Luku 13:23-30; Matteu 7:13, 14

Lesson 147 - Junior

Memory Verse
“Ẹ làkaka lati wọ oju-ọna koto” (Luku 13:24).
Notes

Awọn Ẹkọ Jesu

Bi Jesu ti n lọ lati ilu de ilu ati lati ileto de ileto, O kọ awọn olugbọ Rẹ ni ọna igbala ati iye ainipẹkun. Nigba miiran Jesu fi owe ba wọn sọrọ. Nigba miiran awọn eniyan a maa ni ibeere lati beere lọwọ Jesu. Oun a maa fun wọn ni idahun, O si mọ ohun ti o tọ fun wọn. Bakan naa ni Jesu n ṣe lonii. O le yanju gbogbo ọran ti o ta koko, nitori kò si ohun ti o ṣoro fun Jesu. O mọ ohun ti o jẹ aini ẹni kọọkan: boya itunu, tabi imulọkanle, igbagbọ, tabi ibawi. A le ri i ninu Bibeli tabi ki a gbọ ninu iwaasu, ninu orin, tabi ninu ẹri ẹni kan.

Ninu ẹkọ yii, a bere ibeere yii lọwọ Jesu, “Oluwa, diẹ ha li awọn ti a o gbalà?” Jesu kò dahun pe “bẹẹ ni” tabi “bẹẹ kọ.” O bẹrẹ si i kọ wọn ni ohun ti igbala jẹ, ati pe olukuluku ni yoo ri igbala bi o ba n fẹ. Idahun Rẹ ki i ṣe fun ẹni ti o beere ibeere naa nikan ṣoṣo ṣugbọn fun gbogbo awọn olugbọ Rẹ ati fun gbogbo awọn ti o n ka Bibeli.

Ẹnu-ọna Hiha

Ninu Matteu 7:13 ati 14, a kà pe ẹnu-ọna meji ni o wà, ẹnu-ọna gbooro ati ẹnu-ọna hiha. Ọna meji ni o wà -- ọkan lọ si iparun, ekeji si lọ si iye ainipẹkun. Olukuluku eniyan a maa ba ẹnu-ọna kan tabi ikeji wọle, bakan naa ni olukuluku wà ni oju ọna kan tabi ikeji.

Awọn ti a o gbala a maa ba ẹnu-ọna hiha wọle. Ki ni ṣe ti ẹnu-ọna naa jẹ hiha? Eniyan kò le ri igbala titi di igbà ti o ba rẹ ara rẹ silẹ lati ronupiwada ati lati kọ ẹṣẹ silẹ. Awọn ẹlomiran wà ti wọn ti tobi jù lati ba ẹnu-ọna hihá naa wọle. Ki i ṣe pe wọn ga jù, tabi pe wọn sanra jù, ṣugbọn ni oju ara wọn, wọn jẹ eniyan nla. Wọn ni lati rẹ ara wọn silẹ ki wọn si dabi ọmọ kekere. Jesu wi pe, “Bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin kì yio le wọle ijọba ọrun” (Matteu 18:3).

Kò si Ẹrù

Awọn ti a kò ti i gbala n ru ẹrù. Ẹrù ti awọn ẹlomiran rù ni ododo-ti-ara-wọn, igberaga, ati ainani, tabi ẹrù awọn ẹṣẹ miiran bi iwọra, ikorira, ibinú, irọ, imọ-ti-ara-ẹni-nikan, olẹ tabi irẹnijẹ. Bi wọn ba n fẹ lati bá ẹnu-ọna hihá wọle si iye ainipẹkun, wọn ni lati kọkọ sọ ẹrù yii kalẹ. Jesu yoo gbe ẹru wọnyii kuro bi eniyan ba bẹbẹ fun idariji ati igbala.

