Luku 14:25-33

Lesson 149 - Junior

Memory Verse
“Ẹnikẹni ti kò ba rù agbelebu rẹ, ki o si ma tọ mi lẹhin, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi” (Luku 14:27).
Notes

Ѐrò Ọpọ Eniyan

Ọpọ eniyan ti o n tẹle Jesu gbagbọ pe Oun yoo di Ọba Nla ninu aye yii. Njẹ kò ha ti fi iṣù akara marun-un ati ẹja wẹwẹ meji bọ ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan? Ọpọ olokunrun ni O ti wòsàn, o si ti fi ayọ kùn inu ile pupọ. Njẹ kò ni jẹ iyanu lati ni ọba ti o le fun wọn ni ohun gbogbo ti wọn n fẹ, ki wọn ba le gbadun irọra ati ọlá, ki wọn má si ṣiṣẹ mọ? Pẹlu agbara iyanu Kristi ti o le dá igbi omi òkun paapaa duro, ijọba Romu ki yoo ni agbara lati mú wọn wà labẹ isinrú mọ.

Awọn ọmọ-ẹyin paapaa ni irú ẹro yii, wọn si fẹ pe iná sọkalẹ lati Ọrun wá lati pa awọn ti o gan Jesu. Wọn kò ti i kọ nipa otitọ ti Paulu Apọsteli kede rẹ lẹyin naa sibẹ: “Ijọba Ọlọrun ki iṣe jijẹ ati mimu; bikoṣe ododo, ati alafia, ati ayọ ninu Ẹmi Mimọ” (Romu 14:17).

Jesu mọ ẹro ọpọ eniyan naa, O si gbiyanju lati ṣe àlàyé pe Oun fẹ gbin Ijọba Oun sinu ọkàn wọn. Wọn ni lati maa san owo-ori fun Kesari sibẹ, wọn si gbọdọ gbọran si awọn alakoso wọn lẹnu; ṣugbọn nigba ti a ba ti dari ẹṣẹ wọn ji, wọn le gbadùn ominira Rẹ ninu ọkàn wọn, ki wọn si ni ireti iye ainipẹkun ninu aye ti n bọ.

Ọrọ ti O Le

Jesu ṣe àlàyé ni igba pupọ pe lati tẹle Oun ki yoo mu igbesi aye eniyan rọrùn ninu aye nihin. “Awọn kọlọkọlọ ni ihò, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ni itẹ; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio fi ori rẹ le” (Luku 9:58). Njẹ awọn eniyan yoo fẹ tẹlẹ E sibẹ ni iru ipo bayii?

Ajaga ti O Rọrun

Jesu wi pẹlu pe, “Àjaga mi rọrun, ẹrù mi si fuyẹ” (Matteu 11:30). Bawo ni iru ifararubọ bayii ṣe le rọrun? Ọmọlẹyin Jesu tootọ ti di atunbi, ohun ti Ẹmi si yé e. Didun inú rẹ wà ninu ṣiṣe ifẹ Ọlọrun. O mọ pe gbigba ajaga Jesu si ọrùn ni pe Jesu yoo ru eyi ti o wuwo jù ninu rẹ.

Igbesi aye Onigbagbọ gba ijọsin ati ifararubọ. Jesu maa n fi ajaga Rẹ si ọrùn awọn ti o ba yi pada, wọn a si fi ara wọn fun Un lati sin In. A maa n fi ajaga bọ maluu lọrun nigba ti a ba fẹ ki o fa ẹrù; ṣugbọn isin Jesu ki i ṣe afipaṣe, eyi ti ko wu ni. Ayọ wà ninu jijọwọ aye wa patapata fun Oluwa, isin Rẹ si n fun ni ayọ.

Ayẹ Wà Fun Olukuluku

Igbesi aye wa gẹgẹ bi Onigbagbọ kò jamọ nnkan kan bi a bá mọ ti ara wa nikan. Jesu bukun wa ki a ba le jẹ ibukun fun ẹlomiran. Ki a ba le jẹ iranwọ, a gbọdọ fi ero ti wa silẹ. Jesu fẹ ẹni ti Oun le lò ni igbakigba, ati ni ibikibi ti O ba yàn.

