Joṣua 3:1-17; 4:1-24

Lesson 154 - Junior

Memory Verse
“Gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹẹli emi o wà pẹlu rẹ” (Joṣua 3:7).
Notes

Ni kutukutu Owurọ

Ọjọ ti awọn Ọmọ Israẹli ti n nọga fun dé wayii -- ọjọ ti wọn yoo wọ ilẹ Kenaani. Fun ogoji ọdun ni wọn ti n wo ọna fun akoko naa. A ti sọ ọpọlọpọ ohun iyanu ilẹ Kenaani fun wọn, ilẹ ti n ṣan fun wara ati fun oyin, nibi ti awọn ilu nla wa, ati ile ti a ti kọ silẹ, pẹlu kanga ati ọgbà ajara fun awọn Ọmọ Israẹli.

Ni ọjọ mẹta ṣaaju eyi (Joṣua 1:10, 11), awọn olori ti la ibudo ja lati sọ fun awọn eniyan lati pese ounjẹ silẹ, nitori ko ni pẹ ki wọn to la Odo Jọrdani kọja. Wọn ti ṣe imurasilẹ. Awọn amí meji ti lọ wo ilẹ naa (Joṣua 2:1), wọn si ti jiṣẹ fun Joṣua pe ẹru wa lọkan awọn ti n gbé ni Kenaani. Wọn wi fun Joṣua pe awọn eniyan naa ko ni igboya mọ nitori wọn ti gbọ ohun ti wọn ṣe si awọn ọba Amori.

Ṣaaju iku Mose, Ọlọrun ti yan Joṣua lati ṣe alakoso awọn Ọmọ Israẹli la Jọrdani kọja sinu Ilẹ Kenaani. Joṣua ti de Kenaani ni ogoji ọdun sẹyin lati ṣe amí ilẹ naa. O jẹ ọkan ninu ami meji ti wọn wi pe, “Ẹ jẹ ki a gòke lọ lẹẹkan, ki a si gbà a; nitoripe awa le ṣẹ ẹ” (Numeri 13:30). Ni akoko naa ẹru ti ba awọn Ọmọ Israẹli lati wọ inu ilẹ ileri naa nitori awọn ilu olodi ati awọn omiran. Fun ogoji ọdun wọn rin kiri ninu aginju nibi ti Ọlọrun ṣe ọpọ iṣẹ iyanu lati mu igbagbọ wọn le. Dajudaju oju ti n kán Joṣua lati la Jọrdani kọja. Joṣua ti wi fun wọn tẹlẹ pe Oluwa wa pẹlu wọn (Numeri 14:9); Ọlọrun ko ha si ti fi han awọn Ọmọ Israẹli bẹẹ? Oun ko ha ṣe ileri lati wa pẹlu Joṣua gẹgẹ bi Oun ti wa pẹlu Mose? O ni lati jẹ pe Joṣua gba otitọ ọrọ naa gbọ eyi ti Paulu kọ silẹ lẹyin naa, “Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa? (Romu 8:31).

Nigba ti ọjọ naa kù fẹẹfẹẹ, Joṣua dide ni kutukutu owurọ. Lai ṣe aniani o mọ iwuwo iṣẹ ti a pe oun si gẹgẹ bi aṣaaju, iṣẹ si wa lati ṣe lati le gbọran si gbogbo ọrọ Oluwa.

Itọni Fun Awọn Eniyan Naa

Lẹẹkan si i, a ran awọn oniṣẹ si awọn eniyan naa pẹlu aṣẹ Oluwa. A paṣẹ fun awọn eniyan naa lati ya ara wọn si mimọ ni imurasilẹ, nitori Oluwa yoo ṣe nnkan àrà laaarin wọn.

Awọsanma ko si lori wọn mọ lati maa tọ wọn ati lati maa daabo bo wọn. A paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati maa ṣọ Apoti Majẹmu ninu eyi ti walaa Ofin, ọpa Aarọni ti o rudi, ati ikoko wura ti o ni manna ninu gbé wà (Heberu 9:4). Awọn alufaa ni o ru Apoti-Ẹri naa. A sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe ki wọn wà ni nnkan bi aabọ ibusọ lẹyin Apoti-Ẹri naa; nipa bayii gbogbo wọn ni wọn le ri Apoti-Ẹri naa ti wọn si le mọ ibi ti wọn n lọ. Wọn ko ti i gba ọna naa ri ṣugbọn wọn ni lati tẹle Apoti-Ẹri naa lẹyin. Nigba ti awọn alufaa ti wọn ru u ba ṣi, nigba naa ni awọn Ọmọ Israẹli gbọdọ ṣi.

