Lesson 153 - Junior
Memory Verse
“Nigbati emi ba ri ẹjẹ na, emi o ré nyin kọja” (Ẹksodu 12:13).Notes
Jẹriko
Ni apa iwọ-oorun Odo Jọrdani, laaarin ọpọlọpọ igi ọpẹ, ni ilu daradara Jẹriko wà. Ilu ti o kun fun ọrọ pupọ ni, a si fi odi nla yi i ká lati sé awọn ọta ti o le wá gbogun ti i mọ òde, ti wọn le fẹ ji wura ti o wà ninu ilu Jẹriko, ṣugbọn eniyan buburu ni wọn, Ọlọrun si ti ṣe ileri lati fi ilu wọn fun awọn Ọmọ Israẹli.
Awọn Ọmọ Israẹli ti de agbegbe Kenaani, ilu kin-in-ni ti wọn si ni lati doju ija kọ ni Jẹriko. Joṣua ti rán awọn amí lati lọ wo bi awọn eniyan ti o wa ninu rẹ ti pọ to ati iru eniyan ti wọn jẹ. Ẹnu ọna wa lara odi ilu naa eyi ti a maa n ṣi silẹ nigba ọsan, awọn ami naa si wọle lai si pípẹ wọn bi leere ohunkohun, wọn wọ ilu naa gẹgẹ bi alejo ti ko le ṣe awọn eniyan ni ibi.
Awọn ogiri ti o yi Jẹriko ka fẹ to bẹẹ ti a le kọ ile si ori wọn. Ọkan ninu awọn iru ile bẹẹ ni ile-ero ti i ṣe ti Rahabu, nibi ti awọn ami wọnyii de si ti wọn sun mọju.
Ifura
Ọba Jẹriko mọ pe awọn Ọmọ Israẹli pagọ si odi keji Jọrdani, o si mọ iru ewu ti ogun nla bayii le jẹ fun ilu rẹ. Awọn ami ti rẹ naa n ṣọ ẹṣọ bakan naa, wọn si ri awọn ọkunrin ajeji meji ti wọn wọ si ile-ero ti Rahabu. Wọn sọ fun ọba o si rán awọn oniṣẹ lati wá wọn lọ.
Awọn ile ti o wa ni Jẹriko jẹ ile ti a fi orule pẹrẹsẹ bo, Rahabu si tẹ ọgbọ si ori orule rẹ lati sa a ninu oorun. Labẹ ọgbọ yii ni o fi awọn ami meji wọnyii pamọ si; nigba ti awọn oniṣẹ si de o wi fun wọn pe awọn alejo naa ti kuro ni ilu, ati pe bi wọn ba yara lepa wọn, wọn le bá wọn ki wọn to rekọja odò. Ọrọ naa mu wọn lọkan ti awọn oniṣẹ naa fi mura kikan lati lepa wọn lẹsẹ kan naa. Ilẹ ti n ṣú lọ a si ti sé ilẹkun nla ẹnu ode to bẹẹ ti ko si ẹni ti o le jade tabi ki o wọ inu ilu naa. ki i ṣe ohun ti tọna lati purọ, ṣugbọn abọriṣa ara Kenaani ni oun i ṣe, ko si mọ ofin, “Iwọ kò gbọdọ jẹri eke.”
Igbagbọ Rahabu
Ohun ti fifi awọn amí wọnyii pamọ já si ni pe Rahabu jẹ onikupani eniyan fun ọba rẹ; bi wọn ba si mu un boya pipa ni wọn i ba pa a. Ṣugbọn o bẹru Ẹni kan ju bi o ti bẹru iku lọ. O bẹru Oluwa. Bayii ni o sọ fun awọn amí: “OLUWA Ọlọrun nyin on li Ọlọrun loke ọrun, ati nisalẹ aiye.” O mọ pe gbogbo agbara wa lọwọ Rẹ, o si ni igbagbọ pe O le ṣe ohun nlá nlà ju eyi ti eniyan le ṣe lọ.
