Lesson 145 - Junior
Memory Verse
“Emi ni ajinde, ati ìye: ẹniti o ba gbà mi gbọ, bi o tilẹ kú, yio yẹ” (Johannu 11:25).Notes
Aisan
Jesu lọ bẹ Maria, Marta ati Lasaru wò, Marta ti ṣe iyọnu lati ṣe ounjẹ ati lati fi fun Jesu (Luku 10:40). Maria ni o jokoo lẹba ẹsẹ Jesu lati kọ ẹkọ lọdọ Rẹ (Luku 10:39). Ni isin irẹlẹ, Maria fi ororo ikunra olowó iyebiye kùn Un ni ẹsẹ (Johannu 12:3). Lai ṣe aniani Jesu ti wà pẹlu ẹbi yii ni igba pupọ, nitori O fẹran wọn.
Ninu ile yii ti wọn ti gba Jesu ni alejo, ati inu igbesi-aye ọkunrin kan ti Jesu fẹran, ni aisan wọ. A ka ninu Oniwasu 9:2 pe “Bakanna li ohun gbogbo ri fun gbogbo wọn.” ki i ṣe pe awọn alaiwa-bi-Ọlọrun nikan ni o n ṣaisan, tabi pe a dá awọn olododo si ki wọn má ṣe ṣaisan. Nigbà ti ara Onigbagbọ ba ṣe alaida, yoo gbẹkẹle Oluwa fun iwosan gẹgẹ bi Bibeli ti kọ ọ lati ṣe. “Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? Jẹ ki o gbadura … Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pẹ awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rẹ, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa: adura igbagbọ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide” (Jakọbu 5:13-15).
Nigbà ti ara Lasaru kò dá, awọn arabinrin rẹ ranṣẹ si Jesu, gẹgẹ bi a ti n ṣe nigbà ti a ba gbadura. Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹyin pe aisan Lasaru jẹ fun ogo Ọlọrun. O si wi pe aisan Lasaru kò ni yọri si ikú ṣugbọn pe Ọmọ Ọlọrun yoo di ayinlogo.
Ilọra
A le ro pe Jesu yoo lọ sọdọ Lasaru lẹsẹkẹsẹ. Jesu kò ṣe bẹẹ lakoko yii. Fun ọjọ meji, O n ba iṣẹ Rẹ lọ ni ibi kan naa, niwọn bi oye wa ti mọ, ki O to mẹnu ba lilọ sọdọ Lasaru rara. Boya eyi jẹ lati yiiri igbagbọ Lasaru ati awọn arabinrin rẹ wò. A kò mọ boya Jesu tilẹ ranṣẹ si wọn rara, ṣugbọn ilọra Rẹ kò fi hàn pe Oun kò ni i lọ. Lai ṣe aniani, nipa aitete lọ Kristi, Ọlọrun di ayinlogo ju pe ki a ti wo Lasaru sàn ni gẹrẹ ti o ti bẹrẹ si ṣaisan. Jesu wi pe eredi ilọra naa ni lati fun wọn ni igbagbọ si i ati lati mu ki o jinlẹ si i ninu ọkàn wọn.
Agbara Jesu i ba ti mu Lasaru lara da lai tilẹ jẹ pe Jesu wa nibẹ nitori Ọrọ Jesu mu awọn ẹlomiran lara da. Nigba ti ara ọmọ-ọdọ balogun ọrun kò dá, ọga rẹ tọ Jesu wa o wi pe, “Sọ kiki ọrọ kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada.” Ẹnu ya Jesu si igbagbọ balogun ọrun naa, O si wi fun un pe yoo ri fun un gẹgẹ bi igbagbọ rẹ. A si mu ọmọ-ọdọ naa lara da ni wakati kan naa (Matteu 8:5-13). Ni akoko miiran, Jesu wo ọmọbirin obirin ara Sirofenikia sàn lai si ni tosi rẹ. Iya naa tọ Jesu lọ nitori ọmọbirin rẹ. “O si bẹ ẹ ki on iba lé ẹmi ẹṣu na jade lara ọmọbirin rẹ” (Marku 7:26). Jesu yẹ igbagbọ rẹ si, O si wi fun un lati maa ba ti rẹ lọ, a “si mu ọmọbirin rẹ larada ni wakati kanna” (Matteu 15:28). Iya yii lọ si ile o si ri i bẹẹ.