Boya o ti gbiyanju nigbà kan ri lati bá ọna kekere kan wọle pẹlu ẹrù kan ni ọwọ rẹ tabi ẹru kan ti o rù si ẹyin. Boya o bẹrẹ lọ silẹ tabi o gbiyanju lati rákò ki o ba a le wọle lai gbe ẹrù ti o wa ni ẹyin rẹ silẹ. Ẹni kan ṣoṣo ni àyẹ wa fun lati ba ẹnu-ọna hiha ni wọle lẹẹkan. Kò gbọdọ ni ẹru ẹṣẹ kan lọwọ, bi o ti wu ki o kere to. Bi ohun ti o gbé lọwọ ba jẹ eyi ti o gùn tabi ti o tobi, o ṣe e ṣe ki o ti gbiyanju ni oriṣiriṣi ọna lati gbé ẹru naa wọle. Bi o ba fẹ ba ẹnu-ọna hiha naa wọle, beere pe ki Jesu wa gbé ẹrù ẹṣẹ kuro ninu ọkàn rẹ.

Ẹnu-ọna Mejeeji

Ẹnu-ọna keji jẹ onibu, pẹlu irọrun ni eniyan si le wọle nibẹ pẹlu awọn ẹrù rẹ ati ẹṣẹ rẹ. A maa n tan awọn ẹlomiran jẹ lati rin ọna gbooro yii nitori awọn eniyan pupọ ni wọn n rin nibẹ. Ilẹkun ẹnu-ọna hiha ṣi si oju ọna tooro nibi ti ko si ọpọlọpọ ẹrọ to bẹẹ.

“Ẹni meji ni aye gba,

Kò lé, kò si din,

Jesu ati iwọ.”

Njẹ o le fi oju inu wo awọn ti n rin irin-ajo loju ọna meji yii? Ni oju ọna gbooro a le ri awọn eniyan pẹlu ẹrù wọn nlá nlà; ẹrù ẹṣẹ ati ainireti. Ẹni kan ko le ran ẹni keji lọwọ nitori olukuluku ni o ni ẹru ti rẹ. Ọna gbooro kun fun ọpọlọpọ arin-rin-ajo ṣugbọn ti wọn kò le ran ara wọn lọwọ! Awọn eniyan diẹ ni wọn wà ni oju ọna tooró; gbogbo ẹṣẹ wọn ni a ti mú kuro. Lẹyin eyi Jesu wà nibẹ lati fun wọn ni iranlọwọ ati lati sọ ọrọ imulọkanle fun wọn bi wọn ti n lọ lori òke ati ni pẹtẹlẹ. Ọna tooró - ẹri ọkàn mimọ ati irẹpọ didun!

Làkàkà

Nibo ni opin awọn ọna yii? O dabi ẹni pe awọn ẹlomiran n tẹle awọn ero. Wọn kò ha ronu ibi ti wọn n lọ? Wọn kò ha mọ pe ọna gbooro yoo yọri si ikú ati iparun (Matteu 7:13)? Wọn kò há mọ pe ọna tooro nì lọ si Ọrun ati iye ainipẹkun (Matteu 7:14)?

Jesu mọ bi eyi ti ṣe iyebiye to, nitori O wi pe, “Ẹ làkaka lati wọ oju-ọna koto.” Làkàkà! Ki ni itumọ eyi? Lati làkàkà ni lati sa gbogbo ipá ati lati ṣe gbogbo eyi ti o wà ni agbara ẹni lati ṣe. Awọn ẹlomiran yoo wá ọna lati wọle, ṣugbọn wọn ki yoo le wọ ọ, nitori wọn ko làkàkà. Awọn ẹlomiran yoo kuna ore-ọfẹ ati ogo Ọlọrun nitori wọn n fi imẹlẹ wá a dipo ki wọn ṣiṣẹ ki wọn si làkàkà lati wọle. O wà nipá eniyan lati ṣiṣẹ ki o si sẹ ara rẹ ki o ba le wọ ẹnu-ọna kotó, nitori o lọ taara si iye ainipẹkun.

Kò si ọna miiran si Ọrun ju ẹnu-ọna hihá lọ. Jesu wi pe, “Emi li ọna, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi” (Johannu 14:6). Awọn miiran le gbiyanju lati bá ọna miiran wọle (iṣẹ rere ara wọn), ṣugbọn ole ati ọlọṣa ni wọn (Johannu 10:1), wọn ki yoo si “jogún ijọba Ọlọrun” (1 Kọrinti 6:10).

