Deuteronomi 19:1-21; Joṣua 20:1-9

Lesson 139 - Junior

Memory Verse
“Ni ibẹru OLUWA ni igbẹkẹle ti o lagbara: yio si jẹ ibi àbo fun awọn ọmọ rẹ” (Owe 14:26).
Notes

Oju fún Oju

Oju fun oju, eyin fun eyin, “Ẹnikẹni ti o ba ta ẹjẹ enia silẹ, lati ọwó enia li a o ti ta ẹjẹ rẹ silẹ” (Gẹnẹsisi 9:6), ni ofin fun awọn Ọmọ Israẹli. Bi ẹni kan ba pa eniyan, ibatan ti o sun mọ ẹni ti a pa ni lati pa ẹni naa. Ko si iye owo ti a le fi san ẹsan iwa buburu naa ọranyan ni pe ki a ta ẹjẹ silẹ.

Ikú ti o ṣeeṣi ṣẹlẹ lati ọwọ ẹnikẹni ni a ko kà si ipaniyan, a ko si gbọdọ gbẹsan lọnakọna. Bi awọn ọkunrin meji ba n ṣiṣẹ pọ ninu igbo, ti aake si yọ ninu ẹrú ti o si pa ẹni keji, a ki yoo dá ẹnikẹni lẹbi fun eyi, nitori eeṣi ni o ṣe.

Ṣugbọn bi arakunrin ẹni ti a pa naa ba kun fun irunu si ẹni ti o ṣeeṣi paniyan naa to bẹẹ ti ko fẹ lati gba pe eeṣi ni o ṣe tabi bẹẹ kọ? O le pa a lai fun un aye lati ṣe àlàyé. O ṣe e ṣe ki o jẹ pe o ti ni ohun kan ninu si ẹni ti ọmọ ake rẹ pa eniyan naa, ki o si rọ pe aye ṣi silẹ fun oun nisisiyii lati gbẹsan.

Aabo

Ọlọrun ti ṣe ipese silẹ fun oniruuru iṣẹlẹ. O mọ pe o ṣe e ṣe fun awọn alaiṣẹ lati jiya nitori ofin, “Ẹnikẹni ti o ba ta ẹjẹ enia silẹ, lati ọwó enia li a o si ta ẹjẹ rẹ silẹ”, nitori naa O pese ibi aabo. Pẹpẹ ti o wa ninu Agọ jẹ ibi aabo fun igba diẹ, lẹyin ti awọn Ọmọ Israẹli si ti de ilẹ Kenaani, ilu mẹfa ni wọn o yà sọtọ gẹgẹ bi ibi aabo fun ẹni ti o ṣeeṣi ta ẹjẹ silẹ.

Awọn Ọmọ Lefi kọ gba ilẹ ini ni Kenaani nipa eyi ti wọn o fi maa ri ounjẹ oojọ wọn, ṣugbọn a fun wọn ni ilu mejidinlaadọta (48) lati maa gbe. Lati inu idamẹwa awọn eniyan ni wọn ti maa ni ounjẹ oojọ wọn. Gbogbo akoko wọn ni wọn n lo fun iṣẹ-isin awọn Ọmọ Israẹli. Ẹkó awọn eniyan Ọlọrun duro lori ẹsin wọn, iṣẹ awọn Ọmọ Lefi si ni lati maa ṣe olukọ.

Mẹfa ninu awọn ilu mejidinlaadọta (48) naa, mẹta ni iha ila-oorun Jordani, ati mẹta ni iha iwọ-oorun rẹ, ni wọn jẹ ilu aabọ. Mẹta ti o wà ni Kenaani ni a maa n sọrọ rẹ ni igba iṣẹ-iranṣẹ Kristi ni aye. Ni ariwa, ni ilu ti a n pe ni Galili nikẹyin, ni ilu Kadeṣi wà; ni guusu Juda, ni Hebroni, ati ni agbedemeji ilẹ ini Efraimu, ni Ṣekemu wa. Ibi ti a tẹ awọn ilu wọnyii dó si jẹ ibi ti ko ni gba ẹnikẹni ju ọgbọn mile lati ile rẹ nigba ti o ba n sá lọ fun aabo.

Oju Ọna ti O mọ Gaara

Opopo ọna ti o lọ si awọn ilu aabo wọnyii ni lati jẹ eyi ti o lọ tààrà ti o si mó. Ẹni ti o n sa asala fun ẹmi rẹ ki yoo ni aye lati duro fun idiwọ oju ọna tabi lati maa yà sihin sọhun. Akọle oju ọna ti o hàn daradara ni a kọ Milat si (itumọ eyi ti i ṣe aabọ) ti a si gbe e si ikorita kọọkan, ti yoo maa tọka si ilu naa. Ohun gbogbo ni a ṣe lati mu ki o rọrun fun ẹni ti o ṣeeṣi pa eniyan lati le sá asala.

