Johannu 11:47-54; Luku 13:10-17

Lesson 146 - Junior

Memory Verse
“Ko si ẹnikan ti o ni ifẹ ti o tobi jù eyi lọ, pe ẹnikan fi ẹmí rẹ lelẹ nitori awọn ọrẹ rẹ” (Johannu 15:13).
Notes

Iwosan Obirin ti O Yarọ

Jesu n bá iṣẹ rere Rẹ lọ: O n dari ẹṣẹ ji, O n wo olokunrun sàn, O si n fi ayọ sinu ọkàn awọn ti o rẹlẹ nibikibi ti O ba lọ. Ṣugbọn awọn akọwe ati awọn Farisi kò fẹ ri ohun rere kan ninu ohun ti Jesu n ṣe. Oun ti ba wọn wi nitori ọkàn ẹṣẹ wọn, wọn si n jowú ayọ ti O n fi fun awọn ti o gba A gbọ.

Ni Ọjọ Isinmi kan, nigba ti Jesu n waasu ni sinagọgu kan, O kiyesi obinrin kan ti o yarọ. Obinrin yii wa sinu sinagọgu lati sin Ọlọrun, boya kò tilẹ ni ireti pe oun yoo tun sàn mọ, ṣugbọn lai kà irora rẹ yii si, o fẹran Ọlọrun sibẹ. Nigba ti Jesu ri i, O pe e wa sọdọ ara Rẹ, O si wo o sàn.

Ẹyin obinrin yii ti kákò fun ọdun mejidinlogun, o si ni lati maa wo ilẹ nigba gbogbo. O le duro daadaa nisisiyii bi gbogbo eniyan. Rò bi inu rẹ yoo ti dun to!

Kò Si Ifẹ

Njẹ inu olori sinagọgu yii dùn pe a ṣe iṣẹ-iyanu ninu ile-isin rẹ? Rara o. O dabi awọn akọwe ati awọn Farisi iyoku ti wọn wi pe, “Mu u kuro, mu u kuro.” Wọn kò fẹ ki Ọkunrin oloootọ yii jọba lori wọn. O wi pe Jesu n ba Ọjọ Isinmi jẹ. Njẹ iwọ le fi oju inu wo erò rẹ pe kò tọ lati wo otoṣi obirin alabuku ara yii sàn ni Ọjọ Isinmi? Bi olori sinagọgu yii ba ni ifẹ ninu ọkàn rẹ, oun i ba ba obirin naa yọ pe Ẹni-iyanu bayii wà ti o le wo olokunrun sàn.

Ọmọ Abrahamu

Awọn Ju ro ara wọn si ẹni ti o sàn ju awọn orilẹ-ẹde miiran lọ. Bi obirin yii bá jẹ Keferi, olori sinagọgu naa i ba ti rò pe oun ni idi ti o tọna lati hu iru iwa bẹẹ; ṣugbọn “ọmọbirin Abrahamu” ni oun i ṣe. Ju ni obinrin naa, o si ni ẹsin kan naa pẹlu olori sinagọgu yii – titi Jesu fi wò o san. Lẹyin naa ni o gbà Jesu gbọ.

Jesu sọ fun awọn akọwe ati awọn Farisi pe wọn yoo kó agbo ẹran wọn jade lati fun wọn ni omi ni Ọjọ Isinmi. Wọn n ronu nipa ẹran wọn, wọn si n fi aanu hàn fun wọn, ṣugbọn wọn kò bikita fun obinrin yii ti o ti jiya fun ọdun mejidinlogun. Nigba ti Jesu ba wọn sọrọ bayii, oju ti wọn. Awọn ọrẹ obinrin yii si yọ gidigidi.

Iṣẹ-iyanu ti o Tobi Ju

Jesu ti ṣe iṣẹ-iyanu miiran ti o tobi, ti o si mu ariyanjiyan wà laaarin awọn eniyan. O ti ji Lasaru dide kuro ninu okú.

Ọpọ awọn Ju ti wa ba Maria ati Marta ṣọfọ fun ikú arakunrin wọn; nigbà ti wọn si ri iṣẹ iyanu ti o mu un pada wà laaye, awọn miiran ninu wọn gbagbọ pe Jesu ni Messia naa. Ta ni ẹlomiran ti o tun le mu ẹni ti o ti kú lati ọjọ mẹrin sẹyin pada wà laaye? Ṣugbọn awọn miiran wà ti inu bi nitori iṣẹ nla naa ti Jesu ti ṣe. Wọn lọ sọdọ awọn olori ẹsin wọn, awọn igbimọ Sanhedrin, wọn si n fẹ ki wọn dá iṣẹ ti Jesu n ṣe duro. Wọn n jiyan bi iṣẹ iyanu bayii ba n lọ bẹẹ, awọn eniyan yoo fi ẹsin awọn Ju silẹ, wọn yoo si pejọ sọdọ Jesu, wọn yoo si fẹ fi I jọba.

