Deuteronomi 31:16-22; 32:1-47

Lesson 141 - Junior

Memory Verse
“Ki ẹ jẹ oluṣe ọrọ na, ki o má si ṣe olugbó nikan” (Jakọbu 1:22).
Notes

Ojuṣe lati Ṣe

Mose ati Joṣua fi ara wọn hàn niwaju Ọlọrun ninu Agọ bi a ti pa a laṣẹ fun wọn. Ifarahan Oluwa ni iri ọwọn awọsanma wà ninu Agọ naa gẹgẹ bi Ọlọrun ti i maa pade Mose ni igba iṣaaju (Ẹksodu 33:9). Agó yii ni ibi ti awọn Ọmọ Israẹli ti i maa pade lati sin Oluwa nigba ti awọn alufaa ba n ṣe irubọ. Dajudaju Mose ati Joṣua parọró gidigidi ki wọn ba le gbọ ọrọ ti Ọlọrun yoo ba wọn sọ.

Oluwa sọ pe ọjọ iku Mose sun mọ tosi. Nigba naa Joṣua yoo di alakoso awọn Ọmọ Israẹli. Iṣẹ ti Ọlọrun fi le Joṣua lọwọ niyii. Iṣẹ ti o wuwo pupọ ni – lati ṣe akoso awọn Ọmọ Israẹli wọ ilẹ ileri. A wi fun Joṣua pe ki o ṣe giri ki o si mu aya le, ki o ma ṣe fi àyẹ silẹ fun ifoya ati ailera. Oluwa ti O ṣeleri lati wà pẹlu Joṣua ni yoo jẹ ipá ati iranwọ rẹ.

Gbogbo eniyan kó ni a fun ni iṣẹ alakoso gẹgẹ bi a ti fun Joṣua. Sibẹ Ọlọrun fun gbogbo awọn ọmọ Rẹ ni ojuṣe (iṣẹ ati ẹrù). Awa “nri ọtọ-ọtọ ẹbun gbà gẹgẹ bi ore-ọfẹ ti a fifun wa” (Romu 12:6).

“Mo ni ’ṣẹ lati ṣe,

Ọlọrun lati yìn;

Ọkàn aikú lati gbala,

Lati ṣe yẹ f’ọrun.”

Ẹri si Wọn

Ọlọrun fun Mose ni iṣẹ kan ṣe sii ṣaaju ikú rẹ. A rán Mose lati fi orin kan le awọn Ọmọ Israẹli lọwọ. Mose ti kọ orin idasilẹ kan lẹyin ti Oluwa mu wọn la Okun Pupa kọja (Ẹksodu 15:1). Orin ti Ọlọrun fi fun un nisisiyii jẹ ẹri si awọn Ọmọ Israẹli ti yoo tun ṣe aigbọran si Oluwa. Akoko yoo de nigba ti Ọlọrun kọ tun ni daabo bo wọn, bẹẹ ni Oun ko si ni pese fun wọn nigba ti wọn ba ti yà kuro lọdọ Oluwa. Ọlọrun ki i kọ ẹnikẹni ayafi bi ẹni naa ba kọkọ yipada kuro lẹyin Rẹ. Bi orin Mose ko ba tilẹ le mu ki awọn Ọmọ Israẹli ma ṣaigbọran, o le mu wọn wa si ironupiwada.

Ni ọjọ kan naa ti Mose ri aṣẹ naa gbà, a tipa Ọlọrun mi si i lati kọ orin naa gẹgẹ bi ẹri nipa ijolootọ Ọlọrun. Mose kọ orin naa o si fi kó awọn Ọmọ Israẹli fun itọni. Paulu kọwe pe. “Ẹ jẹ ki ọrọ Kristi mã gbé inu nyin li ọpọlọpọ ninu ọgbón gbogbo: ki ẹ mã kó, ki ẹ si mã gbà ara nyin niyanju ninu psalmu, ati orin iyin, ati orin ẹmi, ẹ mã fi ore-ọfẹ kọrin li ọkàn nyin si Oluwa” (Kolosse 3:16).

Orin Naa

Nipa orin yii, a rán awọn Ọmọ Israẹli leti titobi Oluwa ati ododo Rẹ. Kikokiki orukọ Oluwa le mu ki wọn ma ṣe dẹṣẹ. “Ọrọ rẹ ni mo pamó li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ si ọ” (Orin Dafidi 119:11). “Awọn ti o si mọ orukọ rẹ o gbẹkẹ le ọ” (Orin Dafidi 9:10).

Mose fi Oluwa wé apata ti yoo jẹ aabo fun wọn, eyi ti o ni ipilẹ ti a kọ si le mì. “Pipe li Ọlọrun li ọna rẹ; ọrọ OLUWA li a ti dan wó: on si ni asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. Nitori tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe OLUWA? tabi tani iṣe apáta, bikoṣe Ọlọrun wa?” (2 Samueli 22:31, 32).