Awọn Onigbagbọ ti wọn n rin lọ si Kenaani ti Ọrun ni lati tẹ oju wọn mọ Amọna, ani Kristi. Wọn ko rin ọna naa ri; ṣugbọn nipa titẹle Oluwa nipa igbagbọ, wọn o gba ilẹ-ini wọn nipa ti ẹmi. Gẹgẹ bi Apoti-Ẹri ti awọn alufaa ru ti lọ siwaju lati lọ wá ibi isinmi fun awọn Ọmọ Israẹli, bẹẹ gẹgẹ ni Jesu ti lọ ṣaajú lati lọ pese ayẹ silẹ fun awọn eniyan Rẹ (Johannu 14:2).

Joṣua sọ fun awọn eniyan naa pe lila Jọrdani kọja yoo jẹ ami pe Ọlọrun wà pẹlu wọn, ati ẹjẹ pe awọn olugbe ilẹ naa ni Oluwa tikara Rẹ yoo le jade.

Awọn Alufaa

Ni ikẹyin, ohun gbogbo ti wa ni imurasilẹ. Lai ṣe aniani gbogbo oju ni o wà lara Apoti-Ẹri, ki o ma ba jẹ pe nigba ti o ba ṣi awọn eniyan a ṣe alai ri i. Anfaani iyanu ati ojuṣe awọn alufaa ni nipa gbigbe Apoti-Ẹri mimọ naa. Nikẹyin a paṣẹ wayii fun wọn lati ṣi, ṣugbọn omi odo naa wa ni aye rẹ sibẹ. O ti jẹ iran iyanu to nigba ti awọn alufaa ti wọn gbe Apoti-Ẹri tẹ siwaju ninu igbagbọ ati igbọran, ti awọn eniyan si bẹrẹ si tẹle wọn! Awọn alufaa naa de eti bebe omi naa - sibẹ ko si nnkan ti o ṣẹlẹ. Oluwa ko ha wi pe a o ke awọn omi Jọrdani kuro? A ke wọn kuro nigba ti ẹsẹ awọn alufaa naa kan omi. Omi naa bi sẹyin, ani ikun-omi ti igba ikore! “Awọn alufa ti o ru apoti majẹmu OLUWA, si duro ṣinṣin lori ilẹ gbigbẹ lãrin Jọrdani, gbogbo awọn enia Israẹli si kọja lori ilẹ gbigbẹ.”

Oluwa ké omi Jọrdani kuro. Nibi oke ti omi ti n ṣan wa, omi duro bi okiti kan, o fun awọn Ọmọ Israẹli ni anfaani lati gba ilẹ gbigbẹ kọja. Iṣẹ-ami nla ti Oluwa ṣe ti o tobi! Dajudaju O ṣe nnkan fun awọn Ọmọ Israẹli. Ki i ṣe bi omi naa ti maa n ṣe ni yii. Ko si àlàyé kankan a fi pe Ọlọrun ni O ṣe eyi fun wọn.

Gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ko ha le wi pe O ti ṣe iṣẹ-iyanu fun wọn bi? Boya a ti yiiri awọn kan wò ri lati mọ bi wọn ni igbagbọ ninu Ọlọrun, gẹgẹ bi awọn alufaa ti wọn tẹ siwaju bi o tilẹ jẹ pe ikun-omi wa niwaju wọn. Nigba ti wọn gbọran si Ọlọrun lẹnu, O yi awọn ohun idena naa kuro.

Awọn Ohun Iranti

Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli re Jọrdani kọja tan, awọn alufaa ti wọn n ru Apoti Majẹmu duro ni ipo wọn titi a fi sọ fun wọn pe ki wọn kuro nibẹ. Wọn ni lati ṣe ohun iranti si aarin odo naa. Àbá Joṣua kọ; Ọlọrun ni O paṣẹ pe ki wọn ṣe bẹẹ. Awọn kan le ṣe alai bikita lati ṣe gbogbo nnkan ti Ọlọrun pa laṣẹ -- ṣugbọn Joṣua ko jẹ ṣe bẹẹ. Awọn kan i ba sa asala fun ẹmi wọn pe boya omi naa le pada lẹyin ti awọn eniyan ti re kọja tan - ṣugbọn awọn alufaa Ọlọrun wọnyii ko ṣe bẹẹ. Ohun ti a sọ fun wọn ni wọn ṣe, wọn si kiyesara lati gbọran ni kikun si gbogbo aṣẹ Oluwa. Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan Rẹ ti isisiyii gbọran ni kikun pẹlu.

Joṣua fi okuta mejila ṣe iranti si aarin odo nibi ti awọn alufaa ti duro. Wọn gbe iranti miiran kalẹ ni Gilgali, ibudo wọn kin-in-ni ni iha iwọ-oorun Jọrdani.

A ti kọ yan ọkunrin mejila, ọkan lati inu ẹya kọọkan, lati ṣe iṣẹ iranti pataki kan fun Oluwa. Ọkọọkan ninu awọn ọkunrin mejila naa gbe okuta kan lati aarin odo Jọrdani le ejika rẹ wa si Gilgali. Nibẹ ni awọn okuta na wa lati maa ran wọn leti nipa agbara Ọlọrun nigba ti O mu ki odo Jọrdani gbẹ fun wọn lati kọja lori ilẹ gbigbẹ.

