Luku 15:1-32

Lesson 150 - Junior

Memory Verse
“Nitori Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là” (Luku 19:10).
Notes

Sisunmọ Jesu

Nigba ti Jesu n kọ ni, awọn agbowo-ode ati awọn ẹlẹṣẹ wa si ọdọ Rẹ ki wọn ba le gbọ ohun ti O fẹ sọ. Jesu kò jẹ da ẹnikẹni pada ti o ba tọ Ọ wa pẹlu oungbẹ ninu ọkàn rẹ lati gbọ ọrọ Rẹ. Nipa gbigbọ Ọrọ Jesu ati nipa gbigba A gbọ, awọn ẹlẹṣẹ le ri igbala (Johannu 5:24), nitori “nipa gbigbọ ni igbagbọ ti iwá, ati gbigbọ nipa ọrọ Ọlọrun” (Romu 10:17). Dipo ti I ba fi dá awọn eniyan pada, Jesu a maa sun mọ awọn ti o ba sun mọ Ọ (Jakọbu 4:8).

Bi o tilẹ jẹ pe awọn akọwe ati awọn Farisi jẹ ẹlẹsin, ero wọn si awọn ẹlomiran yatọ. Wọn kùn nitori Jesu ṣe inu rere si awọn ẹlẹṣẹ O si gba wọn laye lati gbọ ẹkọ Rẹ. Ẹsun ti wọn fi Jesu sun jẹ otitọ - Oun n gba awọn ẹlẹṣẹ. Idi rẹ ti O fi wa si aye yii ni lati gba awọn ẹlẹṣẹ là (1 Timoteu 1:15).

Ohun ti o buru ninu ọrọ ti awọn Farisi sọ ni ọna ti wọn gba sọ ọ. Olukuluku Onigbagbọ ni o n sọ bakan naa, ṣugbọn ninu ọrọ iyin. Ẹri yii wà lọkan Onigbagbọ: “Emi mọ pe Jesu n gba ẹlẹṣẹ nitori O gbà mi si ile nigba ti O gba ọkàn mi là”.

Agutan ti o Sọnu

Ni idahun si ibeere awọn akọwe ati awọn Farisi, Jesu pa owe kan ti o fi han bi O ti fẹran ọkan kan ati bi O ti ka a si iyebiye to. Owe agutan ti o sọnu fi han wa bi laalaa ti Jesu n ṣe ti pọ to lori ọkan kan ki ó ba le ri igbala.

Ibi pupọ ninu Bibeli ni a fi awọn eniyan wé agutan. Wolii Isaiah sọ pe, “Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹle ọna ara rẹ” (Isaiah 53:6). Onisaamu gba ẹṣẹ rẹ nigba ti o wi pe, “Emi ti ṣina kiri bi agutan ti o nù” (Orin Dafidi 119:176). Jesu wi pe, “Emi ni oluṣọ-agutan rere: oluṣọ¬-agutan rere fi ẹmi rẹ lelẹ nitori awọn agutan” (Johannu 10:11).

Ninu owe yii, ọkunrin naa ni ọgọrun agutan. A le ro pe o ṣi ni ọpọlọpọ sibẹ ti ko fi yẹ ki o bikita nipa ọkan ṣoṣo, tabi pe ẹyọ kan ko to lati ṣe wahala le lori lati maa wa a. Ko ri bẹẹ pẹlu ọkunrin yii tabi pẹlu Jesu Ẹni ti O mọ agutan ti Rẹ (Johannu 10:27), bẹẹ ni ko ri bẹẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹyin Rẹ.

Oluṣọ-agutan

A kò rán ọmọ-ọdọ tabi alagbaṣe lati lọ wá agutan ti o sọnu yii. ọkunrin naa, tikara rẹ, ni o lọ lati wá agutan kan naa ti o sọnu. Ninu Matteu 18:12 owe naa sọ fun wa pe oluṣọ-agutan naa lọ si ori oke lati wa agutan naa ti ko le ran ara rẹ lọwọ. A pe Jesu ni “ Oluṣọ-agutan nla ti awọn agutan” (Heberu 13:20). Awọn ti n ya aworan ti gbiyanju lati fi ifẹ Jesu lori ọkan ti o sọnu yii han ni ọna ti o wú ni lori. Awọn ti n ya aworan miiran fi Jesu han, ninu iji ati otutu, bi O ti n wá ọdọ-agutan ti o fi ori há saarin ẹgun lori oke ti o lewu kan, ati bi awọn gunnugun nla si ti mura tán lati kọlu ọdọ-agutan ti ko le ran ara rẹ lọwọ yii.

