Deuteronomi 33:1-29

Lesson 142 - Junior

Memory Verse
“Tali o dabi rẹ, iwọ enia ti a ti ọwó OLUWA gbàla” (Deuteronomi 33:29).
Notes

Olufunni ni Ofin

Ọlọrun ti lo Mose lati ti ipasẹ rẹ fun awọn eniyan Rẹ ni Ofin. Lẹyin ti a ti dá wọn silẹ ni Egipti, ti a si mú wọn la Okun Pupa já, wọn dó si iwaju Oke Sinai (Ẹksodu 19:1, 2). Ọlọrun ti sọ pe awọn Ọmọ Israẹli yoo “jẹ orilẹ-ẹde mimó” ati “iṣura” bi wọn ba gbọran si aṣẹ Oun. Wọn wi bayii fun Mose, “Ohun gbogbo ti OLUWA wi li awa o ṣe,” Gẹgẹ bi aṣoju awọn eniyan naa Mose lọ lati bá Ọlọrun sọrọ.

Ki Mose to gun ori Oke lọ lati lọ gba Ofin lọwọ Ọlọrun, a sọ fun gbogbo eniyan naa lati mura silẹ ati lati ya ara wọn si mimọ, nitori wọn o gbó ohùn Ọlọrun lati inu awọsanma ti o ṣú dùdù bi O ti n ba Mose sọrọ (Ẹksodu 19:9). Wo o bi Mose yoo ti gbadura to, bi yoo ti ṣe ifararubọ to, bi yoo si ti wá ọkàn rẹ ri to lati mura silẹ lati ba Ọlọrun sọrọ! Awọn eniyan naa ko gbọdọ fi ọwó kàn oke naa paapaa, nitori Ọlọrun Mimó wà nibẹ, ṣugbọn a paṣẹ fun Mose lati wá si iwaju Rẹ.

Ko si iyemeji ninu ọkàn awọn eniyan naa pe Ọlọrun wà nibẹ. O fi agbara ati ogo Rẹ han nipa aara, manamana, ati iná (Ẹksodu 19:16, 18). Awọn eniyan wáriri wọn si sá sẹyin nigba ti a sé Mose nikan mó ọhun pẹlu Ọlọrun. Fun ogoji ọsan ati ogoji oru (Ẹksodu 24:18), Mose wà lori Oke naa ti ikuuku bọ lati gba Ofin ti a fi ika Ọlọrun kọ (Ẹksodu 31:18), lori walaa okuta meji (Ẹksodu 34:1). Nigba ti Mose de lati ibi ti o ti wà pẹlu Ọlọrun oju rẹ n dán fun imọlẹ ati ogo Ọlọrun (Ẹksodu 34:29).

A Dahun Ipe Ọlọrun

Mose jẹ olufunni ni Ofin, eniyan nla ti Ọlọrun, nitori o mura tan lati jé ipe Ọlọrun ati lati di àyẹ naa mu eyi ti Ọlọrun fẹ ki o di mu. Mose la igba ipese silẹ fun iṣẹ Ọlọrun já. O sẹ ara rẹ a si ya a kuro lọdọ ẹbi rẹ nigba miiran. Boya Ọlọrun yoo lo ọ lati jẹ ibukun nla fun awọn ẹlomiran bi iwọ naa ba mura tan lati jẹ ohunkohun ti Oun ba n fẹ ki o jé.

Iṣẹ Mose fẹrẹ pari. O mọ pe lai pẹ oun yoo fi awọn Ọmọ Israẹli silẹ (Deuteronomi 31:14). Mose ti kó lati fẹran wọn gẹgẹ bi ọmọ oun tikara rẹ. O ti kó wọn o si ti ṣiṣẹ fun wọn ki wọn ba le ni eyi ti o dara ju lọ ninu ohun gbogbo – ogún rere lati ọdọ Oluwa. Kọ ṣe ju eyi pe ki o sure idagbere fun wọn. Bakan naa, Jakọbu ti bukun awọn ọmọkunrin rẹ ki o to kú (Gẹnẹsisi 49). Awọn ẹbi awọn ọmọkunrin wọnyii ni wọn di ẹya awọn Ọmọ Israẹli. Nigba ti Mose bukun ẹya kọọkan, ibukun naa wá sori gbogbo ẹbi naa ki i ṣe lori ẹni ti o jẹ olori ẹbi nikan.