Jesu sọ fun awọn eniyan nigba kan pe, “Ẹ máṣe bẹru awọn ti ipa ara enia kú, lẹhin eyini ti nwọn kò si li eyiti nwọn le ṣe mọ… “Ẹ bẹru ẹniti o lagbara lẹhin ti o ba pa-ni tan, lati wọ-ni lọ si ọrun apadi” (Luku 12:4, 5). Eyi ni ẹru ti Rahabu ti moye rẹ niwọn ọpọlọpọ ọgọrun ọdun ṣaaju igba ti Jesu waasu ni ayé.
Àmi Tootọ
Rahabu fi ẹmi rẹ wewu nipa gbigba wọn silẹ, o si beere fun aanu nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ba wọ inu ilu Jẹriko ni iṣẹgun. O sọ pe awọn ti gbọ nipa ohun iyanu ti Ọlọrun ti ṣe fun awọn eniyan Rẹ ki wọn to fi Egipti silẹ. Awọn ara ilu Jẹriko mọ pe awọn Ọmọ Israẹli ti ni iṣẹgun ninu gbogbo ogun ti wọn ti jà, eyi si mu ki ẹru ba wọn to bẹẹ ti ọkan wọn “di omi” ninu wọn. O mọ pe Ọlọrun yoo fun awọn eniyan Rẹ ni ilu yii pẹlu.
Awọn amí naa ṣe ileri pe wọn yoo san oore ti o ṣe fun wọn pada. Ohunkohun ki yoo ṣẹlẹ si i ati awọn ara ile rẹ bi wọn ba wa ninu ile rẹ, bi o ba le ṣe ileri pe oun ki yoo sọ fun ọba pe wọn wọ si ibẹ. Gẹgẹ bi àmì tabi ẹri fun ileri wọn, oun yoo so okùn owú ododo kan mọ ferese ile rẹ. Nigba ti awọn ọmọ-ogun ti n bọ wa ba ri i, wọn yoo mọ pe eyi ni ile Rahabu ẹni ti o bá Israẹli dọrẹ.
Awọn amí ti pari iṣẹ wọn, gẹgẹ bi o si ti jẹ oru ti a si ti ti ilẹkun odi ilu. Rahabu fi okun òdòdó ni sọ wọn kalẹ lati ilé rẹ si ilẹ lẹyin odi ilu. O fun wọn ni imọran pe ki wọn fi ara pamọ fun ọjọ diẹ titi awọn oniṣẹ ti o wá wọn lọ yoo fi pada. Wọn ṣe bẹẹ, wọn si sá asala lọ si agọ awọn Ọmọ Israẹli.
Okun Owu Ododo Ni
Okun owu ododó naa ju ami nikan lọ fun ile Rahabu. O jẹ apẹẹrẹ Ẹjẹ Jesu, okun owu ododo ti a nà ká gbogbo Iwe Mimọ. Lati igba ti a ti pa ẹran lati fi awọ rẹ bo Adamu ati Efa nigba ti wọn dẹṣẹ ninu Ọgbà Edẹni, tita ẹjẹ silẹ jẹ apẹẹrẹ imukuro ẹṣẹ. “Ati laisi itajẹsilẹ kò si idariji” (Heberu 9:22). Abẹli fi ọdọ-agutan ti o pa lati inu agbo ẹran rẹ rubọ si Ọlọrun, a si tẹwọ gba a bi ẹbọ ti o tọna. Baba ninu idile kọọkan ni o maa n ru ẹbọ sisun titi di igba ti Ọlọrun fi isin agọ lelẹ, a si fi iṣẹ pipa ẹran naa le awọn alufaa lọwọ, ati tita ẹjẹ silẹ fun imukuro ẹṣẹ awọn eniyan.
Gbogbo awọn irubọ wọnyii jẹ apẹẹrẹ wiwa Jesu Ọdọ-agutan Ọlọrun Ẹni ti o ko ẹṣẹ araye lọ. A ta Ẹjẹ Rẹ silẹ ni Kalfari lati pese etutu silẹ fun gbogbo awọn ti o ba n fẹ ki a gba wọn la.