Ewu

Ẹnikẹni ti o ba sọnu ti o si jinna si agbo – i baa jẹ agutan tabi eniyan – o wà ninu ọpọlọpọ ewu. Agutan ti o sọnu wà ninu ewu jijẹ ohun ijẹ fun awọn ẹranko buburu nigba ti o jinna si aabo oluṣọ-agutan. Dafidi sọ fun ni pe kiniun kan ati amọtẹkun kan wa lati pa ninu agbo agutan rẹ (1 Samuẹli 17:34-37). Ọlọrun fun Dafidi ni agbara nigba wọnyii lati pa ẹranko buburu naa ati lati gba ọdọ-agutan naa pada. Ki ni iwọ ro pe yoo ṣẹlẹ bi Dafidi oluṣọ-agutan ko bá si nibẹ?

Eniyan paapaa ni ọta. Nigba ti o ba lọ kuro lọdọ Ọlọrun o fi ara rẹ sinu ewu. Ninu 1 Peteru 5:8 a kà pe, “Ẹ mã wà li airekọja, ẹ mã ṣọra; nitori Ѐṣu, ọtá nyin, bi kiniun ti nke ramuramu, o nrin kãkiri, o nwá ẹniti ti yio pajẹ kiri.” Paulu kilọ nipa awọn olukọni eke, awọn ti o fi wé “Ikõkò buburu” (Iṣe Awọn Apọsteli 20:29). Iji lile le bi lu awọn ti o fi aabo inu agbo silẹ. Iji ibinu Ọlọrun wà lori awọn ti ko gbagbọ (Johannu 3:36). A si ti fi “hàn lati ọrun wá si gbogbo aiwa-bi-Ọlọrun ati aiṣododo enia” (Romu 1:18).

Ibi Aabo

Oluṣọ-agutan wá a kiri titi o fi ri ọkan ti o ṣonu naa. Pẹlu ifẹ ati pẹlẹpẹlẹ ni o rọra gbe eyi ti o sọnu naa. Eyi ti o ti rẹ, ti o ti di alailera, ti o si ti daamu, ni o rọra gbé le ejika rẹ, si ibi agbara ati aabo.

Wo o bi ayọ naa ti pọ to! Dajudaju, ẹni ti a gbala yoo layọ pupọ gẹgẹ bi oluṣọ-agutan rere ti o pe awọn aladugbo rẹ lati ba a yọ ti ni ayọ pẹlu. “Njẹ melomelo li enia san jù agutan lọ?” (Matteu 12:12). Nigba ti ẹlẹṣẹ ba ronupiwada, oun yoo ni ayọ pẹlu awọn Onigbagbọ iyoku, awọn angẹli ni Ọrun paapaa yoo yọ pẹlu.

Owo Fadaka ti O Sọnu

Jesu tun mu apẹẹrẹ miiran wá lati fi han bi ọkàn kan ti o sọnu ti niye lori to, ati iru ayọ ti o maa n wà nigba ti a ba jere rẹ pada. Ni ọna kan ẹlẹṣẹ dabi fadaka ti o sọnu. Awọn mejeeji ni o niye lori, a si le fi ikọọkan ninu wọn paarọ fun ohun miiran. Dajudaju ẹni kọọkan ninu wa ni o ti ra nnkan ri ninu ile itaja pẹlu owo rẹ, ṣugbọn ki ni eniyan le fi dipo ẹmi rẹ? A ti ka nipa Esau, arakunrin Jakọbu, ẹni ti o ta ogun-ibi rẹ fun okele ounjẹ kan (Heberu 12:16), eyi ti o dabi eniyan ti o pọn ounjẹ le ju ẹmi ara rẹ lọ. Judasi, ẹni ti o ti jẹ ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin Jesu, fi Ọmọ Ọlọrun han nipa fifi ẹnu ko O ni ẹnu, o si gba ọgbọn owo fadaka lati ṣe eyi (Matteu 27:3), lọna bayii o sọ anfaani rẹ si iye ainipẹkun nù. Wolii Isaiah sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe wọn ti ta ara wọn fun aiṣedeedee wọn (Isaiah 50:1) ati lọfẹẹ (Isaiah 52:3). Ẹni ti o ba ronupiwada ti o si fi aye rẹ fun iṣẹ-isin Jesu yoo ri iye ainipẹkun gbà (Johannu 3:15; 12:25), pẹlu ọpọlọpọ awọn ibukun miiran.