Gẹgẹ bi Onigbagbọ Tootọ

Mose n fẹ ki awọn Ọmọ Israẹli jé ọmọ-ẹyin tootọ fun Oluwa. Bakan naa ni awọn koko ti o ṣe pataki ninu awọn ẹbun wọnyii jẹ ti awọn eniyan Ọlọrun ni igba isisiyii pẹlu. Fun Reubẹni, ire ti Mose sú fun wọn ni pe awọn ẹbi naa yoo wà laaye, wọn ki yoo kú. A ti ṣeleri wiwa laaye nipa ti ẹmi fun awọn Onigbagbọ yatọ si iku ti o n duro de ẹlẹṣẹ. “Nitori ikú li ẹre ẹṣẹ; ṣugbọn ẹbun ọfẹ Ọlọrun ni iye ti kọ nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa” (Romu 6:23).

Ibukun ẹya Juda ni pe Ọlọrun yoo gbà a lọwọ awọn ọta rẹ, yoo si gbó ohùn rẹ, gẹgẹ bi Ọlọrun yoo ṣe gbó ohùn awọn eniyan Rẹ. “OLUWA jina si awọn enia-buburu; ṣugbọn o gbó adura awọn olododo” (Owe 15:29). “Awọn olododo nke, OLUWA si gbó, o si yọ wọn jade ninu iṣé wọn gbogbo” (Orin Dafidi 34:17).

Alufa fun Ọlọrun

Awọn Ọmọ Lefi ti yọọda lati wà ni iha ti Oluwa. A ti fi wọn jẹ alufaa fun Ọlọrun. Lara awo igbaya olori alufaa ni Urimu ati Tummimu wà nipasẹ eyi ti wọn fi n ni imọ otitọ lati fi ṣe idajọ awọn Ọmọ Israẹli (Ẹksodu 28:30). A fi ororo yan awọn alufaa, a yà wọn sọtọ, a si yà wọn si mimó (Ẹksodu 28:41) “lati ṣiṣẹ ni ibi mimó” (Ẹksodu 28:43). Lẹyin ti wọn jẹ mimó tán, awọn alufaa ni awọn ọrọ wọnyii ni ara fila wọn: “MIMỌ SI OLUWA” (Ẹksodu 28:36).

Awọn ọmọ Lefi kọ ni ipin ninu ilẹ nigba ti a pin Kenaani fun awọn Ọmọ Israẹli, nitori Oluwa ni ipin wọn (Numeri 18:20). Nigba pupọ ni iṣẹ wọn yoo mu wọn lọ kuro lọdọ ẹbi wọn. Sibẹ wọn jẹ oloootọ si Ọlọrun ati si awọn Ọmọ Israẹli lati kó wọn ni Ofin ati lati rú ẹbọ si Oluwa. Mose bukun awọn ọmọ Lefi o si ni ki Ọlọrun tẹwọgba iṣẹ wọn ki O si daabo bo wọn.

Olufẹ Oluwa

Mose pe Bẹnjamini ni olufẹ Oluwa, o si wi pe yoo maa gbe lai lewu, nipa gbigbẹke oluwa.

“Iwọ sa rọ mọ apa Jesu,

Yio ran ọ lọwọ, ran ọ lọwọ,

Bi o ba gbẹkẹle ifẹ Rẹ,

Yio f’orin k’ọkàn rẹ.

“Gbẹkẹ rẹ le, gba ifẹ Rẹ gbọ,

Gbẹkẹ rẹ le, yio ṣãnu fun ọ;

Gbẹkẹ rẹ le, yio mu ọ de ’le

Gbẹkẹle Olugbala”.

Ibukun Josẹfu (awọn ọmọ rẹ meji – Efraimu ati Manasse) ni a sọ sori ilẹ rẹ -- awọn ohun iyebiye Ọrun ati ti aye. Ninu wọnyii ni ibukun ti ẹmi ti ibukun ti ara wà. Oun ni a fi ẹkun ọpọlọpọ ati aṣẹ nla fun, eyi ti a muṣẹ ni apa kan nipasẹ awọn aṣiwaju nla meji -- Joṣua lati inu ẹya Efraimu, ati Gideoni lati inu Manasse.