Lonii paapaa awọn eniyan ti n gbe ni ọpọlọpọ ibusọ si ile-isin to bẹẹ ti kò ṣe e ṣe lati fi ororo kùn wọn lori ki a si gbadura le wọn lori, maa n ri iwosan. Wọn a kọ iwe-ẹbẹ ranṣẹ fun adura, awọn eniyan Ọlọrun a si gbadura fun imularada wọn. Ogunlọgọ eniyan ni wọn ti ri iwosan nipa igbagbọ ninu Jesu bi o tilẹ jẹ pe ibùgbe wọn jinna pupọ. Ṣugbọn Jesu kò fi ọna bayii gbe Lasaru dide.
Jesu ninu Ewu
Nigba ti Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pe wọn n lọ si ọdọ Lasaru, wọn lodi si i, wọn si rán Jesu leti pe awọn Ju ti wá ọna lati sọ Ọ ni okuta (Johannu 8:59; 10:31). Jesu kò bikita pupọ nipa ewu nigba ti iṣẹ ba wà lati ṣe. O ni lati ṣe iṣẹ Rẹ nigba ti anfaani wà nitori O wi pe oru ati okunkun n bọ nigba ti ẹni kan ki yoo le ṣe iṣẹ (Johannu 9:4).
Lai fi ewu pẹ, Jesu lọ sọdọ Lasaru, ẹni ti o ti kú ni akoko yii, Jesu mọ pe akoko to lati fi ogo Ọlọrun hàn. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin pe Lasaru ti sùn ati pe Oun yoo ji i dide kuro ninu oorun ikú. Awọn ọmọ-ẹyin ba Jesu lọ, ni aimọ boya a o ti ipa ọwọ awọn Ju sọ Oun ati awọn ni okuta.
Ni Bẹtani
Jesu kò lọ si ọdọ Maria ati Marta lati tù wọn ninu nikan. O ni ero ti o ga ju bẹẹ lọ ninu ọkàn Rẹ -- iṣẹ-iyanu fun ogo Ọlọrun. Ile wọn wà ninu ibanujẹ, nitori o ti di ọjọ kẹrin ti wọn ti sin Lasaru. Pupọ ninu awọn ọrẹ wọn wà nibẹ lati tù wọn ninu, ṣugbọn wọn n foju sọna fun Ọrẹ ti o dara ju lọ, Jesu.
Marta lọ pade Jesu. O mọ pe Oun le ṣe ki arakunrin wọn ma kú. O gbagbọ pe oun yoo tun ri Lasaru ni Ọjọ Ajinde.
Jesu wi pe, “Emi ni ajinde, ati iye: ẹniti o ba gbà mi gbọ, bi o tilẹ kú, yio ye.” Jesu ni gbogbo agbara ni Ọrun ati ni aye (Matteu 28:18) – agbara lati sọ ni di alaaye ati agbara lati wo alaisan sàn. Marta sọ pe oun gbagbọ pe Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe, ati pe adura Rẹ le gbà fun ohunkohun.
Marta tọ arabinrin rẹ lọ, pẹlu iroyin pe Oluwa ti de, O si n pẹ e. Maria lọ ba Jesu, o jẹwọ igbagbọ rẹ ninu agbara Rẹ lati wosan. I ba ṣe pe Jesu ti wà nibẹ, oun i ba ti bẹ Ẹ ki O wo arakunrin oun sàn; ṣugbọn o ro pe O dé pẹ jù.
Wọn lọ fi ibi ti wọn tẹ Lasaru si hàn Jesu. Ọkàn ibanikẹdun Jesu gbọgbẹ bi O ti ri Maria ati awọn iyoku ti wọn n sọkun. Ọmọ Ọlọrun ni O jẹ ṣugbọn eniyan ni pẹlu, O si fi ibanujẹ Rẹ hàn, nitori O sọkun bi O ti n lọ si iboji Lasaru.
Ni Iboji
Awọn eniyan ti n ṣọfọ ni wọn duro lẹba iboji Lasaru ni ọjọ naa. Wọn kò mọ pe lai pẹ iṣẹ-iyanu nlánlà kan yoo ṣẹlẹ nibẹ. Lakọkọ wọn kò ṣú si aṣẹ Jesu nigbà ti O wi fun wọn pe ki wọn gbé okuta ẹnu ọna iboji naa kuro. Wọn rò pe ireti kọja, nitori dajudaju ni akoko naa ara Lasaru yoo ti dibajẹ.