A Ri I Pada

Ninu okunkun ni fadaka naa ti sọnu, gẹgẹ bi ọna eniyan buburu ti ṣe okunkun (Owe 4:19). Fadaka naa ṣe iyebiye fun obirin naa o si n wa a kiri gẹgẹ bi Jesu ṣe fẹran ẹlẹṣẹ to, O fẹ lati ra a pada. Obirin yii fara balẹ wá fadaka naa pẹlu atupa ati igbalẹ. Ki ni ohun ti a n lò lati fi wá ọkàn ti o sọnu? Jesu ni Imọlẹ aye (Johannu 8:12). Onisaamu wi pe, “Ọrọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ mi, ati imọlẹ si ipa ọna mi” (Orin Dafidi 119:105). Ẹmi Ọlọrun a maa da eniyan lẹbi fun ẹṣẹ a si maa fa a wá sọdọ Oluwa (Johannu 6:44). A maa n dá ẹlẹṣẹ lẹbi “niti ẹṣẹ ati niti ododo, ati niti idajọ” (Johannu 16:8). Ninu “pantiri” aye ni a ti maa n ri ẹlẹṣẹ, nibi ti o wa ati bi o ti ri gan an.

Yiyọ Ayọ

Obirin yii fi ara balẹ wá owo naa titi o fi ri i, nitori o ka a si gẹgẹ bi apẹẹrẹ wiwa ni mimọ rẹ. A ko le ṣẹṣẹ maa wi pe inu rẹ dun nigba ti o ri fadaka naa. Awọn ẹlomiran tun layọ pẹlu, nitori o pe awọn ọrẹ ati aladugbo rẹ lati ba a yọ. Bakan naa, ayọ wa laaarin awọn angẹli Ọlọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada.

Jesu fi owe yii kọ ni lati fi hàn awọn akọwe ati Farisi bi iwa wọn si awọn ẹlẹṣẹ ṣe yatọ pupọ si ti Ọlọrun.

Ni Ilu Okeere

Jesu sọ nipa ọkunrin kan ti o ni ọmọkunrin meji. A ti pese itura ati aabo ninu ile ti o dara fun wọn. Eyi aburo kò fẹ lati wà labẹ itọni baba rẹ mọ. Boya o ti dara pọ mọ ẹgbẹ buburu, tabi o ti n ka awọn iwe ti kò dara, tabi boya “ọkàn buburu ti aigbagbọ” (Heberu 3:12) ni o wà ninu rẹ. Boya o rò pe bi oun ba lọ jinna si baba oun, oun yoo ni ominira ju bẹẹ lọ, yoo si le ṣe ohunkohun ti o ba wù u. O beere owo lọwọ baba rẹ, kò tilẹ beere pẹlu ọwọ paapaa. Ninu ifẹ ati inu rere, baba rẹ fun un ni eyi ti o tọ si i. Ọdọmọkunrin yii jade lati lọ jẹ igbadun ayé ni ilu ti o jinna rere, nibi ti ọkàn rẹ fà si.

Ohun ibanujẹ ni lati kà pe ọmọkunrin yii n fẹ ọnà ti ara rẹ, o si fi baba rẹ silẹ. Kò mọ wahala ti o n duro de oun lọhùn nipa ṣiṣe bẹẹ. Bakan naa ni o jẹ ohun ibanujẹ lonii lati ri awọn ti wọn jẹ alaimoore si Ọlọrun, ti iṣakoso Rẹ kò si tẹ wọn lọrun mọ. Wọn n fẹ ọna ti ara wọn, nikẹyin wọn a si ya ara wọn sọtọ kuro lọdọ Ọlọrun ati ohun rere. Awọn ọmọ miiran a tilẹ pinnu lati sá lọ si ilu miiran. Wọn rò pe wọn yoo le gbadun ara wọn ni ibomiran. Gẹgẹ bi ọmọ-oninakuna wọn kò ronu ohun ti yoo jẹ abayọri si rẹ. I ba ti dara to bi wọn ba le ronu nipa ohun ti o ṣẹlẹ si ọmọkunrin yii, ki wọn si kiyesi ara wọn ki wọn má ṣe bá ara wọn ni ọna jijin rere si Ọlọrun ati ile.

Ọmọkunrin naa ná gbogbo ohun ti o ni, iyàn nla si bẹrẹ si i mu. Boya ọpọlọpọ ni awọn ọrẹ ti o ba a ná owo rẹ, ṣugbọn akoko de ti o wà ninu aini, kò si si ẹni ti o ba a ṣọrẹ mọ. O ni lati lọ ṣe iṣẹ fifi ounjẹ bọ awọn ẹlẹdẹ ninu papa. Nibẹ, lai si ounjẹ ati lai si ọrẹ, iyẹ rẹ walé.