Jesu ni àyẹ kan fun olukuluku awọn eniyan Rẹ lati dí. Boya ipò ti o rẹlẹ ni: ṣugbọn bi a ba duro nibi ti O fi wa si, a o wà nibẹ nigba ti O ba pẹ wa fun iṣẹ-isin ti o tobi ju bẹẹ lọ.

Iṣẹ ti A Yàn fun Dafidi

A ranti pe Dafidi n ṣọ agbo ẹran baba rẹ nigba ti Samuẹli ranṣẹ pe e lati yàn an ni ọba Israẹli. Bawo ni i ba ti ri bi Dafidi ba ti pinnu pe iṣẹ oun kò ṣe pataki to bẹẹ ati pe agbo ẹran naa le maa boju to ara wọn nigba ti oun ba lọ kí ọrẹ rẹ. A ki ba ti ri i nigba ti Samuẹli ranṣẹ pe e, oun i ba si ti padanu ọlá jijẹ ọba.

Sibẹ, Dafidi ni ọdún pupọ niwaju rẹ lati fi kọ ẹkọ ki o to le gba itẹ Israẹli; ati ni akoko iyiiriwo yii, o gbọran si Ọlọrun lẹnu nigba gbogbo ju lati tẹ ara rẹ lọrùn. Nigbooṣe o di ọba Israẹli ti o tobi ju lọ nitori o jẹ oloootọ ninu ohun kekere ki o ba le wu Ọlọrun nigba gbogbo.

Ifẹ Jesu

Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin Rẹ wi pe: “Emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi” (Johannu 6:38). O wá lati jiya ati lati kú fun ẹlẹṣẹ. Oun tikara Rẹ kò dá ẹṣẹ ri, Oun kò si yẹ lati kú; ṣugbọn didun inu Rẹ ni lati ṣe ifẹ Ọlọrun ati lati ta Ẹjẹ Rẹ silẹ ki O ba le gba awọn ti o ti nù là. O fi ayọ gba iṣẹfẹ lati ọdọ awọn ẹlẹgàn ọpọ eniyan, iyà, otutu, ati ebi, nitori O mọ pe Oun n ṣe ifẹ ti Baba Rẹ. Ati nitori ayọ ti a gbé kà iwaju Rẹ, O fara da agbelebu lai ka itiju si.

Ipese fun Ẹbi Wa

Nigba ti Jesu wi pe: “Bi ẹnikan ba tọ mi wá, ti kò si korira baba rẹ, ati iya, ati aya, ati ọmọ, ati arakọnrin, ati arabirin, ani ati ẹmi ara rẹ pẹlu, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi.” Oun kò sọ pe gẹrẹ ti ẹni kan ba ti di Onigbagbọ, o ni lati fi ẹbi rẹ silẹ lati maa boju to ara wọn. Ninu iwe ti Paulu kọ si Timoteu, o wi pe “Bi ẹnikẹni kò bá pẹse fun awọn tirẹ, papa fun awọn ará ile rẹ, o ti sẹ igbagbọ, o buru ju alaigbagbọ lọ” (1 Timoteu 5:8). Ṣugbọn bi ẹnikẹni ninu ẹbi wa ba fẹ yi ọkàn wa kuro ninu isin Ọlọrun, a gbọdọ yàn lati sin Ọlọrun. Iye ainipẹkun ṣe pataki ju ọjọ diẹ ti a o bá ẹbi wa gbé pọ pẹlu alaafia ninu aye nihin.

Iṣẹ wa ni lati jere ẹbi wa ti kò ti i ri igbalà fun Ọlọrun. A kò fẹ ki wọn lọ sinu iya ainipẹkun. Pẹlu ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn wa, a o fẹran wọn to bẹẹ ti a o gbadura kikankikan pe ki awọn pẹlu le ri igbalà. A o ṣe wọn ni oore lati fi hàn wọn pe a fẹran wọn; a o si maa gbe igbesi aye wa niwaju wọn ni ọna ti yoo fi mọ pe Onigbagbọ ni wa.