A si paṣẹ fun wọn lati kọ awọn ọmọ wọn nipa ohun iranti wọnyii. Ni ọjọ iwaju wọn n bọ wa beere pe, “Eredi okuta wọnyi?” Wọn o sọ fun awọn ọmọ naa pe awọn okuta naa jẹ ami pe Israẹli la Jọrdani kọja lori ilẹ gbigbẹ. Nipa bẹẹ iṣẹ-iyanu Ọlọrun yoo wa ni iranti titi aye.

Awọn Ọkunrin Ologun

Laaarin awọn Ọmọ Israẹli ni awọn ọkunrin ologun ti ẹya Reubẹni, Gadi, ati aabọ ẹya Manasse. Dipo ki wọn wọ inu ilẹ ileri fun ilẹ-ini wọn, awọn ẹya meji ati aabọ yii ti yàn lati jokoo si iha ila-oorun Jọrdani (Numeri 32:5). Wọn ti gba lati fi awọn ọkunrin ologun wọn ṣọwọ si odikeji Jọrdani pẹlu awọn Ọmọ Israẹli iyoku. Wo iru iriṣiriṣi erò, ayọ ati ibanujẹ ti o kun ọkan wọn ni ọjọ naa! Lai ṣe aniani inu awọn Ọmọ Israẹli dun lati wọ ilẹ ileri ti wọn ti n pongbẹ rẹ; sibẹ, ninu ọkan wọn ibanujẹ diẹ yoo wa pe lara awọn arakunrin wọn yoo duro sẹyin, nipa idanu ara wọn.

Lẹyin ti gbogbo eniyan naa ti yara wọ inu Kenaani, ti wọn si ti gbe awọn ami iranti kalẹ, Joṣua paṣẹ fun awọn alufaa ki wọn jade kuro ninu Jọrdani. Titi ohun gbogbo fi pari wọn duro ni ipo wọn, Ọlọrun si dá omi duro pẹ titi fun wọn. Nigba ti awọn alufaa goke si oke-odo naa, omi Jọrdani tun pada si aye rẹ.

Kenaani

Gilgali ni awọn Ọmọ Israẹli kọkọ tẹdo si. Wọn ti wọ ilẹ ileri naa ni akoko lati mura silẹ fun Ajọ Irekọja (Lefitiku 23:5), eyi ti wọn pamọ (Joṣua 5:10) ni iranti ọjọ ti Oluwa mu wọn jade kuro ni Egipti (Ẹksodu 12:6, 14, 17).

Awọn eniyan naa fi ọwọ fun Joṣua, wọn si bẹru rẹ gẹgẹ bi wọn ti bẹru Mose, nitori nipasẹ Joṣua ni Ọlọrun ti mu wọn wọ ilẹ Kenaani, ilẹ ti o n ṣàn fun wara ati fun oyin.

Ọlọrun mu awọn Ọmọ Israẹli la Odo Jọrdani kọja, odi nla nla ti a ti ọwọ Ọlọrun gbe kalẹ. Wọn ko ṣẹṣẹ ni lati ṣe afara tabi kan ọkọ oju-omi tabi ṣẹ adilu igi ti yoo fó loju omi ki wọn to le kọja. Ki i ṣe nipa iṣẹ ọwọ wa, bi ko ṣe nipa igbagbọ ninu agbara ati aanu Ọlọrun, ni a fi n wọ ilẹ ileri wa ti ẹmi lonii. “Ki iṣe nipa iṣẹ, ki ẹnikẹni má bã ṣogo” (Efesu 2:9). Gẹgẹ bi Ọlọrun ti mu awọn Ọmọ Israẹli la ikun-omi Jọrdani kọja, bẹẹ gẹgẹ ni Oun yoo mu awọn eniyan Rẹ ti oni wọ inu ilẹ-ini wọn ti ẹmi, ti i ṣe ilẹ rere.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni awọn Ọmọ Israẹli ṣe mura silẹ lati la Odo Jọrdani kọja?
  2. Ta ni ṣiwaju awọn ero ti wọn tò lọwọọwọ naa?
  3. Bawo ni awọn eniyan ṣe la odo naa kọja?
  4. Ṣe apejuwe bi odo naa ti ri ni akoko naa, eyi ti i ṣe igba ikore.
  5. Ki ni ṣe ti awọn alufaa duro si aarin odo naa?
  6. Ki ni wọn gbé?
  7. Ki ni àlàyé ti wọn ṣe nigba ti awọn ọmọ beere pe, “Eredi okuta wọnyi?”
  8. Nibo ni wọn ti ri awọn okuta naa?
  9. Nigba wo ni awọn alufaa kuro ni aarin Odo Jọrdani?
  10. Ta ni a ti yàn ṣe aṣiwaju awọn Ọmọ Israẹli?