Deuteronomi 31:14, 15; 32:48-52; 34:1-12

Lesson 143 - Junior

Memory Verse
“Nitõtọ, bi mo tilẹ nrin larin afonifoji ojiji ikú emi ki yio bẹru ibi kan: nitori ti Iwọ pẹlu mi” (Orin Dafidi 23:4).
Notes

Aṣaaju

Ọlọrun ti pe Mose si ipo nlá nlà. Mose jẹ aṣaaju awọn Ọmọ Israẹli, o si tun jẹ olufunni ni ofin (Johannu 1:17). Ọlọrun ni O pẹ e, ti O yàn an, o si jẹ oloootó (Numeri 12:7; Heberu 3:2). Mose jẹ alagbawi nla fun awọn Ọmọ Israẹli; eyi ni pe, o duro laaarin wọn ati Ọlọrun lati bẹbẹ fun wọn. Fun ọpọlọpọ igba ni Ọlọrun n fi aanu hàn fun awọn Ọmọ Israẹli nitori adura Mose. Ni akoko kan, nigba ti wọn dẹṣẹ, Mose gbadura pe ki Ọlọrun dariji wọn; bi bẹẹ kọ, ki O pa orukọ oun ré kuro ninu Iwe Ọlọrun. O fẹran awọn Ọmọ Israẹli to bẹẹ ti o fé fi ara rẹ rubọ ki wọn ba le jé eniyan Ọlọrun. Oluwa wi fun Mose pe, “Ẹnikẹni ti o ṣẹ mi, on li emi o paré kuro ninu iwé mi” (Ẹksodu 32:33). Ọlọrun dariji awọn Ọmọ Israẹli nitori adura Mose, ṣugbọn a rán ajakalẹ arun si wọn, wọn si jiya ẹṣẹ naa.

Eniyan Ọlọrun

A n pe Mose ni eniyan Ọlọrun (Deuteronomi 33:1), oun si jẹ bẹẹ nitootọ nitori Ọlọrun n ba a sọrọ gẹgẹ bi ọré si ọré (Ẹksodu 33:9, 11). Mose ri ogo Oluwa. Kọ si ẹni ti o le ri oju Ọlọrun ki o si wà láàyẹ (Ẹksodu 33:20). Ọlọrun fi Mose pamó sinu “palapala” apata, O si fi ọwó Rẹ bọ o mọlẹ. Mose wo akẹyinsi Ọlọrun bi O ti n kọja lọ --anfaani ti o ya ni lẹnu, eyi ti a kọ gba ẹnikẹni láyẹ lati ni, gẹgẹ bi a ti mọ mọ.

Iranṣẹ Ọlọrun

Oluwa ṣiṣẹ fun Mose, Mose si ṣiṣẹ fun Oluwa. Ninu gbogbo apele ti Mose ni, boya eyi ti o tobi ju lọ ni “Iranṣẹ OLUWA” (Deuteronomi 34:5). Jesu tikararẹ Rẹ mú awọ iranṣẹ (Filippi 2:7), O si kó awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe ẹni ti o ba fé tobi ni yoo jẹ iranṣẹ (Marku 10:43, 44).

A le rọ pe iranṣẹ jẹ ẹni ti o n ṣiṣẹ fun ẹlomiran, ṣugbọn iranṣẹ tootọ n ṣe ju eyi ni lọ. Iranṣẹ wà labẹ akoso oluwa rẹ, yoo si ya ara rẹ sọtọ fun un. Iranṣẹ ki i ṣe aniyan nipa ohun ti ara rẹ; dipo eyi, ifẹ ati aṣẹ oluwa rẹ ni oun yoo ṣe lai ka ohun ti yoo gba iranṣẹ naa. A mọ nipa awọn iranṣẹ miiran paapaa ti wọn ti fi ẹmi wọn lelẹ fun oluwa wọn. Bibeli sọ diẹ fun ni nipa ojuṣe awọn iranṣẹ -- wọn ni lati gbọran (Efesu 6:5), ki wọn jẹ oloootọ (Kolosse 3:22), ki wọn maa tẹriba (1 Timoteu 6:1), ki wọn ki o si maa ṣe ohun ti o wu ni ninu ohun gbogbo (Titu 2:9). Gẹgẹ bi iranṣẹ Ọlọrun, Mose gbọdọ ti ṣe gbogbo awọn nnkan wọnyii.

Onirẹlẹ

Nigba ti Ọlọrun pe Mose sinu iṣẹ-isin Rẹ, o rọ pe oun kọ yẹ. O jẹ onirẹlẹ, o si sọ fun Oluwa pe “olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo” (Ẹksodu 4:10). Nigba ti Mose ti ni idaniloju pe Ọlọrun yoo wà pẹlu oun, o sé ara rẹ ki o ba le jẹ iranṣẹ Ọlọrun. “Ẹnikẹni ti o ba si rẹ ara rẹ silẹ, li a o si gbéga” (Luku 14:11). Mose jẹ iranṣẹ Oluwa, ṣugbọn Ọlọrun gbe e ga titi “wolĩ kan kọ si hù mó ni Israẹli bi Mose” (Deuteronomi 34:10).