A sure fun ẹya Sebuluni ati Issakari pupọ. A sọ fun wọn pe ki wọn maa yọ, tabi ki wọn ni ayọ, olukuluku ni ipo ti rẹ. “Ayọ OLUWA on li agbara nyin” (Nehemiah 8:10). Wọn o ṣe iṣẹ-isin fun Ọlọrun nipa iṣẹ irubọ ododo ati nipa pipe awọn ẹlomiran lati wá sin Oluwa. Awọn ẹlomiran ro pe awọn eniyan Sebuluni ni di oniṣowo nitori wọn n gbé lẹba okun; ati pe awọn eniyan Issakari di olutọju ọgba ajara tabi agbẹ; ṣugbọn olukuluku wọn ni o n ṣiṣẹ ni ipo ti rẹ fun ọla Oluwa.

Awọn ẹya Gadi jẹ ninu awọn Ọmọ Israẹli ti wọn yàn lati jokoo ni iha ila-oorun Odo Jordani ti wọn ko si lọ si ilẹ Kenaani. Wọn kó pese silẹ fun awọn ẹbi wọn ati ẹran ọsin wọn (Numeri 32:16). Nigba naa ni awọn jagunjagun wọn bá iyoku awọn Ọmọ Israẹli lọ si ilẹ Kenaani lati jà fun wọn (Joṣua 4:12). Oye ye wa nipa ire ti a sú fun Gadi pe ẹya rẹ yoo dagba. Peteru gba awọn Onigbagbọ tootọ niyanju lati maa “dàgba ninu ore-ọfẹ ati ninu imọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi” (2 Peteru 3:18).

Nipa Dani a sọ pe o jẹ ọmọ kiniun, boya itumọ eyi ni pe o ni ọkàn bi kiniun, akikanju, ati onigboya. Ọkunrin kan ninu ẹya yii, Samsoni, fi ara rẹ han ni alagbara nitori ni igba kan o pa ẹgbọrọ kiniun kan. (Awọn Onidajọ 14:5, 6). Samsoni jẹ onigboya, o si pa ọpọlọpọ ninu awọn ọta awọn Ọmọ Israẹli. Ni ikú rẹ awọn ọta ti o pa “pọjù awọn ti o pa li aiye rẹ lọ” (Awọn Onidajọ 16:30). Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan Rẹ ki o jẹ alagbara ninu Oun, ki wọn si kun fun igboya (Joṣua 1:7).

Naftali ni yoo ni itẹlọrun yoo si kun fun ibukun Oluwa. “Ore mi yio si tẹ awọn enia mi lọrun, li OLUWA wi” (Jeremiah 31:14).

“Halleluya! Mo ti ri I

Ẹniti ọkàn mi ti n fẹ!

Jesu fun mi ni itẹlọrun;

Ẹjẹ Rẹ si gbà mi là.”

Aṣeri ni a ṣe ileri ọlà fun, irẹpọ pẹlu awọn ti o yi i ka, ati agbara gẹgẹ bi ọjọ rẹ. “OLUWA li agbara ẹmi mi; aiya tali yio fọ mi?” (Orin Dafidi 27:1).

Mose rán awọn Ọmọ Israẹli leti pe kọ si ẹni ti o dabi Oluwa pe ati Oun yoo jẹ aabo ati isinmi wọn. Mose pari ọrọ rẹ bayii pe awọn Ọmọ Israẹli yẹ lati maa yọ pe Oluwa bukun fun wọn to bẹẹ. Onigbagbọ ko ha le sọ bakan naa bí?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni Mose ṣe mọ pe oun kọ ni pẹ kú?
  2. Ki ni ohun ti o ti ṣe fun awọn Ọmọ Israẹli?
  3. Awọn wo ni o sure fun?
  4. Bawo ni a ṣe mọ pe Ọlọrun fẹran awọn eniyan yii?
  5. Fi ibukun awọn Ọmọ Israẹli wé ibukun ọmọ Ọlọrun ni ọjọ oni.