Aabo Wa
Aabo wa lonii ni Ẹjẹ Jesu. Nigba ti Ẹjẹ naa ba bo ọkan wa ti o si wẹ ẹṣẹ wa nu a o bọ lọwọ apanirun. A o wa lai lewu gẹgẹ bi ile Rahabu ti wa lai lewu ninu ile naa ti a ta okun owu ododo si oju-ferese rẹ. Ṣugbọn a ni lati wa labẹ ẹjẹ naa. Ọranyan ni fun awọn ara ile Rahabu lati wa ninu ile naa ki wọn ba le wa lai lewu. Awọn Ọmọ Israẹli ki ba ti le mọ wọn yatọ ni ode laaarin awọn ara ilu Jẹriko. Wọn ni lati wà lẹyin okun ododo ni.
Bẹẹ gẹgẹ ni a gbọdọ wà labẹ Ẹjẹ naa. Ọlọrun ki yoo kà wa si Ọmọ ti Rẹ mọ bi a ba pada sinu ẹṣẹ. Nigba ti a ba duro niwaju Onidajọ gbogbo aye, iṣẹ rere wa ki yoo ra ọna si Ọrun fun wa. Ẹjẹ Jesu, eyi ti o n wẹ wa mọ kuro ninu ẹṣẹ gbogbo, ni yoo jẹ ẹbẹ wa.
Ko si bi eniyan le jẹ Onigbagbọ rere to ni igba kan ri, bi o ba fi ibi aabo nì silẹ lẹyin okun owu ododo, yoo ri fun un bi ẹni pe ko tilẹ ti wa nibẹ nigba kan ri.
Ere Rahabu
Gbogbo awọn ara ilu Jẹriko ni o ti gbọ pe awọn Ọmọ Israẹli jẹ ayanfẹ eniyan Ọlọrun. Wọn ti n kiyesi irin wọn fun ogoji ọdun sẹyin, wọn tilẹ ranti awọn ajakalẹ-arun ti Ọlọrun rán si Egipti gẹgẹ bi idajọ lori awọn aninilara awọn Ọmọ Israẹli. Awọn olugbe ilu Jẹriko ni igbagbọ ninu agbara nla Ọlọrun, wọn bẹru, wọn si wariri. Ṣugbọn Rahabu, obirin kan ṣoṣo ni o wá oju rere Ọlọrun. Nitori o ṣe bẹẹ o gba ẹmi gbogbo awọn ara ile rẹ la nigba ti a pa ilu naa run.
A ka Rahabu pẹlu awọn akọni ninu igbagbọ ninu Heberu 11. O fẹ Ọmọ Israẹli kan o si di iya nla ni idile Dafidi Ọba, lati inu idile ọba ti a ti bi Jesu (Matteu 1:5).
A le ri i daju pe ki i ṣe gbogbo awọn ti o bẹru idajọ Ọlọrun ni a o gbala. Awọn ẹmi eṣu paapaa bẹru wọn si wariri, ṣugbọn ọrun apaadi ni yoo jẹ ipin wọn titi lae. Ẹbi Rahabu nikan, awọn ti o wa lẹyin okun owu ododo nì ni a gbala. Kiki awọn ti Ẹjẹ Jesu wẹ ẹṣẹ wọn nù ni yoo gbadun igbala ayeraye.
Questions
AWỌN IBEERE- Ṣe apejuwe Jẹriko?
- Ki ni ṣe ti awọn amí lọ si Jẹriko?
- Nibo ni wọn wọ si ni Jẹriko?
- Bawo ni Rahabu ṣe fi awọn amí pamọ?
- Bawo ni o ṣe mu wọn jade kuro ninu ilu naa?
- Ki ni àmì tootọ naa?
- Ki ni eyi duro fun tabi ti o n ṣe apẹẹrẹ rẹ?
- Ki ni Àmì Tootọ ti wa?
- Ki ni ere Rahabu nitori pe o bá awọn Ọmọ Israẹli dọrẹ?
- Ki ni yoo mu wa ri oju rere Ọlọrun ni ọjọ idajọ?