Lesson 140 - Junior
Memory Verse
“Ẹniti o ba si tọ mi wá, emi ki yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri” (Johannu 6:37).Notes
A ti kó ẹkó nipa ẹrẹ ti a ṣeleri fun awọn ti o ba gbọran, ati ohun ti awọn alaigbọran yoo ri gbà pẹlu. “Ibukún, bi ẹnyin ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbó, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni; ati egún, bi ẹnyin kọ ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbó ti ẹnyin ba si yipada kuro li ọna ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, lati ma tọ ọlọrun miran lẹhin, ti ẹnyin kọ mọ rí” (Deuteronomi 11:27, 28). Awọn miiran ninu awọn Ọmọ Israẹli ṣe aigbọran lẹyin ikilọ yii. Wọn sọ ibukun Ọlọrun nù nipa yiyipada kuro lọdọ Rẹ. Ọlọrun ti sọ ohun ti wọn le ṣe nigba ti wọn ba wa ni iru ipo bayii. Wọn ni lati ranti ọrọ Oluwa. Wọn si gbọdọ ranti awọn aṣẹ Rẹ ti O ti pa fun wọn, nigba ti egun ba wá sori wọn. O ti sọ ọna ti egun yii yoo fi kuro lori wọn nitori Ọlọrun “kọ fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣegbé, bikoṣe ki gbogbo enia ki o wá si ironupiwada” (2 Peteru 3:9).
Awọn Igbekun
Pupọ ninu awọn Ọmọ Israẹli ni a ti kó ni igbekun lọ si orilẹ-ede miiran (2 Awọn Ọba 18:11; 24:10, 14, 25:11). Ahasi. . . . kọ si ṣe eyiti o tó li oju OLUWA. . . . Nitorina OLUWA Ọlọrun rẹ fi i le ọba Siria lọwọ; nwọn si kọlù u, nwọn si kó ọpọlọpọ ni igbekun lọ ninu wọn, nwọn si mu wọn wá si Damasku” (2 Kronika 28:1, 5).
Ọpọlọpọ eniyan lonii ni wọn jé igbekun ọta wọn ẹmi – Satani. Ileri Ọlọrun wà fun wọn gẹgẹ bi o ti wà fun awọn Ọmọ Israẹli. Nitori ẹni kan kọ ri ojurere Ọlọrun nisisiyii kọ fi han pe oun kọ le ri i mó. Ọlọrun ti fi aṣẹ lelẹ pe egún ti o n tẹle aigbọran le ṣe yi pada si ibukun ti o wà fun igbọran.
Ohun Iran-ni-leti
Igbesẹ kin-in-ni si ọdọ Ọlọrun n wá nipa mimọ ipo ti eniyan wà ati aini rẹ. Awọn Ọmọ Israẹli mó pe igbekun ni wọn, ati pe, Ọlọrun kọ ja ogun fun wọn mó gẹgẹ bi O ti ṣe nigba kan ri. Wọn ranti bi Ọlọrun ti wà pẹlu wọn lati bukun wọn. Wọn mọ pe igbesi-aye wọn ti yatọ. A rán wọn leti ileri Ọlọrun fun awọn wọnni ti yoo pada sọdọ Rẹ.
Oju ọmọ oninakuna ti o ti fi ile baba rẹ silẹ, ti o si ti ná gbogbo ohun ti o ni “walẹ” (Luku 15:17). O ranti awọn ibukun ti o ti gbadun ninu ile baba rẹ. O mọ ipo ọṣi ti ó wà. O pinnu ninu ọkàn rẹ lati pada si ọdọ baba rẹ. (Luku 15:18). Oun kọ ṣe awawi tabi ki o di ẹbi rẹ le ẹlomiran lori. O mọ pe oun jẹbi niwaju Ọlọrun ati eniyan.