Ilẹkun ti ó Tì

Bi o tilẹ jẹ pe ẹnu-ọna há, a kò ti i tabi ki a pa a de. Igba kan n bọ, boya lai pẹ yii, nigbà ti Baale ile yoo ti ilẹkun. Awọn ti wọn ti n pinnu lati wá igbala ṣugbọn ti wọn ti n fi ọjọ igbala dọla fun igba pipẹ, yoo wá ọna lati wọle ṣugbọn wọn ki yoo le wọle nitori a ti sé ilẹkun nigbà naa.

Ọna wo ni iwọ n rìn lonii - ọna tooro tabi ọna gbooro? Bi o kò ba si ni oju ọna si Ọrun, bá ẹnu ọna tooro wọle. Má ṣe fi akoko ṣòfo! Yara ki a to ti ilẹkun.

O ti Pẹ Ju

Jesu sọ pe awọn kan yoo wá de lẹyin ti a ba ti ti ilẹkun. Wọn o maa kànkùn wọn o si maa beere pe ki a ṣilẹkun fun wọn, pe, “Oluwa, Oluwa, ṣí i fun wa.” Wọn o gbọ ọrọ iparun – “Emi kò mọ nyin.”

A ri i lati inu ẹkọ Jesu pe awọn miiran yoo gbiyanju lati fi ọrọ ẹnu wọn wá ọna lati wọle fun ara wọn. Wọn o sọ ti iṣẹ rere ati ododo ara wọn fun Baale ile naa. Wọn o sọ fun Un gẹgẹ bi wọn ti gbọ ẹkọ Rẹ, ati pe awọn miiran tilẹ ti bá Jesu jẹun paapaa. Baale naa kò ni sẹ eyi, nitori ó le jẹ otitọ; ṣugbọn eyi ni kò tó.

Bibeli sọ fun ni pe eniyan ni lati jẹ oluṣe Ọrọ naa ki o má ṣe olugbọ nikan (Jakọbu 1:22). A ti kà nipa Judasi ẹni ti o ti jẹ ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin Jesu. O ti wà lọdọ Jesu ni igbà pupọ, o ti gbọ awọn ẹkọ Rẹ, o tilẹ ti bá Oluwa jẹun paapaa, sibẹ Judasi fi Ọmọ Ọlọrun hàn (Matteu 26:20, 21; Marku 14:18). Bibeli kò sọ fun ni pe Judasi ronupiwada ki o si tun ri igbala.

Boya nigba kan awọn eniyan ti wọn n kankun wọnyii ti ri igbala, wọn si ti rin ọna tooro naa. O daju pe wọn yà gba ọna miiran eyi ti o mu wọn lọ kuro ni oju-ọna ti o lọ si Ọrun. Jesu yoo wi pe Oun kò mọ wọn nitori ẹṣẹ wà ninu ayé wọn. Oluwa mọ awọn ti i ṣe ti Rẹ (Nahumu 1:7; 1 Kọrinti 8:3; 2 Timoteu 2:19), awọn iyoku ni a o si dá lẹbi.

Ọlọrun yoo kó awọn eniyan Rẹ jọ lati Ariwa ati Gusu, lati Ila-oorun ati Iwọ-oorun, sinu Ijọba Rẹ, awọn ti o si n ṣiṣẹ ẹṣẹ ni a o si sé mọ ode titi lae.

“Ilẹkun kan, ani ọkan ṣoṣo,

Sibẹ apa rẹ jẹ meji,

Ninu ati lode,

Apá wo lo wà?”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni Jesu sọ pe ki a làkàkà fun?
  2. Ki ni ṣe ti awọn kan yoo wá ọna lati wọle ti wọn kò si ni le wọle?
  3. Ki ni awọn ẹnu-ọna meji naa ati awọn ọna meji naa?
  4. Nibo ni opin awọn ọna meji wọnyii?
  5. Bawo ni a ṣe le wọ ẹnu-ọna kotó naa?
  6. Ta ni yoo ti ilẹkun naa?
  7. Awọn wo ni a o tì mọ ode?
  8. Ki ni ṣe ti Jesu sọ pe ki wọn maa lọ?