Isaiah 12:1-6; Habakkuku 3:17-19

Lesson 151 - Junior

Memory Verse
“Kiyesi i, Ọlọrun ni igbala mi; emi o gbẹkẹle, emi ki yio si bẹru” (Isaiah 12:2).
Notes

Ọgbà Ọlọrun

Ọlọrun fun awọn eniyan ti O da ni ohun gbogbo ti o yẹ lati mu inu wọn dùn. Ifẹ Rẹ nigba ti O fi wọn sinu Ọgbà Edẹni ni pe ki wọn maa yọ ninu ẹwà ibugbe wọn, ki wọn si yin Oun logo bi awọn angẹli ti n ṣe ni Ọrun. Wọn si ṣe bẹẹ -- titi ẹṣẹ fi wọle. Ẹṣẹ mu ayọ naa kuro ninu ọkan wọn, o jà wọn ni olẹ ẹwà ti o yi wọn ka, o si ti wọn jade kuro ninu paradise bọ sinu aye ẹgún lati maa ṣiṣẹ fun ounjẹ oojọ wọn.

Nigba ti Ọlọrun yan awọn Ọmọ Israẹli gẹgẹ bi eniyan ọtọ fun ara Rẹ, O tun da ibukun Rẹ lu wọn, ni ireti pe wọn o yin In fun oore Rẹ ki wọn si gbadun igbesi aye ti o ṣànfaani. O ti ṣeleri ohun gbogbo fun wọn eyi ti wọn le la ala rẹ tabi ti wọn le reti rẹ. Ṣugbọn wọn ṣẹ pẹlu, wọn si sọ eyi ti o pọ ju lọ nu ninu ẹrẹ ti Ọlọrun fẹ fi fun wọn. Wọn di eniyan ti a tuka kiri ti wọn si ti jiya inunibini kikoro lati ọpọlọpọ ọdun yìí wá.

O Ba Ọlọrun Ninu Jẹ

O dun Ọlọrun de ọkan pe awọn eniyan Oun ṣá Oun ti si apa kan. Wọn ko tilẹ jẹ oloootọ si I bi awọn ẹranko ti i jólóòtọ si oluwa wọn. Nipasẹ Wolii Isaiah, Ọlọrun wi pe: “Mal mọ oluwa rẹ, kẹtẹkẹtẹ si mọ ibujẹ oluwa rẹ: ṣugbọn Israẹli kò mọ, awọn enia mi kò ronu” (Isaiah 1:3). Awọn ẹsẹ Iwe Mimọ ti o mu ni lọkàn pupọ wa ninu iwe awọn wolii naa nibi ti Ọlọrun gbe fi ibanujẹ kigbe pe awọn ayanfẹ Oun ti kuro lọdọ Oun, olukuluku si ti tẹ si ọna ara rẹ. Nigba ti Jesu wa ni aye O sọkun lori Jerusalẹmu: “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, … igba melo ni emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ labẹ apá rẹ, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ!” (Matteu 23:37). O sọ eleyi nigba ti o ku diẹ ki a kan An mọ agbelebu; O fi ọrọ yìí kun un: “Ẹnyin ki yio ri mi mọ lati isisiyi lọ, titi ẹnyin o fi wipe, Olubukún li ẹniti o mbọ wá li orukọ Oluwa” (Matteu 23:39). Ko si igbà kan lati akoko naa ti awọn Ju ti i tẹwọgba Jesu ni apapọ, ṣugbọn ọjọ kan n bọ wa nigba ti ọpọlọpọ Ju yoo tẹwọgba A gẹgẹ bi Messia, ti wọn o lọ si Jerusalẹmu lati juba Rẹ ni akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun, akoko pataki ti a sọ asọtẹlẹ rẹ jake-jado Bibeli. Ni ọjọ naa Oun ni yoo jẹ Ọba wọn, Oun yoo si jọba pẹlu Ijọ Rẹ ni ododo kaakiri àgbaye.

Ni ti akoko naa ni Isaiah sọ: “Ati li ọjọ na iwọ o si wipe, OLUWA, emi o yin ọ: bi o tilẹ ti binu si mi, ibinu rẹ ti yi kuro, iwọ si tù mi ninu” (Isaiah 12:1). Lẹyin ọpọlọpọ ọgọrun ọdun ti wọn ba ti jiya idajọ Ọlọrun, awọn Ju yoo ronupiwada, wọn o si ri itunu ninu Oluwa. Gbogbo aigbọran ati ikorira wọn ati kikuro lọdọ Ọlọrun ni a o dariji ti a o si gbagbe, bi wọn ti n rẹ ara wọn silẹ niwaju Ọba wọn.