O yẹ ki awọn Ọmọ Israẹli ti ni iwuri lati fi ogo fun Ọlọrun nitori ijolootọ Rẹ si wọn, gẹgẹ bi ojuṣe wọn. A sọ fun wọn lati “ranti ọjó igbãni,” bi Ọlọrun ti boju to wọn. Bi o ba jẹ pe wọn ti kere ju ni ọjọ-ori, awọn obi wọn le sọ fun wọn bi Ọlọrun ṣe mu wọn la aginju já ti O si ti pa wọn mó “bi ẹnyin oju rẹ.”

Bawo ni Ọlọrun ti yatọ to si awọn Ọmọ Israẹli – “Ọlọrun otitọ ati alàiṣegbe”! Awọn Ọmọ Israẹli ti dẹṣẹ, wọn si ti ṣọtẹ si Ọlọrun. Oluwa jẹ Ọlọrun otitọ -- Ẹni ti kọ le ṣeke (Titu 1:2; Heberu 6:18). Ohunkohun kọ tase ninu ohun rere ti OLUWA ti sọ fun ile Israẹli; gbogbo rẹ li o ṣẹ” (Joṣua 21:45). A kọ le sọ bẹẹ nipa awọn Ọmọ Israẹli. Wọn sin Ọlọrun oloootọ ati mimó ṣugbọn wọn kọ jẹ oloootọ si I bi Oun ti jé si wọn. Ni ọpọlọpọ ọdun ṣiwaju akoko yii awọn Ọmọ Israẹli ti jé ẹjẹ kan: “Ohun gbogbo ti OLUWA wi li awa o ṣe” (Ẹksodu 19:8). Wọn ba majẹmu ati adehun ribiribi naa jé.

Oloootọ ati olododo ni Ọlọrun. Kọ si ẹni ti yoo padanu nipa sisin In. “Ati gbogbo ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabirin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori orukọ mi, nwọn o ri ọrọrun gbà, nwọn o si jogún iye ainipẹkun” (Matteu 19:29). Oluwa ki i rán ijiya kọja bi o ti tó. “Idajọ Oluwa li otitọ, ododo ni gbogbo wọn” (Orin Dafidi 19:9). Ọlọrun ki i kuna lati fun eniyan ni ẹre fun iṣẹ-isin rẹ tabi fun iya ti o jẹ nitori Rẹ. “O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ; iwọ ṣe olõtọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bó sinu ayọ oluwa rẹ” (Matteu 25:23). “Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba” (2 Timoteu 2:12).

Bakan Naa Lonii

Pupọ eniyan ni wọn ni ẹri kan naa lonii bi eyi ti o wà ninu orin Mose nipa ijolootọ Ọlọrun. Olukuluku ọmọ Ọlọrun, ni igba kan ri, ni o n rin kaakiri ninu aginju ẹṣẹ. Oluwa ri wọn ninu aṣálẹ O si rán ojo ẹmi si wọn. Oluwa nikan ṣoṣo ni O gbà wọn. O tó wọn O si ṣamọna wọn de inu ilẹ rere. Gẹgẹ bi a ti fi oyin, ororo, alikama daradara ati omi inu eso ajara bó awọn Ọmọ Israẹli, bẹẹ naa ni ọna ti ẹmi nisisiyii, a n fi ẹkun rẹrẹ ohun ti o dara ju lọ bó awọn eniyan Ọlọrun. Wọn n gbadun eso ati itunu Ọrọ Rẹ ati Ẹmi Rẹ.

Ikilọ

Orin Mose jé ikilọ fun wa lonii. Ohun ti o wà ni ikẹyin orin naa ko dun mọ ni nitori o n sọ nipa igbesi aye awọn apẹyinda. A ba jẹ ṣọra ki apa ti o kẹyin orin naa ma ṣe jẹ ẹri wa gẹgẹ bi apa kin-in-ni ti jé. Bi idẹra ti n ba awọn Ọmọ Israẹli bẹẹ ni wọn sọ ibẹru Oluwa nù. Wọn di sisanra, alaini itara, ati alaiyẹ. Wọn ko ni itẹlọrun, wọn si “tapa” si Oluwa. Lai ṣe aniani wọn ro pe awọn ti mọ ọn ṣe pupọ wọn ko si fi ọlá fun Ọlọrun lori iṣẹgun wọn lori ọtá. Wọn fẹ ọna ti wọn, wọn si n pongbẹ fun iyipada. “Bayi li OLUWA wi, ẹ duro li oju ọna, ki ẹ si wọ, ki ẹ si bere oju-ọna igbàni, ewo li ọna didara, ki ẹ si rin nibẹ, ẹnyin o si ri isinmi fun ọkàn nyin” (Jeremiah 6:16).