Lẹyin ti o ba ti de ilu naa oun yoo wà laaarin awọn ọrẹ. Awọn ọmọ Lefi n sin Ọlọrun awọn ni o si jẹ oniwarere ju lọ laaarin awọn eniyan naa, wọn a si ṣe gbogbo ohun ti o wa ni ipá wọn lati ran awọn ẹni ti o n wa aabo lọdọ wọn lọwọ. Bi ẹni ti o ṣeeṣi pa eniyan naa ba ku yoo jẹ ẹjọ ti rẹ, nitori a ti pese ohun gbogbo silẹ fun anfaani rẹ.

Ṣugbọn o ni lati duro ni ilu naa ki oun ba le wa laaye. Bi agbẹsan ẹjẹ ba ri i ni ẹyin odi ilu naa, o ni ẹtọ sibẹ lati pa a. Ko ni anfaani lati lọ si ile afi nigba ti olori alufaa ba kú ni o le lọ lai sewu. O dabi ẹni pe iku olori alufaa jẹ tita ẹjẹ silẹ fun ẹni naa ti wọn ṣeeṣi pa.

Mimọọmọ Pa Eniyan

Nigba miiran ẹni ti o mọọmọ paniyan a maa gbiyanju lati fi ara rẹ pamọ si ilu aabo. O si le jẹ pe awọn eniyan n fẹ mọ bi ọran ẹni kan ti o sa wa sibẹ lọna ẹtọ ba tọna tabi bẹẹ kọ. Ni iru ọran bẹẹ wọn o mú ọkunrin naa wá fun idajọ. Adajọ ti o maa n dá ẹjọ fun awọn eniyan a maa jokoo ni ẹnu bode ilu. O kere tan ẹlẹri meji ni lati wá tako ẹni ti o n jé ẹjọ naa, wọn o si bura pe ni tootọ ni o jẹbi. Ọtọọtọ ni a gbọdọ ṣe iwadi lẹnu ẹlẹri kọọkan, ki ẹni kan má ba gbọ ohun ti ẹni keji sọ; bi adajọ naa ba wi pe ẹni naa jẹbi ipaniyan, wọn o fi i le agbẹsan ẹjẹ lọwọ lati pa a. Ṣugbọn bi ko ba jẹbi, anfaani wà fun un lati wà ni ilu aabọ.

Idajọ Tootọ

Awọn ọran miiran le wá siwaju awọn adajọ naa, ninu eyi ti ede-aiyedẹ wà laaarin ẹni meji. Ẹni kọọkan ti o ba mú ọran kan wa siwaju adajọ ni lati mu ẹlẹri meji tabi mẹta wa pẹlu. A ranti pe nigba ti awọn Ju n tako Jesu, wọn ni lati mu ẹlẹri meji wa, wọn si ri awọn meji ti o bura ẹké, ọrọ wọn kọ si ba ara wọn mu (Marku 14:59). Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan Rẹ ṣe idajọ ododo, awọn ẹlẹri si ni lati sọ otitọ nipa ẹni ti o n jẹ ẹjọ naa. Bi ẹni ti a mu wa fun idajọ ba jẹ alaijẹbi, idajọ ti olufisun n fẹ mú wa si ori ẹni ti a pe ni ẹjọ naa ni yoo wa si ori oun tikara rẹ. Nitori eyi awọn eniyan a maa ri i daju pe ẹni ti awọn n fi sun jẹbi ni tootọ ki wọn to mu un wá sọdọ adajọ fun idajọ, eyi ti o le pada wa si ori oun tikara rẹ.

Jesu Aabo Wa

A le ri aworan Kristi ninu ilu aabo yii. Gbogbo wa ni a ti dẹṣẹ. Ko ṣe e ṣe fun wa ki a má ṣe bẹẹ, nitori a bi wa pẹlu irú ẹṣẹ ninu wa. Idajọ n tẹle wa lẹyin; afi bi a ba sá lọ sọdọ Jesu, Aabo wa, ki a si fi ara pamọ sinu Rẹ, a o jẹbi ijiya ayeraye.

Kọ ṣanfaani fun ẹnikẹni lati sọnu. Ọna opopo ti o lọ si ọdọ Jesu han gbangba. A ni Bibeli ti o n sọ fun wa pe ki a ronupiwada ki a si kọ ẹṣẹ wa silẹ ki a ba le ri igbala. O rọrun fun ẹnikẹni lati mọ. “Awọn ẹro ọna na, bi nwọn tilẹ jẹ ọpe, nwọn ki yio ṣì i” (Isaiah 35:8).

