Numeri 27:15-23; Deuteronomi 34:9; Joṣua 1:1-18

Lesson 152 - Junior

Memory Verse
“Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹẹli emi ki yio kọ ọ” (Joṣua 1:5).
Notes

Ijolootọ Mose

Iṣẹ Mose eniyan Ọlọrun, oloootọ aṣaaju fun Israẹli fun ogogji ọdun, ti pari. Wo bi suuru rẹ ati ẹbẹ rẹ niwaju Ọlọrun ti pọ to! Njẹ ẹlomiran ha wà ti o le rọpò rẹ? Njẹ ẹlomiran ha wa ti o le ṣe aṣaaju ọpọ awọn eniyan yìí lọ si Ilẹ Ileri?

Ọlọrun ti n pese ẹlomiran silẹ gẹgẹ bi aṣaaju Israẹli. Nigba ti akoko to lati yan arọpò Mose, ki i ṣe awọn eniyan ni o dibò; bẹẹ ni Mose paapaa kò gbẹkẹle ọgbọn ti ara rẹ lati yàn. Awọn eniyan Ọlọrun ni awọn wọnyii, o si jẹ ojuṣe Rẹ lati yan alaṣẹ titun naa. Mose gbadura: “Jẹ ki OLUWA, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ki o yàn ọkunrin kan sori ijọ, ti yio ma ṣaju wọn jade lọ, ti yio si ma ṣaju wọn wọle wá” (Numeri 27:15-17).

Lai si aniani Mose le mọ awọn iranṣẹ Ọlọrun tootọ laaarin awọn alagbara ọkunrin rẹ. Awọn eniyan naa le ri ẹni ti o jẹ akikanjú ọkunrin ninu ogun ti o si fi hàn pe oun le ṣe aṣaaju awọn eniyan. Ṣugbọn Ọlọrun nikan ni O ni agbara lati mọ “ọkàn gbogbo enia.” Ọlọrun mọ ju ẹnikẹni lọ, ẹni ti yoo gbọran si Oun lẹnu ti yoo si sin Oun tọkàntọkàn.

Ẹmi Iyasọtọ lati Kekere

Nigbà ti Joṣua wà ni kekere ni o ti ya ayé rẹ sọtọ fun isin Ọlọrun (Numeri 11:28), o si ti ṣe iranṣẹ Mose fun ọdun pupọ, ni ṣiṣẹ ti o rẹlẹ fun ọkunrin naa ti o fẹran, gẹgẹ bi fun Ọlọrun. O ni anfaani lati gun okẹ de apakan pẹlu Mose nigbà ti o lọ gba Ofin lọdọ Ọlọrun. Eyi ni lati fi ifẹ ti o tobi ju bẹẹ lọ fun Ọlọrun sinu ọkàn Joṣua, ati ipinnu lati gbe igbesi aye rẹ lati wu U. Lẹyin eyi o ti lo akoko pupọ ninu Agọ, dajudaju o n gbadura fun Mose, o si n ya ara rẹ si mimọ fun Oluwa.

Nigbà ti Mose n fẹ akikanju ọkunrin ti yoo ṣaaju awọn Ọmọ Israẹli lọ si ogun lati bá awọn ara Amaleki jà, Joṣua ti ṣe tan lati lọ. Ọlọrun fun Israẹli ni iṣẹgun nla ni ọjọ naa.

O jẹ iwa eniyan lati bu ọlá fun ẹni ti o ba hu iwa akọni. Boya awọn eniyan n wo Joṣua gẹgẹ bi akọni fun orilẹ-ede nigbà ti ogun naa pari. Bi o tilẹ jẹ pe ọgbọn ati igboyà Joṣua jẹ ohun pataki ju eyi ti Ọlọrun le lo, Ọlọrun kò tilẹ darukọ wọn nigbà ti O yan Joṣua gẹgẹ bi aṣaaju Israẹli ni ọjọ iwaju. O n wo ohun kan ti o ṣe pataki ju eyi lọ Ọlọrun sọ fun Mose: “Iwọ mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkunrin ninu ẹniti ẹmi wà” (Numeri 27:18). Iṣẹ ti ọgbọn tabi agbara wa le ṣe kò jamọ nnkan kan bi a ba fi we ohun ti Ẹmi Ọlọrun le tipasẹ wa ṣe bi a ba jọwọ ara wa silẹ!