A le ri bi ẹṣẹ kan yoo ti fa ni lọ si ẹṣẹ miiran. Boya ni akọkọ awọn Ọmọ Israẹli jẹ alafara diẹ nipa fifi rere ṣiṣe silẹ, lai pẹ wọn bẹrẹ si huwa buburu. Dipo bibu ọlá fun Ọlọrun, wọn gbagbe Rẹ wọn si sin awọn oriṣa (ọlọrun titun) awọn ti kọ ṣe wọn loore ri, ti ko si le ràn wọn lọwọ rara. “Nitori awọn enia mi ṣe ibi meji: nwọn fi Emi, isun omi-iye silẹ, nwọn si wà kanga omi fun ara wọn, kanga fifó ti kọ le da omi duro” (Jeremiah 2:13).

Idajọ

Awọn ti o ba kọ Apata igbala silẹ maa n kọlu apata iparun. “Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kọ le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká” (Galatia 6:7). I ba ṣe pe awọn eniyan gbón, wọn i ba ronu bi awọn ti n lo igbesi aye wọn (Deuteronomi 32:29). Iwọ ha n gbe lọna ti ibukun Ọlọrun le fi wà lori rẹ nisisiyii ati ni Ọjọ Idajọ pẹlu?

Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ba kùna lati jẹwọ oore ti Ọlọrun ti ṣe fun wọn, Oun yoo gba awọn nnkan rere naa pada kuro lọwọ wọn. Ọlọrun yoo pa oju Rẹ mó kuro lara wọn (ẹsẹ 20). Oun ko ni daabo bo wọn tabi fun wọn ni idẹra mó. Wọn ko ni ni Oluwa lati kó ati lati tó wọn mó. A o tú wọn kaakiri a o si pa wọn run pẹlu ipaya ogun lode ati ẹru ninu (ẹsẹ 25, 26).

Niwọn bi awọn Ọmọ Israẹli ti tabuku si Ẹlẹda wọn, a o ti ọwọ awọn eniyan ẹlẹgbẹ wọn tabuku si wọn. Ọlọrun wi pe, Oun, ninu idajọ, yoo rán awọn ọfà Rẹ -- ebi, ogun ati iyọnu (ẹsẹ 23-25). Ko le si asalà bẹẹ ni ko si ẹni ti o le gba ni là kuro ni ọwọ Rẹ. “Ohun ẹru ni lati ṣubu si ọwó Ọlọrun alãye” (Heberu 10:31).

Orin Mose sọ gbogbo nnkan wọnyii fun awọn Ọmọ Israẹli ki wọn to ṣẹlẹ rara. Niwọn igba ti awọn Ọmọ Israẹli gbọran si Oluwa lẹnu ti wọn si gbẹkẹle E, wọn ni gbogbo awọn ohun rere ti O ti ṣeleri. Lara ibukun naa ni iṣẹgun lori ọtá, pẹlu ounjẹ ati itura. Nigba ti wọn sinmi le Oluwa, ọkunrin kan lẹ lé ẹgbẹrun ọtá wọn (Joṣua 23:10). Samsoni ṣe ju bẹẹ lọ o fi pari ẹrẹkẹ kẹtẹkẹtẹ kan “’pa ẹgbẹrun ọkunrin” (Awọn Onidajọ 15:15).

Bi o tilẹ je pe a kó awọn Ọmọ Israẹli ni orin Mose yii, a si kilọ fun nipa idajọ Ọlọrun lori alaigbọran, akoko de nigba ti wọn gbagbe Ọlọrun. Nipa kikunà lati jẹ oluṣe gẹgẹ bi wọn ti jẹ olugbó (Jakọbu 1:22), awọn Ọmọ Israẹli di igbekun dipo aṣẹgun. “Ibaṣepe awọn enia mi ti gbó ti emi, ati ki Israẹli ki o ma rin nipa ọna mi! Emi iba ti ṣé awọn ọta wọn lọgan, emi iba si ti yi ọwọ mi pada si awọn ọta wọn” (Orin Dafidi 81:13, 14).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Mose ati Joṣua fi wọ inu Agọ lọ?
  2. Iṣẹ wo ni Ọlọrun gbé le Joṣua lọwọ?
  3. Ọrọ itọni wo ni Ọlọrun fi fun un?
  4. Ki ni Ọlọrun ni ki Mose ṣe ṣaaju ikú rẹ?
  5. Ki ni idi rẹ ti a fi kọ orin yii?
  6. Awọn wo ni a kó ni orin naa?
  7. Ki ni ṣẹlẹ nigba ti itura de ba awọn Ọmọ Israẹli ti wọn si gbagbe Ọlọrun?
  8. Ki ni wọn jere nipa fifẹ iyipada ati nipa titọ awọn ọlọrun titun lẹyin?