Ṣugbọn a kò ni gba ọjẹgẹ pẹlu ẹṣẹ wọn. A kò le jere ẹnikẹni fun Olugbala bi a ba tikara wa rẹ iduro wa gẹgẹ bi Onigbagbọ silẹ. Ikọ Ọlọrun ni a jẹ. Awa ni aṣoju Ijọba Ọrun ninu aye yii; aye si gbọdọ ri Jesu ninu wa. “Lati Sioni wá, pipé ẹwà, Ọlọrun ti tan imọlẹ” (Orin Dafidi 50:2). Sioni ti Ẹmi ni Ijọ Akọbi lonii, ati nipasẹ olukuluku ọmọ Ijọ naa si ni ẹwà iwa-mimọ yoo ti mọlẹ. Ọlọrun yoo di mimọ ninu awọn eniyan Rẹ.

Ipinya pẹlu Ẹṣẹ

A kọ ẹkọ pe bi ẹnikẹni ba tọ wa wá pẹlu ẹkọ ẹké, a kò gbọdọ kà á si (2 Johannu 10, 11). A o fẹ ri i pe o ri igbalà; ṣugbọn kaka ki a fi ẹmi wa wewu nipa fifi eti si ẹkọ ẹke rẹ, a o yẹra fun un.

A gbọdọ pa ara wa mọ kuro ninu ẹṣẹ. Bi a ba ni inu didun lati ṣe ifẹ Ọlọrun, igbà pupọ ni ohun ti a n ṣe kò ni yé ẹlẹṣẹ, a si le ṣe inunibini si wa pẹlu gẹgẹ bi ẹni ti kò ni ifẹ ará. Ni igbà kan Jesu wi pe: “Ẹ máṣe rò pe emi wá rán alafia si aiye, emi ko wá rán alafia bikoṣe idà. Awọn ara-ile enia si li ọta rẹ” (Matteu 10:34-36). Bi awọn eniyan ba wà ni ile wa ti kò fẹran Ọlọrun, wọn le rò pé a n fi akoko wa ti a n lò ninu isin Ọlọrun ṣòfò. Wọn le fi isin wa atọkanwa ṣe yẹyẹ. Njẹ Ọlọrun ni a fẹ wú tabi eniyan? Nigba ti a ba duro ni idajọ niwaju Ọba awọn ọba, ẹbi wa tabi ọrẹ wa kò ni le ràn wa lọwọ. Ѐro wa paapaa yoo hàn kedere niwaju Ọlọrun, Oun yoo si ri i bi a bá ti sin In pẹlu gbogbo ọkàn wa.

Njẹ a n fi ifẹ Ọlọrun ṣiwaju ohun gbogbo miiran ti a n ṣe? Boya ẹni kan le ti ni igbọgbẹ ọkàn fun ẹṣẹ rẹ, o si n fẹ fi ohun gbogbo fun Oluwa ki o ba le ri idariji ẹṣẹ rẹ gbà, ki o si ni alaafia ninu ọkàn rẹ. Fun igba diẹ, o sin Ọlọrun pẹlu igbóná ọkàn, o si dupẹ fun ifẹ Ọrun ti a fi hàn fun un. Ṣugbọn bi akoko ti n lọ, ọwọ rẹ di fun itọju ẹbi rẹ, tabi iṣẹ rẹ, oun kò si ri àyẹ fun Ọlọrun gẹgẹ bi o ti maa n ṣe nigbà kan ri. Nigba ti o mọ pe oun n fẹ ni Ọlọrun, o fẹ fi ohun gbogbo ti o wà nipá rẹ fun Oluwa; ṣugbọn nisisiyii ti gbogbo nnkan lọ deedee pẹlu rẹ, o rò pe, dajudaju Jesu kò beere lọwọ oun lati lo akoko pupọ bẹẹ fun isin Rẹ. Ọkunrin yii dabi ọmọlé ti Jesu sọ nipa rẹ, ẹni ti o fi ipilẹ ile rẹ sọlẹ, ṣugbọn ti kò ṣiro iye owó ti yoo gba a lati fi kọ ile. Ki ile rẹ to pari rara, gbogbo owó rẹ ti tán patapata; ile ti a kò pari yii ni awọn eniyan ri, ti wọn si n ṣe yẹyẹ; “Ọkọnrin yi bẹrẹ si ile ikọ, kò si le pari rẹ” (Luku 14:30).