Ninu Ide

Awọn Ju wà labẹ isinru awọn ara Romu, ṣugbọn niwọn bi wọn ti n gbe ni idakẹ jẹẹ, awọn ara Romu gbà wọn láyẹ lati sin gẹgẹ bi wọn ti n fẹ, wọn si gba olori alufa ni àyẹ lati maa ṣe akoso ni iwọnba. Nisisiyii, bi awọn eniyan ba fẹ kede Jesu pe ọba ni, eyi yoo jẹ pe wọn fẹ da oju ijọba Romu bọlẹ. Dajudaju eyi yoo bi Kesari ninu, yoo si wá ba awọn Ọmọ Israẹli jà: lai si aniani, nitori wọn lagbara jù wọn lọ, yoo si bori iṣọtẹ naa, wọn yoo si gba iru ominira ti wọn ti ni tẹlẹ lọwọ wọn.

Kaiafa ni olori alufaa ni ọdún naa. Awọn alufaa ki i ṣe iran Aarọni mọ, gẹgẹ bi Ọlọrun ti lana silẹ. Ẹnikẹni ni o le fi owo ra ipò naa lọwọ ijọba Romu. Gẹgẹ bi olori igbimọ naa, Kaiafa sọrọ nisisiyii lati fi ara mọ ijiyan ti awọn akọwe ati awọn Farasi mu wá: “Ẹnyin kò mọ ohunkohun rara. Bẹẹni ẹ kò si ronu pe, o ṣànfani fun wa, ki enia kan kú fun awọn enia, ki gbogbo orilẹ-ẹde ki o má bà ṣegbé.” Ki ni ṣe ti gbogbo awọn Ju yoo fi jiya lọwọ awọn ara Romu? Jesu ni Ẹni ti o n dá gbogbo wahala yii silẹ. Ki ni ṣe ti a kò le pa A ki a ti ipa bẹẹ dá gbogbo ariyanjiyan naa duro ki o to di pe ọwọ kò ni ká awọn ọmọlẹyin Kristi mọ?

Asọtẹlẹ Tootọ

Ọlọrun mọ pe awọn eniyan yoo feti si ohun ti olori alufaa ba sọ, nitori wọn gba á sibẹ gẹgẹ bi aṣoju wọn niwaju Ọlọrun. Bi Kaiafa tilẹ rò pe eebu ni ọrọ ti oun fi ibinu sọ yii jẹ fun Jesu, Ọlọrun ló o lati sọ asọtẹlẹ otitọ nipa iṣẹ-iranṣẹ Olugbala. O wá lati kú ki O ba le gba ẹlẹṣẹ là kuro lọwọ ikú ayeraye. Iku Ọkunrin kan, eyi ni Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, ni yoo ṣe etutu fun ẹṣẹ ọpọ eniyan.

Awọn ọrọ wọnyii mu ki igbimọ naa pinnu. Wọn yoo mu Jesu lẹsẹkẹsẹ, wọn yoo si pa A. Ni ọna bayii, wọn yoo bori ohun ti wọn n pẹ ni iṣọtẹ, wọn yoo si gba orilẹ-ẹde Ju silẹ kuro ninu iparun.

Aago Ẹṣẹ ti O Kún

Awọn Ju wọnyii i ba jẹ mọ abayọrisi ohun ti wọn n ṣe! (Luku 19:43, 44) Ọlọrun ki i rán idajọ Rẹ jade ni kikún titi aago ẹṣẹ yoo fi kún. A ranti pe Ọlọrun ti ṣe ileri lati pa awọn ọmọ Amori run fun iwa-buburu wọn, ṣugbọn O sọ fun Abrahamu ni igbà aye rẹ pe ẹṣẹ wọn kò ti i kún. Irinwo (400) ọdun lẹyin naa ni iparun de ba wọn.

Ninu itan igbesi aye awọn Ju, igba gbogbo ni wọn maa n ṣọtẹ si Ọlọrun, Oun si ti jẹ ki wahala dé ba wọn. Ṣugbọn aago ẹṣẹ wọn kún nigba ti wọn kan Jesu mọ agbelebu, Messia naa ti O wá lati yọ wọn ati lati gba wọn là kuro ninu ẹṣẹ wọn. Wọn ro pe wọn yoo wà ni oju rere pẹlu awọn ara Romu nipa pipa Kristi (eyi ti i ṣe awawi lasan fun owú wọn), dipo eyi idajọ Ọlọrun wá sori wọn nipa igbogun ti ọmọ-ogun Romu kan ti a n pẹ ni Titu; ninu ogun yii, iwà-ikà ti a kò le nikan fi ẹnu sọ tán ni a ṣe si awọn Ju. Titi di oni, wọn n jiya idajọ Ọlorun sibẹ. Awọn ti wọn kan Jesu mọ agbelebu wi pe, “Ki ẹjẹ rẹ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa”. Lootọ ni awọn ọrọ wọnyii n tẹle wọn titi di oni-oloni!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ninu ẹkọ wa oni, iṣẹ-iyanu wo ni ó bí awọn Ju ninu?
  2. Nibo ni a ti ṣe iṣẹ-iyanu naa?
  3. Ki ni olori sinagọgu ro nipa iṣẹ-iyanu yii?
  4. Ki ni iwọ ro pe o yẹ ki o jẹ ero ọkàn rẹ?
  5. Ki ni asọtẹle Kaiafa?
  6. Ọna wo ni o fi jẹ otitọ?
  7. Ki ni ipinnu igbimọ naa?
  8. Ọna wo ni awọn Ju gbà jiya fun kikan Jesu mọ agbelebu?