Johannu 10:1-18, 22-42

Lesson 144 - Junior

Memory Verse
“Emi ni oluṣọ-agutan rere: oluṣọ-agutan rere fi ẹmí rẹ lelẹ nitori awọn agutan” (Johannu 10:11).
Notes

Si Ọna Titọ

Jesu wá si aye lati jẹ Oluṣọ-agutan Rere ti yoo tọ awọn agutan Rẹ si ipa ọna otitọ. Awọn Ọmọ Israẹli jẹ eniyan ti Ọlọrun yàn, “agutan papa rẹ,” ṣugbọn wọn ti dẹṣẹ pupọ to bẹẹ ti Ọlọrun fi jẹ ki a tú wọn kaakiri gbogbo aye. Ọpọlọpọ awọn ọba ati alufaa, ti wọn jẹ oluṣọ-agutan wọn ni atetekọṣe, ti di eniyan buburu, wọn si ti mú awọn Ọmọ Israẹli ṣako. Nisisiyii Jesu wá lati kó awọn otoṣi aṣako wọnyii pada sinu agbo alaafia lẹẹkan si i. A sọ nipa ti Jesu ni akoko kan ti O n waasu fun ogunlọgọ eniyan: “nu wọn ṣe e, nitoriti ãrẹ mu wọn, nwọn si tuká kiri bi awọn agutan ti ko li oluṣọ” (Matteu 9:36).

Ṣugbọn ki i ṣe pupọ ninu awọn “agutan” wọnni ni wọn fẹ ki a gbà wọn là. Jesu tọ awọn ti Rẹ wá, ṣugbọn awọn ti Rẹ kò gba A. “Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun” (Johannu 1:12). Awọn ti o gba A kò ju iba agbo kekere lọ, ṣugbọn wọn mà fẹran Oluwa o! Wọn ba A lọ sibikibi ti O ba lọ. Ni akoko kan nigba ti awọn ọpọlọpọ eniyan pada lẹyin Jesu, O beere lọwọ awọn oloootọ diẹ ti o duro ti I boya awọn paapaa fẹ pada sẹyin. Peteru dahun pe, “Ọdọ tali awa o lọ? iwọ li o ni ọrọ iye ainipẹkun” (Johannu 6:68).

Agutan Miiran

Nigbà ti awọn Ju kọ lati gbọ ti Jesu, O kọjú si awọn Keferi. O sọ fun awọn eniyan naa pe: “Emi si ni awọn agutan miran, ti ki iṣe ti agbo yi: awọn li emi kò le ṣe alaimu wá pẹlu, nwọn ó si gbọ ohùn mi; nwọn o si jẹ agbo kan, oluṣọ-agutan.” Ati Ju ati Keferi ni lati wá nipasẹ Jesu ki a ba le gbà wọn là; gbogbo awọn ti o ba ri igbala si jẹ ti agbo kan, eyi ti Jesu jẹ Olori Oluṣọ-agutan fun.

Agutan Alailagbara

Olukuluku agutan ni o gbọdọ ni oluṣọ-agutan. Agutan kò le dá ile mọ, ti o ba si sọnù kò le nikan pada saarin agbo mọ. Wò bi apejuwe Isaiah ni fifi wa wé agutan ti ṣe deede to: “Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹle ọna ara rẹ (Isaiah 53:6).

Lati igba ti a ba ti bi ọmọ ni o ti maa n fi iwa ẹṣẹ hàn. Oun a binu a si ke bi wọn kò ba tẹ ẹ lọrun. Bi o ti n dagbà si i bẹẹ ni titẹ si iwa buburu yii n dagba pẹlu rẹ; bi a kò ba si kó wọn ni ijanu ọmọ naa le di eniyan buburu patapata. Iwa ẹda ni fun eniyan lati kọ ẹyin si Ọlọrun, ati lati tẹle itanjẹ Satani. Iṣubu awọn obi wa àkọkọ ninu Ọgba Edẹni ni o gbé ẹda ẹṣẹ yii wọ gbogbo eniyan.