Ijọba Ninu Ọkan

A ko ṣẹṣẹ ni lati duro di igba Ijọba Ẹgberun Ọdun, nigba ti a o gbe ijọba Kristi kalẹ ninu ayé, ki a to gbadun awọn ibukun ti a n sọrọ rẹ ninu ori-ẹkọ yii. Nisisiyii Ijọ tootọ ti n fi ayọ fa omi jade “lati inu kanga igbala wá.” Bi a ba ti n fi ayé wa fun Jesu ti a si n ri idariji gbà fun ẹṣẹ wa, ayọ Oluwa yoo wọ inu ọkàn wa ninu eyi ti gbogbo ayọ ti a ti ni ri yoo di alainilaari. Ijọba Rẹ ti bẹrẹ ninu ọkan wa.

Ayọ ninu Idanwo

Ọnà Onigbagbọ le má fi igbà gbogbo dán, ṣugbọn alaafia ti inu wa bakan naa, bi o tilẹ ṣe pe wahala wa fun un lode ara. O le kọrin lati ọkàn wá, ki o si fi tinutinu rẹrin ninu idanwo ti o gbona janjan.

Jesu sọ fun awọn ọmọlẹyin Rẹ pe wọn o jiya inunibini, ṣugbọn O fi kun un pe: “Ẹ mã yọ, ki ẹnyin ki o si fò fun ayọ; nitori ẹre nyin pọ li ọrun: bẹẹni nwọn sá ṣe inunibini si awọn wol ti o ti mbẹ ṣãju nyin” (Matteu 5:12). Awọn kan rò pẹ nigbà ti oju wọn ba fàro ni wọn jẹ olufọkansin, ṣugbọn Jesu n fẹ ki awọn eniyan Oun maa yọ, ani ninu idanwò pẹlu. “Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye” (Johannu 16:33).

Orin Iyin Dafidi

A kà nipa hilà-hilo ti o bá Dafidi nigbà ti Ọba Saulu gbiyanju nigbà pupọ lati pa a. O ni lati fi ile ati ẹbi rẹ silẹ ki o ba le gba ẹmi rẹ là, pupọ ninu awọn ọrẹ rẹ si kọ ọ silẹ. Ṣugbọn ninu gbogbo ọdun iyiriwo wọnyii o le kọrin si Oluwa; pupọ ninu awọn Saamu ti o si kọ silẹ nigbà ti o wà ninu wahala ti o jinlẹ jẹ orin iyin. O kọrin si Oluwa pe: “Ni iwaju rẹ li ẹkún ayọ wà: li ọwọ ọtún rẹ ni didùn-inu wà lailai” (Orin Dafidi 16:11). Ti o ba ṣe e ṣe fun Dafidi lati kọrin si Oluwa ninu idanwo rẹ lati ibẹrẹ titi de opin, o ṣe e ṣe bakan naa fun olukuluku Onigbagbọ. Bi a ko ba ni ohù n fun orin, sibẹ a le maa kọrin didun lati inu ọkàn wa si Oluwa (Efesu 5:19).

Agbara Orin

Awọn kan le jẹ ki irẹwẹsi sọ orin wọn di alainilaari, wọn a wa di alailagbara nipa ti ẹmi. Isaiah wi pe: “OLUWA JEHOFA li agbara mi ati orin mi.” Agbara ati orin maa n rin pọ ni. Nigba ti igboyà ba kunà, kọrin. Ọlọrun maa n fun awọn eniyan Rẹ ni orin ni oru lati tu ọkàn wọn lara. Nigbà ti Nehemiah gba ipẹ lati ọdọ Ọlọrun lati tún odi Jerusalẹmu kọ, awọn Ọmọ Israẹli gẹgẹ bi orilẹ-edẹ ti pada di ẹrú gẹgẹ bi igba ti wọn wa ni Egipti. Ṣugbọn Nehemiah mu wọn lọkàn le: “Ayọ OLUWA on li agbára nyin” (Nehemiah 8:10). Nigba ti wọn yi ọkàn wọn pada si Ọlọrun, ayọ ti wọn ni fun wọn ni igboya ati agbara lati tẹ siwaju ati lati mọ odi, lai fi iyọṣutisi awọn Keferi ti o n wò wọn pẹ.

Ti aarẹ ba mu igbagbọ wa, tí à ti rìn ní ọnà igbagbọ si di ẹtì, o yẹ ki a bẹrẹ si yin Oluwa. Ki a ranti awọn ibukun ti O ti ṣe fun wa sẹyin; ki a si kà ninu Bibeli awọn ileri ti O ti ṣe fun awọn oloootọ. Orin iyin, ati ọpẹ yoo gba ọkàn wa kan, agbara ọtun yoo si ṣàn wọ inu wa. Igbagbọ wa yoo ru soke, a o si mọ ọn lara bi i ti Dafidi nigba ti o wi pe, “Nitori nipa rẹ li emi ti là arin ogun kọja: nipa Ọlọrun mi emi ti fò odi kan” (2 Samuẹli 22:30).