Ipadabọ
Ọpọlọpọ eniyan ni o mọ pe ẹṣẹ wà ni igbesi aye wọn. Gẹgẹ bi ọmọ oninakuna, ebi n pa wọn, wọn kọ ni ọrẹ, wọn si n ṣiṣẹ ninu ẹrọfọ ẹṣẹ. O dabi ẹni pe awọn miiran fẹran lati wà ninu iru ipo bayii, nitori kọ ṣe ohunkohun lati kuro ninu ipo ẹsẹ ti wọn wà. Ọmọ oninakuna ṣe jù pe ki o pinnu lati pada sọdọ baba rẹ. O mu ipinnu rẹ ṣẹ -- o pada, o si gbà pe oun ti dẹṣẹ (Luku 15:21). Nigba naa ni o ri idariji ati aanu gbà lọdọ baba rẹ dipo idajọ.
Ibukun Ọlọrun kọ wá sori awọn Ọmọ Israẹli titi wọn fi pada sọdọ Ọlọrun. “Ṣugbọn bi ẹnyin ba yipada si mi, ti ẹ si pa ofin mi mọ, ti ẹ si ṣe wọn, bi o tilẹ ṣepe ẹnyin ti a ti tì jade wà ni ipẹkun ọrun, emi o ko wọn jọ lati ibẹ wá, emi o si mu wọn wá si ibi ti mo ti yàn lati fi orukọ mi si” (Nehemiah 1:9). Awọn ti wọn pinnu lati yipada si Ọlọrun ṣugbọn ti wọn ko mú ipinnu wọn ṣẹ, ko le ri ibukun Ọlọrun gbà. Oluwa n fẹ igbọran pipe – “pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo inu rẹ.”
Ibanujẹ Ẹni Iwa-bi-Ọlọrun
Lati wi pe, “Ẹlẹṣẹ ni mi, mo ti sọnu, mo si ṣegbe,” kọ le yi ipo eniyan pada. Ironupiwada nikan (lati yipada pẹlu ibanujẹ kuro ninu ipo ẹṣẹ ti eniyan wà) pẹlu igbagbó ninu Ọlọrun ni o le mu igbala ati ibukun Ọlọrun wá. “Nitoripe ibanujẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun a ma ṣiṣẹ ironupiwada si igbala” (2 Kọrinti 7:10). Ẹni ti o ba ni ibanujẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun maa n kaanu fun ṣiṣe ohun ti kọ tó, ki si i ṣe nitori idajọ ti yoo mù wá. Inú rẹ a bajẹ nitori kọ bu ọlá fun Ọlọrun ati nitori o ti dẹṣẹ si I. Ikorira fun ẹṣẹ ati ifẹ si iwa mimó ni yoo si tẹle ibanujẹ rẹ yii.
Oluwa wi pe oun yoo wẹ ọkàn mó, Oun yoo si fi ifẹ Ọlọrun sinu rẹ dipo ifé si ẹṣẹ ati iwà buburu. “Emi o si fun wọn li ọkàn lati mọ mi, pe, Emi li OLUWA, nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nitoripe nwọn o fi gbogbo ọkàn wọn yipada si mi,” (Jeremiah 24:7). Gbogbo ọkàn wa ni Ọlọrun n fé. Eniyan kọ le sin In pẹlu ọkàn ti o pin yélẹyẹlẹ (Matteu 6:24).
Ironupiwada
Majẹmu Titun ati Majẹmu Laelae pẹlu n kilọ fun gbogbo eniyan lati ronupiwada. A kà pe Ọlọrun yoo dari irekọja wọn ji, yoo si ṣaanu fun wọn bi awọn eniyan maa ba ronupiwada, ti wọn yoo si yipada si Oluwa (1 Awọn Ọba 8:47-50; 2 Kronika 7:14). Esekiẹli sọ fun awọn Ọmọ Israẹli lati “yipada, ki ẹ si yi kuro ninu gbogbo irekọja nyin. . . . . nitori kini ẹnyin o ṣe kú, ile Israẹli?” (Esekiẹli 18:30, 31).
