i ṣe fun wa lati pamó, a ko gbọdọ ba a ṣọrẹ, tabi ki a kin in lẹyin ninu iṣẹ buburu rẹ. A ni lati kà a si bi ẹni pe o ti kú; nitori bi a ba fi ọkàn si ohun ti o n wi, o le ṣi wa lọna kuro lọdọ Ọlọrun.
Bi a ba fẹran Ọlọrun ni tootọ a ko ni gbọjẹgẹ fun ẹnikẹni ti o ba mu ẹkọ eke wá. Ẹmi Ọlọrun ṣe deedee pẹlu Ọrọ Rẹ yoo si fi ohun ti o tọna han wa. A ni lati gbọran si eyi ti o tọna, bi o ba tilẹ jẹ pe ẹni ti o mu ẹkọ eke wa jẹ ẹni ti o ṣọwọn fun wa. O ṣe pataki ju lati gbó ti Ọlọrun ki a si ni itilẹyin Rẹ ju lati té eniyan lọrun, tabi ifẹ ti ara wa. Ni ọjọ kan Jesu n bọ wa fun iyawo Rẹ, Ijọ mimó: gbogbo awọn ti o si ti dẹ ọwọ otitọ yoo gbọ idajọ yii: “Emi wi fun nyin, emi kọ mọ nyin nibiti ẹnyin gbé ti wá; ẹ lọ kuro lọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ ẹṣẹ” (Luku 13:27).
Questions
AWỌN IBEERE- Nibo ni awọn alala eke yoo ti wá?
- Bawo ni awọn Ọmọ Israẹli ṣe ni lati ṣe si wọn?
- Ki ni ṣe ti awọn iran ati alá eke wọnyii yoo fi wá?
- Bawo ni awọn Ọmọ Israẹli yoo ṣe mọ eyi ti o jẹ eke yatọ si eyi ti o jẹ otitọ?
- Awọn wo ni o ṣe daanindanin ninu Ọrọ Ọlọrun?
- Ki ni abayọri si boya a pa gbogbo Ọrọ Ọlọrun mó tabi a kọ pa á mó?
- Ki ni yẹ ki a ṣe si awọn ti o ba mu ẹkó eke tọ wá wá?