Oore-Ọfẹ ti O To Fun Wa

Jesu ki i beere lọwọ wa ju ohun ti a le ṣe. Kò yẹ ki a bẹrù, nigba ti a bá bẹrẹ si sin Ọlọrun, ti a si fi aye wa fun Un, pe Oun yoo beere ohun ti a kò le ṣe lọwọ wa. O ti ṣeleri pe oore-ọfẹ Oun tó fun wa. O fẹ ki a jọwọ ifẹ ọkàn wa silẹ fun Oun. O n fẹ ki a wulò ni ibikibi ti Oun ba yàn, tabi ki a dákẹ jẹẹ, ki a si ni itẹlọrun bi Oun kò ba lò wá rárá fun igbà diẹ.

Nigba miiran eniyan le rò pe oun ni ipẹ lati ṣe iṣẹ nla kan fun Oluwa, yoo si sare jade lati ṣe iṣẹ naa ki o to wà ni imurasilẹ patapata. Ọlọrun n fẹ ki awọn òṣiṣẹ Rẹ kẹkọọ jinlẹ daradara ninu Ọrọ Rẹ, ki wọn ti ni iriri ninu Ihinrere, to bẹẹ ti wọn yoo mọ iru idanwò ti wọn yoo bá pade, ki wọn si ni ọgbọn lati yanju ohunkohun ti o wù ki o ṣẹlẹ. Bi ẹni kan, ninu itara rẹ, ba sare jade ki o to mura tán patapata fun iṣẹ naa, ọkọ igbagbọ rẹ yoo rì, yoo si mú itiju ba isin Kristi.

Ẹlomiran ẹwẹ le rò pe oun ni ipẹ si iṣẹ iranṣẹ Ihinrere, ki o si maa duro ki a le ran an jade, ṣugbọn, o ṣe e ṣe, ki akoko naa to de ki o ti wa bẹrẹ si binu si idaduro naa. Nigba ti Ọlọrun ba pe ẹni ni tootọ, ti o si ti mura tan, bi akoko ba to gan an, àyẹ yoo ṣi silẹ. Ọlọrun n fẹ awọn ti Oun le gbẹkẹle, ti wọn yoo jẹ ki Ẹmi Ọlọrun maa dari wọn dipo ọgbọn ti wọn, awọn ti yoo sin In pẹlu irẹlẹ, ti kò ni gberaga nitori iṣẹ ti wọn n ṣe fun Oluwa. Bi eniyan ba gbẹkẹ le Ọlọrun patapata, igbagbọ rẹ yoo mu un duro ni ibikibi ti Oluwa ba fi i si.

Ni ọjọ kan, lai pẹ, Ọlọrun yoo pẹ: “Kó awọn enia mimọ mi jọ pọ si ọdọ mi: awọn ti o fi ẹbọ ba mi da majẹmu” (Orin Dafidi 50:5). Bawo ni ayọ wa yoo ti pọ to pe a fi gbogbo nnkan silẹ lati tẹle Jesu! Bi o tilẹ jẹ pe ifararubọ naa le dabi ẹni pe o tobi nisisiyii, a ki yoo ranti rẹ mọ nigba ti a bá bọ sinu ogo, ti Oluwa ti pese silẹ fun awọn ti o fẹran Rẹ ni tootọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ọpọ awọn eniyan wọnyii ni ireti pe Jesu yoo ṣe nipa ọrọ Ijọba?
  2. Ki ni ṣe ti wọn n fẹ ni Jesu ni Ọba?
  3. Nibo ni Jesu n fẹ gbin Ijọba Rẹ si?
  4. Bawo ni nnkan ti Jesu n fẹ ki a fi silẹ ki a ba le sin In ti pọ to?
  5. Ki ni Jesu sọ nipa ajagà Rẹ?
  6. Darukọ awọn nnkan ti a le ṣe lati fun awọn ẹlomiran ni iwuri lati ri igbalà?
  7. Nibo ni Dafidi wà nigba ti a pẹ é lati yàn án ni ọba?
  8. Ta ni Dafidi gbiyanju lati wù?
  9. Ta ni Jesu gbiyanju lati wù?
  10. Bawo ni o ṣe yẹ ki a gbé igbesi aye wa?