Agutan ki i gbiyanju lati wẹ ara rẹ mọ. Awọn ẹyẹ ati ajá maa n gbadun liluwẹ ninu omi, awọn ologbo a si maa lo akoko pupọ lati fi wẹ ara wọn. Ṣugbọn ni ti agutan, rárá kò le wẹ ara rẹ mọ! O maa n wa ninu eeri titi di igbà ti yoo ri ẹni kan lati wẹ ara rẹ fun un.

O dabi ẹni pe eniyan ti kò ni Ọlọrun maa n tẹ si iwa buburu nigba gbogbo. Oun kò le wẹ ẹṣẹ rẹ mọ. Bi kò ba ṣe ti Ẹmi Ọlọrun ninu aye, ti n dá awọn eniyan lẹbi fun ẹṣẹ, wọn kì ba ti le gbiyanju lati yi ọna wọn pada. Ẹlẹṣẹ jẹ alailagbara lati wẹ ara rẹ mọ kuro ninu ẹṣẹ, gẹgẹ bi agutan ti kò le wẹ eeri ara rẹ mọ.

Ilẹkun Agbo-Agutan

Jesu wi pe Oun ni Oluṣọ-agutan Rere, O si tun sọ pe Oun ni Ilẹkun awọn agutan. O fi kun un pe Oluṣọ-agutan rere ni lati ba Ẹnu-ọna wọle. Bawo ni Jesu ṣe le jẹ Ilẹkun, ki O si tun ba ibẹ wọle? Johannu sọ fun ni pe Ọlọrun ni Ọrọ naa, Ọrọ naa si di ara O si n ba wa gbe. Eyi n sọ nipa Jesu. Jesu si bá Ọrọ wọle ni ti pe O mu awọn asọtẹlẹ ti awọn wolii Majẹmu Laelae ti kọ silẹ nipa Messia tabi Oludande ti yoo dé ṣẹ.

Niti awọn wolii ẹké, Ọlọrun sọ lati ẹnu Jeremiah pe: “Emi kò ran awọn woli wọnyi, ṣugbọn nwọn sare: emi kò ba wọn sọrọ, ṣugbọn nwọn sọ asọtẹlẹ” (Jeremiah 23:21). Awọn wọnyii ni olẹ ati ọlọṣa ti o ti wá ki Jesu to de si aye. Wọn kò ti ipasẹ Ọrọ Ọlọrun, tabi ipasẹ Iwe Mimọ, tabi ipasẹ Ẹnu-ọna wọle. Ọlọrun kò rán wọn. Ẹnikẹni ti o le tun de lẹyin naa, ti o pe ara rẹ ni Kristi naa yoo jẹ olẹ ati ọlọṣà. Kò si ọna miiran lati ri igbala ju lati wá nipasẹ Jesu -- Ọrọ naa – ati Ẹjẹ Rẹ ti O ta silẹ ni Kalfari.

Oluṣọ-Agutan Tootọ

Oluṣọ-agutan rere fẹràn awọn agutan rẹ, a si maa tọjú wọn tọsan-toru, ni akoko otutu ati ni akoko ooru; a maa fi igbesi aye rẹ daabo bò wọn. Jesu wi pe oluṣọ-agutan rere yoo tilẹ fi ẹmi rẹ lelẹ fun agutan rẹ. A ranti pe nigba ti Dafidi jẹ ọdọmọkunrin oluṣọ-agutan, o pa kiniun ati àmọtẹkun ti wọn gbiyanju lati gbé awọn ọdọ-agutan lọ lati inu agbo baba rẹ. Oun kò sa lọ nigbà ti o ri i ti kiniun naa n bọ, bẹẹ ni kò fi agbo agutan rẹ silẹ fun ẹranko buburu naa lati fàya ati lati pa jẹ. N ṣe ni o duro titi sibẹ ti o si ba kiniun naa jà titi o fi kú. Bẹẹ ni o si ṣe si àmọtẹkùn naa.