“Ifẹ Tirẹ Ni Ki A Ṣe”

Mose jọwọ ara rẹ silẹ fun ifẹ Ọlọrun ni igba ikú rẹ gẹgẹ bi igba ti o wà laaye. Ki i ṣe gbogbo eniyan ni o mọ akoko ti oun yoo kú, ṣugbọn Ọlọrun sọ ọ fun Mose. Lẹsẹkẹsẹ ni Mose rọ nipa awọn Ọmọ Israẹli, o si bẹ Ọlọrun lati yan aṣaaju kan fun wọn, ki wọn má ba dabi agutan ti kọ ni oluṣọ (Numeri 27:16, 17). Mose kọ ṣe awawi, bẹẹ ni kọ ba Ọlọrun jiyan lori ẹni ti yoo ṣe arọpo rẹ ati nipa ikú rẹ. Ọlọrun yan Joṣua lati rọpo rẹ. Mose ki Joṣua laya, o si fi iṣẹ aṣaaju le e lọwọ niwaju gbogbo eniyan (Numeri 27:22, 23; Deuteronomi 31:7, 8).

Mose lo ọpọlọpọ ọdun ninu ayé, ṣugbọn kọ dagba to awọn miiran ninu awọn baba nla rẹ. Mose jé ẹni ọgọfa (120) ọdun nigba ti o kú, nigba ti baba rẹ Amramu jé ẹni ogoje ọdun o din mẹta (137), baba rẹ agba Kohati jẹ ẹni aadoje ọdun o le mẹta (133), baba-baba rẹ agba, Lefi si jẹ ẹni ogoje ọdun o din mẹta (137) (Ẹksodu 6:16-20). Mose ṣiṣẹ fun Ọlọrun nigba aye rẹ, nigba ti Ọlọrun si sọ fun un pe ki yoo wà laaye mó, Mose ni itẹlọrun lati ṣe ifé Ọlọrun. Iṣẹ rẹ ti pari: o ti mú awọn Ọmọ Israẹli de bẹbe Kenaani; o ti kó wọn ni orin kan nipa aanu ati ẹsan Ọlọrun, o si ti sure fun awọn ẹya Israẹli nigba ti o n dágbere fun wọn.

Ọlọrun ti ṣe itọju Mose daradara nitori nigba ti o di ẹni ọgọfa ọdun paapaa, ojú rẹ riran kedere, kọ ṣe baibai, bẹẹ si ni agó ara rẹ dara pẹlu. Mose kọ dubulẹ aisan ni ireti ikú. O rin lọ sori oke lati lọ wà pẹlu Ọlọrun.

Riri Kenaani Lokeere

Oluwa ti ṣeleri fun Mose pe yoo ri ilẹ ileri lokeere nibi ti awọn Ọmọ Israẹli n lọ. Bi Mose ti gun ori Oke Pisga, dajudaju inu rẹ dun, nitori o n gbọran si Ọlọrun lẹnu. Dipo ki o maa banujẹ nitori o n fi awọn Ọmọ Israẹli silẹ, inu Mose dùn lati lọ wà pẹlu Oluwa.

Lati ṣonṣo ori oke yii, Mose le ri ilẹ naa nitosi ati ni ọna jijin réré, ilẹ ti yoo jẹ ti awọn Ọmọ Israẹli. Lati ilẹ Gileadi ni iha ila-oorun Odo Jordani, si iha iwọ-oorun titi de okun; lati gbogbo ilẹ Naftali ni iha ariwá titi de gbogbo ilẹ Juda ni guusu -- pẹtẹlẹ, afonifoji, ati awọn ilu nlá nlá -- Mose ri ilẹ naa ti o n ṣàn fun wara ati fun oyin.

Ọlọrun Sinku Rẹ

Lati Kenaani ti ayé yii nibi ti Mose ko ni le dé, o gbé oju rẹ si oke Ọrun nibi ti o n mura lati wọ. “Olododo ni ireti ninu ikú rẹ” (Owe 14:32), ati “lati kú jẹ ere” (Filippi 1:21).

Ki i ṣe Mose nikan ni o wà lori oke naa nitori Ọlọrun wà pẹlu rẹ (Orin Dafidi 23:4). Ọlọrun ṣe itọju Mose, kọ si jẹ ki awọn eniyan sinkú rẹ, boya, ki wọn má ba ṣe iboji rẹ, ki wọn si maa bọ ọ. Onisaamu wi pe, “Iyebiye ni ikú awọn ayanfẹ rẹ li oju OLUWA” (Orin Dafidi 116:15).

Siṣọfọ Fun Mose

Awọn Ọmọ Israẹli ṣọfọ Mose fun ọgbọn ọjọ gẹgẹ bi wọn ti ṣe fun Aarọni arakunrin rẹ (Numeri 20:29). Nipa ti ara, wọn yoo padanu rẹ, ati adura rẹ, ati imọran rẹ pẹlu. Gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, wọn ni ireti pe wọn yoo tun ri, wọn kọ si banujé “gẹgẹ bi awọn iyoku ti kọ ni ireti” (1 Tẹssalonika 4:3).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ẹni ọdun meloo ni Mose nigba ti o kú?
  2. Ki ni ṣe ti ẹnikẹni kọ mọ ibi ti iboji rẹ wà?
  3. Ki ni iran nlá nla ti o ri ki o to kú?
  4. Sọ ipo ti agó ara Mose wà?
  5. Iṣẹ wo ni Mose pari rẹ ki o to kú?
  6. Ki ni ṣe ti Mose kọ rẹwẹsi nigba ti o mọ pe oun fẹ kú?
  7. ỌỌjọ meloo ni awọn Ọmọ Israẹli fi ṣọfọ rẹ?