Johannu Baptisi waasu pe: “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹdẹ,” o si tun wi pe “Nitorina, ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada” (Matteu 3:2, 8). Jesu wi pe, “emi kọ wá lati pẹ awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada” (Matteu 9:13). Peteru waasu pe, “Nitorina ẹ ronupiwada, ki ẹ si tun yipada ki a le pa ẹṣẹ nyin ré” (Iṣe Awọn Apọsteli 3:19). Ninu Bibeli, lati ibẹrẹ titi de opin, ni a ri pe “ki a wasu ironupiwada ati idariji ẹṣẹ li orukọ rẹ, li orilẹ-ẹde gbogbo” (Luku 24:47).
Ibukun Pupọ
Nigba ti ẹni kan ba ronupiwada ni tootọ, oun yoo fi gbogbo igbesi-aye rẹ fun Jesu – lati gbọran, lati fẹran, lati gbẹkẹle ati lati gbara lé E. Ki ni Ọlọrun ṣeleri fun ẹni ti o ba ronupiwada? Oun ti ṣeleri aanu ati idariji (Isaiah 55:7). Ọlọrun yoo gba a (Orin Dafidi 34:7; Daniẹli 6:27). “Kọ si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrìn dede” (Orin Dafidi 84:11), nitori O ti wi pe, Oun yoo “ṣe nyin ni ire” (Deuteronomi 28:63). Wọnyii ni di ninu ibukun ti Ọlọrun ti ṣeleri fun awọn wọnni ti yoo yipada si I, ti wọn yoo si maa gbọran. A maa n ni gbogbo nnkan wọnyii pẹlu alaafia ni ọkàn, ẹri-ọkàn ti o mó, iṣẹgun lori ẹṣẹ, igbagbọ, ireti, ati ifẹ Ọlọrun ti n jọba ninu ọkàn eniyan. Ka ninu Luku 15:18-24, gbogbo ohun rere ti a fi fun ọmọ onikuna nigba ti o pada si ile.
Yiyanju ati Yiyeni Ọrọ Naa
Ẹkọ wa fi ye wa pe ọna kan wà ti a le fi pada sọdọ Oluwa, o si n ki wa laya lati pada “nigbati ẹ le ri i” (Isaiah 55:6). A rọ awọn Ọmọ Israẹli lati gbọran si Ọlọrun lẹnu. Kọ le si awawi kan rárá, nitori Ọrọ Ọlọrun yanju, o si wà ni ẹde ti o le yé wọn. Igbalà ati igbọran si Ọlọrun ki i ṣe ohun ti kọ le ṣe e ṣe tabi ti o ṣoro. Ko di igba ti eniyan ba ṣe wahala pupọ tabi fi ara da iṣoro ti o le, tabi lo akoko pupọ ni kikọ ẹkọ ki o to le ri igbala. Ọlọrun fi ohun kan siwaju awọn Ọmọ Israẹli ati awa naa lonii, eyi ni lati yàn – iye ati ire tabi iku ati ibi (Deuteronomi 30:15). Lati gba “iye ati ire”, tẹle aṣẹ Rẹ: Bi iwọ “ba si yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ gbó, gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo.”
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti a kó awọn Ọmọ Israẹli ni igbekun?
- Ki ni Ọlọrun sọ fun wọn lati ṣe ki wọn ba le pada si ilẹ ileri?
- Ki ni Ọlọrun maa n ṣe fun ẹni ti o ba ronupiwada?
- Ki ni itumọ ironupiwada?
- Bawo ni a ṣe le ni ibukun Ọlọrun ni igbesi-aye wa?
- Ki ni Ọlọrun fi siwaju eniyan lati yàn?
- Ki ni eniyan gbọdọ ṣe lati ni “iye ati ire”?