Nigba ti awọn akọwe ati awọn Farisi bẹrẹ si ṣe inunibini si Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin Rẹ fun wiwaasu pe Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe, Oun kò dá iwaasu Rẹ duro. Bi o tilẹ jẹ pe ọranyan ni pe ki O kú nitori Ihinrere Rẹ, tọkantọkan ni O fi ṣe e, pe ki gbogbo awọn ẹni ti o ba gbagbọ ba le ri igbala nipa Ẹjẹ Rẹ ti Ó ti ta silẹ. I ba rọrun pupọ fun Jesu bi o ba ṣe pe O dá iṣẹ-iranṣẹ Rẹ duro. A kì ba ti ṣe inunibini si I tabi ki wọn kàn An mọ agbelebu; ṣugbọn bẹẹ ni ọna ki ba ti si fun wa lati ni idariji ẹṣẹ wa, a ki ba si ti ni anfaani ṣiṣe wá yẹ fun Ọrun.

Awọn Ajeji Oluṣọ-agutan

Jesu wi pe awọn àjẹji oluṣọ-agutan ti jade lọ sinu aye lati kó agbo jọ, ṣugbọn awọn agutan Ọlọrun tootọ kò ka iru awọn oluṣọ-agutan bẹẹ si, wọn kò si ni jẹ ki a ṣi wọn lọna. Awọn àjẹji oluṣọ-agutan wà ninu aye lode oni. Awọn kan n sọ pe kò ṣe danindanin fun awọn eniyan lati gbadura agbayọri fun idariji ẹṣẹ wọn, ki wọn to le yẹ lati pade Jesu. Olẹ ati ọlọṣà ni iru awọn eniyan bẹẹ, awọn ẹni ti o ba si tẹti si ti wọn yoo di olẹ pẹlu. Wọn n fẹ lati fo odi (ogiri) dipo ki wọn bá ẹnu-ọna wọ inu agbo. Awọn oluṣọ-agutan alagbaṣe wọnyii a maa waasu ohunkohun ti awọn eniyan ba n fẹ lati gbọ, ki wọn ba le ri owó gbà lọwọ wọn. Awọn ọmọ-ẹyin oluṣọ-agutan, awọn alufa oloootọ, n waasu otitọ Ọrọ Ọlọrun nitori wọn fẹran awọn eniyan, wọn si fẹ rí i pé wọn murasilẹ fun Ọrun, ki wọn má ba ṣegbe ni ayeraye.

Ounjẹ Agutan

Nigba ti Jesu pe Peteru lati di ọmọ-ẹyin oluṣọ-agutan, O wi pe, “Mã bọ awọn agutan mi” (Johannu 21:16). Ounjẹ Onigbagbọ wà ninu Bibeli -- ounjẹ ti ẹmi. Jesu wi pe, “Emi li onjẹ iye.” “Nitoripe onjẹ Ọlọrun li ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ti o si fi iye fun araiye” (Johannu 6:35, 33).

Awọn oniwaasu ti kò waasu pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe, Ẹni ti O kú, pe nipa Ẹjẹ Rẹ ti a ti ta silẹ ni a ti le ri igbala, n fi ebi pa agbo wọn. Bi a ba waasu Jesu, a o waasu ibi Rẹ nipasẹ Maria wundia, igbesi-aye Rẹ ailẹṣẹ, ikú Rẹ lori agbelebu fun ẹṣẹ wa, ajinde Rẹ, ati bibọ Rẹ lẹẹkeji. A o kọ ni ni gbogbo Ọrọ naa: idalare nipa igbagbọ; isọdimimọ ti i ṣe wiwà ni mimọ fun Ọlọrun; ati ifiwọni Ẹmi Mimọ. Eyi ni ounjẹ Onigbagbọ. Bi wọn kò ba gbọ ki a waasu ẹkúnrẹrẹ Ọrọ Ọlọrun, ebi ẹmi yoo pa wọn kú.

A Sọ Agutan Ni Orukọ

Jesu ni Oluṣọ-agutan Rere nigbà ti o wà ninu aye, Oun si ni Oluṣọ-agutan sibẹ fun olukuluku Onigbagbọ tootọ. O ti fi Ẹjẹ Rẹ rà wọn, O si fẹran wọn, O si n ṣe itoju wọn. O ti ṣe ileri lati mú wọn lọ si inu pápá oko tutu lẹba iṣan-omi didan, ti o si mọ gaara. “Kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrin dede” (Orin Dafidi 84:11).