Ni akoko kan Jesu kò ṣiṣẹ àmi nitori aigbagbọ awọn eniyan (Matteu 13:58). Nigba ti awọn kan wi pe ọmọbirin Jairu kú, Jesu wi fun baba rẹ pe, “Má bẹru: gbagbọ nikan ṣa” (Luku 8:50). Fun baba ọmọ kan ti ẹmi eṣù n dà láàmú Jesu wi pe, “Bi iwọ ba le gbagbọ, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ” (Marku 9:23). Awọn eniyan a maa wi pe “Riri ni igbagbọ”, ṣugbọn Jesu yi ọrọ naa pada, O si wi pe bi wọn ba gbagbọ wọn o ri. Jesu wi pe “Ohunkohun gbogbo ti ẹnyin ba bẹre ninu adura pẹlu igbagbọ, ẹnyin o ri gbà” (Matteu 21:22). Awọn eniyan yoo ri ifarahàn ogo Ọlọrun ju bẹẹ lọ lonii bi wọn ba ni igbagbọ ju bẹẹ lọ ninu Ọlọrun.
Ọrọ Jesu ki awọn ti o duro yika iboji Lasaru laya, wọn si gbe okuta naa kuro. Jesu gbe oju Rẹ soke O si gbadura – ki i ṣe adura lori aini bi ko ṣe idupẹ, pe Ọlọrun ti gbọ ti Rẹ ná ati pe Oun yoo gba ogo lati ọdọ awọn ti wọn yi I ká.
Boya awọn ọmọ-ẹyin n wi laaarin ara wọn pe, “Kò ha wi pe n ṣe ni Lasaru sùn, ati pe Oun o ji i dide? Oun kò ha wi pe aisan Lasaru ki i ṣe si iku? Ki ni itumọ ọrọ Rẹ, tabi ki i ṣe Lasaru ni o kú ti wọn si ti sin yii?” Oye Ọrọ Jesu fẹrẹ yé wọn ná.
Ẹmi Titun
Wọn gbọ Jesu kigbe ni ohùn rara, “Lasaru, jade wá.” Wọn ri ẹni ti o ti kú fun ọjọ mẹrin, o si jade wá pẹlu aṣọ isinku ti a fi de ọwọ ati ẹsẹ rẹ. Ni aṣẹ Jesu wọn tú u. Lasaru wà laaye nipa agbara Jesu. Ayọ yoo ti pọ to ni ọjọ naa! Ẹkún ati ibanujẹ ni o ti wà ki Jesu to de. Nipa ọrọ ti O sọ, O yi gbogbo rẹ pada si ayọ. Ni tootọ nitori igbagbọ wọn ninu agbara Jesu, Lasaru yẹ, bi o tilẹ jẹ pe o ti kú.
Agbara Jesu kò mọ sibẹ. Ọpọlọpọ awọn eniyan ti wọn ti kú ninu ẹṣẹ (Kolosse 2:13) ni wọn gbọ ohùn Jesu bi O ti pe orukọ wọn. Wọn jade wá lati maa rin ni ọtun iwa (Romu 6:4), nitori wọn gbagbọ pe ninu Jesu ni ajinde ati iye wà. A ti dẹ wọn tọwọ-tẹsẹ; ṣugbọn wọn le ba Onisaamu sọ fun Oluwa bayii, “Iwọ ti tú ìde mi” (Orin Dafidi 116:16). Ohun ti Jesu ṣe fun Lasaru nipa ti ara, Oun yoo ṣe e lonii nipa ti ẹmi.
Olukuluku ẹlẹṣẹ dabi Lasaru nigbà ti o wà ninu iboji -- okú, ti a dẹ, ti o si wà ninu okunkun. Olukuluku Onigbagbọ dabi Lasaru lẹyin ti a ti ji i dide ninu iboji – o ni iye. A ti tú ide ẹṣẹ rẹ kuro. O wà ninu imọlẹ o si n rin ninu imọlẹ (Johannu 8:12).
Aisan Lasaru jẹ fun ogo Ọlọrun. Dajudaju lati ji okú dide tobi ju ṣiṣai jẹ ki ikú pa ni. Ọpọlọpọ awọn Ju ti lọ tu Maria ati Marta ninu. Wọn ba awọn eniyan iyoku pejọ ni iboji naa. Wọn ti ri agbara Jesu ti n ṣiṣẹ iyanu. Ọpọlọpọ ṣe ju riri lọ -- wọn ni igbagbọ ninu Jesu. Ọpọlọpọ ni wọn ri, ṣugbọn iba awọn ti o gbagbọ ni wọn ni iye ainipẹkun (Johannu 3:36).
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti Lasaru fi ṣaisan?
- Ki ni awọn arabirin rẹ ṣe?
- O pẹ to igba wo ti Lasaru ti kú?
- Bawo ni a ṣe ji i dide?
- Ki ni ṣe ti ọpọlọpọ eniyan fi pejọ si iboji naa?
- Bawo ni Ọlọrun ṣe gba ogo?
- Ki ni ileri ti a ṣe fun awọn ti o ba gba Oluwa gbọ?