Ọlọrun n fẹ ki inu awọn eniyan Rẹ maa dùn. Jesu wi pe “Ẹ bẹre, ẹ o si ri gbà, ki ayọ nyin ki o le kún” (Johannu 16:24). Lati inu alaafia atọkàn-wa ti Jesu n fun ni ni ayọ wa ti n wá. “Nitori ijọba Ọlọrun ki iṣe jijẹ ati mimu; bikoṣe ododo, ati alafia, ati ayọ ninu Ẹmi Mimọ” (Romu 14:17).

Ayọ ninu Ibanujẹ

Njẹ bi a ba ti gbadura ti a si ti beere awọn nnkan lọwọ Ọlọrun ṣugbọn ti Oun ko ti i fun wa n kọ? O ha yẹ ki a sọkun pe a ni ijatilẹ? Ni akoko ti Habakkuku Wolii sọrọ, ẹṣẹ papọju lori ilẹ. Awọn eniyan Ọlọrun ti kuro lọdọ Rẹ, idajọ si ti de ba wọn. Ojo ti dasẹ lati maa rọ, abayọrisi eyi si ni iyan. Ṣugbọn Habakkuku jẹ eniyan Ọlọrun tootọ o le wi pe: “Bi igi ọpọtọ ki yio tilẹ tanná, ti eso kò si ninu àjara; iṣẹ igi-olifi yio jẹ aṣedanù, awọn oko ki yio si mu onjẹ wa; ... ṣugbọn emi o ma yọ ninu OLUWA, emi o ma yọ ninu Ọlọrun igbàla mi” (Habakkuku 3:17, 18).

Ayọ Onigbagbọ ki i ṣe lati inu awọn nnkan ti o ni, igbadun ti o yi i ká, tabi ifẹ inu rẹ ti a mu ṣẹ. Ayọ rẹ wà nipa ṣiṣe ifẹ Ọlọrun. Oun yoo sọ pẹlu Dafidi Onisaamu pe: “Inu mi dùn lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun mi, nitõtọ, ofin rẹ mbẹ li aiya mi” (Orin Dafidi 40:8).

Boya Oluwa n yiiri Onigbagbọ naa wò. A n da a bi wura ninu ooru gbigbona nlá nlà. Eredi rẹ?

“Lẹba ina ileru ti a dá lẹẹmeje

O jokoo n wo ohun iyebiye ti a wà ninu ilẹ,

Finnifinni ni O tẹju mọ ọn,

Bi o ti n fina mọ ọn fikanfikan.

O mọ pe yoo le yeje idanwo ina naa

Wura ti o peye ju ni O n fẹ

Lati fi ṣe ade fun Ọba,

Ti a ṣe lọṣọ ti ko lẹgbẹ.

A ha n fẹ lati la igbà iyiriwo kọja, boya ki awọn eniyan ṣe inunibini si wa, ki a ba le já si wura ti o mọ gaara fun ilo Ọlọrun?

Ifojusọna

Awọn eniyan Ọlọrun tootọ a maa fi ayọ sin In – ki i ṣe pẹlu ibanujẹ, tabi isọreti nù, tabi aniyan nipa ọjọ ọla. Ojoojumọ ni ọjọ idupẹ, nitori wọn n sin In pẹlu ifojusọna lati ri I nigbakigba ti O ba fara han ni awọsanma, gẹgẹ bi Ọkọ-Iyawo ọkàn wọn. Jesu wi pe nigba ti a ba ri ti ifoyà nla ati wahala ba de sori ayé, “Njẹ ki ẹ wò òke, ki ẹ si gbé ori nyin soke; nitori idande nyin kù si dẹdẹ” (Luku 21:28).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Lori adehùn wo ni awọn eniyan akọkọ fi gbé Ọgbà Edẹni?
  2. Inu Ọlọrun ha dùn nigbà ti Adamu ati Efa ṣẹ?
  3. Asọtẹlẹ wo ni Jesu sọ nipa awọn Ju nigba ti O sọkun lori Jerusalẹmu?
  4. Ki ni Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun?
  5. Nibo ni Ijọba Ọlọrun wa nisisiyii?
  6. Ki ni yẹ ki a ṣe nigba ti wọn ba n ṣe inunibini si wa?
  7. Iru orin wo ni Dafidi kọ nigba ti o n sá kiri?
  8. Ipo wo ni Israẹli wà nigba ti Habakkuku kọ asọtẹlẹ rẹ silẹ?
  9. Ni iru igbà wo ni Habakkuku wi pe oun yoo yọ?
  10. Ki ni ṣe ti o fi le maa yọ?