A ti yan Joṣua lati ba Kalẹbu lọ nigbà ti awọn ami mejila lọ si Kenaani ni ọdún meji-din-logoji (38) ṣiwaju akoko yìí. Yatọ si ti awọn ami mẹwaa iyoku, Ọlọrun sọ nipa Joṣua ati Kalẹbu pe wọn ni ẹmi miiran. Ọlọrun le ṣiṣẹ, ki O si ki awọn eniyan layà nipasẹ wọn.

Ẹkọ Ṣe Pataki

Fun ọdun pupọ ni Ọlọrun ti n kọ Joṣua lẹkọọ fun iṣẹ aṣaaju yìí. O fẹrẹ to ogoji ọdun sẹyin ti Joṣua ti yà ara rẹ sọtọ fun iṣẹ-isin rẹ, gẹgẹ bi Eliṣa, ẹni ti “ntu omi si ọwọ Elijah.” A kò kà pe agara iṣẹ rẹ da a, tabi ki o maa rò pe n jẹ oun tun le ṣe iṣẹ-isin ti o dara ju eyi lọ. Nipa iriri o fara balẹ kọ ẹkọ ti yoo mu un jẹ ọlọgbọn ati aṣaaju ti o ni òye.

A sọ fun ni pe nigba kan ti Joṣua ṣi wà ni ọmọde sibẹ, ti kò ti i ni iriri to, inu rẹ ko dùn nigbà ti o rò pe awọn kan wà ti wọn n fẹ pin ọla ati ẹyẹ ti i ṣe Mose. A ti yan awọn aadọrin agbaagbà lati ran Mose lọwọ, wọn si ni lati lọ si inu Agọ lati lọ ṣe iṣẹ-isin wọn. Ṣugbọn meji ninu awọn ọkunrin wọnyii wà ninu agọ wọn, wọn si n ṣotẹlẹ. Joṣua sare lọ sọdọ Mose, o si ro pe o yẹ ki a dá awọn ọkunrin wọnyii lẹkun. Ṣugbọn Mose ko ro pe wọn n gba ọlá ti oun lọwọ oun. O wi pe, “Gbogbo enia OLUWA iba le jẹ wol, ki OLUWA ki o fi ẹmi rẹ si wọn lara! (Numeri 11:29).

Ọlọrun ki i rán ẹni ti Oun ko ti i kọ lẹkọọ jade lati maa boju to awọn agutan Rẹ. Awọn aṣaaju ti O n yàn gbọdọ ti ni ẹkọ - ki i ṣe ninu Ẹkọ Ihinrere nikan, ṣugbọn nipa gbigbe igbesi aye Onigbagbọ. Wọn ni lati ni ọgbọn eyi ti o n wá nipasẹ iriri. Jesu tikara Rẹ gbe laaarin awọn eniyan fun ọgbọn (30) ọdun ki O to bẹrẹ iṣẹ-iranṣẹ Rẹ. Akoko naa kò ṣòfò rará. Nigbà ti O wà ni ọmọ ọdun mejila, a ri I ninu Tẹmpili, O n sọ nipa iṣẹ Baba Rẹ ti n bẹ ni Ọrun; lai si aniani, igbesi aye ti O gbe lẹyin naa fa awọn eniyan mọra. O jiya pẹlu awọn eniyan, ki O ba le mọ irora wọn, ki Oun si le mọ ati tù wọn ninu. A dan An wò ni gbogbo ọna gẹgẹ bi awa (ṣugbọn lai lẹṣẹ), ki Oun ba le ran awọn ti a n danwo lọwọ. Lẹyin ti Ẹmi Mimọ ti bale E paapaa nigba ti a ri I bọmi ninu Odo Jọrdani, O lọ si iju, ki a ba le ti ọwọ eṣu dan An wò, fun ogoji ọjọ ki o to bẹrẹ iṣẹ-iranṣẹ Rẹ. Dajudaju, oye gbogbo ajeji idanwo ti o le de ba wa lẹ ye E!