Bi a ba ri ọkan ninu awọn ti o ṣeeṣi pa eniyan ti o kọ lati lọ si ilu aabo, ti o si jẹ ki a pa oun lasan, a o kà a si aṣiwere ni tootọ. Ṣugbọn ki ni ki a sọ nipa ọpọlọpọ awọn eniyan ti o kọ lati wa sọdọ Jesu pẹlu ironupiwada? Wọn wà lẹyin odi “ilu aabọ” a si le ke wọn kuro nigbakigba lati lọ sinu iya ayeraye. Olukuluku eniyan ni àyẹ ṣi silẹ fun lati wa sọdọ Jesu. O wi pe, “Ẹniti o ba si tọ mi wá, emi ki yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri” (Johannu 6:37). Bi ẹlẹṣẹ yoo ba sa lọ sọdọ Jesu, oun yoo ri isinmi yoo si bọ lọwọ apanirun. Ki ni ṣe ti oun ko fi sá asala?

Wiwà ninu Jesu

Ofin ni ki ẹni ti o ṣeeṣi paniyan naa wà ninu ilu aabọ. A ni lati maa gbe inu Kristi, ki a si pa ara wa mó kuro ninu ẹṣẹ nipa Ẹjẹ Jesu, bi a ba n fẹ lati wà lai lewu. Jesu kọ ni ta ẹnikẹni ti o tọ Ọ wá fun aabo nù laelae, ṣugbọn ẹni naa ni agbara lati jade lọ kuro bi o ba fẹ.

A ti dari ẹṣẹ ẹni naa ji i, inu rẹ si n dun laaarin “odi” aabo Kristi. Ṣugbọn boya o gbagbe lati gbadura ọwó rẹ si di to bẹẹ ti kọ ri aye ka Bibeli. Lai pẹ jọjọ, ọkàn rẹ bẹrẹ si i fà lati mọ ohun ti o n ṣẹlẹ ni ẹyin odi “ilu,” o si lọ si ẹnu ọna lati wo ohun ti o n ṣẹlẹ. Nibẹ o ri gbogbo “agbegbe naa” ti o lọ titi niwaju rẹ, o si bẹrẹ si i maa rọ pe oun wà ninu ahamọ ninu “ilu” naa. Aye ha, o si rọ pe a n fi ẹtọ oun du oun nipa mimu ki oun duro nibẹ. Ni ọjọ kan o rin jade lọ si gbangba “ode.” O mi kanlẹ pe oun bó. Ko si ẹni ti yoo sọ ohun ti yoo ṣe fun un mó, o si bẹrẹ si sare lọ, o si n ro pe oun ko tun si ninu ahamó ofin iṣakoso igbesi-aye Onigbagbọ mọ.

Njẹ o ha ti di ominira bi? Ilẹ ọta ni ó wà. A n sọ fun un pe ki o yara pada kiakia ki ọwọ ọta to tẹ ẹ. Sa pada sabẹ ààbo laaarin odi ilu yara ki o to pẹ ju! Nitori ẹmi rẹ, yara sá pada!

Ṣugbọn ọkunrin naa kọ lati pada. Nisisiyii a ri ẹni kan ti o n bọ wa ba a. Satani tikara rẹ ni, o si ni ẹtọ lati pa ẹnikẹni ti o ba ri ni ẹyin odi ilu ààbọ. Ni ikẹyin ọkunrin ti o sá asala yii yoo lọ sinu idajọ ti kọ lopin.

Titi ayeraye ni yoo maa rọ nipa alaafia ti o wà ni ilu aabo, iru ifẹ ti o gbadun nigba ti o n gbe nibẹ. Yoo si maa rọ nipa Jerusalẹmu ti Ọrun nibi ti gbogbo awọn eniyan ti o duro ninu ilu aabo n lọ. Awọn n gbadun ayeraye nigba ti oun n jẹ irora. Bawo ni i ba ti dara to bi o ba ti duro ninu ilu ni! Tabi ki o si tete pada nigba ti ilẹkun ṣi silẹ fun un, nigba ti gbogbo eniyan n ke pe, “Pada, pada.” O ti pẹ ju nisisiyii; oun yoo si wa lode titi laelae.

Gbogbo awọn ti o ka ọrọ wọnyi i ba jẹ sa wa sinu ilu aabọ; bi o ba ti wà lai lewu ninu ilu naa, ma ṣe yọju lasan pada lati wo nnkan ti o wà lode. Ẹ jẹ ki a maa gbadura nigba gbogbo pe ki Oluwa pa wa mọ si abẹ Ẹjẹ naa ki a ba le jogun iye ainipẹkun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ilu aabọ?
  2. Ki ni ṣe ti Ọlọrun pese ilu aabo silẹ?
  3. Ki ni aabo wa?
  4. Ki ni maa n ṣẹlẹ si awọn ti o fi ilu aabo silẹ -- nipa ti ara ni akoko awọn Ọmọ Israẹli, ati nipa ti ẹmi ni akoko tiwa yii?
  5. Ṣe àlàyé bi awọn ti o fi ilu aabo silẹ ṣe le tun pada ri igbala.
  6. Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ti o ba kọ lati pada sibẹ?