Ẹṣẹ Ja a ni Olẹ

Ọmọkunrin yii jẹ apẹẹrẹ apẹyindà -- ẹni ti o mọ ifẹ Ọlọrun ṣugbọn ti o pada sẹyin ti o si fi ọpọlọpọ nnkan ṣofo ninu aye ẹṣẹ. Ọpọlọpọ ẹlẹṣẹ ni o jẹ nigba ti iyẹ wọn ba walé, wọn o ri i pe afẹ aye ti gba ohun rere gbogbo kuro lọwọ wọn. Gẹgẹ bi ọdọmọkunrin yii, wọn wà ninu aini. Wọn kò ni ohun wọnni ti o jẹ pataki lati mu ki ẹmi wa laaye. Wọn o ri ara wọn pe wọn jẹ ẹrú eṣu. Wọn ti nawo wọn ti nara fun ohun wọnni ti ki i tẹ ni lọrun (Isaiah 55:2).

Ọdọmọkunrin naa mọ ọna lati yọ kuro ninu ipo buburu yii. O pinnu lati tọ baba rẹ lọ ati lati jẹwọ ẹṣẹ ati ikuna rẹ. O ṣe ju pe ki o pinnu lasan lọ; o mu ipinnu rẹ ṣẹ.

Pada si Ile Baba

Dajudaju baba rẹ ti n wo ọna o si ti n reti ipadabọ rẹ; nitori nigba ti o “wà li okere,” baba rẹ sure lati pade rẹ. Ọmọ-oninakuna yii jẹwọ ẹṣẹ rẹ, ó ni oun ti dẹṣẹ si baba oun ati Ọlọrun. O rò pe oun kò yẹ ni ẹni ti a le maa pe ni ọmọ rẹ mọ, ṣugbọn baba rẹ fi tayọtayọ gbà a si ile. Boya ọdọmọkunrin yii n reti ibawi, ṣugbọn dipo eyi, o ri ifẹnu-ko-ẹnu ati idariji gbà.

Awọn ọmọ oninakuna bẹẹ wà ninu aye lonii. Nigba kan ri wọn ti mọ Oluwa. Nitori aibọwọ fun ofin Ọlọrun, wọn fẹ ọna ti ara wọn titi Ọlọrun fi gbà fun wọn lati rin gẹgẹ bi wọn ti fẹ. Wọn ti lo akoko wọn, owo wọn, agbara wọn lati sin ara wọn ati aye. Iyẹ wọn i ba jẹ pada wale, ki ni i bá ti dara to! Oluwa yoo pade wọn bi wọn yoo ba pada pẹlu ironupiwada ati irẹlẹ.

Gẹgẹ bi ọmọ-oninakuna ninu owe yii, wọn o ri gbà ju eyi ti wọn beere. O pada ninu àkisà o si n bẹbẹ pe ki a fi oun ṣe ọmọ-ọdọ, ṣugbọn a fi aṣọ ti o dara ju lọ wọ ọ, ati bata, ati oruka ipò ọlá. Oluwa a maa fi agbada igbala wọ awọn eniyan Rẹ, agbada òdodo, a si fi imura Ihinrere wọ ẹsẹ wọn ni bata (Isaiah 61:10; Efesu 6:15).

Ebi pa ọmọ-oninakuna naa. Baba rẹ fi ounjẹ bọ ọ -- ki i ṣe ounjẹ ajẹkù tabi ẹran ti kò ni laari, ṣugbọn abọpa ẹran ti a ṣẹṣẹ pa. Wò o bi ayọ wọn ti pọ to! Ọmọ-oninakuna ti pada wá ile – a si gbà a pada si ipò rẹ! Kò tun ni idalẹbi ninu ọkàn rẹ mọ. O tun wà laaye lẹẹkan si i, ẹni ti o ti kú ninu irekọja ati ẹṣẹ (Efesu 2:1).

Njẹ awọn akọwe ati awọn Farisi dabi ẹgbọn ọmọkunrin yii -- amọ-ti-ara-rẹ-nikan, afunnu, alasọ, alai-le-dariji-ni, ẹni ti o kọ ibatan rẹ silẹ? Nipa riro pe ile naa kò tobi to fun awọn mejeeji, o duro si ode nigba ti awọn iyoku n yọ nitori ẹlẹṣẹ kan pada wálé, ẹni ti Jesu dé lati wá ati lati gbalà (Luku 19:10).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ohun ti awọn akọwe ati awọn Farisi n kùn si?
  2. Ki ni àṣiṣe ti o wà ninu ohun ti wọn n sọ?
  3. Bawo ni ẹlẹṣẹ ṣe dabi agutan ti o sọnu?
  4. Ki ni ṣe ti o lewu lati jẹ agutan ti o sọnu?
  5. Ki ni ṣe ti obinrin naa fi n wá owo fadaka rẹ ti o sọnu?
  6. Ki ni ṣe ti Jesu n wá awọn ti o sọnu ?
  7. Nibo ni ọmọ-oninakuna ti ṣe aṣiṣe rẹ?
  8. Ta ni maa n yọ nigba ti ẹlẹṣẹ kan ba ri igbala? Ki ni ṣe?