Loju Awọn Eniyan

Ọlọrun ri ẹmi tootọ ninu Joṣua. Yiyàn rẹ si ti de nisisiyii, Mose mu Joṣua wá siwaju Ijọ eniyan; ati si ibi ti gbogbo eniyan ti le ri i, o gbé ọwọ le ori Joṣua, o si fi agbara rẹ sori aṣaaju titun yii. A mu ki awọn alufaa pẹlu mọ pe Joṣua ko gba ọla yii fun ara rẹ, ko fi ara rẹ ṣe alakoso lori wọn, ṣugbọn Ọlọrun ni o yàn án lati ipasẹ Mose iranṣẹ Rẹ. Lati igba yii lọ, awọn eniyan ni lati maa bu ọla fun Joṣua ki wọn si maa bu iyin fun un gẹgẹ bi wọn ti ṣe fun Mose.

Ọlọrun yoo maa ba awọn alufaa sọrọ nipa Urimu ati Tummimu, wọn yoo si jẹ ki ifẹ Ọlọrun di mimọ fun Joṣua. Lẹyin naa awọn eniyan gbọdọ gbọran si ohun ti Joṣua ba pa láṣẹ. Ọlọrun yoo maa ṣe Amọna wọn sibẹ.

Mimu Aya le

Mose kú. Fun igba diẹ Joṣua yoo mọ ọn lara lati dá nikan ṣoṣo wà. Gbogbo ẹrù awọn ọmọ Israẹli ti wá sori rẹ, oun ko tilẹ le ba Mose sọrọ mọ nipa awọn iṣoro rẹ. Ṣugbọn Ọlọrun wá fun un, O si ki i laya. O sọ fun Joṣua leralera pe, “Ṣe giri, ki o si mu àiya le.”

Iṣẹ pupọ wà lati ṣe. Irinkiri fun ogoji ọdun ninu aginju ti dopin, o si to akoko lati rekọja Jọrdani. Eyi ki i ṣe akoko lati bẹrù; ta ni yoo si foyà pẹlu awọn ọrọ wọnyii ti Ọlọrun sọ fun Joṣua: “Ki yio sí ọkọnrin kan ti yio le duro niwaju rẹ li ọjọ aiye rẹ gbogbo: gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹẹli emi o si wà pẹlu rẹ: Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹẹli emi ki yio kọ ọ” (Joṣua 1:5). Ko yẹ ki eniyan bẹru pẹlu awọn ileri ati iranwọ Ọlọrun wọnyii.

Awọn ileri wọnyii wa fun wa bakan naa lonii. Njẹ ẹru n ba wa lati gbẹkẹle Ọlọrun? Nigba ti ara wa ba ṣe alai da, njẹ a maa n gbadura si I lati wo wa sàn, ki a si gbẹkẹle E pe Oun yoo ṣe e? Nigbà ti a ba wa ninu wahala, njẹ a maa n kó aniyan wa lọ sọdọ Jesu, ki a si mọ pe Oun n ṣe aniyan wa?

Awọn Ẹlẹri ti O Ni Igboya

Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe, “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ orilẹ-ẹde gbogbo, … ki ẹ ma kọ wọn lati ma kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin: ẹ si kiyesi i, emi wà pẹlu nyin nigbagbogbo, titi o fi de opin aiye” (Matteu 28:19, 20). Jesu wà pẹlu awọn ẹlẹri Rẹ lonii, a si gbọdọ jẹ alagbara ati onigboya.

Ki ni yoo fun wa ni igboya yii? Igbọran si Ọrọ Ọlọrun ni. Ọlọrun sọ fun Joṣua lati gbọran si gbogbo Ofin Rẹ, gẹgẹ bi Mose ti ṣe. “Má ṣe yà kuro ninu rẹ si ọtún tabi òsi, ki o le dara fun ọ nibikibi ti iwọ ba lọ. Iwé ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rẹ li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rẹ: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọna rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ” (Joṣua 1:7, 8).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni yoo jẹ aṣaaju titun fun Israẹli?
  2. Nigba wo ni a kọkọ gbọ nipa rẹ?
  3. Iṣẹ nla wo ni o ṣe ni ibẹrẹ irin-ajo Ọmọ Israẹli?
  4. Bawo ni o ti sin Mose pẹ to ki a to yàn án ni aṣaaju?
  5. Ki ni Ọlọrun sọ nipa Joṣua nigba ti O yan an ni aṣaaju?
  6. Igba miiran wo ni a gbọ ti a sọ iru ọrọ bayii nipa Joṣua ati ọrẹ rẹ Kalẹbu?
  7. Ọrọ ikiya wo ni Ọlọrun sọ fun Joṣua lẹyin ti Mose kú?
  8. Ki ni Joṣua gbọdọ ṣe ki o ba le dara fun un?