Jesu mọ orukọ agutan Rẹ kọọkan. A kò kere jù bẹẹ ni a kò jinna ju fun Un lati ni ikẹ Rẹ. Ifẹ ayeraye ni O fi fẹ wa, O si ti ṣe ileri pe kò si ẹni ti yoo le já wa gbà kuro lọwọ Baba. Ọna kan ṣoṣo ti agutan le fi sọnu ni pe ki o fi idánú tabi ipinnu ara rẹ ṣako lọ.

Agutan ti O Nù

Boya agutan kan ti duro ni ita lẹba agbo. O jẹ koriko, kò si wòke, o jẹ ẹ titi o fi jinnà si awọn agutan iyoku. Ki i ṣe pe o pinnu lati ṣako lọ, ṣugbọn o dabi ẹni pe koriko ti o wà ni okeere diẹ tutu ju ti itosi lọ, agutan naa kò si wo oluṣọ-agutan. Lai pẹ, kò si koriko mọ -- apata nikan ati ẹgun oṣuṣu ni o yi i ka. Nigba ti agutan naa gboju soke, oun nikan ni o wà nibẹ o si bẹrẹ si ké. Ṣugbọn ẹnikẹni kò si ni tosi lati gbọ.

Ni aṣalẹ naa nigba ti oluṣọ-agutan da awọn agbo-ẹran rẹ wọle, o kà wọn, ọkan sọnu. O ha wi pe: “Eyi kò ṣe nnkan kan. Ki ni agutan kan jẹ laaarin ọpọlọpọ ti mo ni? Mo le gboju fo o”? Rara! O wi pe, “Ọkan sọnu ninu awọn agutan mi, mo si ni lati lọ wá a lẹsẹkẹsẹ.” Nigba ti o si di oru, nigba ti okunkun ati otutu ti bolẹ, o n rin kiri laaarin awọn apata ati ẹgún titi o fi gbọ igbe agutan ti o sọnu naa. O gbé e o si mu un pada sinu agbo. Bawo ni inu agutan naa ti dùn to lati wà lai lewu lẹẹkan si i laaarin awọn agutan iyoku! Lẹyin eyi, lai ṣe aniani, o ṣọra o si ri i pe ni igbà gbogbo ni oun n wà ni aarin agbo.

Jesu wi pe bi Oun ti fẹran awọn agutan Oun ni yii, awọn Onigbagbọ tootọ. Boya ẹni kan jẹ lọ si ẹba agbo, oluwarẹ kò si tẹ oju rẹ mọ Oluṣọ-agutan nipa gbigbadura ati kika Ọrọ Ọlọrun. Ni ọjọ kan o wa ri i pe oun ti wà lẹyin agbo Ọlọrun: oun ti tun lọ sinu ẹṣẹ. Ṣugbọn Jesu fẹran rẹ sibẹ, Oun o si jade lọ wá agutan naa nitori ẹni ti O fi ẹmi Rẹ lelẹ, ṣugbọn ti o ti ṣako lọ. Awọn angẹli ni Ọrun paapaa yoo yọ nigba ti ẹni ti o ti nù naa ba pada sinu agbo.

Ẹ jẹ ki a tẹle Oluṣọ-agutan Rere pẹlu idaniloju pe ipa-ọna ti O ti yàn ni o lọ si Ọrun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni Oluṣọ-agutan Rere?
  2. Awọn wo ni agutan?
  3. Awọn wo ni awọn “agutan ile Israẹli ti o nù”?
  4. Bawo ni Jesu ṣe jẹ Ilẹkun fun awọn agutan?
  5. Ki ni Jesu pe awọn wọnni ti kò bá Ẹnu-Ọna wọle?
  6. Awọn wo ni wolii ẹké lonii?
  7. Ki ni Jesu ṣe nigba ti O ri i pe agutan kan sọnu?